Home Blog Page 43

Òsèré tíátà, Osuofia, sò̩rò̩ lórí ikú o̩mo̩bìnrin re̩

Òsèré tíátà, Osuofia, sò̩rò̩ lórí ikú o̩mo̩bìnrin re̩

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi osere tiata, Nkem Owoh ti a mo si Osuofia, ti soro lori iku omobinrin re keji, Kosisochukwu.

Eni odun merinlelogun naa di oloogbe leyin aisan ranpe ni ojo kejidinlogbon osu keje, 2023, ti won si te si isinmi ni Ojobo, ojo kerinlelogun osu kejo, si abule Amagu, Udi, ipinle Enugu.

Nigba to n soro lori isele laabi naa, Osuofia fi imoore re han fun gbogbo ife ati atileyin ti idile re gba ni akoko ti won n kedun naa.

O sapejuwe iku omo re owon o
naa bii ipadanu ti oun ko lero re rara.

“Mo fe dupe lowo gbogbo yin fun atileyin ati ife ti e fi han emi ati ebi mi. Nigba ti isele ibanuje yii waye, ko si ohun to bani ninu je bii pe ki o mo pe iwo nikan lo wa.

“Pelu imoore atinuwa ni mo fi gba iwe yin, ipe ibanikedun. A ti ri opolopo ayipada leyin odun die seyin. Sugbon ayipada yi ni mi o lero, mo si ni imolara ipadanu nla.

“Amo sa, mo mo pe nitori igbani niyanju yin, maa la akoko yi koja. E se fun iranlowo ti e se fun mi lati la ibanuje mi koja,” o ko o si oju opo Instagram ni ojo Aje.

Kò sí ohun tó dàbíi pípadà sí e̩se̩ àárò’ – AY lórí iná tó sé̩yo̩ ní ilé re̩

Kò sí ohun tó dàbíi pípadà sí e̩se̩ àárò’ – AY lórí iná tó sé̩yo̩ ní ilé re̩

Mary Fágbohùn

Gbajumo aderinposonu Naijiria, Ayodeji Makun, ti a mo kaakiri si AY, ti safihan pe ohun to ku ti oun ni pelu oun ni awon nnkan ti oun mu lo si irinajo saaju ijamba ina to sele ni ile oun.

E ranti pe aderinposonu naa ni ina jo ile re to wa ni Eko bale ni ibere osu yii.

Nigba to n saroye nipa isoro re naa lori X, ti a mo teleri si Twitter, AY safihan bi o se ri lara oun lati padanu gbogbo awon nnkan to se iyebiye fun oun.

Nigba to fi fonran ninu eyi ti a ti ri ile naa to wa labe atunse lede, o wi pe: “O dabi eemo lati ri pe awon bata, eso ara ati aso ti mo ni bayii ni eyi to wa pelu mi nigba ti mo rin irinajo.

“Ko si ohun to dabii pipada si ese aaro.”

Mò ń bá ohun ò̩gbìn àti igi sò̩rò̩ – Olorin, Joeboy

Mò ń bá ohun ò̩gbìn àti igi sò̩rò̩ – Olorin, Joeboy

Mary Fagbohun

Olorin Naijiria, Joseph Akinfenwa Donus, ti a mo si Joeboy, ti safihan pe oun n ba ohun ogbin soro.

Olorin ‘Baby’ naa so di mimo pe oun ni ohun ogbin merin si inu yara oun ti oun maa n ba soro.

Nigba to farahan lori eto Zero Conditions laipe yi bii alejo, Joeboy so pe jije eni emi “se pataki.”

O wi pe, “O nilo atileyin ti emi. O se pataki. Ti o ba je eni ti kii se oogun, o nilo lati gbadura.”

Lori idi to fi da ona igi si ara, Joeboy so pe oun feran iseda.

O wi pe, “Fun mi, mo feran iseda. Mo feran ohun ogbin. Mo ni ohun ogbin merin si inu yara mi.

“Mo pe oruko won ni Anthony, Themal, Raphael ati Vanessa. Mo si maa n ba won soro. Mo maa n so bi o se n se mi fun won. Mo ro pe o san lati ba awon ohun ogbin soro ju ki n soro fun awon eniyan.”

Ipa tèmi náà láwùjo̩ ni owó tí mò ń ná lórí àwo̩n ò̩jè̩wé̩wé̩ olórin – Olamide

Ipa tèmi náà láwùjo̩ ni owó tí mò ń ná lórí àwo̩n ò̩jè̩wé̩wé̩ olórin – Olamide

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria, Olamide Adedeji, ti a mo si Olamide, ti safihan idi to fi da ile ise orin sile.

Oga YBNL naa wi pe oun bere ile ise orin naa nitori ki oun le na owo oun eyi “to ti n po” lori ise orin awon oje wewe olorin.

O safihan eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan pelu Ebro Darden ti Apple Music.

O wi pe, “Mo sese bere si mu owo wole ni sugbon owo naa n di pupo fun mi. Mo wa so pe, bee ni, ko si ohun ti mo fe fi awon owo yi se mo, oya, mo nilo lati gba awon olorin tuntun.

“O je ona kekere temi lati da nnkan pada si awujo.”

Ile ise YBNL Nation ti Olamide je ile fun awon iran olorin takasufe tuntun kaakiri orile ede bii; Fireboy DML ati Asake.

Adekunle Gold, Lil Kesh, Chinko Ekun, Young Jonn, ati Pheelz wa labe ile ise orin naa teleri.

È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya

È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya

Olorin Naijiria, Iyanya Onoyom Mbuk, ti a mo si Iyanya, ti safihan pe esun ti orebinrin oun teleri omo Ghana, osere tiata Yvonne Nelson fi kan oun wi pe oun ni ibasepo miran pelu Tonto Dikeh fere je ki oun padanu ibasepo ti oun wa ninu re.

Olorin ‘Kukere’ naa so eyi di mimo nigba to farahan lori eto Tea With Tay laipe yi ti osere tiata, Temisan Emmanuel Ahwieh, ti a mo si Taymesan se atokun re.

E ranti pe Yvonne Nelson ninu iwe re, ‘I Am Not Yvonne Nelson’ to gbe jade ni ojo kejidinlogun osu keje, 2023, salaye nipa bi o se mo pe orekunrin re teleri, Iyanya, ni ibasepo miran pelu osere tiata, Tonto Dikeh.

Iyanya so pe leyin ti iwe naa jade, omobinrin kan ti oun n wa lati fe ko fe gba fun oun.

O wi pe, “Ohun to sele [esun Yvonne Nelson] fe dani lori ri, arakunrin. Isele naa fere mu ki n padanu ibasepo mi. Ibasepo ti mo wa ninu re bayii.

“Saaju iwe yi [iwe Yvonne Nelson], mo n ba omobinrin kan ti ko mo nnkankan ti ko si ni okiki soro sugbon lojiji iwe naa jade, gbogbo nnkan beere si ni gbon. Omobinrin naa wa so pe , ‘Omo, arakunrin yi, o ti yi pada? Se o daa loju pe iru eyi ko ni sele si mi?’”

Owó yóò tán ló̩wó̩ re̩ tí o bá ń náwó bíi tèmi – DJ Chicken so̩ fún Portable

Owó yóò tán ló̩wó̩ re̩ tí o bá ń náwó bíi tèmi – DJ Chicken so̩ fún Portable

Mary Fágbohùn

DJ Chicken, asakojopo orin ni Naijiria, ti so fun olorin alariyanjiyan, Portable, pe owo yoo tan lowo re ti o ba gbiyanju lati nawo bii ti oun.

O so eyi nigba to n beere bi oro Portable nipa pe o loro se je okodoro to.

Asakojopo orin naa, ninu eto Instagram wo mi ki n wo o kan, da Portable lebi pe ko le e ran oko miran leyin ijamba to sele.

O ni Portable o se ra oko miran leyin isele naa to ba je pe loooto ni owo to n pariwo re wa lowo re.

“Portable, ti o ba na iru owo ti mo n na ni ose, owo yoo tan lowo re. Ko si owo lowo re.

“O ye ki o ti ra oko tuntun leyin ti ijamba oko naa waye to ba je pe loooto ni owo wa lowo re.”

E ranti pe Portable ati awon okunrin re ni a ri ninu fonran kan to n lo kaakiri ti won n bu DJ Chicken nitori esun pe o fi owo ranse si iyawo re.

È̩bùn O̩ló̩run ni wíwá sáyé – Mercy Johnson

È̩bùn O̩ló̩run ni wíwá sáyé – Mercy Johnson

Mary Fágbohùn

Osere tiata Naijiria olugbafe eye, Mercy Johnson Okojie, ti beere fun adura lati odo awon afenifere re bi o se saami ojo ibi odun kokandinlogoji.

Osere naa, eni ti a bi ni ojo kejidinlogbon osu kejo 1984, lo si gbogbo oju opo ayelujara re lati sajoyo ojo ibi re ni ojo Aiku.

Ninu atejade to fi lede ni ojo opo Facebook re, osere naa nigba to n dupe lowo Olorun fun gbogbo awon aseyori re, wi pe “ebun ni aye kii se eto”.

O ko o wi pe, “Itelorun ni mimo pe aye je ebun kii se eto ati pe otito si wa leyin itelorun.

“E jowo, E o nilo lati fi aworan mi lede, e kan so ‘Adura ope ni idake jeje si Olorun fun mi’… Omo Olojo Ibi!”

Òògùn owó ni mo fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí mo pa ṣe— Ọ̀daràn lahùn

Òògùn owó ni mo fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí mo pa ṣe— Ọ̀daràn lahùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi ti mú Ọgbẹni Ibrahim Umar, ẹni ogójì ọdún, tó pa àwọn òṣìṣẹ́ méjì níléeṣẹ́ kan tó wà lágbègbè Gamawa, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa, níìpínlẹ̀ Bauchi.

Àwọn méjèèjì ọ̀hún tí wọ́n pàdé ikú òjìji láti ọwọ́ ọ̀daràn náà ni: Kabiru Idi, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì àti Bato Ali, ẹni ọdún méjìdínlógún.

Òun tí a gbọ́ ni pé Ibrahim tí í ṣe ọmọ ìlú Ungogo, lọ sílùú Taranka, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa, láti lọ̀ọ́ hùwà láabi ọ̀hún, tọ́wọ́ sì tẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ ibi ọhún tán.

Ọ̀gbẹ́ni Adamu, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta kan tó ń gbé nílùú Taranka, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa yìí kan náà, ló lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá agbègbè ọ̀hún láti lọ fẹjọ́ sùn wọn pé àwọn kò tí ì rí àwọn òṣìṣẹ́ méjèèjì táwọn ń wá láti nǹkan bíi oṣù kan sẹ́yìn .

Àtẹ̀jáde kan tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Wakili, fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí ni wọ́n ti sọ pé ìwádìí ìjìnlẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ibrahim ló pa àwọn méjèèjì ọ̀hún láti lò wọ́n fún ètùtù ọlà.

‘Lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá gbá a mú tán, wọ́n lọ̀ ọ́ yẹ ilé rẹ̀ wò, wọ́n sì bá gálọ́ọ̀nù ńlá kan tí ẹ̀jẹ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́, èyí tí wọ́n gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni tó pa ló wà níbẹ̀.

Lójú-ẹsẹ̀ ni wọ́n ti jù ú sáhàámọ, láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwádìí wọn.

Ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ló ti jẹ́wọ́ pé lóòótọ́, òun lòun pa àwọn èèyàn ọ̀hún láti fi wọ́n ṣòògùn owó. Lẹ́yìn náà ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ síbi tó sìnkú wọn sí.

Wọ́n ti hú òkú àwọn èèyàn náà jáde, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti fìdí òótọ̀ múlẹ̀.

Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú àwọn èèyàn ọhún fáwọn èèyàn wọn, kí wọ́n lè lọ ṣètò ìsìnkú wọn. Bákan náà ni wọ́n láwọn máa fojú ọdaràn náà balé -ẹjọ́ lópin ìwádìí àwọn.

Kò pọndadan ká lo Àmọ̀tẹ́kùn fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́- Àjọ elétò ìdìbò

Kò pọndadan ká lo Àmọ̀tẹ́kùn fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́- Àjọ elétò ìdìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ẹni tó wẹjú ni ẹ̀rù n bà.
Àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC), ti sọ pé àwọn kò níí i ṣàmúlò ikọ̀ elétò ààbò ilẹ̀ Yorùbá tá a mọ̀ sí Àmọ̀tẹ́kùn fún ètò ààbò níbi ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó ń bọ̀.

Alága àjọ náà, Isiaka Ọlagunju, ló fìdí èyí múlẹ̀ lásìkò àbẹwò tó ṣe sí Correspondents’ Chapel), ìyẹn ẹ̀ka ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo NUJ), nílé ẹgbẹ́ wọn tó wà ní Òpópónà Àgọ́ Tapa, ní Mọkọla, n’Íbàdàn.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lòfin fún ní ojúṣe pàtàkì jù lọ láti pèsè ètò ààbò lásìkò ètò ìdìbò. Síbẹ̀síbẹ̀, a ti bèèrè fún àtìlẹ́yìn àwọn elétò ààbò mí-ìn bíi sífú dìfẹǹsì, àwọn aláàmójútó ọgbà ẹ̀wọ̀òn, àti bẹ́ẹ̀ , bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n a kò pe àwọn Àmọ̀tẹ́kùn nítorí àwọn èèyàn kò ní nígbàgbọ́ nínú wọn nígbà tó jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló ni wọ́n, a ò sì fẹ́ nǹkan tó máa tàbùkù ètò ìdìbò yìí ”.

Ọkùnrin amòfin àgbà yìí fi kún un pé “a ò lè torí pé ẹgbẹ́ PDP tó ń ṣèjọba ló yàn wá sípò yìí, ká wá sọ pé ẹgbẹ́ PDP ló gbọdọ̀ wọlé ìdìbò. Ààyè pé à ń kọ ìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan ti kọjá lọ, ẹgbẹ́ tí àwọn aráàlú bá dìbò fún jù lọ ló máa wọlé ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.

Ààrẹ Ọlagunju fìdí rẹ̀ múlẹ̀ síwájú pé àwọn èèyàn tí kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lajọ náà yóò gbà gẹ́gẹ́ bíi àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò ṣètò ìdìbò ọ̀hún, àti pé láìpẹ́ làwọn yóó ṣàyẹ̀wò fáwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, láìpẹ́ yìí làjọ OYSIEC kéde ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, (27) oṣù Kẹrin, ọdún 2024, gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìdìbò àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Díẹ̀ lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú alága àjọ elétò ìbò ìpínlẹ̀ yìí ni Ọ̀mọ̀wé Babatunde Adeniyi, Ọ̀gbẹ́ni Kunmi Agboọla àti Emmanueli Ọlanrewaju.