Home Blog Page 40

ÀIàyé lórí ohun tó fàá tí Dangote kò fi ní ‘lé l’ókè-òkun.

CAPE TOWNSOUTH AFRICA, 06MAY11 - Aliko Dangote, President and Chief Executive Officer, Dangote Group, Nigeria, during the African Fellowship Programe with Young Global Leaders announcement at the World Economic Forum on Africa 2011 held in Cape Town, South Africa, 4-6 May 2011. ..Copyright (cc-by-sa) (C) World Economic Forum (www.weforum.org/Photo Matthew Jordaan matthew.jordaan@inl.co.za

ÀIàyé lórí ohun tó fàá tí Dangote kò fi ní ‘lé l’ókè-òkun.

Gbọ́láhàn Quseem

Oríṣiriṣi ifànfà ló ti wáyé láàrin àwọn ará ‘lú ‘lórí ọrọ ti Dangote sọ, níbi ti àwọn kan ti n fara mọ́ pe ohun tó ṣe dára fun ìdókòòwò, nítorí pé sísan owó ‘légbé rọrùn ju kíkọ́ ‘lé lọ.

Síbẹ̀ awọn kan wa to tako erongba rẹ pe pẹlu gbogbo owo to ni, ṣe o yẹ k’iru olowo bi tiẹ ma ni ‘le l’oke-okun tabi yalegbe

Dangote ṣalaye pe ohun to fa t’oun fi gbe awọn igbesẹ ti oun gbe ni lati ri pe orilẹ-ede Naijiria goke agba.

“Idi ti mi o fi ni ile ni ‘lu London tabi Amẹrika ni pe, mo fẹ mojuto idagbasoke didaleeṣẹ silẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Mo fẹ ki orilẹ-ede Naijiria mu awọn ala rere rẹ ṣẹ. Koda, Yatọ si ile ti mo ni ni ‘lu Eko, mo ni ile miran ni Kano to jẹ ilu mi. Igbakugba ti mo ba lọ si ‘lu Abuja, mo maa n san owo ‘le nibẹ ni.”

Ìjọba orílẹ́-èdè UAE ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría.

Ìjọba orílẹ́-èdè UAE ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría.

Gbọ́láhàn Quseem

Mínísítà ètò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Idris ti sọ́ di mímọ̀ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ti l’ànfààní láti gba físà lati rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè United Arab Emirates(UAE) báyìí lẹ́yìn tí ìjọba orílẹ́-èdè naa ti gbẹ́ṣẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíríà.

Minisita ṣalaye ọrọ naa fawọn akọroyin n’ile-iṣẹ ijọba niluu Abuja, o ni igbesẹ naa waye lẹyin ti ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria s’asọye pọ pẹlu orilẹ-ede UAE lori ọrọ fisa ọhun.

Minisita ni, ijọba Naijiria ti n ba ijọba orilẹ-ede UAE sọrọ naa tipẹ, lori bawọn ọmọ Naijiria yo ṣe l’anfaani pada lati maa gba fisa lati rinrin-ajo lọ si orilẹ-ede UAE ọhun.

‘’ Ọjọ-Aje, ọjọ kẹẹdogun osu yi ni ibuwọlu adehun lori ọrọ naa waye.

Lati oni lọ, awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrin-ajo lọ si orilẹ-ede UAE ti lanfaani lati ṣe bẹẹ bayi i,” minisita eto iroyin lo fi kun ọrọ rẹ bẹẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọdun 2022 ni ijọba orilẹ-ede UAE fofin de fisa awọn ọmọ Naijiria lọ si orilẹ-ede naa.

Sé Ládojà náà ṣetán láti jẹ ọba kó tó j’ọba?

Sé Ládojà náà ṣetán láti jẹ ọba kó tó j’ọba?

Gbọ́láhàn Quseem

Ọ̀rọ̀ ifànfà tó wáyé lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Adétúnjí gbéṣẹ̀ kí ó tó dipé Ọba Mahood Olalekan Balogun di Olúbàdàn tuntun, ló tún fẹ́ dá wàhálà míràn sílẹ̀ báyìí, ní bí í ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe gbé ìlànà tuntun kalẹ̀ lórí bí wọn yó ṣe máa j’oyè ọ̀hun.

Gbogbo eeyan lo ti mọ pe gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rasidi Adewolu Ladoja ni yo bọ s’ori apere lẹyin Ọba to ṣẹṣẹ jẹ yi.

Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju asiko yi ni wahala ẹni ti ipo Olubadan kan ti kọkọ suyọ ni kete ti ọba ana, Oba Mahood Olalekan Balogun waja.

Ọrọ ọhun lo ti n ja raninraninn fun bi oṣu mẹrin, ki gbogbo rẹ to dopin lọjọ Ẹti, ọjọ Kejila, oṣu Keje, ọdun 2024 nigba ti ‘jọba ipinlẹ Ọyọ gbe ọpa-aṣẹ fun Ọba Akinloye Owolabi Olakulehin, gẹgẹ bi Olubadan kẹtalelogoji.

Ninu iwe ilana eto ti wọn ṣe lọjọ naa, ijọba Ọyọ kọọ sibẹ pe, Oloye to ba ni ade to ga julọ ninu awọn ti ipo ọhun tọ si ni yo j’oye Olubadan.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Gomina ana ni, ‘pinlẹ Ọyọ, Oloye Ladoja ti sọ nigba diẹ sẹyin pe oun ko le de ade kankan, gẹgẹ bi ilana ti ijọba gbe kalẹ.

Ọna lati dena Ladoja, lati ma ṣe di Olubadan ni ijọba gbe kalẹ, ninu agbeyẹwo ilana ti wọn yoo fi maa jẹ oye ọhun ni lọdun 2023.

Abala kẹrin ninu akọsilẹ ilana jijẹ oye Olubadan ti ọdun 1957 sọ pe “ẹni ti wọn yo mu gẹgẹ bi ọmọ oye ti Olubadan tọsi ni oloye ti ipo rẹ ba ga ju .”

Ṣugbọn ninu abala kẹrin agbeyẹwo ilana ti ijọba Seyi Makinde ṣe lọjọ Kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2023, o sọpe: “ẹni ti wọn yo mu gẹgẹ bi ọmọ oye ti Olubadan kan ni ọba ti ade rẹ ga julọ.”

Ko sẹni meji ti ipo rẹ tun ga ju ti Ladoja lọ ninu awọn to n jẹ oye Olubadan bayi, ṣugbọn ti baba naa ti kọ jalẹ wi pe oun ko le ba wọn de ade paali.

Ohun to sunmọ ni pe, Oloye Ladoja le ma ni anfaani lati de ipo Olubadan ti
ilana yi ba di mumu sẹ.

NAFDAC gbẹsẹ lé ayédèrú oògùn amárale táwọn ọkùnrin fi ń ṣe ‘kerewà’ ní Sókótó

NAFDAC gbẹsẹ lé ayédèrú oògùn amárale táwọn ọkùnrin fi ń ṣe ‘kerewà’ ní Sókótó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó rí sí oúnjẹ jíjẹ àti òògùn lílò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ‘National Agency For Food And Drug Administration And Control’ (NAFDAC), ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Sókótó, ti kéde pé àwọn ti gbẹ́sẹ̀ lé òbítíbitì ayédèrú òògùn òyìnbó kan táwọn ọkùnrin máa ń lò tó máa ń fún wọn lágbára láti bá obìnrin sùn dáadáa tí wọ́n kó wọ̀lú náà lọ́nà àìtọ́

Ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun yii, ni Ọga agba patapata fun ajọ naa nipinlẹ Sokoto, Ọgbẹni Garba Adamu, sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa aṣeyọri wọn nipinlẹ Ṣokoto ati agbegbe rẹ lọdun yii.

O ni, ‘A ti gba obitibiti ayederu oogun oyinbo kan tawọn ọkunrin maa n lo lati fi ba awọn obinrin sun, a ṣewadii daadaa nipa oogun ọhun, a si ni ẹri to daju ṣaka pe awọn eroja kan ti wọn fi ṣoogun ọhun ko daa fun lilo awọn araalu, akoba nla gbaa ni oogun naa maa fa fun awọn ti wọn ba lo o lọjọ iwaju.

O waa rọ awọn araalu ọhun, paapaa ju lọ awọn ọkunrin ti wọn maa n lo awọn oogun to le jẹ ki wọn ba obinrin sun daadaa lasiko ibalopọ pe ki wọn jawọ ninu iwa palapala naa, nitori pe ki i ṣe ohun to daa fara rara, to si ni ipalara fun wọn lọjọ iwaju.

O ni bi wọn ba maa ra oogun yoowu, ki wọn ri i daju pe eyi to jẹ ojulowo, to si ni ontẹ NAFDAC lara ni wọn ra lọja.

llé tí àwọn àgùnbánirọ̀ ń gbé wó l’Ékìtì ,àwọn èèyàn farapa yánnayànna

llé tí àwọn àgùnbánirọ̀ ń gbé wó l’Ékìtì ,àwọn èèyàn farapa yánnayànna

Ibrahim Adédèjì.

Ọ̀pọlọpọ àwọn àgùnbánirọ̀ ni wọ́n farapa yannayanna lásìkò tí ilé tí wọ́n ń gbé tó wà ní Ìsẹ̀/Ọ̀rún-Ekiti, níjọba ìbílẹ̀ Emure, ní ìpínlẹ̀ Èkìtì wó lulẹ̀.

Awọn agunbanirọ naa ti ọpọlọpọ wọn jẹ obinrin ni wọn fara pa, ti wọn si ti ko wọn lọ si ileewosan to wa ni ibudo wọn fun itọju.

Gẹgẹ bi awọn t’ọrọ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye fun akọroyin, ni pe ile ọhun ti wọn lo ti pẹ, nitori latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ekiti silẹ lo ti wa nibẹ lo sadeede wo ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ naa, lakooko ti awọn to n sin ijọba naa n sun lọwọ.

Oṣiṣẹ ajọ naa kan to b sọrọ sọ pe loootọ ni ile awọn obinrin to wa ninu Ibudo awọn agunbanirọ sadeede da wo ni kutukutu owurọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu yii.

‘’A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko si ẹni to ku sinu iṣẹlẹ naa, awa oṣiṣẹ ti a wa ninu ibudo naa la sare waa yọ awọn diẹ ti ile naa wo lu, ti a si ko wọn lọ si ileewosan fun itọju to peye’.

Awọn agunbanirọ naa ti wọn to bii ẹgbẹrun kan ati aabọ (1,500) ni wọn wa ni ipagọ naa fun idanilẹkọ ọlọsẹ mẹta ki iṣẹlẹ ile wiwo naa too sẹlẹ.
ohun ti gbọ ni pe awọn meji pere ni wọn fara pa

Ìbọn tó ba Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump, N tí àwọn èèyàn kan sọ níbẹ̀

Ìbọn tó ba Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump, N tí àwọn èèyàn kan sọ níbẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

À fi kí orí máa kóni yọ nínú ewu gbogbo.
Àwọn oṣojúmikòró tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà daba wípé ìró ìbọn yẹn wá láti ilé alájà kan tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún sì ibi pátákó tí Trump tí ń sọ̀rọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà to ṣẹ̀.

Ọ̀kan nínú wọn, Greg, so fún akọ̀ròyì pé óun rí arákùnrin tí ó ń fàyà á wọlẹ lórí òrùlé ilé alájà kan náà ni bí ìṣẹ́jú marun sì àsìkò tí Trump bọ́ sí orí pátákò láti sọ̀rọ̀. Ó ní pé òun tọ́ka ẹni tí òun fura sí yìí fún àwọn ọlọ́pàá.

“ìbọn wá ní ọwọ́ rẹ̀. Ó hàn dájúdájú wí pé arákùnrin náà mú ìbọn lọ́wọ́. Àá ń tọ́ka ẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá àmọ́ ṣe ni wọn ń sáré kiri lórí ilẹ̀. A sì ń sọ fún wọn wí pé arákùnrin náà wà lórí òrùlé pẹ̀lú ìbọn àmọ́ nkan tó ń ṣẹlẹ̀ kò yé àwọn ọlọ́pàá,” Greg ṣàlàyé.

Óṣojúmìkòró miran, Jason sọ fún oníròyìn wípé óun gbọ́ ìró ìbọn ni ìgbà márùn ún.

“A rí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí wọ́n bẹ́ mọ́ Trump láti dáàbò bò ó. Gbogbo èèyàn tó wà lójú agbo náà bẹ̀rẹ̀ ni kíákíá.

Lẹ́yìn náà ni Ààrẹ tẹ́lẹ̀ri Trump dìde dúró òsì náà ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan.

Tim to wá ní àpéjọpọ náà pelu sọ pé òun gbọ́ ìró ìbọn lọ́pọ̀lọpọ̀

Ọba Ọlákùlẹ́yìn gbọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn Kẹtàlélógójì

Ọba Ọlákùlẹ́yìn gbọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn Kẹtàlélógójì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Wọ́n ní orì tí yóó dádé, inú agogo idẹ ní tií wá,ọrùn tí yóó lèjìgbà ìlẹ̀kẹ̀,inú agogo idẹ ní tií wá, ìbàdí tí yóó lo mọ́sàajì, aṣọ Ọba tí í taná yanranyanran,,inú agogo idẹ ní tií wá, èyí ló bí bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti gbé ọ̀pá àṣẹ fún Olúbàdàn tuntun,níbi àkànṣe ètò ìfinijoyè tó wáyé ní gbàgede Mapo nílùú Ìbàdàn l’ọ́jọ́ Ẹtì .

Nínú ọ̀rọ̀ tí Mákindé sọ níbi ìpéjọpọ̀ náà, ó ṣe àlàyé wí pé ìgbésẹ̀ tí òun gbé láti fún Olúbàdàn tuntun ní ọ̀pá àṣẹ àti ìwé ẹ̀rí ìyanisípò wà ní ìbámu pẹ̀lú agbára tí a fún un gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Lẹ́yìn tí Olúbàdàn tuntun Ọba Owólabí Ọlakulẹhin, Ige Ọlakulẹhin 1 gba ọ̀pá àṣẹ ni Kábíyèsí náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó wá sí ibi àjọyọ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń gbàdúrà pé ìlú Ìbàdàn yóó máa gòkè àgbà síi.

Àwọn ládéládé-lóyèlóyè, aṣojú ìjọba, àwọn alákòóso ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn asíwájú ẹ̀ṣin àti ọ̀kanòjọ̀kan ẹgbẹ́ àwùjọ kò gbẹ́yìn níbi àkànṣe ètò náà.

Lára wọn ni Mínísítà fún àkóso iná ọba, Adebayo Adelabu tí ó ṣojú Ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí, Bọla Ahmed Tinubu, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé, Igbákejì rẹ̀, Adebayo Lawal, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dapọ Abiọdun, igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Olaide Adelami, igbákejì Gómìnà Ọ̀ṣun, Kola Adewusi, Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọba Adewusi Enitan Ogunwusi, Sultan Sokoto, Sa’ad Abubakar, Ewi Ado, Oba Rufus Adeyemo Adejugbe, Olugbon Orílé Ìgbọ́n, Ọba Francis Olusola Alao Asẹ́yìn ìlú Ìṣẹ́yìn, Sefiu Oyebola Adeyeri III, Ajirotutu I, Olú Igboọra, Ọba Jimoh Olajide Titiloye, Olóyè Rashidi Ladọja àti àwọn Gómìnà tẹ́lẹ̀rí n’ípìínlẹ̀ Ọyọ, Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Yorùbá, Edo àti Delta, Alhaji Dauda Akinola, Kọmisana Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ayọdele Ṣonubi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Gbajúgbajà olórin, Taye Currency ló kan ìlù sí àwọn èèyàn n’íbàdí níbi ìpéjọpọ̀ náà.

Lórí owó oṣù tó kéré jùlọ Tinubu àtẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àáyá ń tiro, Ògúngbè ń bẹ̀rẹ̀

Lórí owó oṣù tó kéré jùlọ Tinubu àtẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àáyá ń tiro, Ògúngbè ń bẹ̀rè̩

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìpàdé láàárín ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tó wáyé ní ilé ìjọba ní ìlú Abuja ti wá sópin.

Ṣùgbọ́n wọn kò ì tíì fẹnukò lọrí owó oṣù tó kéré jùlọ fún àwọn òṣìṣẹ́.

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Nigeria Labour Congress, Joe Ajaero àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ti Trade Union Congress, Festos Osifo ni wọ́n ṣaájú ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Tinubu lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Keje, ọdún 2024.

Níṣe ni ìrètí wà pé lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìpàdé náà ni ààrẹ Tinubu yóò kéde pé àwọn ti fẹnuk]o pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àma tí èyí kò ṣẹlẹ̀.

Mínísítà fétò ìròyìn, Mohammed Idris tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà ṣàlàyé pé ìjíròrò ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí owó oṣù náà àti pé ìpàdé tí ààrẹ ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ni láti fẹnukò lórí iye kan ní pàtó.

Idris ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní lẹ́yìn ìjíròrò wọn pẹ̀lú ààrẹ, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní kí ààrẹ fún àwọn ní ọ̀sẹ̀ láti lọ jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn kí wọ́n sì jábọ̀ padà nígbà náà.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan yìí, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba yóò fẹnukò lórí iye kan pàtó àti pé yóò so èso rere fáwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ẹ ó rántí pé láti bíi oṣù mélòó kan ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí owó oṣù tó kéré jùlọ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà igba lé ní àádọ́ta náírà (N250,000) ni àwọn ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ àmọ́ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ aládani ní àwọn kò lè san ju ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) lọ.

Bákan náà ni àwọn gómìnà ní àwọn kò lè san ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) tí ìjọba àpapọ̀ ní àwọn fẹ́ san.

Ọwọ́ àwọn àjọ òṣìṣẹ́ sifudiẹnsi tẹ àwọn afurásí méjì tí wọ́n ṣòwò egbòogi oloró ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Ọwọ́ àwọn àjọ òṣìṣẹ́ sifudiẹnsi tẹ àwọn afurásí méjì tí wọ́n ṣòwò egbòogi oloró ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

lbrahim Adédèjì.

Ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ sífúdìfẹǹsì ẹka tí ìpínlẹ̀ Òǹdó, ti tẹ àwọn afurasí méjì kan tí wọ́n fẹsùn kàn pé wọ́n ń ṣòwò òògùn olóró nílùú Aykurẹ.

Awọn afurasi ọhun, Chukwudi Victor Amoke, ọmọ bibi ijọba ibilẹ Igboeze, nipinlẹ Enugu, ati ọrẹ rẹ, Timilẹyin Abed, to wa lati Ilogbo Ekiti, lọwọ tẹ nitosi ileetura kan ti wọn n pe ni Benue, eyi to wa lagbegbe Ṣáṣá, Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro sifu difẹnsi tipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Daniel Aidamembor, fi ṣọwọ si awọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje yii, o ni iṣẹ ti Chukwudi ati ẹni keji rẹ yan laayo ju lọ ni pinpin ati tita oriṣiiriṣii oogun oloro fawọn onibaara wọn niluu Akurẹ ati agbegbe rẹ.

Aidamembor ni agbegbe Zone A Glory Land, l’Akurẹ, ni Chukwudi fi ṣe ibugbe, nigba ti Timilẹyin to jẹ ọrẹ rẹ n gbe l’Ojule kẹrinlelogun ninu ọja Ṣaṣa, niluu Akurẹ, kan naa.

Yatọ si ọkan-o-jọkan oogun oloro to ni awọn ba nikaawọ wọn, awọn afurasi mejeeji lo ni wọn tun jẹwọ lasiko ti awọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo pe loootọ lawọn n ṣowo egboogi oloro.

O ni awọn ti n gbe igbeṣẹ lati fi awọn mejeeji ṣọwọ sọdọ ajọ to n gbogun ti oogun oloro lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ọrọ wọn.

ìrújú sẹlẹ̀ lórí àgbékalẹ̀ ètò òṣèlú France

ìrújú sẹlẹ̀ lórí àgbékalẹ̀ ètò òṣèlú France

Gbọ́láhàn Quseem

Lẹ́yin ìkéde èsì ìbò ní France, ìrújú wà lórí bí àgbékalẹ̀ ìlànà ìṣèjọba yó ṣe rí lórílẹ́-èdè náà pẹ̀lú bí kò ṣe sí ìkankan nínú àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lórílẹ̀-èdè náà ṣe le dá ìjọba ṣe pẹ̀lú iye ìbò tí wọ́n ní.

Nibayii naa, Aarẹ orilẹ-ede naa, Emmanuel Macron ti rọ olootu ijọba, Gabriel Attal pe ko ṣi ni suuru naa, ko si maṣe kọ ‘we fi ipo rẹ silẹ nitori ati mu ki eto iṣejọba duro re lẹyin esi idibo naa.

Olotu ijọba France, Gabriel Attal kede pe oun fẹ kọwe fi ipo silẹ ki Aarẹ Macron to tako igbesẹ naa .

Labẹ ofin ilẹ naa, Aarẹ ni yoo kede ẹni ti yo jẹ olotu ijọba orilẹ-ede naa lati ara akojọpọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ni ‘le aṣofin orilẹ-ede naa. Ohun ti ẹgbẹ oṣelu National Popular Front n sọ bayi ni pe awọn yo fi orukọ eeyan ti awọn fẹ ni ipo olotu ranṣẹ si ko to
di opin ọṣẹ.