Home Blog Page 29

Lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀  ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ẹlẹ́wọ̀n fẹṣẹ̀ fẹ.

Lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀  ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ẹlẹ́wọ̀n fẹṣẹ̀ fẹ.

Gbọ́láhàn Quseem

Ìjoba orílẹ̀-èdè Haèiti ti kéde kónílégbélé oní wákàtí méjìléláàdọ́rin lẹ́yìn tí àwọn agbébọn kan yawọ ọgbà ọ̀wọ̀n Port-au Prince.

Eeyan mejila lo padanu ẹmi wọn, ti ẹlẹwọn to le ni ẹgbẹrun mẹrin si sa kuro lọgba ẹwọn naa.

Awọn olori ikọ agbebọn naa, ni awọn gbe igbesẹ yii lati fi tipatipa jẹ ki olootu ijọba orilẹ-ede naa, Ariel Henry, ẹni to wa ni oke okun, kọwe fipo rẹ silẹ.

Ikọ agbebọn naa n gbero lati gba isakoso ida ọgọrin ọgba ẹwọn Port-au-Price.

Lati ọdun 2020 ni irufẹ ikọlu yii ti n waye, to si ti ṣekupa ọpọlọpọ awọn eeyan.

Atẹjade kan ti ijọba fi lede salaye pe ọgba ẹwọn meji, ọ̀kan ni olu ilu orilẹede naa, ati ọgba ẹwọn mii to sun mọ ọ , Croix des Bouquets ni awọn agbebọn naa kọlu lopin ọsẹ to kọja.

Lara awọn to wa ni atimọle ni ọgba ẹwọn Port-au-Prince ni awọn ọmọ ikọ agbebọn to lọwọ ninu iku Aarẹ Jovenel Moise lọdun 2021.

Akọroyin AFP to ṣe abẹwo si ọgba ẹwọn Port-au-Prince ni oun ri to oku eeyan mẹwaa nilẹ, ti awọn kan si wa pẹlu apa ibọn lara.

O ni ilẹkun ọgba ẹwọn naa wa ni ṣiṣi silẹ, ti ko si daju pe ẹnikẹni wa lọgba ẹwọn naa.

Iroyin nipa rogbodiyan ọhun bẹrẹ ni Ọjọbọ ọsẹ to kọja, nigba ti Olootu ijọba orilẹede Haiti, rin irinajo lọ si Nairobi lati lọ jiroro bi wọn yoo ṣe gbe ikọ ologun Kenya wa si Haiti.

Olori ikọ agbebọn naa, Jimmy Cherizier, ẹni ti ọpọ tun mọ si Barbecue, kede pe igbesẹ naa da lori ọna lati yọ oun kuro nipo gẹgẹ bi olori.

Ileeṣẹ ọlọpaa Haiti ti ransẹ si ileeṣẹ ologun lati kun wọn lọwọ fun ipese aabo ni olu ilu, sugbọn awọn agbebọn ṣe ikọlu naa lọjọ Satide.

Ileeṣẹ iroyin Reuters salaye pe, ilẹkun ọgba ẹwọn naa wa ni sisi, ti ko si ẹsọ alabo kankan ni ayika lọjọ Aiku,

Àwọn èèyàn kan lo ayédèrú ìbuwọ́lù Buhari gbowó tùùlù ní CBN

Àwọn èèyàn kan lo ayédèrú ìbuwọ́lù Buhari gbowó tùùlù ní CBN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kánjúà ń dàgbà,ọgbọ́n inú rẹ̀ ń rewájú.
Ìjọba Nàìjíríà ti ta ọlọ́pàá Interpol lólobó láti bá àwọn nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́ta kan tí wọ́n ṣe àdàmọ̀dì òǹtẹ̀ ààrẹ àná ní Náíjíríà, Muhammadu Buhari láti fi gba owó tùùlù jáde ní akoto owó ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, CBN.

Ìwé àkọránṣẹ́ kan tí ìjọba kọ sí Interpol ni wọ́n ti ní àwọn afurasí náà tún ṣe àdàmọ̀dì òǹtẹ̀ akọ̀wé ìjọba sí Ààrẹ Buhari nígbà náà, Boss Mustapha láti gba owó $6.23m ní CBN.

Àwọn afurasí náà gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ọ̀hún ṣe tò ó ni Odoh Ocheme, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ CBN, Adamu Abubakar àti Imam Abubakar.

Olùwádìí pàtàkì kan tí Ààrẹ Bola Tinubu gbà láti ṣèwádìí àwọn ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ́ CBN, Godwin Emefiele ló kọ lẹ́tà náà sí Interpol gba ọ́fíìsì ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà.
Wọ́n ní ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Odoh Ocheme, ẹni tó ti na pápá bora báyìí àti àwọn méjì yòókù náà gbìmọ̀ pọ̀ láti jí owó tó tó bílíọ̀nù mẹ́sàn-án náírà látara ṣiṣẹ́ ayédèrú ìwé kan èyí tí wọ́n ní Buhari ló buwọ́lu ìwé náà.

Lẹ́tà náà ṣàfihàn pé ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti ṣetán láti ka ẹ̀sùn mẹ́fà sáwọn ènìyàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ́rùn nílé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Abuja àmọ́ tí àwọn ènìyàn náà ti na pápá bora.

Ẹ̀wẹ̀, Adájọ́ Inyang Ekwo ti ilé ẹjọ́ gíga Abuja ti gbé àṣẹ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kìíní ọdún 2024 pé kí wọ́n fi òfin gbé àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà.

Godwin Emefiele ló ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Maitama fẹ́sùn ṣíṣe owó ìlú báṣubàṣu èyí tí ìjọba àpapọ̀ fi kàn-án.

Ikú Sisí Quadri, àwọn àgbàgbà òṣèré mómi lójú pòròpòrò

Ikú Sisí Quadri, àwọn àgbàgbà òṣèré mómi lójú pòròpòrò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kò sí, kóówá n relé bọ́jọ́ bá tipé.
Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá ò níín sinmi àròyé .
Láti ọjọ́ Ẹtì tí ìròyìn ikú òjìji tó pa gbajúmọ̀ onítíátà nnì Tọlani Quadri Oyebamiji, tí gbòde kan làwọn èèyàn ti ń ṣe dárò adẹ́rìn-ín-pòṣónú yìí.

Yàtọ̀ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń gbádùn bó ṣe máa ń bú àwọn èèyàn bíi ẹni láyin nínú fíìmù, àwọn àgbààgbà lágbo tíátà Yorùbá náà sọ̀rọ̀ nípa Sisi Quadri lójú òpó ayélujára Sítágíràmù wọn.

Lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó ṣèdárò ikú Sisí Quadri ni Biola Bayo, Ibrahim Yẹkini, Odunlade Adakola, Mr Latin, Ibrahim Chatta, Regina Chukwu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ibrahim Yẹkini sọ pé “Ilé ayé ilé asán.”

Ní ti Bọlaji Amusan, Mr Latin, ó ní kí Olúwa fún un nísinmi ayérayé.

Regina Chukwu ni “Kò burú o. Bẹ́ẹ̀ mo ṣì ń ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́jọ́ mélòó kan sẹ́yìn o, láì mọ̀ pé ó ń gbìyànjú láti ṣẹ́gun ikú lọ́wọ́.”

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ò mọ̀ pé mo kọ́ṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi aṣojúlóge fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ aṣojúlóge ni mo ń ṣe fáwọn onítíátà tẹ́lẹ̀. Ó dàárọ̀ o, Ọ̀gá.”

Fẹmi Adebayọ Salami, ní ọjọ́ burúkú ni ọjọ́ ikú olóògbé náà jẹ́, ó sì gbàdúrà kí Ọlọrun tu ìdílé rẹ̀ nínú.
Ọdunlade Adekọla ni “Èyí ba ni nínú jẹ́ púpọ̀ . Ọrun ire, Sisi Quadri.”

Ibrahim Chatta, Saidi Balogun, Laide Bakare, àtàwọn gbajumọ òṣèré tíátà mii tún banujẹ lórí ikú Sisí Quadri.

Ikú òṣèré tíátà Yorùbá nnì,Tolani Quadri Oyebamiji, Sisí Quadri sì ń ṣe ọpọ olólùfẹ rẹ̀ bí ìrànrán.

Káàkiri ojú òpó ayélujára làwọn èèyàn ti ń bèèrè pé kí ló ṣokùnfà ikú rẹ̀ àti pé ipò wo ní ó wà tí ọlọjọ fi dé báa.

Nígbà ti oníròyìn kàn sí ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ kéde ikú rẹ̀ lójú òpó ayélujára Otunba

Adekunle Abolade tí gbogbo ayé mọ sí Dodo Èdè.

Lójú òpó rẹ̀ tó ti kéde ikú Ṣiṣi Quadri, ó sọ pé oun ṣẹ́ṣẹ wo fiimu ti Sisi Quadri ti kópa nínú rẹ̀ Anikulapo tán ni ló wùúrọ òní.

Ó ní Sisí Quadri kú nínú fíìmù náà tó sì ti wá padà jáde láyé lójú ayé gangan.

Nínú àlàyé rẹ̀ tó ṣe Dodo Èdè ní ìlú Ogbomosho ni Sisí Quadri dákẹ sí àti pé ní ilé ìwòsàn Fásitì Ladoke Akintola ló ti ń gba ìtọjú lórí àìlera tó ń kojú lẹnu lọọlọ yìí.

Alága nígbà kan rí fún ẹgbẹ́ sọrọ sọrọ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun yi sọ pé lọwọlọwọ báyìí òun wà lójú ọnà Iwo sí Ogbomosho láti lọ wo irú ètò tó yẹ ní ṣíṣe fún ẹ̀yẹ ìkẹhìn olóògbé

Ikú Sisí Quadri dùn mí nítorí mó sẹsẹ wò fíìmù Anikulapo tàn níbi tó tí ku nínú rẹ̀ ní.

Lára ìbéèrè tí àwọn èèyàn ń bèèrè nípa ikú Sisí quadri ni pé wọ́n fẹ́ mọ irú ikú tó mu ẹmi rẹ̀ lọ.

Báwọn kan ṣe ń sọ pé àìsàn kídìrín ni àwọn mii ń sọ pé àìsàn ráńpẹ́ ló ṣokùnfa ìdágbére rẹ̀
fáyé.

Dòdò Èdè sọ fún akọròyìn pé òun kò lè sọ pàtó ohun tó ṣokùnfa ikú rẹ̀ àmọ́ ó ti tó ọjọ́ mélòó kan tó wà ní ilé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọjú ní Ogbomoso.

”Ogbomoso ló dákẹ sí. Ibẹ̀ ni wọ́n sì ti pe mi láti sọ. Lọ́wọ́ báyìí òkú rẹ̀ wà ní àyè ìgbókùúpamọ́sí táa mọ sí mọ́ṣùárí. Kí Ọlọ́run tẹ́ẹ sí afẹ́fẹ́ rere”

Ó fikún-un pé àwọn mọ̀lẹ́bí ni wọ́n wà nípò láti sọ ohun tó pa Sisí Quadri.

Ó ní ikú rẹ̀ jẹ́ ìbànújẹ ńlá fún àwọn èèyàn ìlú Ìwó tó jẹ́ ibi tí wọ́n ti bí Sisí Quadri.
Ó jẹ́ ká mọ wí pé Sisí Quadri fi bàbá sílẹ , ìyàwó àti ọmọ.

E̩gúngún ń rìn ní bèbè è̩wò̩n

E̩gúngún ń rìn ní bèbè è̩wò̩n

Yínká Àlàbí

Egungun ti gbogbo eniyan mo̩ si ‘ara o̩run’ lo ma ti n rin ni bebe e̩wo̩n aye bayii.
Ni ilu Agege ni ipinle̩ Eko ni awon egungun kan ti ko ara wo̩n jo̩ ti won si be̩re̩ si ni wo̩ igboro ka.
Ni o̩wo̩ iro̩le̩ ti wo̩n jade naa ni iroyin kan awo̩n o̩lo̩paa E̩le̩re̩ lara pe̩lu o̩se̩ buruku ti n se ni ilu. Wo̩n be̩re̩ si ni fi e̩ku eegun hale̩ mo̩ awo̩n eniyan, ti awo̩n o̩lo̩ja yii ba ti sare kuro nidii o̩ja ni awo̩n kan a ti pale̩ oja wo̩n mo̩.
E̩yi ya awo̩n ara adugbo Agege le̩nu,wo̩n si sare gba o̩ga o̩lo̩paa agbegbe naa laago, ni eyi ti o mu ki awo̩n o̩lo̩paa pale̩ wo̩n mo̩ ni kia.
O̩ga o̩lo̩paa E̩le̩re̩ ni wo̩n maa foju ba ile e̩jo̩ fun e̩sun ole jija, dida ilu ru ati e̩sun miiran ti awo̩n ara ilu ba tun mu wa ki awo̩n to pa faili wo̩n de.
Oga o̩lo̩paa ni adoju ti asa ni awo̩n eniyan naa nitori pe Egungun kii dede jade laisi o̩dun tabi etutu kankan, eyi si maa je̩ ki awo̩n foju wo̩n wina labe̩ ofin ile̩ wa lati le ko̩ awo̩n miiran to n pale̩mo̩ iwa buruku be̩e̩ lo̩gbo̩n.

Ẹ se sùúrù fún Tinubu, ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti kú kó tó gbàjọba lọ́wọ́ Buhari – Fayose.

Ẹ se sùúrù fún Tinubu, ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti kú kó tó gbàjọba lọ́wọ́ Buhari – Fayose.

Gbọ́làhàn Quseem

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì tẹ́lẹ̀, Ayodele Fayose, ti sọ pé ó yẹ kí àwọn aráàlú gbóríyìn fún Ààrẹ Bola Tinubu fún àwọn akitiyan rẹ̀ láti sọ ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà jí padà.

Fayose lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels, nibi to ti ni ọrọ aje Naijiria ti di oku ki Tinubu to gba ijọba.

O ni “Oku ni ọrọ aje Naijiria ki ijọba to bọ sọwọ Tinubu, nitori naa, ohunkohun ti a ba n sọ, o yẹ ka kan sara si i.”

Ti ẹ ko ba gbagbe, lẹyin ti Aarẹ Tinubu fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro ni gbogbo nnkan bẹrẹ si n gbowo lori ni Naijiria, ti awọn araalu si n kigbe ebi.

Eyi lo mu ki ọpọ araalu maa sọ pe ijọba Tinubu ko san awọn nitori ebi ti wa niluu, ti awọn mii si n sọ pe mariwo ni ijọba Buhari to kọja, lai mọ pe egungun gan ni ijọba Tinubu yoo jẹ.

Amọ ṣa, Fayose ti sọ pe Tinubu n gbiyanju, o si n ṣe awọn ohun to yẹ lati ṣatunṣe si awọn nnkan ti ijọba Buhari ti bajẹ ni Naijiria.

Gomina Ekiti tẹlẹ naa sọ pe ko si iṣẹ iyanu kankan ti Tinubu le ṣe lati tun ohun ti ijọba ana ti bajẹ ṣe laarin oṣu mẹsan an pere.

Ninu ifọrọwerọ naa ni Fayose ti naka abuku si ijọba Muhammadu Buhari.

O ni o jẹ ohun ibanujẹ pe ijọba Buhari ti fa ọwọ aago ilọsiwaju Naijiria sẹyin gidi, iya rẹ si lawọn araalu n jẹ loni yii.

Fayose ni “Ẹ wo ọdun mẹjọ ti Aarẹ Buhari lo lori oye, ti Tinubu ba tilẹ ni afojusun rere fun Naijiria, bawo ni yoo ṣe ṣe? Ẹ wo gbogbo gbese to jẹ silẹ, bawo ni yoo ṣe yanju rẹ?”

Gomina tẹlẹri ọhun wa rọ Aarẹ Tinubu ko dẹkun ati maa gboriyin fun Buhari nitori Buhari kii ṣe ibukun fun Naijiria.

Lẹyin naa lo rọ Tinubu ko gbagbe nipa Buhari, ko si ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe o mu ileri to ṣe fun awọn ọmọ Naijiria lasiko ipolongo ibo rẹ ṣẹ.

Èsì ìpàdé Ààrẹ Tinubu pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ́ Afenifere rèé lórí wàhálà tí n bẹ ní ‘lùú.

Èsì ìpàdé Ààrẹ Tinubu pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ́ Afenifere rèé lórí wàhálà tí n bẹ ní ‘lùú.

Gbọ́láhàn Quseem

Ààrẹ Bola Tinubu ti ṣe àbẹwò sì adari ẹgbẹ Afenifere, Pa Reuben Fasoranti fún igbà akọkọ lẹyìn ti o di ààrẹ orilẹede Naijiria

Àbẹwò ọhun waye ni ilu Akure ni ọjọ kejidinlogbon oṣù keji ni ilé adari ẹgbẹ naa.

Ipade naa to wayẹ ni atilekun mori pelu adari Afenifere ati awọn agba-gba ẹgbẹ naa bi Bashorun Sehinde Arogbofa, Akọwe ìjọba àpapọ̀ tẹlẹ Oba Olú Falae

Lẹyìn wákàtí kan ti ipade naa bẹrẹ, ààrẹ Tinubu gbera kuro ni ilé adari ẹgbẹ Afẹ́nifẹ́re.

Agbẹnusọ fún ẹgbẹ Afenifere Ogbeni Jare Àjàyí sọ pẹ awọn ẹgbẹ Afenifere ba ààrẹ Tinubu sọrọ lórí atunto orileede Naijiria ni ẹka òṣèlú, ọrọ ajé, ìbarà eni gbepọ ati awọn ẹka miran.

Laara awọn nnkan ti ẹgbẹ Afenifere bẹrẹ fún nipa atunto orileede Naijiria ni ki awọn agbegbe lẹtọ sì ànfàní lori awọn ọun alumọni ti ìjọba ba ri l’agbegbe wọn

” Gẹgẹ bi o ṣe wa bayi, awọn agbegbe ti orileede Naijiria tin ri epo rọbi lo ni ànfàní sì awọn owo kan sùgbọ́n eleyi ko gbọdọ̀ wa fún epo rọbi nikan, awọn àgbègbè ti ohun alumọni ilẹ̀ wa naa lẹtọ lati maa gba awọn owo kan naa lowo ìjọba gege bi ẹtọ.”

Ogbeni Jare Àjàyí tun sọ pe ààrẹ Tinubu fi daa Pa Fasoranti ati awọn agba Afenifere loju pe ìnira ti awọn ọmọ Nàìjíríà n koju lọwọ yóò di ohun afiseyin teegun n fiṣo.

O ni “Ààrẹ sọ fun wa pe : ṣe ni mo gbàdúrà lati di ààrẹ orilẹede Naijiria . Mo kọrin, mo si jo si. Gbogbo idojukọ yi ni mo ti gbaradi fún. Gẹgẹ bi mo ṣe ṣe ni ilu Eko ti o fi di ipinlẹ ti ọrọ ajé rẹ ni idagbasoke julọ ni ilẹ Africa mo fé fi ipinlẹ to muna doko silẹ fún atunto”

Àjàyí sọ pẹ ààrẹ Tinubu gbe iwe moyege ti INEC fún wa hàn adari ẹgbẹ Afenifere.

Gomina ipinlẹ Ondo Lucky Aiyedatiwa ati Gomina ana dokita Olusegun Mimiko wa lara awọn to peju sibi ìpàdé naa.

Àwọn wo ni ó jẹ ànfààní Ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ pín fáwọn aráàlú?

Àwọn wo ni ó jẹ ànfààní Ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ pín fáwọn aráàlú?

Gbọ́láhàn Quseem

Ijọba orileede Naijiria ti gbe awọn amuyẹ ti araalu gbọdọ ni, ko to di pe wọn le jẹ anfaani owo iranwọ ẹgbẹrun marundinlọgbọn (N25,000) naira ti wọn fẹẹ gbe sita.

Owo naa ni ijọba sọ pe idile mẹẹdogun ni yoo jẹ anfaani yii, ati pe wọn gbọdọ ni awọn amuyẹ to ba ilana ti wọn ka silẹ mu, bi igbe aye irọrun ṣe n le koko.

Bi awọn araalu ṣe n pariwo pe ilu ko fararọ, Aarẹ Bọla Tinubu ti sọ pe niṣe ni wọn yoo bẹrẹ sii fi awọn owo naa ranṣẹ sinu apo ile ifowopamọ awọn alaini ati awọn to ku diẹ kato fun.

Ko to di pe wọn da awọn eto owo iranwọ to wa nita tẹlẹ duro, ọmọ Naijiria ti ko din ni miliọnu mẹta ni wọn ti n jẹ anfaani naa.

Ṣugbọn nitori awọn nnkan ti ko fararọ niluu, ijọba ni lati kede idaduro awọn eto iranwọ naa, sibẹ ijọba ni awọn fẹẹ le alekun awọn to n jẹ anfaani yii si idile miliọnu mẹẹdogun.

Minisita fọrọ eto iṣuna ati alakoso minisita fọrọ eto ọrọ aje, Wale Ẹdun ninu ifọrọwerọ to ṣe laipẹ yii pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels jẹ ko di mimọ pe araalu to ba fẹẹ jẹ anfaani gbọdọ ni nọmba idanimọ apapọ ti a mọ si National Identification Number (NIN).

Lara awọn amuyẹ miran to tun mẹnuba ni pe awọn to ba maa jẹ anfaani yoo tun ni nọmba idanimọ ile ifowopamọ, iyẹn Biometric Verification Number (BVN) ati foonu alagbeka.

Ẹdun ni eyi ni lati rii pe owo naa de ọdọ awọn ti ijọba ni lerongba, ki magomago ma si lọ wọnu eto ọhun.

O tẹsiwaju pe apapọ owo ti idile kọọkan yoo gba jẹ ẹgbẹrun marundinlọgọrin (N75,000) naira.

“Ẹgbẹrun marundinlọgbọn ni idile kọọkan yoo gba laarin oṣu kan, idile kan si gbọdọ ni eeyan marun-un, ki eto naa le kari fun oṣu mẹta. Idile miliọnu mẹẹdogun ni yoo gba owo yii fun oṣu mẹta, eyi ti apapọ rẹ jẹ idile marundinlọgọrin.”

Yatọ si eyi, Minisita fọrọ eto iṣuna tun ṣalaye siwaju pe ijọba tun fẹẹ ṣe iranwọ fawọn oniṣẹ ọwọ, oniṣowo, ọdọ, olokoowo kekeeke, awọn obinrin ati awọn oni worobo.

O ni ẹgbẹrun lọna aadọta (N50,000) naira ni awọn wọnyi yoo gba gẹgẹ bi owo iranwọ ti wọn ko si ni da a pada.

Sibẹ, ilana igbalode ni wọn yoo fi ṣe akọsilẹ awọn ti yoo jẹ anfaani, to fi jẹ pe eeyan ti ko din ni ẹgbẹrun kan lo maa lanfaani ni ijọba ibilẹ 774 to wa kaakiri Naijiria.

Aadọta biliọnu ni ijọba ya sọtọ fun eto yii.

Ẹdun ni ọna to dara leyi lati fi ṣe iranwọ faraalu lasiko yii.

Lẹ́yìn àádọ́ta ọdún, ilé-iṣẹ́ kan l’ Amẹrika tun wọnú Òṣùpá.

Lẹ́yìn àádọ́ta ọdún, ilé-iṣẹ́ kan l’ Amẹrika tun wọnú Òṣùpá.

Gbọ́láhàn Quseem

Ileeṣẹ aladani kan nilẹ Amẹrika lo ti fi itan tuntun balẹ pẹlu bi irinṣẹ wọn ti wọn pe ni spacecraft ṣe balẹ sinu Oṣupa lẹyin bi aadọta ọdun le sẹyin ti iru ẹ ti ṣẹlẹ gbẹyin.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileeṣẹ to fikalẹ si ilu Houston ti wọn pe orukọ rẹ ni Intuitive Machines ni wọn ran Odysseus Robot wọn lọ sinu Oṣupa, to si balẹ sibẹ gẹgẹ bi erongba wọn.

Ọdun 1972 ni iru nnkan bayii ti ṣẹlẹ gbẹyin nilẹ Amẹrika nigba ti ikọ ti wọn pe ni Apollo gbe iru igbesẹ naa, ti ẹrọ wọn si balẹ sori iyẹpẹ to wa ninu Oṣupa, eyi ti wọn pe ni Lunar Soil

Idunnu nla lo jẹ fun awọn alaṣẹ, alakoso ati gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ Intuitive Machines wi pe awọn naa tun le fi itan tuntun miran balẹ, eyi to fun wọn ni ireti pe ko si ohun ti wọn ko tun le ṣe nilẹ Amẹrika.

Itosi agbegbe kan tri wọn pe ni Lunar South Pole la gbọ pe ẹrọ Odysseus Robot naa balẹ si, to si gba awọn alabojuto rẹ ni ọpọlọpọ iṣẹju ko to di pe wọn le fidi rẹ mulẹ pe o ti balẹ lotitọ.

Aami kan ni wọn lo sọ pẹlu ẹrọ ti wọn fi n tọpinpin rẹ, eyi gan-an lo fun wọn ni aridaju pe Spacecraft wọn ti de ibi to n lọ.

Tim Crane to jẹ alabojuto fun ileeṣẹ naa sọ pe “Ohun ti a le fidi rẹ mulẹ, lai ṣiyemeji ni pe irinṣẹ wa ti balẹ silẹ ninu Oṣupa, a si ma maa mọ bi nnkan ṣe n lọ nibẹ.”

Ajọ to n ṣakoso Space nilẹ Amẹrika, iyẹn Nasa sọ pe awọn ti gba yara ninu Odysseus fun awọn irinṣẹ igbalode mẹfa ọtọọtọ.

Loju ẹsẹ ti iroyin naa jade ni alakoso wọn, Bill Nelson ti ki ileeṣẹ Intuitive Machines ku oriire itan tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fi balẹ, bẹẹ lo sọ pe aṣeyọri nla lo jẹ.

“Ilẹ Amẹrika tun ti pada sinu Oṣupa.”

“Loni, fun igba kọkọ ninu itan igbesi aye ẹda, ileeṣẹ aladani – ileeṣẹ ilẹ Amẹrika – ran irinṣẹ wọn lọ soke nibẹ yẹn. Oni yii si fi han nipa agbara ati ileri ajọ Nasa nipa ibaṣepọ pẹlu awọn ileeṣẹ aladani.”

Agogo mọkanla kọja iṣẹju mẹtalelogun (23:23 GMT) ni wọn sọ pe Odesseus naa balẹ sinu Oṣupa.

Wọn ni ko kọkọ si ami kankan nigba to balẹ, ṣugbọn nigba to maa to iṣẹju meloo kan, ami sọ, ami naa si jẹ eyi to n daku-daji, to fi jẹ ki wọn mọ pe o ti de ibi to n lọ, pẹlu awọn aworan to tun fi ranṣẹ.

Lẹyin bi wakati diẹ. Odysseus naa bẹrẹ sii ṣalaye awọn ohun to n ṣẹlẹ ninu Oṣupa, to si tun jẹ ki wọn mọ pe ohun duro bo ti yẹ.

Òṣèrékùnrin, Mr. Ibu dágbére fáyé

Òṣèrékùnrin, Mr. Ibu dágbére fáyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Baà kú làá dère, èèyàn kò sunwọ̀n láàyè. Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé gbajúmọ̀ òṣèré, John Okafor tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mr. Ibu, ti jáde láyé.

Ẹnìkan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ òsèrékùnrin náà, ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ kí wọ́n dá orúkọ rẹ̀ sọ pé lóòótọ́ ni òṣèré náà kú lọ́jọ́ kejì, oṣù Kẹta, ọdún 2024.
Onítọ̀hún ṣàlàyé pé iléèwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí Mr. Ibu ti ń gba ìtọjú fún ẹsẹ̀ rẹ̀ kan tí wọ́n gé lọ́dún 2023, ló kú sí.
Àmọ́ ẹbí rẹ̀ kò tíì sọ ohunkóhun lórí ikú gbajúgbajà òṣèré ọ̀hún.

Ìròyìn sọ pé láti ìgbà tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ kejì fun ni ẹṣẹ̀ lápẹ́ yìí, ni ara rẹ̀ kò ti yá dáadáa mọ́.
Mr Ibu wa nile iwosan fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ti awọn ọmọ Naijiria si dáwó jọ fún un lati tọ́jú ara rẹ̀.

Nínú atẹjade tí mọlẹbi fi sójú òpó ayẹlujara Mr Ibu, ṣàlàyé pé Mr Ibu ti ṣe iṣẹ́ abẹ méje láti rí i pé ó wà láàyè, wọ́n ní láti gé ọ̀kan lára ẹsẹ rẹ̀.

Ẹgbẹ́ oníṣèṣe gbé Emir Ilorin àti ọlọ́pàá re’lé ẹjọ́ bí wọ́n ṣe dá àjọ̀dún wọn dúró

Ẹgbẹ́ oníṣèṣe gbé Emir Ilorin àti ọlọ́pàá re’lé ẹjọ́ bí wọ́n ṣe dá àjọ̀dún wọn dúró

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní àìrìnjìnà, làì rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Àwọn ẹlẹ́sìn Ìṣẹ̀ṣe lágbayé, International Council for IFA Religion ti wọ́ àjọ ọlọ́pàá Nàìjíríà àti Emir Ilorin lọ ilé ẹjọ́ gíga ní ìlú Ìlọrin tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò onísẹ̀se náà, Lọya Femisi, ṣe sọ, ìpinnu láti wọ́ àjọ Ọlọ́pàá lọ ilé ẹjọ́ kò sẹ̀yìn bí wọ́n ṣe dá àwọn onísẹ̀se Ìlú Ìlọrin dúró láti se ọdún Ìsẹ̀ẹse àgbáyé tó wáyé ní ogunjọ oṣù kẹjọ, ọdún 2023.

Ọ̀gbẹ́ni Fẹmisi ṣàlàyé pé àjọ ọlọ́pàá sọ pé káwọn oníṣẹ̀ṣe gbé ọdún wọn kúrò ní Ìlọrin, ó ní wọ́n fi ẹ̀tọ́ wọn dùn wọ́n.

Ó ní èyí ló fàá tí wọ́n fi gbé ẹjọ́ náà dìde sí àjọ ọlọ́pàá, Emir Ìlú Ìlọrin àti àwọn yòókù.

Ọ̀gbẹ́ni Femisi tún sọ pé àwọn ọrọ̀ tí ọgá àgbà ọlọ́pàá sọ lórí afẹ́fẹ́ lọ́jọ́ ọdún náà yàtọ gédégbé sí ọ̀rọ̀ àjọsọ àwọn nígbà tí àwọn se ìpàdé pọ̀.

Ó fi kún un pé àwọn ní ẹrí tó dájú láti gbé kalẹ̀ fún ilé ẹjọ́.

Ìgbẹ́jọ́ náà wáyé, l’ọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n níwájú Adájọ́ Taoheed Umar.

Agbẹjọ́rò àgbà, Olóyè Malcolm Omirhobo (SAN) ló dúró fún àwọn onísẹ̀se nílé ẹjọ́.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, Ọ̀gbẹ́ni yíì ni ògbóntarìgì agbẹjọ́rò ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó sì jẹ́ oní ṣẹẹ̀ṣe.

Òun kan náà ló múra bíi Babaláwo wọ ilé ẹjọ́ ‘Supreme’ l’Abuja àti ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ nílùú Èkó l’óṣù kẹfà ọdún 2022.