Home Blog Page 34

Ẹ̀wọ̀n n rùn lóríi ọkùnrin yìí’ físà sílùú òyìnbó ló fi n lu jìbìtì l’Akurẹ

Ẹ̀wọ̀n n rùn lóríi ọkùnrin yìí’ físà sílùú òyìnbó ló fi n lu jìbìtì l’Akurẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí èèyàn bá n yọ́lẹ̀ ẹ́ dà, ohun aburú á máa yọ́wọn ṣe.

Ilé-ẹjọ́ Májísírètì kan tó fìkàlẹ̀ sílùú Akurẹ, ti ní kí baba àgbàlagbà kan, Daniel Adedọtun, ṣì lọ máa gbatẹ́gùn nínú ọgbà àtúnrọ ìwà tó wà ní Olokuta, lórí ẹ̀sùn fífi físà gbígbà lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní jìbìtì.

Bàbá ẹni ọdún mẹtalelọgọta ọ̀hún àtàwọn mí-ìn táwọn ọlọ́pàá ṣì ń wá báyìí ni wọ́n fẹsun kàn pé wọ́n fi ẹ̀tàn gba owó tó dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù lọnà ogun Náírà (#19.7m) lọwọ́ àwọn èèyàn kan nílùú Akurẹ, lórí ọrọ̀ pé wọ́n fẹ́ bá wọn gba fisa ìlú òyìnbó laarin oṣu Kejì si Ikẹwaa, ọdun yii.

Lára ẹsùn mẹ́fà tí wọ́n kà sí bàbá yìí lọ́rùn nígbà tó ń fara hàn níwájú Onídàájọ Damilọla Ṣekoni, lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Kejìlá yìí, ni ìgbìmọ̀-pọ̀ hùwà tó lòdì sófin, olè jíjà, fífi ọ̀nà èrú sọ nnkan oní nnkan di tẹni, fífi ẹ̀tàn gbowó lọ́wọ́ ẹni àti jìbìtì lílù.

Àwọn ẹ̀sùn yìí ni ọlọ́pàá agbèfọ́ba, Simon Wada, ní ó ta ko abala kín-ín-ní, ìlà kín-ín-ní àti ẹ̀kẹta, okoòlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ́ta dín mẹ́rin (516) nínú ìwé òfin ìpínlẹ̀ Ondo ti ọdún 2006.

Wada ní owó tó tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án Náírà ni afurasí ọ̀hún fẹ̀tàn gbà lọ́wọ́ ọkùnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fọlayẹle, pẹ̀lú ìlérí pé òun fẹ́ ràn án lọ́wọ́ láti gba ìwé-ẹ̀rí tí yóó fi kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Jìbìtì mílíọ̀nù méje Náírà ni Abilékọ kan tí wọ́n porúkọ rẹ̀ ní Christianah Jombo, fi gbára ní tirẹ̀, èyí tó san fún afuarsí oníjìbìtì yìí láti bá a fi gba físà Amẹ́ríkà fún àbúrò rẹ̀ kan, Abilékọ Aderonkẹ Ayangbemi. Bẹ́ẹ̀ ló tún fọ̀nà èrú gba mílíọ̀nù márùn-ún àtààbọ̀ Náírà lọ́wọ́ Fẹmi Bayọde, lórí ọ̀rọ̀ ìlú òyìnbó yìí kan náà.

Níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wada ní òun fẹ́ kílé ẹjọ́ ṣì fi olùjẹ́jọ́ náà pamọ́ sọ̀gbá ìtúnirọ títí dìgbà tí ìmọràn yóò fi wá láti ọ́fììsì àjọ tó ń gba adájọ́ nímọ̀ràn.

Nígbà tó ń gbé ìpinnu rẹ̀ kalẹ̀, Onídàájọ Ṣekoni gba ẹ̀bẹ̀ agbèfọ́ba wọlé, lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ mí-ìn sí ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kín-ín-ní, ọdún 2024

Adejumo Lewis , Ògbóntarìgì òṣèré tíátà, jáde láyé

Adejumo Lewis ,
Ògbóntarìgì òṣèré tíátà, jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àìsàn nìkan niè ẹ̀dá rí wò, kò séèyàn tó rí ti ọlọ́jọ́ ṣe .
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Dejumo Lewis tí jáde láyé.

Àgbà òṣèré náà lo ọgọ́rin ọdún ní dúníyàn.

Saidi Balogun, gbajúmò òṣèré tíátà ló kéde ìpapòdà Lewis lórí òpó ayélujára rẹ̀ lọ́jọ́ Sátidé.

Ó gbé fọ́nrán olóògbé náà síta, tó sì, sọ pé “Ód’ìgbà, kí Ọlọ́run tẹ́ ọ sáfẹ́fẹ́ rere, RIP”

Ohun tó ṣokùnfa ikú Lewis ni kò tí ì hàn sí aráyé báyìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn òṣeré tíátà l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin ló bọ́ sórí ayélujára láti sàárò èèyàn wọn tó lọ.

Lewis jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, ó kópa nínú eré sinimá ‘The Village Headmaster láti ọdún 1968 sí 1988, tó jẹ́ pé òun ló kópa gẹ́gẹ́ bíi Kábíyèsí nínú sinimá ọ̀hún

Àwọn sinimá mìíràn tó jẹ́ ti Lewis ni “A Place in the Stars” (2014), “Crossroads” (2020), and “Power of 1” (2018),


 

Aláṣẹ Iléeṣẹ́ Crime Alert wẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn jìbìtì

Aláṣẹ Iléeṣẹ́ Crime Alert wẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn jìbìtì

Ọrẹ Òtítọ́jù

Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Crime Alert Security Network, ní Ìbàdàn, Olaniyan Gbenga Amos ti dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí Iléẹjọ́ to n joko nílùú Ìbàdàn ni ó jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì.

Ẹwọn ọdún marindinlọgọrin ni Adajọ Bayo Taiwo ti ile ẹjọ giga to n joko niluu Ibadan, gbe kalẹ fun oludasilẹ ileeṣẹ Crime Alert Security Network, Olaniyan Gbenga Amos lori ẹsun jibiti naa.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé Olaniyan ni ọwọ́ àjọ EFCC tẹ ní ọdún 2020 lẹ́yìn tó lu ọpọ èèyàn ní jibiti owo ìdókòwò pẹ̀lú ileeṣẹ rẹ.

Ó se ìlérí pé òun yoo da owo ati ele ori owo pada fun awọn to ba dokowo sugbọn ọrọ gba ibo miiran jade, ti ko si ri owo naa san pada.

Ẹsun marindinlogogi ni EFCC ka si ẹsẹ Olaniyan niwaju ileẹjọ.

Nínú atẹjade tí agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale gbe sita lọjọ Isẹgun, o ni Olaniyan ati ileeṣẹ rẹ, Detorrid Heritage Investment Limited ni wọn gbe lọ ileẹjọ ni ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2023.

Ọdún tó kọjá , ẹlẹrìí àjọ EFCC, Juliet Odogu sọ fún ilé-ẹjọ́ pé o tó igba ni iye àwọn èèyàn tí Olaniyan lu ní Jibiti ni owo to to aadọjọ milọnu naira.

Ó ní àwọn èèyàn san ẹgbẹrun márùn un náírà si milọnu mẹsan an naira fun Olaniyan lẹyin ti wọn ba dowopọ.

Bákan náà ló se àfihàn ìwé àkọsílẹ̀ tí àwọn èèyàn náà fi san owó fún ileeṣẹ Olaniyan fún Ilé-ẹjọ́.

Gẹ́gẹ́ bí EFCC se sọ, Olaniyan ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn pé ó gba mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún náírà lọ́wọ́ Fadipe Ayorinde pẹ̀lú ìlérí pé yóó gba ìdá ọgbọ̀n pẹ̀lú owó tó fi dókòwò lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà.

Lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso – Ọba Ghandi

Lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso – Ọba Ghandi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé n tí Ọlọ́run bá ti kọ mọ́ ẹ̀dá, dandan ni kó wá sí ìmúṣẹ.
Ṣọun tuntun nílẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi Laoye, Orumagẹgẹ III, ti ní bótilẹ̀ jẹ́ pé òun ti fi iṣẹ́ Pásítọ̀ sílẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ìjọ ìràpadà, RCCG, tó tóbi jùlọ lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, òun ti di Olùṣọ́ Àgùntàn fún gbogbo ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ báyìí.

Ọba Laoye fi ọ̀rọ̀ yìí léde lẹ́yìn tí ó gba ọ̀pá àṣẹ láti ọwọ́ Gómìnà Ṣeyi Makinde níbi ayẹyẹ ìgbọ̀pá àṣẹ tó wáyé ní pápá ìṣeré Ṣọ̀ún ti ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́.

Ó ní Ọba tí òun jẹ kìí ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn Kírísítẹ̀nì nìkan, bíkòṣe Mùsùlùmí, àwọn Ẹlẹ́sìn àbáláyé àti gbogbo ẹni tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan.

Ṣọ̀ún tuntun ní bótiwù kí ẹ̀dá làkàkà tó, Ọlọ́run nìkan ló lè fini jẹ ọba.

Ó pàrọwà sí àwọn tí wọ́n jọ du ipò náà pé kí wọ́n gbaàgbé ọ̀rọ̀ àná, kí wọ́n sì sowọ́pọ̀ láti gbé ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ dé ibi gíga.

Ọba Laoye ní gbogbo ìmọ àti ìrírí tí òun ní nípasẹ̀ iṣẹ́ Pásítọ̀ àti okoòwò nílùú Amẹ́ríkà ni òun yóò papọ̀ láti mú ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ gun òkè àgbà.

Ó ní òun yóó ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìdàgbàsókè ọlọ́dún márùndínlọ́gbọ̀n fún ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ láti di ìlú tó ṣee mú yangàn jù báyìí lọ.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Gọmina Ṣeyi Makinde lóríi bí ó ti fi ọmọnìyàn ṣe láti mú kí ìfẹ́ Olódùmarè ṣẹ lórí ìyànsípò òun gẹ́gẹ́ bíi Ṣọun ìkọkànlélégún nílẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́

Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí wẹ̀wọ̀n l’Óndó

Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí wẹ̀wọ̀n l’Óndó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìjàngbọ́n kìí bímọ re.
Ilé-ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Òǹdó kan, tó fìlú Àkúrẹ́ ṣe ibùjókòó , ló ti rán àwọn mẹfa kan lẹwọn ọdún méjì fún dída omi àlàáfíà ìlú Ayetoro níjọba ìbílẹ̀ Ìlàjẹ ní ìpínlẹ̀ náà rú.

Àwọn mẹfa náà ni Oluwambe Ojagbohunmi, tó jẹ́ olórí ìjọ The Holy Apostles’ Church, Aiyetoro, tó sì tún pera rẹ̀ ní adarí ìlú náà, Victor Akinluwa, Isaac Ikuyelorimi, Lawrence Lemamu, George Eyekole àti Segun Okenla.

Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà ni ọlọ́pàá mú ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kínní, ọdún 2018 lórí ẹsùn pé àwọn ni wọ́n wà nídìí rògbòdìyàn tó bẹ sílẹ̀ nílùú Ayetoro lé yìí tó fa ìpalára fáwọn kan, tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì bàjẹ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ igbẹjo, ẹsùn mẹwàá ni agbẹjọro olupẹjo, Babatunde Falodun kà sí wọn lẹsẹ nileẹjọ tó fi mọ́ ìwà ipá, ìdàlúrú, ìdigunjalè àti bíba dúkìá onídúkìá jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí Falodun ṣe wí, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí ló tako àlàkalẹ̀ abala kọkanleaadọtalenirinwo nínú òfin ọdaràn, ìdì kẹtadinlogoji, apá kìíní, nínú òfin ìpínlẹ̀ Òǹdó ti ọdún 2026.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn náà, George Eyekole, ni wọ́n fi ẹsùn ìgbìyànjú láti paniyan kàn nítorí ó yìnbọn mọ́ ọkùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Olu Obolo, tí eléyìun sì tako àlàkalẹ̀ abala okòólélọ́ọ̀dúnrún nínú òfin ọ̀daràn, ìdì kẹtàdínlógójì, apá kìíní, nínú òfin ìpínlẹ̀ Òǹdó ti ọdún 2026.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀daràn náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan wọ́n, ilé-ẹjọ́ dẹ̀bi rù wọ́n lórí mẹ́ta nínú àwọn ẹsùn náà tó níí ṣe pẹ̀lú bíba dúkìá jẹ́.

Nínú ìdájọ́ rẹ̀, Onídájọ́ David Kolawole wí pé àwọn ọ̀daràn náà jẹ̀bi bíba dúkìá onídúkìá jẹ́, ó sì ní kí wọ́n lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbára àbí kí wọ́n sanwó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà.

Bákan náà ló ní kí oníkálùkù wọn ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún náírà gẹ́gẹ́ bíi owó gbà má bínú fún àwọn dúkìá tí wọ́n bàjẹ́.

Ẹ̀wẹ̀, Eyekole ni kò níí ní ànfààní láti san owó ìtanràn tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ fẹ́ san ní bí adájọ́ tún ṣe fún-un ní ọdún márùn míràn pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára nítorí ìgbìyànjú láti pànìyàn lákòókò làásìgbò náà.

Gbogbo àwọn ọ̀daràn náà ni Onídàájọ́ Kolawole ní kí wọn tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn láti gba àlàáfíà láàyè nínú ìlú náà.

Kolawole fi kún-un pé, àwọn ọdaràn náà ni yóò forí fá ti ìdàrúdàpọ̀ kankan bá tún wáyé nínú ìlú ọ̀hún lẹ́yìn tí wọ́n bá sanwó ìtanràn tí wọ́n sì padà sáàrin ìlú, àti pé owó ìtanràn náà ni yóó di dídápadà fún wọn.

Ìjọba Nàìjíríà kéde ẹ̀dínwó 50% lórí owó ọkọ̀ lásìkò ọdún

Ìjọba Nàìjíríà kéde ẹ̀dínwó 50% lórí owó ọkọ̀ lásìkò ọdún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Tinubu ti buwọ́lu adin kù ida aadọta lori iye owo ọkọ ti awọn ọmọ Naijiria to ba rinrinajo lasiko ọdun.

Ètò ẹdinwo náà yóò wáyé láàrin ọjọ́ kọkànlelógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2023, sí ọjọ́ kẹrin, oṣù Kínní, ọdún 2024.

Nínú ìkéde ti olùdámọ̀ràn fún Ààrẹ lórí ètò ìròyìn, Bayo Onanuga, fi síta, wọ́n ní àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ rìnrìn àjò fún ọdún, lè bẹrẹ láti ọjọ́ kọkànlelógún, kí wọ́n ò sì san ìlàjì owó tó yẹ kí wọ́n ó san.

Ó nì ìjọba àpapọ̀ ni yóó san ìdá àádọ́ta tó kù fún àwọn iléeṣẹ́ ọkọ̀ tó bá kó èrò.

Bákan náà ni wọ́n lè rìnrìnàjò wọn láì san owó kankan tí wọ́n bá wọ ọkọ̀ rélùwéè lásìkò ọdún.

Nǹkan dé ! Portable ati Pasuma ti di ìṣòro fún ṣọọsi ṣẹ̀lẹ

Nǹkan dé ! Portable ati Pasuma ti di ìṣòro fún ṣọọsi ṣẹ̀lẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Túláàsì ní òhun yóó jókòó, ẹnìkan ní kò sáyè,bíí ṣe igiimú onítọ̀ún…..
Àfi bíi ẹni pé àṣà tí gbajúgbajà òǹkọrin hípọọ̀pù nnì, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, táwọn èèyàn mọ̀ sí Portable olórin , máa ń dá, tó máa ń sọ pé, “wàhálà, wàhálà, wàhálà” ti ṣẹ sí i lára ni, látàrí bí ọkan-o-jọkan awuyewuye ṣe ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tí ọkùnrin táwọn ọdọ fẹ́ràn orin rẹ̀ náà bá lọ. Tuntun tó ṣẹlẹ̀ báyìí ni awuyeyewu tó ń lọ láàrin àwọn wòlíì àti adarí ṣọọṣi Ṣẹ̀lẹ́, látàrí bí Portable àti Wasiu Alabi Pasuma, Ọganla onífújì, ṣe lọ kọrin níbi ayẹyẹ àṣálẹ́ ìyìn ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún kan. Èyí bi àwọn àgbààgbà ìjọ náà nínú gidigidi.

Ètò ìjọsìn ọ̀hún ti wọ́n pè ní Ankara/Praise Night, ló wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kejìlá yíì, nínú ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ Land of Goshen Cathedral, lágbègbè Ogudu/Ọjọta, l’Ekoo, níbi tí wọ́n ti fìwé pe Portable, tó tún máa ń pe ará ẹ̀ ní Ìdààmú Àdúgbò, àti Pasuma sí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan, àti àwọn adarí ìjọ Ṣẹ̀lẹ́ kan korò ojú sí bí wọ́n ṣe pe àwọn tí kì í ṣe olórin ẹ̀mí síbi ètò ìjọsìn yìí, tí wọ́n sì kìlọ̀ gidigidi fún Portable láti má ṣe yọjú síbi ètò náà, àmọ́ Portable ati Pasuma lọ. Sùtánà Sẹ̀lẹ́ funfun kinniwin ni Portable wọ̀, àwọn méjéèjì sì kọrin gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lóde àríyá, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn náwó fún wọn, táwọn olólùfẹ́ wọ́n sì dárayá gidi.

Èyí ló fa wàhálà báyìí, nítorí ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ àwọn àgbààgbà tí Olùdarí ẹsìn ọhún kan nínú, tí wọn si ti n sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn.

Nínú fídíò kan tó bọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kejìlá yìí, Olùdarí ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ kan, Wòlíì Tayọ Ọkẹ, fi àìdùnnú rẹ̀ hàn sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó ní nǹkan àbùku àti ìtìjú pátápátá gbáà ni báwọn olórin wọ̀nyí ṣe wáá ṣeré ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn, ó ní irú nǹkan báyìí kò wáyé nínú àwọn ìjọ Ọlọ́run tó dé lẹ́yìn Sẹ̀lẹ́, bíi Rìdíìmù, Àpọ́sítólíkì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì mí-ìn.

Iná jólé Alao Akala, ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Iná jólé Alao Akala ní ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní airotẹlẹ ni iná dédé ṣẹ́yọ nínú ọ̀kan lára àwọn ilé tó n bẹ nínú ọgbà Gómìnà tẹ́lẹ̀rí ní ìpìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olóògbé Ọ̀túnba Adebayọ Alao Akala l’ówùúrọ̀ ọjọ́ Ajé.

Ọ̀kan lára àwọn olùgbé ilé náà, tí a fi orúkọ bò l’áṣìírí, fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn pé ní nnkan bíi aago méje ààbọ̀ sí mẹ́jọ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Olùgbé ilé náà ní, “Iná ẹ̀lẹ́ntíríìkì ló dé lójijì l’ówùúrọ̀ ọjọ́ náà tí ó sì jó ẹni kan. Ẹlòmíràn náà tún fi ara pa.”

Ṣùgbọ́n, ìròyìn kan tí a kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sọ pé èèyàn méjì ló kú nínú iná tó jó ọ̀hún .

Bákan náà ni ìròyìn sọ pé obìnrin méjì ló jóna nínú ilé náà, àmọ́ àwọn aláṣẹ kò tíì fìdí èyí múlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí iléṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára “Ogbomoso Insight “ṣe sọ, inú ilé alájà kan ọhún ni Olóògbé Àlàó Akálà gbé títí tó fi di igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún 2003.

Nínú oṣù kínní ọdún 2022 ni Ọ̀túnba Adébayọ̀ Àlàó-Akala jáde láyé.

Ó jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrin ọdún 2007 sí 2011

Láti ìgbà tí Gómìnà tẹ́lẹ̀rí náà ti re ibi àgbà n rè gìrìgìrì ẹsẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ní ilé náà, kí ó tó di pé iná sọ níbẹ̀ l’ówùúrọ̀ ọjọ́ Ajé.

Mo ti fẹ́yàwó kejì, mi ò ṣe mọ́- Ọkọ ìyàwó kan

Mo ti fẹ́yàwó kejì, mi ò ṣe mọ́- Ọkọ ìyàwó kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Túláàsì lóhun ó jókòó, ò lóò ráyè.
Iwájú Onídàájọ Abilékọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan tó wà ní Mapo, nílùú Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni àwọn tọkọ-taya méjì kan, Ọ̀gbẹ́ni Kazeem Jẹjẹ àti Abilekọ Kafilat Jẹjẹ, gbé ara wọn lọ. Kazeem ló gbé ẹjọ́ ìyàwó rẹ̀ lọ sile-ẹjọ ọ̀hún, nǹkan tó sì ń fẹ́ ni kí adájọ́ tú ìgbéyàwó tó wà láàrin àwọn méjèèjì ká.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Kazeem ti sọ pé, ‘‘Oluwa mi, ẹ̀bẹ̀ kan ṣoṣo ti mo bẹ̀ báyìí ni pé kẹ́ ẹ tú ìgbéyàwó ogún ọdún tó wà láàrin èmi àti ìyàwó mi yìí ká, kẹ́ ẹ sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ wáá bá mi lẹ́nu iṣẹ́ mi mọ́ láti fa wàhálà pẹ̀lú mi. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti sú mi pátápátá, mi ò ṣe mọ́ , kò sífẹ̀ẹ́ láàrin àwa méjèjì mọ́, ojoojúmọ́, ìjà ni nínú ilé. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ní nǹkan bíi ogun ọdún sẹ́yìn ni mo pàdé rẹ̀, gbogbo ìwà rẹ̀ ló tẹ́ mi lọ́rùn pátá, a ṣètò ìdána, bẹ́ẹ̀ ni mo sanwó orí rẹ̀ fáwọn ẹbí rẹ̀. Kò sóhun tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ mi tí mi ò fún wọn. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ rárá tá a fẹ́ra wa sílé tán tí ìyàwó mi yìí bẹ̀rẹ̀ sí í yọwọ́-kọ́wọ́, wàhálà ni lójoojúmọ́, nígbà tó tún yá ló bá tún ń lọ rojọ mi níta pé mo ti lo nǹkan ọmọkùnrin mi láti fi ṣòògùn owó lòun kò ṣe rí ọmọ bí látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó.

‘‘ Kò síbi tí mo lè dé báyìí, ṣe làwọn èèyàn á máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, bẹ́ẹ̀ kí í ṣe pé mo lówó lọ́wọ́ ká baà sọ pé lóòótọ́ ni mò lo nǹkan ọmọkùnrin mi fún oògùn owó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti lọ fẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ìyàtọ̀ nínú ìṣesí rẹ̀. Bí mo gbé igbá nínú ilé, mi ò mọ̀ ọ́n gbé ni, kò sígbà tí má a jáde kúrò nínú ilé, ṣe nìyàwó mi á máa tú gbogbo ẹrù mi láti wò ó bóyá mo lóògùn kan tí mo fi pamọ́ fún un. Nígbà tó yá ni bàbá ìyàwó mi gbà mí nímọ̀ràn pé kí ń lọ fẹ́yàwó kejì síta. Àmọ̀ràn pàtàkì ọ̀hún ni mo tẹ̀lé tí mo fi lọ fẹ́yàwó mìíràn síta báyìí. Ọlọ́run sì ti ṣe é, ìyàwó ọ̀hún ti bímọ fún mi, èyí tó fihàn gbangba pé irọ nìyàwó mi ń pa mọ́ mi pé mo ti lo nǹkan ọmọkùnrin mi láti fi ṣòògùn owó. Ẹ ṣáà bá mi lé e kúrò nínú ilé mi lohun tí mo ń fẹ́ báyìí ’’.

Níwọ̀n ìgbà tí kò sí olùjẹ́jọ́, ìyẹn Abilékọ Kafilat Jẹjẹ, nílé-ẹjọ́, adájọ́ ilé-ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 tó ń bọ̀ yìí.

Bákan náà ló kàn án nípa fáwọn akọ̀wé kóòtù pé kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n fún olùjẹ́jú níwèé ìpẹ̀jọ́, kó lè yọjú sílé-ẹjọ́ lọ́jọ́ tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ máa tún wáyé.

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà ni mo ta orí àti ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ – Akeem

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà ni mo ta orí àti ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ – Akeem

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni bá hùwà kòtọ́, ó di dandan kó fojú winá òfin.
Ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ní Eléwéeran, nílùú Abẹokuta, ìpínlẹ̀ Ògùn, ni Ọ̀gbẹ́ni Akeem Usman wà, níbi tó ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe láti lè fọwọ́ òfin mú gbogbo àwọn oníbàárà rẹ̀ gbogbo tó ń ta àwọn ẹ̀yà ara òkú fún, ní pàtàkì , ti ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University’ (OAU) kan, Olóògbé Quadry Salami, tó dẹ́mìí rẹ̀ lẹ́gbòodò láìpẹ̀ yìí, tó sì ta àwọn ibi pàtàkì ẹ̀yà ara rẹ̀ fáwọn oníṣẹ́ ibi kan.

Ohun tí a gbọ́ ni pé Alàgbà Salami tí i ṣe bàbá Quadry ló lọ fẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá agbègbè Kenta, nílùú Abẹokuta, lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2023 yìí, pé òun ń wá ọmọ òun, Quadry, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọkọ́ 100 level nílé -ẹ̀kọ́ ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University,’ (OAU). Bàbá náà ṣàlàyé fáwọn ọlọ́pàá pé láti ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí lòun ti fojú kàn án gbẹyin, ó lóun pe gbogbo fóònù rẹ̀, kò lọ, làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, S.P Ọmọlọla Odutọla, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fáwọn oníròyìn l’Ọ́jọ́rùú, ọjọ́ kẹfà, oṣù Kejìlá, sọ pé fúnra ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ní ìpínlẹ̀ Ògùn, C.P Abiọdun Alamutu, ló ṣaájú ikọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ agbègbè ‘Mile 6’, tó wà nílùú Ajebọ, láti lọ fọwọ́ òfin mú Akeem Usman, lẹ́yìn ti òhun tí wọ́n fi n wá fóònù olóògbé náà tọ́ka sí i pé ọwọ́ rẹ̀ ló wà. Wọ́n gbá a mú, ó sì mú wọn lọ síbi tó sìnkú olóògbé náà sí.

Akeem yìí ló tọ́ka sí oníṣèègùn kan, Ọ̀gbẹ́ni Ifadowo Niyi, tó pé ní ọ̀rẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ló jẹ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá pé òun pẹ̀lú Ifadowo làwọn jọ pín ẹ̀yà ara olóògbé náà fún òògùn owó.

Alukoro ní, ‘‘Akeem ti jẹ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá, ohun tó sọ ni pé òun pẹ̀lú Ifadowo làwọn jọ pa olóògbé náà, táwọn sì pín ẹ̀yà ara rẹ̀, orí olóògbé náà àti ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ni Ifadowo kó lọ, ó sì san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà sínú àkáùǹtì Akeem.

‘‘Lẹ́yìn náà ni Akeem ń ta àwọn ẹ̀yà ara olóògbé náà lẹ́yọkọ̀ọ̀kan fáwọn èèyàn tó nílò rẹ̀ láti fi ṣòògùn Àwúre. Lópin ohun gbogbo, Akeem lọ ri ìyókù mọ́lẹ̀ nígbà tí kò wúlò fún un mọ́.

‘‘ Kódà àwọn méjèèjì ti tún jẹwọ́ fáwọn ọlọ́pàá pé kì í ṣe olóògbé yìí làwọn kọ́kọ́ pa, wọ́n ní àwọn ti fìgbà kan pa àwọn mẹ́rin kan sẹ́yìn, táwọn sì ti forí wọn ṣètùtù Oṣólẹ̀’’.

Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alukoro ní ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ní ìpínlẹ̀ Ògùn tí lóun kò ní í fojú tó dáa wo àwọn ọ̀daràn gbogbo tí wọ́n fẹ́ sọ ìpínlẹ̀ Ògùn di ibùgbé wọn, àfi kí wọ́n fi agbègbè ọhún sílẹ̀ ní kíá.