Home Blog Page 28

Agbófinró!, ọwọ́ òfin ni ẹ fi mú àwọn tó tún fẹ́ koná ogun láàrin Ifẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́ -IPDM

Agbófinró!, ọwọ́ òfin ni ẹ fi mú àwọn tó tún fẹ́ koná ogun láàrin Ifẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́ -IPDM

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní olójú ò ní-ín lajú ẹ̀ sílẹ̀,kí tàlùbọ̀ ó yí wọ̀ọ́,èyí ló mú bí ẹgbẹ́ kan tó jẹ ti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ọmọ bíbí ìlú Iléefẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ifeland Peace & Development Movement (IPDM), ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn adàlúrú kan ṣe ṣekú pa àwọn àgbẹ̀ láàrin ìlú méjèèjì ní kòpẹ́kòpẹ́ yìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ náà, Sọji Awogbade àti Akọ̀wé wọn, Adedayọ Ojo, fi síta ni wọ́n tí sọ pé ṣe làwọn èèyàn ọhún ya wọ abúlé Tòrò, Abà Páànù àti Wánísanni, tí wọ́n sì pa àwọn àgbẹ̀ níbẹ̀ láì ṣẹ̀ wọ́n lẹ́ṣẹ̀ kankan.

Wọ́n ní nínú ìwádìí àwọn ló tún fi di mímọ̀ pé kò sí ìlú kankan láàrin Ifẹ àti Mọdakẹkẹ tó rán àwọn adàlúrú náà niṣẹ, ìwà búburú inú ara wọn ni wọ́n gbé jáde láti fi da omi àlàáfíà ìlú méjèèjì rú.

IPDM sọ síwájú pé ohun kan ṣoṣo tó lè wá ojútùú sí ìwà ọ̀daràn náà ni kí àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ṣe ojúṣe wọn nípa ṣíṣàwárí àwọn tí wọn ń jẹ nídìí mọ̀dàrú yìí, kí wọn sì fojú wọn bá ilé-ẹjọ́ fún ìjìyà tó tọ́ sí wọn láì fi ti ipò tàbí ẹni tí wọ́n jẹ́ láàrín ìlú ṣe rárá.

Ẹgbẹ́ náà ké sí àwọn alákòóso Ìfẹ Development Board, (IDB) àti Modákéké Progressive Union, (MPU), láti bẹ̀rẹ̀ sí í bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ọ̀daràn tí àwọn mọ̀dàrú náà ń hù, kí wọ́n sì máa kéde àlàáfíà fún àwọn ọmọ ìlú wọn, nítorí nínú àlàáfíà nìkan ni ìgbé ayé ìrọ̀rùn wà.

Ṣaájú ni alága ẹgbẹ́ kan nílùú Ileefẹ, ‘Ifẹ Intellectuals’, Ọmọọba Ademuyiwa Adeniran, ti fẹ̀sùn kan àwọn ará Mọdákẹ́kẹ́ pé wọ́n ti fi agbára gba abúlé bíi ọgọ́rùn-ún lọ́wọ́ àwọn.

Ó ní bí wọ́n ṣe ń pa àwọn èèyàn àwọn ní wọ́n ń jí wọn gbé, tí wọ́n sì ń gba dúkìá wọn. Ó ní láàrin oṣù Kẹwàá sí oṣù Kejìlá, ọdún 2023 nìkan, àwọn èèyàn Mọdákẹ́kẹ́ gba abúlé Toro, Yekere, Alápẹ, tí wọ́n sì yí orúkọ wọn padà kúrò ni Ifẹ̀ sí Mọdákẹ́kẹ́.

Ademuyiwa sọ síwájú pé yíyọ tí ẹkùn àwọn ń yọ, bíi ti ojo kọ́ o, ìwà sùúrù tí Ọọ̀ni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ní ló ń ká àwọn lápá kò. Wọ́n wáá ké sì ìjọba láti tètè wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà.

Ṣùgbọ́n nígbà tó ń fún àwọn ‘Ifẹ Intellectuals’ lésì, Alága ẹgbẹ́ Mọdakẹkẹ Think Tank (MTT), Olóyè Kọla Ọlabisi àti Akọ̀wé, Ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Ọladoṣu, sọ pé irọ́ tó jìnnà sóòọ́tọ́ ni gbogbo nǹkan tí ẹgbẹ́ náà n gbé pòòyì ẹnu.

MTT ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ wọn kò yàtọ̀ sí ti ẹni tó fẹ́ gba ogún ológún (sweat) mọ́ tiẹ̀ tó wá ń wá àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ láti fi ọ̀nà èrú gba nǹkan tí kì í ṣe tirẹ̀. Ó ní gbogbo àwọn tí inú wọn kò dùn sí lfẹ̀ àti ìṣọ̀kan tó wà láàrin ìlú Ifẹ àti Mọdákẹ́kẹ́ báyìí ní wọ́n ń dáná ọ̀tẹ̀.

Ẹgbẹ́ náà sọ síwájú pé bí èdè àìyedè bá wà láàrin àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Iléefẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́, kò lẹ́tọ̀ọ́ kí wọ́n so irunmú pọ̀ mọ́ tìpàkọ́, ẹni tí wọ́n bá jọ ń fa wàhálà ni kí wọ́n jọ dojú kọ ara wọn.

Wọ́n wáá ké sí ọ̀ga àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè yìí láti pàṣẹ fún kọmíṣánnà ọlọ́pàá l’Ọ́ṣun láti ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, láti ṣàwárí àwọn agbátẹrù àti aríjẹ-nídìí-mọ̀dàrú tí wọ́n ń pọnmi òkè rú todò , tí wọ́n sì ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé lẹ́kun láàrin ìlú méjèèjì.

Lailatu Li Quadr ò kì ń se o̩jó̩ aye̩ye̩ – Sheikh Tajudeen

Lailatu Li Quadr ò kì ń se o̩jó̩ aye̩ye̩ – Sheikh Tajudeen

Yínká Àlàbí

Oru mo̩ju oni ti aawe̩ Musulumi pe me̩tadinlo̩gbo̩n ni ijo̩ Ridwanullahi to wa ni Liberty estate, Ibafo mu fun wiwa o̩jo̩ Lailatu Li Quadr.
O̩jo̩ yii ni o̩jo̩ ti gbogbo musulumi aye maa n gbadura lati ri ninu Osu Ramadan. Ramadan yii ni awo̩n Aafaa je ki o ye wa pe o loore ju e̩gbe̩run osu (1000 months) lo̩. Wo̩n tun je̩ ki o ye wa pe ti eniyan ba le se alabapade o̩jo̩ Lailatu Li Quadr naa. Eniyan naa ti je̩ e̩bun ayeraye O̩lo̩run to le gbe e̩ni naa fun o̩dun me̩talelo̩go̩rin ati osu me̩rin (83years, 4 months). Eyi si maa n je̩ ki awo̩n Musulumi se oju kokoro re̩.
Nigba ti aawe̩ ba ti pe ogun ni awo̩n Musulumi ododo ti maa n waa. Awo̩n kan tile̩ ti maa n digba dagbo̩n lo̩ si mo̩salasi to ba wu wo̩n nitori awo̩n nnkan to le ba wo̩n laawe̩ je̩.
Awo̩n Aafaa kan ni ko tile̩ le to be̩e̩, eniyan le maa so̩ awo̩n o̩jo̩ aawe̩ ti ko se e pin si meji( odd numbers) bii igba ti aawe̩ ba pe mo̩kanlelogun(21), me̩talelogun(23), marundinlo̩gbo̩n(25), me̩tadinlo̩gbo̩n (27) ati mo̩kandinlo̩gbo̩n (29).
Sheikh Tajudeen ti gbogbo eniyan mo̩ si “ta lo n so̩ro̩” lo wa ge̩ge̩ bii alejo pataki ni o̩jo̩ naa. Ibe̩ ni Aafaa yii ti n salaye fun awo̩n ijo̩ Ridwanullahi pe inu oun dun bi wo̩n se fara bale̩ ti wo̩n ko maa jo ijo e̩le̩ya bii awo̩n kan, ti wo̩n maa n jo ijo e̩le̩ya pe̩lu obinrin olobinrin, Aafaa yii ni ibe̩ ni wo̩n ti maa lu ofin O̩lo̩run.
Aafaa Tajudeen ni Lailatu Li Quadr ni ki a maa pe oruko̩ O̩lo̩run bi agbara wa ba se mo̩, ki a maa fi iyin fun Ojise̩ nla Mohammed (ki ike̩ àti o̩la maa baa), ki a maa ka Alikurani nitori asiko aawe̩ ni O̩lo̩run so̩ kurani naa kale̩ fun wa, ki a maa gbo̩ro̩ O̩lo̩run, ki a je̩ e̩ru to n dupe̩, ki a maa to̩ro̩ aforiji e̩se̩ nitori pe ko si bi eniyan se fe̩ rin ti ori ko ni mi ati adura nipa tito̩ro̩ ohun ti a ba fe̩ lati o̩do̩ Allah.
Aafaa yii ni igba ti a ba fi maa se eleyii tan , a maa rii pe o̩jo̩ ti lo̩ ati pe ko si aaye fun ijo e̩le̩ya kankan.
Chief Imam Liberty estate, Sheikh Ambali Gold ni o gba Aafaa naa lalejo. Imam naa fi kun un pe, aawe̩ ti n lo̩, k a ma se je̩ ki awo̩n ise̩ oloore ti a n se o lo̩, gbogbo iwa e̩se̩ ti a ti fi sile̩, kia ma se pada de ibe̩ mo̩. Lara awo̩n to tun se apo̩nle Sheikh Tajudeen ni Aafaa Moshood Adeyemi ti wo̩n je̩ igbakeji baba Imam, Aafaa Anido̩la, Aafaa Mohammed Soliu Olawale, Aafaa Idowu Jimoh Aliyu, Aafaa Ajiboye, Baba Omisoore, Baba Oshodi, Aafaa Ibrahim, Aafaa Bashir, Toyeeb, Aafaa T Aga, Aafaa S Badejo̩, Aafaa Mustapha, Aafaa Abdullahi, Aafaa Mubarak, Aafaa Mubashir ati awo̩n o̩mo̩ ile kewu pe̩luu gbogbo ijo̩ lo̩kunrin lobinrin Ridwanullahi.
Ni oru naa, Aafaa Soliu siwaju no̩fila, nigba ti Chief Imam ati igbakeji re̩ fi e̩mi imoore han si Aafaa Tajudeen ati awo̩n Aafaa nla-nla ti wo̩n jo̩ wa.

OÚNJE̩ ÈKÓ: Sanwo-Olu kò já Tinubu kulè̩. Ó s’ètò pàtàkì lórí ebi tó ń pa’ra ìlú

OÚNJE̩ ÈKÓ: Sanwo-Olu kò já Tinubu kulè̩. Ó s’ètò pàtàkì lórí ebi tó ń pa’ra ìlú

Akeem Lasisi

Ge̩ge̩ bi awo̩n Yoruba ti maa n wi pe igba ipo̩nju laa mo̩re̩, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinle̩ Eko ti fihan pe ijo̩ba oun kii se eyi to le gb’oju si e̩gbe̩ kan lasiko ti o̩wo̩n gogo ounje̩ n ba awo̩n ara ilu finra o. Bakan naa, o fihan pe oun ko gbo̩do̩ gbe̩yin nibi ti wo̩n ba ti n se oun ti o le mu ki ijo̩ba o̩ga re̩, iye̩n Asiwaju Bola Tinubu, se aseyo̩ri.

Sanwo-Olu fi eyi han nipa sise eto edinwo ounje̩ orisiirisii ni awo̩n o̩ja kan kaakiri Ipinle̩ Eko.

Eto ti wo̩n n pe ni OUNJE̩ EKO naa be̩re̩ ge̩ge̩ bii o̩ja Sunday, Sunday, nibi ti awo̩n ara ilu ti n ra ounje̩ ti o dinwo pe̩lu ida me̩e̩do̩gbo̩n.

Eyi tumo̩ si pe bi osunwo̩n e̩wa kan ba je̩ e̩gbe̩run kan, iye̩n N1000, N750 ni e̩ni to ba ra a yoo san.

Kii se pe Ijo̩ba Sanwo-Olu fi oogun mu awo̩n to n ta o̩ja naa, be̩e̩ ko fi ipa mu wo̩n ki wo̩n le ta a ni e̩dinwo.

Dipo be̩e̩, iromi to n jo leti odo, onilu re̩ n be̩ ninu omi ni.

Be̩e̩, e̩nu fifo kii dun namunamu. Eyi tumo̩ si pe Ijo̩ba ti san asansile̩ owo naa fun awo̩n o̩lo̩ja.

Lara awo̩n OUNJE̩ EKO naa ni ire̩si, e̩wa, gaari, ata ati tomato.

O̩go̩o̩ro̩ awo̩n ara Eko lo n wo̩ lo̩ si awo̩n o̩ja ti a n wi yii.

Ko yo̩ olowo sile̩, be̩e̩ ko yo̩ me̩kunnu sile̩.

Bakan naa, ati onile ati alejo; ati Yoruba, Hausa, Igbo ati be̩e̩ be̩e̩ lo̩ ni wo̩n n je̩ anfaani OUNJE̩ EKO naa.

Lasiko o̩dun Ajinde ti Easter, ijo̩ba Sanwo-Olu tun se be̩be̩ nipa sisi o̩ja naa ni o̩jo̩ E̩ti, iye̩n Friday. Biba ni ero tun po̩ nibe̩.

Nigba to n so̩ro̩ lori OUNJE̩ EKO naa, Gomina Sanwo-Olu ni oun mo̩ pe ara n ni awo̩n ara ilu latari o̩wo̩n gogo ohun gbogbo.

O ni ohun to se okunfa eyi ni awo̩n atunto pataki ti Ijo̩ba Apapo̩ n se.

O ni Aare̩ Tinubu n gbe igbese̩ naa lati ri pe orile-ede kuro ninu o̩gbun ti o ba a ni, kii se lati fi iya je̩ awo̩n eniyan.

O wa mu u da wo̩n loju pe, laipe̩, nnkan yoo se e̩nu rere, ti yo̩to̩mi yoo si pada si ilu. Se tita-riro laa ko̩ ila, bo ba jinna tan, oluware̩ a di oge.

Koda, Gomina Sanwo-Olu fi idunnu han pe owo Naira ti n gbewo̩n le̩gbe̩e̩ do̩la.

O wa ro̩ awo̩n olutaja ki wo̩n je̩ ki awo̩n nnkan o wale̩.

 

Òjò àdúrà rò̩ níbi wáàsí As~Sabuuru International

Òjò àdúrà rò̩ níbi wáàsí As~Sabuuru International

Yò̩mí Lukman

As~Sabuuru International Prayer Mission ti ebute-metta branch se waasi ita gbangba ni o̩jo̩ ke̩rinlelogun,osu ke̩ta,o̩dun 2024.Ti Late Alh.Fadilat Shelkyh Muhammed Lukman Abubakry Kunle Konisosofunmi je oludasile. Asalatul naa bere nii agbegbe Ikorodu nilu Eko.Gbogbo atotonu waasi naa da lori ki gbogbo awo̩n e̩le̩sin musulumi tabi e̩le̩ya miran tabi elede kan si ekeji gbo̩do̩ nife̩e̩ ara wo̩n, nitori pe ife̩ yii ni Oba mi fi da gbogbo aye yii. Alh.Abdulrasaki Abdulmaliki baba woli, tun me̩nubaa pe aanu se koko ninu osu yo̩-e̩se̩, yo̩-e̩se̩ yii, riran ara ni lo̩wo̩ lati o̩do̩ e̩nikin-in-ni si e̩nikeji sii eniketa ati be̩e̩ be̩e̩ lo̩, labe̩ be̩e̩, ka tun ma se gbagbe iforiji ara wa, ki a ma se joye “Adiye̩ da mi loogun nu, maa fo̩ le̩yin”.
Ni pabanbari ijo̩sin ati ibe̩ru O̩lo̩run se koko ninu igbesi aye gbogbo awa e̩da, nitori pe ibe̩ru O̩lo̩run ni’leke o̩gbo̩n. Nibi ifo̩ro̩-wa-ni-le̩nu-wo pe̩lu awo̩n o̩to̩kulu tabi awo̩n ti a le pe nii opomulero inu ijo̩ As~Sabuuru. Ijo̩ yii je̩ ijo̩ kan pataki ti wo̩n maa n fi adura jagun, ijo̩ to n fe̩ ilo̩siwaju o̩mo̩ e̩gbe̩ ni gbigbi igba ni.
Be̩e̩ si ni ijo̩ yii ko ko iyan awo̩n o̩do̩ kere nitori pe “gbogbo e̩sin ti a ba n sin ti a ko fi ti o̩mo̩de se ko ni pe̩ parun”.
Awo̩n to di ijo̩ naa mu ni – Alh. Amiru Ustman Olorunkemi, Chairman, Hon.Kabri Adigun, Alhaja Fausiah Abubakry Konisosofunmi, Alhaja Modinat Ajoke Abubakry Muhammed, Alhaja Memunat Muritala Muhammed. Ni akotan Alhaji Muritala Muhammed Almiskkily Bilahi ti wo̩n je aburo si oludasile̩ ijo̩ asalatul As-sabuuru International Prayer Mission se o̩po̩lo̩po̩ adura fun gbogbo awo̩n alasalatu patapata nile, loko ati gbogbo awo̩n ti wo̩n gbo̩ waasi jake jado kaakiri origun ilu Nigeria. Alhaji wi pe te̩rin tayo̩ ni awo̩n jo̩ maa pejo̩ se asalatu miran te̩bi tara ati ojulumo̩.

Ìbùkún ńlá , ọ̀kan lára àwọn Olórí Ọọ̀ni bí Ìbejì làǹtìlanti

Ìbùkún ńlá , ọ̀kan lára àwọn Olórí Ọọ̀ni bí Ìbejì làǹtìlanti

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìdùnú subú lu ayọ, nílé lfẹ̀ bí Olorì Tobilọla Ògúnwùsì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Ọọ̀ni Ifẹ̀, Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ògúnwùsì, ti bí Ìbejì báyìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Ọọ̀ni gbé sí ìkànnì fesibúùkù rẹ̀ láìpẹ yìí ló ti ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ire ńlá tó wọlé tọ ilé Odùduwà.

Ògúnwùsì kí ìyàwó rẹ̀, Olorì Tóbilọ́ba, ẹni tó bí Ìbejì làǹtìlanti kú oríire àwọn ọmọ tuntun náà. Ó ní ọmọọbakùnrin kan àti ọmọọbabìnrin kan làwọn ọmọ tí ìyàwó òun bí ọ̀hún

Ó sọ síwájú pé ìyá àtàwọn ọmọ náà wà lálàáfíà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ lórí fesibúùkù rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹta, ọdún yìí, Ọba Ògúnwùsì ní, ‘Ògo ni fún Ọlọ́run fún oun ńlá tó ṣe.

‘Mo kí ilé Odùduwà àti Olorì Tóbilọ́ba, ẹni tó bí Ìbejì làǹtìlanti fún ìtẹ́ Odùduwà lónìí kú oríire. Ìyá àtàwọn ọmọ wà la lálàáfíà fún ògo Ọlọrun.

Awuyewuye bẹ́ sílẹ̀ lórí àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú Minna s’órúkọ Tinubu

Awuyewuye bẹ́ sílẹ̀ lórí àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú Minna s’órúkọ Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹta ọdún 2024 ni ààrẹ Bola Tinubu ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Niger láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àtúnṣe pápákọ̀ òfurufú èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe, tí wọ́n sì sọ ní orúkọ rẹ̀.

Tinubu yóò tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe ètò ọ̀gbìn Niger State Agricultural Revolution Project àti ẹ̀ka ètò Hajj ní pápákọ̀ òfurufú náà.

Àmọ́ ṣíṣe àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Niger sí orúkọ ààrẹ ló ti ń fa awuyewuye, tí àwọn èèyàn sì ń bèèrè pé kí ló dé tí ìjọba fi ń pààrọ̀ orúkọ pápákọ̀ òfurufú náà.

‘Dr Abubakar Imam Kagara International Airport’ ni orúkọ pápákọ̀ òfurufú náà ṣáájú kí wọ́n tó yí orúkọ rẹ̀ padà.

Dókítà Abubakar Kagara ló jẹ́ ògbóǹtarigì akọ̀wé àti akọ̀ròyìn tó kọ́kọ́ kọ ìwé ìròyìn ní èdè Haúsá “Gaskiya Ta Fi Kwabo” ní ọdún 1939.

Abubakar Kagara jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé ní ẹkùn árìwá Nàìjíríà tí ipa tí ó kó nínú ìdàgbàsókè èdè Haúsá kò kéré rárá.

Ìbéèrè tí àwọn lámèyítọ́ ń bèèrè ni pé kí ló dé tí wọ́n fẹ́ yọ orúkọ ẹni tó ti ṣiṣẹ́ takuntakun bíi ti Kagara kúrò lára pápákọ̀ òfurufú náà.

Onímọ̀ nípa ètò òṣèlú kan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ òun sọ fún akọroyin pé tó bá jẹ́ òun ni ààrẹ Tinubu ni, òun kò ní gbà kí wọ́n ṣe àyípadà orúkọ náà sí orúkọ òun.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Mohammed Umar Bago sọ pé ìdí tí àwọn fi pààrọ̀ orúkọ náà ni láti mọrírì ipa tí Tinubu ti kó sí ìdàgbàsókè Niger, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ lápapọ̀ lẹ́nu ìgbà tó gba àkóso ìjọba Nàìjíríà.

Àmọ́ onímọ̀ náà ní ó yẹ kí gómìnà Bago ṣe àkànṣe iṣẹ́ ńlá kan gbòógì tó máa sọ ní orúkọ ààrẹ.

Pípáàrọ̀ orúkọ ní ẹ̀ẹmèjì láàárín ọdún kan.
Kò ì tíì pé ọdún kan, ní ọjọ́ kìíní ọdún 2023 ni Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìrìnnà òfurufú gbé àtẹ̀jáde kan jáde pé àwọn máa ṣe àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú Minna International Airport àtàwọn pápákọ̀ òfurufú mẹ́rìnlá mìíràn ní Nàìjíríà.

Nínú àtẹ̀jáde náà ni wọ́n ti kéde pé pápákọ̀ òfurufú Maiduguri ni àwọn ti yí orúkọ rẹ̀ padà sí pápákọ̀ Muhammadu Buhari tó jẹ́ orúkọ ààrẹ àná ní Nàìjíríà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n yí orúkọ pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Ebonyi ní ìlà oòrùn gúúsù Nàìjíríà padà sí orúkọ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní ilé aṣòfin àgbà, Chuba Okadigbo.

“Kí ni ìdí tí wọ́n fẹ́ fi yí orúkọ pápákọ̀ òfurufú náà padà láì tíì pé ọdún kan tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ sẹ́yìn? Kí ni ipa tí yíyí orúkọ náà padà yóò ní lórí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Niger? Èyí ni ìbéèrè tí onímọ̀ náà ń bèèrè nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger ní àwọn ti sọ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ náà kan tó wà ní Zungeru ní orúkọ Dókítà Kagara nítorí ilé ẹ̀kọ́ náà bá iṣẹ́ rẹ̀ mu.

Ẹ̀wẹ̀, yàtọ̀ sí awuyewuye tó ń wáyé látàrí àyípadà orúkọ náà, Tinubu yóò tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ àkànṣe ètò ọ̀gbìn kan ní ìpínlẹ̀ Niger.

Gómìnà Umaru Bago ti máa ń sọ wí pé ìpínlẹ̀ Niger yóò tó máa pèsè oúnjẹ tí yóò tó wọn jẹ ní ìpínlẹ̀ náà.

Àkànṣe ètò ọ̀gbìn náà tí wọ́n fi lọ́lẹ̀ náà ni Total Agricultural Support Programme (TASP) èyí tó jẹ́ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ Brazil kan.

Wọ́n ní ìrètí wà pé ètò náà yóò pọnkún ìpèsè oúnjẹ àti iṣẹ́ fún àwọn aráàlú.

Kò sí mò̩dàrú nínú ipò Olúbàdàn – Seyi Makinde

Kò sí mò̩dàrú nínú ipò Olúbàdàn – Seyi Makinde

Fẹmi Akínṣọlá

Báakú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , Seyi Makinde, ti kéde ìpapòdà Olúbàdàn kejiìlélógójí ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Kábíyèsí alá yélúwa, Ọba Dr. Moshood Lekan Balogun Alli Okunmade Kejì.

Gómìnà Mákindé kéde èyí nínú àtẹjáde kan ti ó buwọ́lù ni alẹ́ Ọjọ́bọ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún yìí.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé wí pé Kábíyèsí darapọ̀ mọ́ àwọn baba ńlá rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́bọ̀ ní ilé ìwòsàn UCH ti ìlú Ìbàdàn.

Gómìnà Makinde ṣàpèjúwe Ọba Balogun gẹ́gẹ́ bí èèyàn tí iwa rẹ wu ni lórí púpọ̀.

Bákan náà ló ní Balógun ṣe iṣẹ tó lààmì-laaka ní ilẹ̀ Ìbàdàn láàrin Ọdún méjì tó lò lórí àlééfà gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn.

Mákindé nínú ìwé ìkẹ̀dun rẹ́, kí ìgbìmọ̀ àpapọ̀ olóyè Olúbàdàn (Olubadan-in-Council) Ìgbìmọ̀ lọ́ba lọ́ba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àwọn ará ìlú Ìbàdàn àti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ibanikẹdun rẹ̀, Makinde ṣàpèjúwe ìpapòdà Ọba Balogun gẹ́gẹ́ bí Ìrókò ńlá tó ṣubú.

Ó ní ìṣèjọba rẹ̀ fihàn wi pé ó ní ìrírí púpọ̀ eléyìí tí ó sì jẹ́ kó tayọ nínú àwọn Ọba tó ti jẹ ṣaájú ni ilẹ̀ Ìbàdàn.

Ó kí ìdílé Ọba Mashood Lekan Balogun kú ara fẹ́raku, tó sì gbàdúrà pé kí Ọlọrun forí jin àṣìṣe Kábíyèsí ọ̀hún.

Ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin ni Kábíyèsí lò láyé, kí wọ́n tó gbeṣẹ̀`.
Ẹ̀wẹ̀, a ti gbọ́ pé ìsìnkú Ọba Balogun yóò wáyé ní ìlànà ẹlẹ́sìn mùsùlùmí lónìí ọjọ́ Ẹtì.

Olúbàdàn ṣẹ̀ṣẹ̀ lo ọdún méjì lóríi àlééfà ni kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Mọ̀lẹ́bí kan tó fi ọ̀rọ̀ tó àwọn akọ̀ròyìn létí sọ pé, ní agboolé Olúbàdàn ní Alli-Iwo, ni ìsìnkú náà yóó ti wáyé láago mẹ́rin ọ̀san.

Ọ̀pọ̀ ọmọ, ìyàwó àti ọmọ ọmọ ló gbẹ́yìn Olúbàdàn.

Ìdájọ́ ikú ló yẹ kí wọ́n máa fún àwọn ajínigbé– Rẹmi Tinubu

Ìdájọ́ ikú ló yẹ kí wọ́n máa fún àwọn ajínigbé– Rẹmi Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìlú tí kò sófin, àwọn àgbà ní ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀.
Obìnrin àkọ́kọ́ l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abilékọ Olurẹmi Tinubu, ní ẹjọ́ ikú ló yẹ kí wọ́n máa dá fún gbogbo àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá ti jẹ̀bi ẹ̀sùn tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ìjínigbé.

Ìyàwó Ààrẹ sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń fi ìmọ̀lára rẹ̀ hàn lórí bi àwọn agbébọn ṣe ya bo ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàárọ̀ Ọjọ́bọ, ọjọ́ keje, oṣù yìí, ti wọ́n sì jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tó bíi ọrinlelugba (280) pẹ̀lú àwọn olùkọ́ wọn kó lọ.
Rẹmi Tinubu ní ìgbàgbọ́ òun ni pé ẹnikẹni tó bá ti ń lọ́wọ́ nínú jíjí àwọn ọmọ kéékékèké gbé gbọdọ̀ jẹ́ aláàárẹ̀, ọ̀dájú àti ojo ènìyàn.Ó ní báwo lẹni tó gbádùn tàbí níláárí kan ṣe lè wò sùnsùn, kò sì lọ̀ọ́ ka àwọn ọmọ kéékékèké mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn láti jí wọn gbé lọ.

Gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l’Abuja, Ìyàwó Ààrẹ ní àsìkò ti tó fún àwọn aṣòfin Nàìjíríà kí wọ́n tètè ṣòfin tí yóó máa fi ìyà ńlá jẹ gbogbo ọdaràn tó bá ti jẹbi ẹsùn ìjínigbé, nítorí àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní: ‘má fi oko mi ṣ’ọna, ọjọ́ kan náà lèèyàn ń pinnu rẹ̀ ’.

Anthony Joshua f’ ẹ̀ṣẹ́ dá bátànì sí Fancis Ngannou lára ní Saudi Arabia.

Anthony Joshua f’ ẹ̀ṣẹ́ dá bátànì sí Fancis Ngannou lára ní Saudi Arabia.

Gbọ́láhàn Quseem

Abẹ̀sẹ́kùbíòjò ọmọ Nàíjíríà ati orílẹ̀-èdè Britain, Anthony Joshua ti ní kí Francis Ngannou gbé jẹ́ pẹlu bo ṣe f’ ẹ̀sẹ́ wó lẹ́nu nínú ìdìje tó wáyé láàrin àwọn méjèèjì lórilẹ̀-èdè Saudi Arabia.

Abala keji idije naa ni Joshua ti lu Ngannou lalubami.

Koda ninu abala kini idije naa ni o ti kọkọ fẹsẹ wo lulẹ ko to wa pari iṣẹ lara rẹ ni abala keji.

Bi ẹni mutika ni Ngannou ṣe n ta gọọ- gọọ nigba to dide nibi to wo lulẹ si ki Anthony Joshua to fi bajinatu ẹsẹ da bira si lara.

Adari idije naa ṣiju aanu wo Ngannou to si sọ pe o to gẹ.

Wọn ni lati wa awọn olutọju ilera lati ṣabẹwo si tori iya ti Joshua fi jẹ.

Mi o kẹrẹ lati koju ẹnikẹni

‘’Mo n pada lọ sinu ibuba mi lẹyin ija yi. Bi wọn ba tu mi silẹ pada mo tun maa doju ija kọ ẹni ba yọju si mi.’’

Esi ree ti Anthony Joshua fọ lẹyin idije naa gẹgẹ bi Tyson Fury to di bẹliiti WBC lagbaye mu ṣe n wo lẹgbẹ ibi ti ija naa ti waye.

Nigba ti Fury ati Ngannou koju ni oṣu Kẹwaa, o tiraka lati bori rẹ ni toripe Ngannou fẹyin rẹ lelẹ ninu idije naa.

Ami ayo kan lo fi ṣagba Ngannou.

‘’Nigba ti mo ri ija to waye laarin Ngannou ati Fury, mo ni o di dandan ki emi naa koju arakunrin Ngannou yi.Akikanju abẹṣẹkubiojo ni ko si tunmọ si pe ifidirẹmi rẹ yi buu ku rara ati rara’’

‘’Mo sọ fun pe ko ma fi iṣẹ abẹsẹkubiojo yi silẹ. Lẹnu igba to bẹrẹ, awọn ogbontarigi meji lo ti koju bayii.’’

Igba kẹẹrin ree ti Anthiny Joshua yoo jawe olubori laarin oṣu mọkanla.

Eyi si n tọka si pe bo pẹ bo ya igbadi abẹsẹkubiojo to fakọyọ lagbaye to n foju sun yoo ja mọ lọwọ laipẹ.

Olupolongo idije ere idaraya nii Eddie Hearn ti kesi Anthony Joshua latikoju ẹnikẹni to ba jawe olubori laarin Tyson Fury ati Oleksandra Usyk.

Awọn mejeeji yoo gbena woju ara wọn loṣu Kaarin ọdun yi lati mọ ẹni ti yoo gba bẹliiti.

Aaye si tun wa fun wọn lati koju pada lẹẹkan si ki ọdun yi to pari.

”Mi o ni ja laarin ọdun marun un.”Joshua fikun.

O ni ”Eddie Hearn ati awọn ikọ mi yoo maa dari eto ọjọ iwaju mi.”

Èèyàn mẹ́ta r’ẹ́wọ̀n he lórí ìbúgbàmù tó wáyé nílù Ìbàdàn.

Èèyàn mẹ́tà r’ẹ́wọ̀n he lórí ìbúgbàmù tó wáyé nílù Ìbàdàn.

Gbọ́láhàn Quseem.

Ilé-ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà nílùú Ìbàdàn, ti ju arábìnrin kan àti ọkùnrin mẹ́ta sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, fún ipa tí wọ́n kó nínú ìbúgbàmù tó wàyé nílùú Ìbàdàn nínú oṣù Kìnnì.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni ibugbamu nla naa waye, nibi ti awọn eeyan ti ku, ti ọpọ si tun farapa.

Oriṣiriṣi ile nlanla lo tun wo lulẹ lasiko iṣẹlẹ naa to waye ni agbegbe Bodija.

Ile-ẹṣẹ ọlọpaa gbe Ramatu Camara,ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, Ganiu Malik, ẹni ogun ọdun, ati Abubakar Samara, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, lọ si ile ẹjọ fun ẹsun lilo awọn nnkan ija to le pa ilu run, kiko awọn nkan to le fa ibugbamu pamọ, ati awọn ẹsun mi i.

Ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ni ijọba ipinlẹ Oyo kede sita pe ọwọ ti tẹ afurasi mẹta to lọwọ ninu isẹlẹ ibugbamu to waye ni Bodija nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi wọn.

Oludamọran si Gomina lori ọrọ eto abo, Fatai Owoseni lo kede ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Ibadan.

Owoseni ni eeyan mẹta ni iwadi ti fihan pe wọn lọwọ ninu ibugbamu naa, ti wọn yoo si foju ba ileẹjọ lori iwadi ti awọn agbofino se.

O tẹsiwaju pe agbegbe Aderinola ni ibugbamu naa ti waye ki i se agbegbe Dejọ Oyelese.

Bakan naa lo safihan orukọ nkan to bugbamu naa, eyi to pe ni ‘Water Gel Type Based Explosive’ to si jẹ pe ina mọnamọna lo ma sokunfa ibugbamu naa.

O ni ẹrọ aworan CCTV to jẹ ti ọkan lara Ile ti ibugbamu naa kọlu lo tu asiri bi isẹlẹ naa .

Ọlọpaa to rojọ tako wọn nile ẹjọ sọ pe awọn mẹtẹẹta, ati awọn afurasi mii to ti salọ bayii, jẹbi ẹsun pe wọn ko awọn nkan abugbamu sinu ile gbigbe kan, eyi to ṣekupa iya agba ẹni ọdun marundinlaadọrin, Bolanle Badmus, ati awọn mẹtala mi i.

Adajọ ile ẹjọ naa, E.U Akpan, paṣẹ pe ki wọn o ko awọn afurasi naa si ọgba ẹwọn Agodi titi di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.

O ni igbesẹ wọn lodi si abala kẹrindinlọgbọn, ofin Naijiria to ni i ṣe pẹlu igbesunmọmi, ati idena rẹ.