Home Blog Page 44

Díhẹ̀ dìhẹ̀ díhẹ̀, gbèsè Nàìjíríà sún wọ tírílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ̀rún péré (N87tn)

Díhẹ̀ dìhẹ̀ díhẹ̀, gbèsè Nàìjíríà sún wọ tírílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ̀rún péré (N87tn)

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò tó nnkan,kò tó nnkan, ó mà ń dòòyì kọ́ní ńlẹ̀ yí.
Wọ́n ní ó ń bọ̀, ó ń bọ̀, lásìkò yìí gbogbo ara ni wọ́n-ọ́n mú tó o .
Ọ̀rọ̀ ti jọ pé ewu ń bẹ lóko Lóńgẹ́, gbèsè tí orílẹ-èdè Nàìjíríà jẹ ti di tírílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún láàrin oṣù mẹ́ta péré.

Ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè Nàìjíríà, DMO ṣàlàyé pé iye owó yìí ni gbèsè Nàìjíríà lẹ́yìn oṣù mẹ́fà nínú ọdún 2023 yìí.

Èyí túmọ̀ sí pé ìdá márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ni gbèsè náà fi lé síi lẹ́yìn tí gbèsè Nàìjíríà jẹ́ N49tn ní ìparí oṣù kẹta.

Iléeṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè Nàìjíríà ní owó yìí jẹ́ àpapọ̀ gbogbo gbèsè tí Nàìjíríà ń jẹ lábẹ́lẹ́ àti lágbàáyé, tó fi mọ́ gbèsè tí ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì àti Àbújá ń jẹ.

Iléeṣẹ́ náà ní àfikún tiriliọnu tírílíọ́nù méjìlélógún(N22.712tn) ni kókó owó tó gorí gbèsè ọ̀hún.

Ọkùnrin kan tó fẹ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kan náà sọ pé kò sí owú láàrin wọn

Ọkùnrin kan tó fẹ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kan náà sọ pé kò sí owú láàrin wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ohun tó bá wolówó ní-ín fowó rẹ̀ rà.N tó bá sì wu ọmọ ọ́n jẹ, kì í run ọmọ nínú ni ọ̀rọ̀ Ssaalongo Nsikonenne Habib Ssezzigu tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí gba orí ayélujára lẹ́yìn tó fẹ́ ìyàwó méje ní ọjọ́ kan náà.

Lára obìnrin méje ní a ti rí ẹ̀gbọ́n àti àbúrò, tí ìgbéyàwó ọ̀hún sì wáyé ní Abule Bugerek lórílẹ̀ èdè Uganda lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹsàn án ọdún 2023.

Orúkọ àwọn ìyàwó náà ni Mariam, Madinah, Aisha, Zainabu, Fatuma, Rashida àti Musanyusa, tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ tó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ fún ọdún méje.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó wà lórí ayélujára, sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ Caleb Canaan ní ayẹyẹ ìgbéyàwó bẹ̀rẹ̀ ní ago mẹ́jọ àárọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gbé àwọn ìyàwó náà lọ ilé oní dìrí.

“Lẹ́yìn tí ọkọ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ ṣe ìbúra, Nsikonenne àti àwọn ìyàwó rẹ̀ méje gun kẹ̀ẹ̀kẹ̀ káàkiri abúlé bí Kalagi, Kasana àti Nakifuma kí wọ́n tó lọ ilé wọn ní ago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ .”

Nsikonenne ra ọkọ̀ bọ̀gìnì tuntun fún àwọn ìyàwó náà, tó sì rọ àwọn ìyàwó náà láti fẹ́ ẹ pẹ̀lú òtítọ́ inú.

“Kò sí owú láàrin àwọn ìyàwó mi. Mo mọ wọ́n ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí mò ṣì pinnu láti fẹ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú wọn ní ẹ̀kanáà láti ní ìdílé aláyọ̀.”

Nsikonenne ní òun yóò tún fẹ́ ìyàwó sí i lọ́jọ́ iwájú

“Ọmọdé sì ni mí àti pé lọ́jọ́ iwájú, tí Ọlọ́run bá fẹ́ máa fẹ́ ìyàwó sí i .”

Bàbá ọkọ, Hajj Abdul Ssemakula ní fífẹ́ ìyàwó púpọ̀ ló jẹ́ nǹkan tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ mọ̀lẹ́bi wọn.

“Bàbá tó bí bàbá mi fẹ́ mẹ́fa, Bàbá mi fẹ́ márùn un, èmi gan fẹ́ fẹ́ mẹ́rin tí a jọ ń gbé ilé kan náà.”

Habib ló ti wá fi ìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tó fẹ́ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kanáà lórílẹ̀ èdè Uganda.

Saidi Balogun wà lórí ‘Wheelchair’ ,ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣàdúrà fun un. 

Saidi Balogun wà lórí ‘Wheelchair’ ,ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣàdúrà fun un.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Láìpẹ́ yìí ni àwòrán kan gbà orí ayélujára kan, èyí tó ṣe àfihàn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Saidi Balogun, tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ onírin tó wà fún àwọn èèyàn tí ẹṣẹ̀ ń dùn.

Àwòrán yìí sí lọ da ọkàn àwọn èèyàn tó wòó láàmú, pàápàá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ wọn sì lọ ń fi ìtara pèé lórí fóònù tàbí fi àtẹ̀jísẹ́ ránṣẹ́ sì, bí wọ́n ṣe ń béèrè pé kí ló fàá, tí Saidi Balogun ṣe di èrò orí kẹ̀kẹ̀ onírin, náà ni wọ́n ń gbàdúrà fún pé Ọlọ́run yóò fún ní àlàáfíà.

Èrò ọ̀pọ̀ wọn ní pé ìjànbá kan ló wáyé, tí gbajúmọ̀ òṣèré náà kò ṣe leè rìn bó se yẹ, tó sì ń fi kẹ̀kẹ́ onírin ṣe ẹsẹ̀ rìn.

Èyí ló mú kí Saidi Balogun ṣe tètè ṣàlàyé fáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ náà, ìdí tó ṣe ń ló kẹ̀kẹ̀ onírin láti rìn.

Saidi Balogun, nínú fídíò tó gbé sójú òpó Sítágíráàmù rẹ̀ ṣàlàyé pé kò sí ìjàmbá kankan tó ṣe òun, ko ko ko sì ni ara òun le.

Ó ní ère sinimá ni àwọn n ya lọ́wọ́ lásìkò tí òun jókòó sínú kẹ̀kẹ̀ onírin ọ̀hún ní ìbámu pẹ̀lú ipa tí òun kò nínú sinimá àgbéléwò náà.

Kódà, ṣe ni Saidi ń fò sókè, tó sì na apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fi dá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lójú pé sáká ni ara òun dá

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà náà wá ń kilọ fáwọn èèyàn tó ń gbé ayédèrú ìròyìn kiri lórí ayélujára pé kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọn sì dẹ́kun ìwà aláìdára yìí.

Bákan náà lọ wà fi ẹ̀mí ìmoore rẹ̀ hàn sáwọn olólùfẹ́, ẹbí, ara, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ tó kàn sí lásìkò tí wọn rí àwòrán náà, tí wọ́n sì ń gbàdúrà fún.

Tẹkún,tìbànújẹ́ ni Mohbad fi wọ káà ilẹ̀ sùn

Tẹkún,tìbànújẹ́ ni Mohbad fi wọ káà ilẹ̀ sùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìbànújẹ́ ńlá ni kí màjèsín ó tojú òbí rọ̀run.
Pẹ̀lú omijé ni àgbààgbà àti àwọn ọ̀dọ́ tó péjú síbi ètò ìsìnkú Mohbad fi ṣe ìdárò lẹ́yìn tó wọ káà ilẹ̀ lọ nílùú Ikorodu.

Mohbad, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló jáde láyé lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kẹsàn án.

Ọ̀pọ̀ èrò ló péjú síbi ètò ìsìnkún olórin tàkasúfèé yìí, tí wọ́n sì ń kọrin ìbànújẹ kíkankíkan ní ilé ìtẹ́ òkú sí nílùú Ìkòròdú.

Bákan náà ọ̀pọ̀ èèyàn ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n ṣe sin òkú Mohbad láì ṣe àyẹ̀wó láti mọ irúfẹ́ nǹkan tó ṣekúpa.

Ṣaáajú ni iléeṣẹ́ ìròyìn kan, Pulse NG ní àrùn etí ló ṣekúpa Mohbad.

Gẹ́gẹ́ bíi Pulse NG ṣe ṣàlàyé, Mohbad, gbéra lọ ilé ìwòsàn lọ́jọ́ Ìṣẹgun tó sì jáde láyé lẹ́yìn tó gba abẹ́rẹ́ ní ilé wòsàn náà.

Kò tíì sí àrídìmú láti fìdí ikú rẹ̀ múlẹ̀ ohun pàtó tó ṣekúpa Mohbad.
Olóògbé fi ìyàwó àti ọmọ sílẹ̀ láyé.

Ẹ kú ojúlọ́nà ! UAE gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría

Ẹ kú ojúlọ́nà ! UAE gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orílẹ̀-èdè United Arab Emirates(UAE) ti gbẹ́sẹ̀ kúrò l’órí òfin tó fi de ìwé ìrìnnà ọmọ Nàìjíríà sí orílẹ̀èdè ọ̀hún.

Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú Ààrẹ UAE, Sheikh Mohamed bin Zayed Al Nahyan nílùú Abu Dhabi ti í ṣe olú ìlú orílẹ-èdè ọ̀hún.

Ó ti pé oṣù mẹwàá báyìí tí ìjọba UAE ti fòfin dé àwọn arìnrìnàjò láti Nàìjíríà eléyìí tó sì ti ṣàkóbá fún ìdókòwò ọ̀pọ̀ èèyàn.

Nínú atẹjade tí olùdámọ̀rán Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ajuri Ngalale fisíta, ó ṣàlàyé pé ìpàdé Tinubu pẹ̀lú àwọn aláṣẹ UAE so èso rere.

Ngelale sọ nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún pé Ààrẹ Mohamed bin Zayed Al Nahyan fẹnu kò pẹ̀lú Tinubu lórí àwọn kókó kan tí yóò mú ìlọsíwájú bá ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Agbẹnusọ Ààrẹ ní ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Etihad àti ti Emirates tí wọ́n ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró tẹ́lẹ̀ ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.

“Pẹ̀lú ìwé àdéhùn tí Tinubu àti Aarẹ UAE buwọ́lù yìí, ọpọ ìdókòwò ẹlẹ́gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù owó dọ́là ni yóò tibẹ̀ jáde ní Nàìjíríà.

Ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ológun, ètò àt’àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìjọba míì náà yóò jẹ́ ànfààní àdéhùn tuntun láàrin Nàìjíríà àti UAE,” Ngelale ṣàlàyé.

Bákan náà ni Tinubu tún buwọ́lu ìwé àdéhùn pẹ̀lú ìjọba UAE lórí ètò pàsípààrọ̀ owó ti orílẹ-èdè méjèèjì yóò máa kéde rẹ̀ láìpẹ́ .

Lákòótán, Tinubu gbóṣùbà fún Ààrẹ Al Nahyan fún ìpinu rẹ̀ láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà fún ànfàní orilẹede méjèèjì.

Lọ́dún tó kọjá ni ìjọba ilẹ̀ Dubai fòfin de àwọn ọmọ Nàìjíríà láti má lè ṣàbẹ̀wò sílẹ̀ náà mọ́.

Nínú àtẹ̀jáde tí Dubai fi léde, wọn kò sọ èrèdí pàtó tí wọn ṣe gbé ìgbésẹ̀ náà, wọ́n kàn sọ pé kò sí ààyè fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wá sílẹ̀ Dubai mọ́ ni.

Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí wọ́n kọ́nọ́ kéde àwọn òfin tuntun kan nípa ìwé ìrìnnà ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Lásìkò náà ni wọ́n sọ pé àwọn kò ní fún ọmọ Nàìjíríà tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá kéré ju ogójì ọdún lọ ní físà, pàápàá àwọn tó ń lọ láti gbafẹ́e .

Ó ti lé ní ọdún kan àbọ̀ tí Nàìjíríà àti Dubai ti ń forí gbárí lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan.

Nínú oṣù Kẹjọ ọdún tó kọjá, ẹnìkan lójú òpó abẹ́yẹfò rẹ̀ ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ti àwọn ọmọ Nàìjíríà kan mọ́ inú yàrá ní pápákọ̀ òfurufú Dubai.

Ẹni náà ní wọn kò ṣe dáadáa sí àwọn ọmọ Nàìjíríà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé wọn pé pérépéré.

Àmọ́ ìjọba Nàìjíríà, láti ẹnu adarí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà nílẹ̀ òkèèrè, Abike Dabiri-Erewa sọ pé níṣe ni àwọn ọmọ Nàìjíríà náà kò tẹ̀lé òfin tó rọ̀ mọ́ físà ọwọ́ wọn.

Ó ní “ Àwọn èèyàn náà gba físà tó yẹ kí wọ́n fi rìnrìn àjò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àmọ́ lọ láì mú ẹbí wọn kankan dání .”

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀dá ọlẹ̀ ọmọ láì lo àtọ̀ àti ẹyin

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀dá ọlẹ̀ ọmọ láì lo àtọ̀ àti ẹyin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ohun kàyééfì gbáà ló jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣẹ̀dàá ọlẹ̀ ọmọ láì àtọ̀ ọmọkùnrin àti ẹyin ọmọbìnrin tàbí ilé ọmọ.

Àwọn onímọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Weizmann ní àwọn ṣẹ̀dàá ọlẹ̀ ọmọ láti ara àwọn sẹ́ẹ̀lì inú igi, tó sì jọ ọlẹ̀ ọmọ ọjọ́ mẹ́rìnlá.

Wọ́n ṣàlàyé àwọn èròjà tí wọ́n lò tó jẹ́ kí àyẹ̀wò rẹ̀ ṣàfihàn oyún nígbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò náà.

Àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ tí ìgbésẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ rí àyípadà gbòógì kan – bí wọ́n ṣe gba àwọn sẹ́ẹ̀lì náà jọ, tó fi yí padà sí ọmọ tó wà nínú oyún.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Jacob Hanna ti ilé ẹ̀kọ́ Weizmann Institute of Science ní ìgbà tí àyípadà yìí máa ń wáyé ń fa onírúurú àyípadà lára, ìmọ̀ kò sì tíì pọ̀ tó nípa rẹ̀.

Ìwádìí lórí ṣíṣẹ̀dá ọlẹ̀ ọmọ wáyé látara wíwà àlékún ìmọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣẹ̀dàá nǹkan látara àwọn nǹkan tí wọn kò lérò.

Ìdàgbàsókè ti ń débá ẹ̀ka tó ń rí sí ẹ̀kọ́ nípa oyún.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Isreal júwe ìwádìí tí wọ́n gbé jáde gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tó ń ṣàfihàn bí ọlẹ̀ ọmọ ṣe ń dàgbà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Hanna ní àpẹẹrẹ bí ọlẹ̀ ọmọ ènìyàn tó ti dàgbà fún ọjọ́ mẹ́rìnlá ṣe rí ni ìwádìí náà èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí.

Dípò lílo àtọ̀ àti ẹyin gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì láti ara igi ni wọ́n lò, tí wọ́n ṣe àtúnṣe rẹ̀ láti lè di onírúurú ẹ̀yà ara.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa lo àwọn kẹ́míkà kan láti fi mú àyípadà bá àwọn gíìnì rẹ̀ láti sọ́ di gíìnì mẹ́rin tó máa ń wà lára ìbẹ̀rẹ̀ oyún.

Àpapọ̀ sẹ́ẹ̀lì ọgọ́fà ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pò papọ̀ di ẹyọ̀kan tí wọn yóò sì fi ara balẹ̀ fún un.

Ìdá kan nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì tí wọ́n pò papọ̀ yìí ni yóò yí padà láti fi ara jọ ọlẹ̀ ọmọ ènìyàn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Hanna ní tí òdiwọ̀n àwọn sẹ́ẹ̀lì náà bá lọ déédé ní àyíká tó tọ́ yóò kàn bẹ̀rẹ̀ àyípadà náà fúnra rẹ̀.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa fi kalẹ̀ láti máa dàgbà láti jọ ọlẹ̀ ọmọ ènìyàn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnlá tí wọ́n ṣe ìdàpọ̀ rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé “trophoblast” tí ó máa ń di ibi ọmọ àti ẹ̀yà tó máa ń gbé oúnjẹ láti inú ìyá sí ọmọ tí wọ́n ń pè ní “lacuna” ló wà lára rẹ̀.

Bákan náà ni àpò kan tó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín tó ń mú ọlẹ̀ ọmọ dàgbà ló wà lára rẹ̀.

Ìrètí tó wà nibẹ̀ ni pé àwọn ìwádìí báyìí máa ń rán àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́wọ́ láti ṣàlàyé bí sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ṣe ń jáde lára, rí bí ẹ̀yà ara ènìyàn ṣe ń dìde láti inú oyún.

Bákan náà ló máa ṣe àfihàn bí àwọn àìsàn kan tàbí òmíràn ṣe máa ń tọ ìran.

Ìwádìí yìí fi hàn pé ẹ̀yà ara ọlẹ̀ ọmọ kò ní dàgbà àyàfi tí ibi rẹ̀ bá ti kọ́kọ́ yí i ká.

Ó tún jẹ́ ọ̀nà láti mú ìlọsíwájú bá ìlànà oyún níní IVF nítorí ìmọ̀ yóò wà lórí àwọn nǹkan tó máa ń fa kí àwọn ọlẹ̀ ọmọ kan dúró tí àwọn mìíràn sì ń wálẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ ọ̀nà láti mọ̀ bóyá lílo oògùn nínú oyún jẹ́ ohun tó dára.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Robin Lovell Badge tó jẹ́ ẹni tó máa ń ṣe ìwádìí nípa ọlẹ̀ ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́ Francis Crick Institute ní àwọn ìwádìí báyìí dára tí wọ́n sì máa ń dára lójú.

Ó ṣàlàyé pé ìtẹ̀síwájú gbọ́dọ̀ wà lórí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwádìí yìí kì í ṣe kẹ́sẹ járí.

Ó fi kun pé ó máa ṣòro láti mọ ohun tó máa ń jẹ́ kí oyún bàjẹ́ lára ènìyàn tàbí fà àìrí ọmọ bí, tí àwọn ìwádìí yìí kò bá máa ní àṣeyọrí.

Ìhà òfin sí ìwádìí yìí
Iṣẹ́ ìwádìí yìí ti ń fa ìbéèrè pé ṣé ó ṣeéṣe láti ṣe ìwádìí ọlẹ̀ ọmọ kọjá ọjọ́ mẹ́rìnlá.

Èyí kìí ṣe ohun tó lòdì sí òfin nítorí àwọn tí wọ́n ń lò láti fi ṣe ìwádìí yàtọ̀ sí ti ọlẹ̀ ọmọ gangan.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Lovell-Badge ní àwọn kan máa gba ìgbésẹ̀ náà wọlé tí àwọn mìíràn kò sì ní fi ara mọ.

Ó ní bí àwọn ọlẹ̀ ọmọ yìí bá sì ti ń jọ ti ènìyàn sí ni ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìbéèrè yóò máa tí ara rẹ̀ jáde.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Alfonso Martinez Arias ti ẹ̀ka imọ̀ Health Science ní ilé ẹ̀kọ́ Pompeu Fabra University ní ìwádìí náà ṣe pàtàkì púpọ̀.

Ó ní iṣẹ́ ìwádìí náà, fún ìgbà àkọ́kọ́ ṣàfihàn bí ọlẹ̀ ọmọ ṣe ń wáyé, ní èyí tí yóò mú ìwádìí nípa bí ẹ̀yà ara ṣe ń jáde lára wáyé láìpẹ́.

Bó ṣe ń jó, ló ń ṣiṣẹ́ gidi l’Ọ́sun—-Obasanjo

Bó ṣe ń jó, ló ń ṣiṣẹ́ gidi l’Ọ́sun—-Obasanjo
,
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Nàìjíríà, Olóyè Olusegun Obasanjo ti ṣe káre sí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Ademola Adeleke.

Obasanjo ní bí Adeleke ṣe ń jó fún Ọlọ́run, náà ló ń gbé àkànṣe isẹ́ ṣe ní ìpínlẹ̀ Osun.

Obasanjo gbósùbà bẹ́ẹ̀ fún Adeleke níbi ìsìn ìkórè kẹrìndínlógún ìjọ Love of Christ ti Wòlíì Esther Ajayi tó wà lágbègbè Victoria Island nilu Eko.

Lásìkò to ń sọ̀rọ̀ níbi ìsìn náà, Obasanjo yọ suti ètè sáwọn èèyàn tó ń fapa janu nípa bí Adeleke ṣe máa ń jó ijó àjókara.

Obasanjo wá yonbo Adeleke lórí bo ṣe ń jó náà, ó ní Ọlọ́run ló ń jó fún.

Obasanjo pé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi tó òun létí, ijó jíjó yìí kò dá àṣeyọrí Adeleke dúró torí ó ń ṣiṣẹ́ takuntakun bíi gómìnà ni ìpínlẹ̀ Osun.

Adeleke náà sì dìde lásìkò tí Obasanjo ń sọ̀rọ̀ yìí láti ṣe àpọ́nle ààrẹ àná náà.

“Jíjó ijó fún Ọlọ́run jẹ́ ohun ìwúrí, pẹ̀lú pé ó tún fi iṣẹ rere kun.

Ìròyìn to ń kàn mí láti sun jẹ àwọn ìròyìn ìdàgbàsókè tó ń wáyé nibẹ.

Ọlọ́run tó ń jó fún náà yóò da ìbùkún rẹ̀ lé ọ lórí àti ìjọba rẹ.

Bákan náà ni mo tún gbọ́ pé o jẹ gómìnà tó máa ń tẹ́tí sí aráàlú, wọ́n ní ó máa ń gba ìmọ̀ràn tọmọdé-tàgbà.

Inú mi dùn láti gbọ́ nípa èyí, mo sì ń ké sí Ọọ̀ni ilé Ife àtàwọn oríadé míràn níìpínlẹ̀ ọ̀sun láti ṣe àtìlẹ́yìn fún gómìnà Ademola Adeleke.

Èyí ni yóò jẹ ki ìṣẹ́ rere tó ń ṣe túbọ̀ tẹ̀síwájú.

Mo sì ń rọ gómìnà Adeleke náà láti ṣíṣẹ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọba alayé, àwọn àgbààgbà àtàwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun jẹ lógún.”

Nígbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ Obasanjo, Gómìnà Adeleke ni òun máa ń jó láti mọ rírí Ọlọ́run tó dá ayé àti ọ̀run, ojú kìí si ti òun láti jó fún.

” Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì lọ́kùnrin lóbìnrin ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé máa di Gómìnà l’ọ́sun, èyí tó ti wá sí ìmúṣẹ báyìí.

Májẹ̀mú tí mo bá Ọlọ́run dá ní pe máa padà wa dúpẹ́, kí ń sì yín lógo gẹ́gẹ́ bí mo ti ń ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìjọsìn.”

Adeleke wá mẹ́nuba ọ̀pọ̀ àṣeyọrí rẹ̀ láti ìgbà tó ti gorí àga gómìnà níìpínlẹ̀
náà.

Guinness World Record, Ìdílé ọjọ́ ìbí kan náà gba àmì ẹ̀yẹ

Guinness World Record,
Ìdílé ọjọ́ ìbí kan náà gba àmì ẹ̀yẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá
Bóṣe wu olúwa ló ń ṣọlá Rẹ̀ fẹ́ni tó bá wù Ú,ó wá kèèyàn tí yóó bi Í léèrè.
Àwọn ètò kan wà tí ìfarajọ rẹ̀ kò wọ́pọ̀,lára irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kí ènìyàn nínú ẹbí kan náà sùpọ̀ ní ọjọ́ ìbí kan náà pẹ̀lú ara wọn tí èyí kìí sì sábà wáyé lọ́pọ̀ ìgbà.

Ṣùgbọ́n fún ẹbí Mangi ní Larkana, orílẹ̀ èdè Pakistan, nǹkan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá ni àwọn ìdílé yìí ní papọ̀.

Àwọn mẹ́sàn-án ló wà nínú ẹbí yìí, bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ wọn méje èyí tí ìbejì méjì wà nínú wọn.

Ọjọ́ ìbí kan náà ni àwọn ẹbí yìí ní papọ̀. Ọjọ́ kìíní oṣù Kẹjọ ọdún ni ọjọ́ ìbí gbogbo wọn kódà ọjọ́ yìí gan ni bàbá àti ìyá yìí ṣe ìgbéyàwó.

Ní ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ ọdún 1991 tó jẹ́ ìbí wọn ni Ameer àti Khudeja ṣe ìgbéyàwó tí wọ́n sì bí àkọ́bí ọmọ wọn lọ́jọ́ yìí kan náà lẹ́yìn ọdún kan.

Àwọn ọmọ méje tí Ameer àti Khudeja bí ló jẹ́ pé ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ ni wọ́n bí gbogbo wọn.

Èyí ló jẹ́ kí orúkọ wọn ìwé àkọ́ọ́lẹ̀ àgbáyé nítorí kò ì tíì sí ìdílé mìíràn tí wọ́n ní irú àkọ́ọ́lẹ̀ yìí.

Ìdílé kan ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ẹbí Cummins ni wọ́n ti kọ́kọ́ ní àkọ́ọ́lẹ̀ náà pẹ̀lú tó ṣe ogúnjọ́ oṣù kejì ni wọ́n bí gbogbo wọn nínú ìdílé wọn tó jẹ́ ti ènìyàn ẹlẹ́ni márùn-ún.

Ameer ní inú òun dùn tó sì ya òun lẹ́nu nígbà tí àwọn bí àkọ́bí ọmọ àwọn ní ọjọ́ ìbí òun àti ìyàwó òun.

Ó ní ìyàlẹ́nu ló tún jẹ́ fún àwọn nígbà tí àwọn tún ń bí àwọn ọmọ yòókù ní ọjọ́ kan náà àti pé àwọn ri gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn ọmọ náà ni àwọn bí láti ìdí gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ àti pé àwọn kò lo iṣẹ́ abẹ láti fi bí ọmọ kankan rí.

Bákan náà ló ní àwọn dókítà kò lo abẹ́rẹ́ tàbí oògùn láti fi lè jẹ́ kí àwọn ọmọ náà tètè wá rí.

“Ẹ̀bùn ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kìí ṣe wí pé a gbèrò láti bí àwọn ọmọ wa sí ọjọ́ kan náà.”

Ó fi kun pé bíbí ìbejì ní ẹ̀ẹ̀mejì jẹ́ ohun tí kìí sábà wáyé lọ́dọ̀ àwọn tó sì ya àwọn lẹ́nu nígbà tí àwọn bí ìbejì ọkùnrin méjì ní ọdún 2003 tí àwọn sì tún bí obìnrin méjì ní ọdún 2008 ní ọjọ́ ìbí kan náà.

Ní ìdílé Mangi, ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ máa ń jẹ́ fún wọn.

Àkàrà òyìnbó kan ṣoṣo ni wọ́n máa ń lò láti fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí wọn dípò rírà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ameer àti Khudeja ní inú àwọn máa ń dùn pé àwọn àtàwọn ọmọ wọn ń ṣe ọjọ́ ìbí lọ́jọ́ kan náà àti pé ó máa ń dùn mọ́ àwọn ọmọ àwọn nínú.

Ameer ní nígbà tí wọ́n fún àwọn ní ìwé ẹ̀rí fún àkọ́ọ́lẹ̀ orúkọ àwọn nínú ìwé àgbáyé, ó ní òun rò ó pé Ọlọ́run ló fún òun láti fún ní gbogbo ògo.

Kabir Olaoye pe Ghandi Olaoye lẹ́jọ́ , fúnpò Sọ̀ún tuntun

Kabir Olaoye pe Ghandi Olaoye lẹ́jọ́ , fúnpò Sọ̀ún tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó n súnmọ́ òótọ́ bọ̀ báyìí o, ọ̀rọ̀ àwọn àgbà tó ní, ìdààmú ilé ọlá kìí rọ̀,ko ko ko ní-ín le.
Lẹ́yìn tí gómìnà Seyi Makinde ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti buwọ́lu ìyànsípò Ọmọba Afolabi Ghandi Olaoye gẹ́gẹ́ bíi Soun Ogbomoso tuntun, ilé ẹjọ́ gíga kan níìpínlẹ̀ ọ̀hún ti pàṣẹ pé Makinde kò gbọdọ̀ gbé ọ̀pa àṣẹ fún Ghandi gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ilé ẹjọ́ náà pàṣẹ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, agbẹjọro àgbà àti kọmiṣọnna ìjọba ìbílẹ̀ àti oye jíjẹ pé kí wọn semẹdọ ná títí tí ìdájọ́ ẹjọ́ tó wà nílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ oyè yóó fi wáyé.

Ọjọ́bọ ni adájọ́ K.A. Adedokun pàṣẹ yìí nígbà tí ó ń dajọ tí ọ̀kan lára àwọn tó ń du oyè Soun Ogbomoso, Ọmọba Kabir Olaoye gbé wá sílé ẹjọ́.

Adájọ́ Adedokun ní ẹjọ́ tí ó pè lẹsẹ ńlẹ̀ Ọmọba Kabir Olaoye
Bákan náà ni adájọ́ tún pàṣẹ pé Ghandi gan an kò gbọdọ̀ rí ara rẹ̀ gẹgẹ bí Sòún tuntun, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ lọ sí ibi ayẹyẹ kankan láti gba ọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba títí ìdájọ́ yóó fi wáyé lórí ẹjọ́ tó wà n ńlẹ̀.

Adájọ́ Adedokun ní lẹyìn tí òun ṣe àgbéyẹ̀wò àwíjàre Abiodun Ogunjimi tó jẹ́ agbẹjọ́rọ̀ Ọmọba Kabir, òun rí pé ẹjọ́ tí oníbàárà rẹ̀ pé lẹ́ṣẹ̀ ńlẹ̀.

Ilé ẹjọ́ ti wá sún ìgbẹ́jọ síwájú sí ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹsàn án ọdún yìí.

Àwọn mìíràn tí ẹjọ́ náà kàn ní àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oyè lápá àríwá ìlú Ogbomoso, Ọmọba Amos Olaoye, Mọ́gàjí ẹbí Ọláoyè, Olóyè S.O. Otolorin, Areago ìlú Ogbomoso tí ó tún jẹ́ Alága àwọn afọbajẹ, Olóyè Tijani Abioye, Baara ìlú Ogbomoso, Olóyè David Adeniran, Ikolaba ilẹ̀ Ogbomoso àti Olóyè Yusuf Rasaki Oladipupo, Abese ilẹ̀ Ogbomoso.

Lópin ọ̀sẹ̀ tó lọ ni Gómìnà Makinde kéde pé òun ti buwọ́lu ìyànsípò Ọmọba Ghandi gẹ́gẹ́ bíi Sòún tuntun ìlú Ogbomoso

Géndé tó jí ìrẹsì lápòlápò dèrò ẹ̀wọ̀n

Géndé tó jí ìrẹsì lápòlápò dèrò ẹ̀wọ̀n

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ojú kókòrò òhun olè ọ̀kannkanhùn, ló mú kí wọ́n wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Wale Sunday, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ iwájú adájọ ilé-ẹjọ́ Májísíréètì kan tó wà nílùú Badagry, ní ìpínlẹ̀ Èkó, Onídàájọ Fadahunsi Adefioye.

Ẹ̀sùn pé ó jí àpò irẹsi mẹta towó rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún Náírà (N99, 000) tó sì lọ tà á lówó pọọku fún oníbàárà rẹ̀ kan ni wọ́n fi kàn án.

Ọlọ́pàá olùpẹ̀jọ́, A.S.P Clement Okuoimose, tó fojú Sunday balé-ẹjọ́ sọ ní nǹkan bíi aago kan ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹsàn-án, ọdún yìí, ní Sunday ji apo irẹsi méta ọ̀hún níwájú ààfin Agahmathen, lágbègbè Ajara-Agahamathen, nílùú Badagry, nipinlẹ Èkó.

Ẹsùn méjì ọtọọtọ ni agbè fọba fi kan Sunday, ẹsùn àkọ́kó ni pé ó jí àpò irẹsi méta kan tí kì í ṣe ti rẹ̀ . Èkejì ni pé ó jalè láàrin ìlú. Gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí pátá ni olẹ̀pẹ̀jọ́ ní òfin ìlú Èkó kò fààyè gbà rárá.

Ó ní, ‘Iwọ Ọ̀gbẹ́ni Sunday, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ jí àpò ìrẹsì méta kan tó jẹ́ ti Ọ̀gbẹ́ni Usman Hammed. Inú mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Avalon ni oníṣòwò ìrẹsì ọ̀hún kó gbogbo ọjà rẹ̀ sí .’

Lẹ́yìn tí wọ́n ka gbogbo ẹsùn ọ̀hún sí i lẹ́sẹ̀ tán ni Sunday lóun gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan òun pátá.

Láì fàkókò ṣòfò rárá, Adájọ́ Adefioye ní kí wọ́n lọ ju Sunday sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Awhajigoh, tó wà nílùú Badagry. Ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí.