Home Blog Page 33

Òsèré tíátà Laide Bakare se ìgbéyàwó e̩lé̩è̩ké̩ta

Òsèré tíátà Laide Bakare se ìgbéyàwó e̩lé̩è̩ké̩ta

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere tiata Naijiria, Laide Bakare ti setan lati se igbeyawo fun igba keta leyin meji akoko to kuna.

Eni odun metalelogoji naa se ikede yi ni oju awe Instagram re ni ojo Aje.

E ranti pe osere tiata yi saaju se igbeyawo pelu Olumide Kunfulire eni ti o bi omobinrin re Simi, fun ni 2008.

Ni 2013 Bakare tun se igbeyawo leekeji pelu gbajumo ilu Eko, Tunde Oriowo eni ti o bi omokunrin meji fun.

Amo sa, nigba ti o n kede igbeyawo re keta to n bo wa, osere naa fi fonran ara re pelu afesona re lede.

O fi oro ifori sori fonran naa, o ko o pe: “Ife je ohun to rewa. E darapo mo wa ni ojo Abameta yi, ojo kejo osu kejila ni AMORE GARDEN Lekki phase 1 ni aago marun irole. Mo n reti lati gbalejo gbogbo yin.”

 

 

 

Bí ò̩gá mi se mú ìrè̩wè̩sì bá o̩ko̩ mi láti máse fé̩ mi’ – Helen Paul

Bí ò̩gá mi se mú ìrè̩wè̩sì bá o̩ko̩ mi láti máse fé̩ mi’ – Helen Paul

Mary Fágbohùn

Ilumooka aderinposonu obinrin, Helen Paul ti ranti bi oga re lenu ise se gbiyanju lati mu irewesi ba oko re, Femi Bamisile, lati mase fe tabi se igbeyawo pelu re.

O ni oga oun so fun oko oun pe oun ko dara fun lati fe.

Oluko fasiti to fi ile US se ibugbe naa so pe oga asakoso omoniyan (Human Resources, HR,) re lenu ise gbiyanju lati ba ibasepo to wa laarin oun ati oko oun je.

O soro lori eto The Honest Bunch Podcast laipe yi ti oun pelu ilumooka osere tiata , Chinedu Ani Emmanuel, ti a mo si Nedu jo tuko re.

Paul wi pe, “Oga mi pe oko mi o wi pe, ‘Femi, se iru Helen yi lo fe fe? O ju iyen lo. Sugbon ti o ba fe gbadun re, o dara o!’

“Mo mu Femi lo si ofiisi mi nigba naa ni TVC, alakoso HR mi wo Femi o si wi pe, ‘’wo bi o se mo, agbejoro. Ki lo de ti o yan Helen?’”

E ranti pe Helen Paul ati Femi Bamisile se igbeyawo ni 2010. Ibasepo naa ni Olorun si bukun pelu omo meji.

Mo kó̩ èdè Yorùbá láti orí YouTube’ – Olorin Teni

Mo kó̩ èdè Yorùbá láti orí YouTube’ – Olorin Teni

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin, Teniola Apata, ti a mo si Teni, ti safihan pe o ko ede Yoruba lati ori YouTube.

Eni odun mokanlelogbon naa so pe bo tile je pe awon obi oun je Yoruba, oun ko lati so ede naa nipa wiwo fiimu Yoruba lori YouTube nigba ti oun wa ni Amerika.

O safihan eyi lori eto Zero Conditions laipe yi.

O wi pe, “Se e mo bi mo se ko lati so Yoruba? Nigba ti mo lo si Amerika ni. Mo ko lati ori YouTube. Mo n wo fiimu Yoruba gidi.”

Teni tun safihan ninu ijomitoro oro naa pe oun bere si ni mu oti ni odun 2021.

O ni saaju igba naa oun ko mu oti tabi fa siga ri.

Olorin naa tun fihan pe ipinnu oun lati bere si ni mu oti je “ere”.

 

 

Ìdí tí AY kò fi seré níbi eré mi – Basketmouth

Ìdí tí AY kò fi seré níbi eré mi – Basketmouth

Mary Fágbohùn

Gbajumo aderinposonu, Bright Okpocha, ti a mo si Basketmouth ti so pe oun fi iwe ipe ranse si alatako oun teleri ati akegbe oun, AY Makun lati wa si ibi ere oun ni Eko ni ojo Aiku yi.

O fi ose isesi yi han leyin ti o rawo ebe si AY ni gbangba eyi to fi opin si aawo odun metadinlogun to wa laarin won.

Amo sa, o ni, AY ko ni se ere tabi da awada kankan lori itage nibi ayeye naa ti yoo waye ni ile igbalejo Eko Hotel & Suites nitori pe won ti ko gbogbo re sile.

Nigba to n soro laipe yi ninu ijomitoro oro lori mohunmaworan Arise, Basketmouth wi pe, “AY ko si lori patako lati sere sugbon o ni tiketi. Yoo wa. Mo fi tiketi ranse sii ni ojo die seyin.

“Mo mo pe opolopo eniyan lo ti n beere pe, ‘se [AY] yoo dawada?’ ko si lori patako.

“Bi oro aridaju, mi o ni awon aderinposonu pupo lori patako. Mo mo pe Bovi ni yoo se afihan mi. Senator, Dan The Humorous ati Aproko lati Abuja ni yoo sere. Mo ni awon eniyan die lati Ghana pelu.

“AY ko le da awada nitori mo ti se eto mi sile. A n se igbasile re fun mohunmaworan nitori naa wakati meta pere ni. Ni bi a se n soro awon ti yoo dari ati ti won yoo se agbejade re ti wa ni orile ede yi fun bii ojo die seyin.

“Saaju ki won to de, a ti se bi eto naa yoo se ri sile. Kii se iru eto ti enikeni kan le gun ori itage. Kii se iru eto naa. Gbogbo re lo ni asiko. Aitase si asepe.”

Mo fé̩ràn àwo̩n o̩kùnrin tí wó̩n bá ń díbó̩n pé wo̩n kò fé̩ràn mi’ – Olorin Tyla

Mo fé̩ràn àwo̩n o̩kùnrin tí wó̩n bá ń díbó̩n pé wo̩n kò fé̩ràn mi’ – Olorin Tyla

Mary Fágbohùn

Olorin South African Tyla Laura Seethal, ti a mo si Tyla, ti safihan iru okunrin to feran.

Nigba to n soro lori eto Bianca, Tyla wi pe: “Mi o feran awon okunrin to ba wa ba mi. Mo feran awon okunrin to dabii pe won o feran mi. Won gbodo je kayeefi pelu.”

Eni ti a fa sile fun ife eye Grammy naa so itan to wa leyin oro re to lo kaakiri ‘Water.’

O wi pe: “Mo gbo orin naa [‘Water’] mo si yofe lesekan naa. Mo setan ni Cape Town, South Africa. Ni kete ti mo pari igbasile orin naa, mo n gboo lera lera. O dabii pe mo n so fun okunrin lati mase soro lasan, mo fe ki o fi nnkan ti o ni han mi. O dabii orin ti ko to sugbon orin igba ooru lasan ni.”

 

Mi ò kìí mu o̩tí, mò ń gbìyànjú láti jáwó̩ nínú sìgá fífà’ – Charly Boy

Mi ò kìí mu o̩tí, mò ń gbìyànjú láti jáwó̩ nínú sìgá fífà’ – Charly Boy

Mary Fágbohùn

Ilumooka olorin, Charles Oputa, ti a mo kaakiri si Charly Boy, ti safihan pe oun o ki n mu oti.

O ni oun ti n gbiyanju lati jawo ninu siga fifa pelu sugbon ni opo igba ni oun n ba ara oun ninu ijakadi pelu ikudun naa.

Nigba to n soro ninu ijomitoro oro pelu osere tiata Iyabo Ojo, olorin naa gba pe oun maa n mu waini to ni oti die sugbon o duro lori pe oun kii se omutipara.

Eni odun metalelaadorin naa so pe irisi oun niise pelu ajogunba ati igbe aye oun, o ni awon obi oun ati awon baba nla oun gbe aye fun ojo pipe.

“Mo n gbiyanju lati jawo ninu iwa [siga] fifa. Sugbon ko dara fun mi to. Mo ti gbiyanju lati duro fun bii odun meje ri. Mo jawo nigba kan, mo tun pada sibe.”

Ṣùrútù ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ olóògbé Akérédolú bínú sáwọn akọ̀rọ̀yìn

Ṣùrútù ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ olóògbé Akérédolú bínú sáwọn akọ̀rọ̀yìn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjinníà Ṣèyí Mákindé, àti akẹgbẹ́ ẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti ṣàbẹ̀wò sí ìdílé Olóògbé Rótìmí Akérédolú, Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó tó jáde láyé.

Àbẹwò ọ̀hún, èyí tí wọ́n ṣe sílé Akérédolú, tó wà ní Idi-Iṣin, ládùúgbò Jericho, n’Ibadan, láti bá ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo mọlẹbi Gómìnà tó jáde láyé náà kẹ́dùn ló wáyé l’Ọjọ́rùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023.

Ṣùgbọ́n aáwọ̀ kan ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Gómìnà tó dolóògbé náà pẹ̀lú àwọn oníròyìn tó lọ síbẹ̀ láti mójútó ohun tó ń lọ.

Nígbà tí àwọn oníròyìn tẹlé àwọn Gómìnà méjèèjì náà wọnú ọgbà ilé ọ̀hún , níṣe làwọn ọmọ olóògbé fa ìbínú yọ, wọ́n ní kí àwọn oníròyìn jáde nínú ilé àwọn kíákíá, nítorí ilé tí Akérédolú fowó ara rẹ̀ kọ lèyí, kì í ṣe ilé ìjọba ti ẹnikẹ́ni kàn lè máa wọ̀ bó bá ṣe fẹ́.

Àwọn kan nínú ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ olóògbé ni wọ́n pẹ̀tù sí àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú, tí ọ̀rọ̀ náà kò fi di wàhálà ńlá.

Ariwo èdè àìyédè yìí ló jọ pé àwọn Gómìnà méjèèjì gbọ́ tí wọ́n fi yára jáde kúrò nínú ọgbà ilé náà láti bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ .

Gómìnà Abdulrazak, tó ṣàbẹ̀wò ọ̀hún lórúkọ gbogbo Gómìnà Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi alága ìgbìmọ̀ wọn lórílẹ̀-èdè yìí, ṣàpèjúwe ikú Akérédolú gẹ́gẹ́ bíi ìṣẹ̀l ìbànújẹ ńlá.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, Ẹnjnníà Mákindé tí í ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú rere tó ní ìgboyà láti jà fún ààbò àwọn aráàlú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ èmi gẹ́gẹ́ bíi ẹnìkan, àdánù ńlá ni ikú Arákùnrin Akérédolú jẹ́ fún mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan la ti jọ ṣe papọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rẹ́ àti tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Nígbà tá a dá àjọ elétò ààbò Àmọ̀tẹ́kùn sílẹ̀ , ipa takuntakun ni wọ́n kó lórí ọ̀rọ̀ yẹn.

“Bákan náà l’Arákùnrin Akérédolú kópa pàtàkì nígbà tí à n jà fún pé kí ipò Ààrẹ wá sí apá Ìwọ̀-oòrùn Gúúsù orílẹ-èdè yìí, àwọn pẹ̀lú Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra nígbà kan rí ni wọ́n jọ darí ìpàdé náà nílé ìjọba.

“ Wọ́n (Akeredolu) jẹ́ onígboyà èèyàn. Wọn kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lọ́kàn wọn ni wọ́n máa sọ ọ́. Ó kàn jẹ́ pé inú èèyàn kò lè dùn pé kí ẹni tí èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí kú ni, ọpẹ́ ló yẹ ká máa dá fún Ọlọ́run nítorí ipa rere tí wọ́n kó láyé àwọn èèyàn kan, àti fún ìdàgbàsókè àwùjọ”.

Ayedatiwa Gómìnà tuntun ìpínlẹ̀ Òǹdó, kéde àwọn tí yóó bá a ṣiṣẹ́ pọ̀

Ayedatiwa Gómìnà tuntun ìpínlẹ̀ Òǹdó, kéde àwọn tí yóó bá a ṣiṣẹ́ pọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àwọn àgbà tó sọ pé ẹni tó ṣojú kò dà bíi ẹni tó ṣẹ̀yìn, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọnarébù Lucky Orimisan Ayédatiwa, ti kéde odidi ọjọ́ mẹ́ta gbáko láti fi ṣọ̀fọ̀ ikú ọ̀gá rẹ̀, Arákùnrin Rótìmí Akérédolú, ẹni tó jáde láyé l’Ọ́jọ́rùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún yìí.

Ayédatiwa ṣe ìkéde yìí lásìkò tí wọ́n ń búra fún un gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tuntun lọ́fíìsì ìjọba tó wà ní Alagbaka, nílùú Akurẹ, ní nǹkan bíi aago márùn-ún kọjá ìṣẹ́jú mẹrìnlá l’Ọjọrùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023.

Nínú ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ rẹ̀ ní kété tó gba èèkù idà ìṣàkóso, Ayedatiwa ni pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn lòun fi ń tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ńlá tó yí kan òun nítorí ikú tó wọlé mú ọ̀gá òun lọ lójijì.

Ó ní òun bá gbogbo ẹbí Akérédolú, Ọlọ́wọ̀ tìlú Ọ̀wọ̀, Ọba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye, àti gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ Òǹdó pátápátá kẹ́dùn lórí ikú ẹni wọn tó lọ.

Lára àwọn tó wà ní kàlẹ̀ lásìkò ìbúra wọṣẹ́ ọ̀hún ni: Olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọnarebu Ọlamide Ọladiji, Akọ̀wé ìjọba, Abilékọ Ọladunni Odu, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ade Adetimẹhin, àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aṣèjọba àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC.

Ó ní àdánù ńlá ni ikú Aketi jẹ́ fóun, nítorí láti ọdún 2012 ni àwọn ti jọ wà, ìyẹn lásìkò tó kọkọ gbé àpótí láti díje dupò Gómìnà, bó ṣe fìdí rẹmi nígbà náà ló ní kòdí àjọṣepọ̀ àwọn lọ́wọ́ rárá pẹ̀lú bí àwọn tún ṣe jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ fún àṣeyọrí rẹ̀ lọ́dún 2016, tó sì jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà fún ìgbà àkọ́kọ́ .

Ó ní ṣe làwọn jọ wà títí kó tóó wá mú òun gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ lọdún 2020, lásìkò tó ń díje fún sáà kejì.

Gómìnà tuntun yìí ní kò sí àní -àní pé Aketi ti fipa rere lélẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó ṣe ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, tí òun náà sì ṣetán láti tẹ̀síwájú níbi tí ọ̀gá òun bá iṣẹ́ dé.

Ó rọ gbogbo àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Òǹdó láti ṣàtìlẹ́yìn fún òun, kí wọ́n sì tún máa gbàdúrà fún òun, kí iṣẹ́ náà baà lè túbọ̀ rọrùn láti ṣe.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí Gómìnà Lucky Ayedatiwa gba èèkù idà ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Òǹdó ló ti kéde ìyànsípò àwọn èèyàn kan gẹ́gẹ́bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀.

Ní ìbámu pẹ̀lú àtẹ̀jáde tí Ìgbákejì olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọmọkùnrin Sẹgun, fi síta lálẹ́ Ọjọ́rùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejiìlá, ọdún 2023 yìí, ó ní Gómìnà ti fọwọ́ sí ìyànsípò àwọn èèyàn wọ̀nyí, tí iṣẹ́ wọn sì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ lẹ́yẹ-ò-sọkà.

Àwọn márùn-ún tí wọ́n kéde ìyànsípò wọn ni: Ọmọọba Ebenezer Adeniyan, ẹni tí yóó jẹ́ Akọ̀wé ìròyìn tuntun fún Gómìnà Ayédatiwa, Ọ̀gbẹ́ni Smart Ọmọdunbi, Olùbádámọ̀ràn fún gómìnà lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, àti Abire Sunday Olugbenga, Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rọ ayélujára.

Àwọn yòókù ni, Omidan Motunrayọ Oyedele, Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún fọ́tò yíyà, àti Dókítà Temitayọ Iperepolu, ẹni tí yóó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Gómìnà nílé ìjọba.

Ghali Na’Abba,olórí àwọn aṣọ̀fin tẹ́lẹ̀, jáde láyé

Ghali Na’Abba,olórí àwọn aṣọ̀fin tẹ́lẹ̀, jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Baà kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Lásìkò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń dárò ikú Olóògbé Oluwarotimi Akérédolú tí i ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, èyí tó ṣẹlẹ̀ láfẹ̀ẹ̀mọ́jú Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdílọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023 yìí, èèkàn olóṣèlú apá Òkè-ọya ilẹ̀ wa tó jẹ́ olórí àwọn ọmọléègbìmọ aṣojú-ṣòfin l’Abuja tẹ́lẹ̀, Alaaji Ghali Na’Abba, náà tún ti kí ayé pé ó dìgbòóṣe.

A gbọ́ pé òwúrọ̀ ọjọ́ Wẹ́sìdeè yìí kan náà ni ọkùnrin ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin (65) yìí mí èémí ìkẹyìn ní ọsibítù kan nílùú Àbùjá, tí i ṣe olú-ìlú ilẹ̀ wa.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣe sọ ọ́ di mímọ̀, wọ́n lo ti ṣe díẹ̀ tí àìsàn burúkú kan ti ń bá Na’Abba fínra, kí gbogbo ẹ̀ tó wáá já síkú yìí. Ìgbà kan wà tí wọ́n gbé bàbá náà lọ sílùú òyìnbó fún ìtọ́jú. Ọ̀pọ̀ oṣù ló sì fi wà lọhun-un, níbi tí wọ́n ti fún un ní ìtọjú tó péye, ìgbà tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ló padà sílé.

Àmọ́ lẹnu àìpẹ yìí ni àárẹ̀ mí-ìn tún ta lé olórí àwọn aṣòfin tẹ́lẹ̀rí yìí, èyí tó yọrí sí ikú rẹ̀.

Ẹ ò rántí pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, ni Alagba Ghali Na’Abba, ọdún 1999 tí ètò òṣèlú dẹ̀mókírésì ẹlẹ́ẹ̀kẹrin bẹ̀rẹ̀ ni ọkùnrin náà gbáàpótí ìbò, tó sì wọlé sípò aṣojú-ṣòfin Kano Municipal Federal Constituency, nígbà tí Olóyè Oluṣẹgun Ọbasanjọ di Ààrẹ ilẹ̀ wa.

Gẹ́rẹ́ tí wọ́n yọ Olórí àwọn aṣojú-ṣòfin ìgbà náà, Salisu Buhari, nípò, lórí ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí Fásitì Toronto rẹ̀ tó jẹ́ ayédèrú ni Na’Abba di olórí àwọn aṣojú-ṣòfin, ó sì wà nípò náà láti 1999 títí di ọdún 2023, tí ètò ìdìbò mí-ìn wáyé.

Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ahmadu Bello, tó wà ní Zaria, ni olóògbé yìí ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òṣèlú lọ́dún 1979.

Aláṣẹ Iléeṣẹ́ Crime Alert wẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn jìbìtì

Aláṣẹ Iléeṣẹ́ Crime Alert wẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn jìbìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹ̀wọ̀n ò jọlé o, gbogbo
ìgbà tí a ó bá lò lókè èèpẹ̀, kí á má rógun ẹ̀wọ̀n láyé e wa.
Ní báyìí, Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Crime Alert Security Network, ní Ìbàdàn, Olaniyan Gbenga Amos ti dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí Iléẹjọ́ tó n jókòó nílùú Ìbàdàn ní ó jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì.

Ẹ̀wọ̀n ọdún márùndínlọ́gọ́rin ni Adájọ́ Bayo Taiwo ti ilé ẹjọ́ gíga tó n jókòó nílùú Ibadan, gbé kalẹ̀ fún olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Crime Alert Security Network, Olaniyan Gbenga Amos lórí ẹ̀sùn jìbìtì ọ̀hún.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé Olaniyan ni ọwọ́ àjọ EFCC tẹ ní ọdún 2020 lẹ́yìn tó lu ọ̀pọ̀ èèyàn ní jibiti owó ìdókòwò pẹ̀lú iléeṣẹ́ rẹ̀.

Ó se ìlérí pé òun yóó dá owó àti èlé orí owó padà fún àwọn tó bá dókoòwò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ è, tí kò sí rí owó náà san padà.

Èsùn márùndínlógójì ni EFCC kà sí i ẹsẹ̀ Olaniyan níwájú iléẹjọ́.

Nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale gbé síta lọ́jọ́ Ìsẹ́gun, ó ní Olaniyan àti iléeṣẹ́ rẹ̀, Detorrid Heritage Investment Limited ni wọ́n gbé lọ iléẹjọ́ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdún 2023.

Ọdún tó kọjá , ẹlẹ́rìí àjọ EFCC, Juliet Odogu sọ fún ilé-ẹjọ́ pé ó tó igba níye àwọn èèyàn tí Olaniyan lù ní Jìbìtì owó tó tó àádọ́jọ mílíọ̀nù náírà.

Ó ní àwọn èèyàn san ẹgbẹ̀rún márùn un náírà si mílíọ̀nù mẹ́sàn án náírà fún Olaniyan lẹ́yìn tí wọ́n báa dòwòpọ̀.

Bákan náà ló se àfihàn ìwé àkọsílẹ̀ tí àwọn èèyàn náà fi san owó fún ileeṣẹ Olaniyan fún Ilé-ẹjọ́ dókòwò lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà.