Home Blog Page 27

Ẹ forúkọ àti ìdánimọ̀ yín sílẹ̀ – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ fún àwọn olùfẹ̀hónúhàn

Ẹ forúkọ àti ìdánimọ̀ yín sílẹ̀ – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ fún àwọn olùfẹ̀hónúhàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ,èyí ló mú kí Ọ̀gá àgbà pátá fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílèèdè Nàìjíríà, Kayode Egbetokun pe gbogbo àwọn tí wọ́n n gbèrò láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tí yóó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kínní, oṣù Kẹjọ láti tètè wá fi orúkọ àti ìdánimọ̀ wọn sílẹ̀.

Egbetokun lo sọrọ yii lọjọ Ẹti, ọsẹ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, nibi to ti jẹ ko di mimọ pe awọn naa ti n gbaradi fun eto aabo to pe ye lori iwọde ọhun.

Ọga agba ọlọpaa sọ pe ki gbogbo ẹgbẹ, ajọ ati awọn to n gbero lati kopa ninu iwọde fi orukọ silẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to ba sunmọ wọn, lati le mọ iru eeyan ti wọn jẹ.

O tẹsiwaju pe ẹtọ araalu ni lati fi ẹhonu wọn han nipa kikorajọ soju kan, ati pe wọn gbọdọ ṣe ẹ pẹlu alaafia lai si iwa jagidijagan.

“Awa naa fidi ẹtọ araalu labẹ ofin mulẹ nipa iwọde ifẹhonuhan alalaafia.

“Ṣugbọn ṣa, lati le daabo bo dukia ati ẹmi araalu, a rọ gbogbo awọn ẹgbẹ ti wọn n gbero lati kopa ninu iwọde ifẹhonuhan naa lati lọ fi orukọ ati idanimọ wọn silẹ lọdọ ọga ọlọpaa to wa ni ipinlẹ wọn, nibi ti iwọde yoo ti waye.

“Lati le ṣagbatẹru iwọde ifẹhonuhan alalaafia ti ko nii mu ipalara dani, ki wọn lọ fi awọn nnkan wọnyi silẹ: ipinlẹ ti wọn ti fẹẹ ṣe e ati ibi ti wọn yoo korajọpọ si; igba ati asiko ti wọn yoo fi ṣe e; orukọ ati idanimọ awọn adari olufẹhonuhan ati awọn alagbatẹru.”

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn fẹẹ tete mọ awọn to n gbero lati da iwọde ọhun ru, lojuna lati le tete ko wọn pamọ.

Ẹ gbé ìjìyà nlá kalẹ̀ fún àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú- Oluwo

Ẹ gbé ìjìyà nlá kalẹ̀ fún àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú- Oluwo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìlú tí òfin ò bá ti fi ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rinlẹ̀, ìnira ló máa kó bá ìlú
Oluwo tìlú Ìwó níìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo àwọn olùfẹ́hónúhàn láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, àti pé kí wọ́n darí gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wọn sórí ijiya ìjìyà fún gbogbo àwọn ọ̀bàyéjẹ́ tó di ipò òṣèlú mú.

Kabiyesi ni igbagbọ wa wi pe awọn janduku yoo ja iwọde ifẹhonuhan naa gba, ti wọn yoo si lo anfaani ọhun lati ba dukia ijọba jẹ.

Oluwo lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Alli Ibrahim fi sita laipẹ yii, nibi to ti n rọ ijọba apapọ lati gbe ijiya nla kalẹ fun gbogbo awọn jẹgudujẹra to wa nipo iṣakoso.

Siwaju sii ni Ọba Akanbi jẹ ko di mimọ pe lara awọn iṣoro to n dojukọ Naijiria ni iwa jẹgfudujẹra ti awọn to wa ni iṣakoso ti hu, to si ni ki awọn alufẹhonuhan dari ẹdun ọkan wọn sori ijiya to tọ fun gbogbo awọn to ọbayejẹ.

O loun gba pe eto iṣejọba awa-ara-wa faaye gba ifẹhonuhan, ṣugbọn kii ṣe nibi ti awọn oloṣelu ti n ṣakoso awọn janduku lati dabaru eto naa.

Bẹẹ lo ni ki awọn ọdọ tun ero wọn pa, ki wọn si ma ṣe gba awọn oloṣelu to jẹ ọta Naijiria laaye lati lo wọn fun iwa imọtara-ẹni nikan.

Ninu ọrọ rẹ, Oluwo sọ pe “ọpọ awọn ọdọ ọlọpọlọ pipe ni wọn ko ni iwe irinna lọ soke okun.

Ọpọ ni ko ni ile keji, ti wọn ko si ni mọlẹbi loke okun ti wọn le sare lọ ba.

Idi ree ti a fi gbọdọ sa gbogbo ipa ati agbara wa lati jẹ ki Naijiria duro.

Gẹgẹ bi ọba alaye si ilẹ yii, mo nigbagbọ pupọ ninu Naijiria.

Mo fi igbe aye irọrun silẹ ni Canada lati wa ko ipa temi ninu idagbasoke ati ilọsiwaju Naijiria.

Igbesẹ nla ni lati fi Canada silẹ wa jẹ ọba ni Naijiria.”

Oluwo ni oun ṣe eyi nitori pe oun nigbagbọ ninu ọjọ iwaju rere fun Naijiria.

Kabiyesi ọhun ni lati igba toun ti jọba loun ti ko ipa pupọ lati gbogun ti iwa jẹgudujẹra lagboole ọba.

“Ẹ jẹ ka fi iwa ọmọluabi ṣe gbogbo ohun ti a ba fẹ ṣe lati le jẹ ki awọn ti a yan sipo oṣelu ṣe daadaa. Abẹ atunto ni Naijiria wa bayii, ẹ ma ṣe ba a jẹ.

“Ipilẹ adojukọ Naijiria lo wọ lati ọdọ awọn oloṣelu to ti kọja.

Pupọ awọn orileede ni wọn gbe ijiya nla kalẹ fun awọn oloṣelu jẹgudujẹra, awọn ọdọ ni lati beere fun eyi.

“Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ni lati ṣiṣẹ lori eyi, ko si ṣe ohun ti ọmọ Naijiria n fẹ nipa gbigbogun ti awọn jẹgudujẹra.

Ilana yii ni yoo jẹ ki Naijiria dagbasoke, emi naa le kopa ninu ifẹhonuhan ni ilana alaafia,” Oba AbdulRasheed Akanbi lo sọ bẹẹ.

Ó rọ awọn araalu lati gbaruku ti awọn adari nipa adura lati ori aarẹ, to fi dori awọn gomina, sẹnetọ, awọn aṣoju-ṣofin titi de ori awọn alaga ijọba ibilẹ.

Ilé-iṣẹ́ ààrẹ fèsì sí pé Tinubu dá ‘subsidy’ orí epo padà torí ìwọ́de tó ń bọ̀

Ilé-iṣẹ́ ààrẹ fèsì sí pé Tinubu dá ‘subsidy’ orí epo padà torí ìwọ́de tó ń bọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀ yìí ti fèsì sí àhesọ ọ̀rọ̀ tó lu orí ìtàkùn ayélujára pa pé Ààrẹ Bola Tinubu ti dá owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù àti tàríìfù owó iná padà láti lè dá ìfẹ̀hónúhàn táwọn ọ̀dọ́ n gbèrò láti ṣe dúró.

Lọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keje yii ni atẹjade kan eyi to ṣalaye igbesẹ Tinubu lati da ifẹhonuhan to n bọ duro lu ori itakun ayelujara pa.

Àwọn olóṣèlú tó bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ ló ń ti àwọn èèyàn láti ṣe ìwọ́de – Sat Guru Maharaj-ji

Àwọn olóṣèlú tó bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ ló ń ti àwọn èèyàn láti ṣe ìwọ́de – Sat Guru Maharaj-ji

Ọrẹ Òtítọ́jù

Asíwájú ẹsin ìjọ One Love Foundation nílùú Ìbàdàn, Sat Guru Maharaj-ji ti fi ọ̀rọ̀ léde wi pé ìwọ́de tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń gbèrò láti gùnlé bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kìíní oṣù kẹjọ ọdún yìí kìí ṣe fún ànfàní orílẹ-èdè yìí rárá.

Ninu atẹjade to fi sita nibi ipade awọn oniroyin to waye lọjọ Aje ninu ọgba ile ijọsin rẹ to n bẹ lopopona marosẹ Ibadan si Eko, Maharaj-ji ni awọn oloṣelu ti o ti ṣe akoso orilẹede yii tẹlẹri lo ṣe okunfa awọn ipenija to n waye lọwọlọwọ bayii, bẹẹ sini iwa ajẹbanu ti bẹrẹ lati ipasẹ awọn Oyinbo tofun orilẹede Naijiria ni ominira.

Aṣiwaju ẹsin naa ṣe alaye wi pe ohun ti o tọ ni ki awọn eeyan ilu ṣe iwọde lati fi ẹhonu han, ṣugbọn iwọde naa le di nnkan to mu ewu dani ti wọn ba ti ọwọ oṣelu bọ ọ.

O tẹsiwaju wi pe iwọde naa ko ni anfani kankan ti yoo ṣe fun ẹya Igbo, Yoruba ati gbogbo awọn ẹkun Guusu ilẹ adulawọ nitori akoba ti o le ṣe fun eto oṣelu ati ọrọ aje Najiria.

Maharaj-ji kede wi pe ko si agbara tabi omimi kan ti o le yọ arakunrin ati adari ohun, Aarẹ Bọla Tinubu nipo. O ni ohun ti Aarẹ nilo ni lati ṣe amulo agbara ifẹ ti o fi ṣe akoso ipinlẹ Eko ti gbogbo nnkan fi tuba, ti o si tuṣẹ fun gbogbo eeyan.

MTN ti gbogbo iléeṣẹ́ wọn pa káàkiri Nàìjíríà

MTN ti gbogbo iléeṣẹ́ wọn pa káàkiri Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ MTN ti gbé àwọn ọ́fíìsì wọn tì pa káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.

Ìwòye ni pé èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn oníbàárà MTN ṣe yabo iléeṣẹ́ wọn lẹ́yìn tí MTN ti síìmù àwọn èèyàn lópin ọ̀sẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló yabo iléeṣẹ́ MTN láti wá ọ̀nà láti ṣí síìmù wọn padà, tí àwọn mìíràn sì gbìyànjú láti já ẹnu ilẹ̀kùn wọlé.

MTN ní nítorí àwọn èèyàn náà kò so nọ́mbà ìdánimọ̀ wọn mọ́ síìmù wọn ló jẹ́ kí àwọn ti àwọn nọ́mbà náà.

Àmọ́ MTN ti ní àwọn ti ti gbogbo iléeṣẹ́ àwọn pa káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Keje ọdún 2024.

Ojú òpó X wọn ni wọ́n fi ìkéde náà sí.

Ọnà tó lè fi jẹ ànfààní owó ìrànwọ́ okòwò N110bn tí ìjọba gbé kalẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ ní Nàìjíríà rè é o

Ọnà tó lè fi jẹ ànfààní owó ìrànwọ́ okòwò N110bn tí ìjọba gbé kalẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ ní Nàìjíríà rè é o

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ orílẹ-èdè Nàìjíríà ti ṣe àgbékalẹ̀ ètò owó ìrànwọ́ ìdókòwò N110bn fún àwọn ọdọ tí wọ́n ní ilé-iṣẹ́ àti okoòwò kéékèèké, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Nigeria Youth Investment Fund.

Owo yii lo wa lati fi mu imogbooro ati ilọsiwaju ba iṣẹ ti awọn ọdọ yan laayo, gẹgẹ bi ajọ NOA to n ri si ilanilọyẹ ṣe sọ.

Ijọba apapọ gbe eto yii kalẹ lati fi gbogun ti airi iṣẹ ṣe laarin awọn ọdọ, to jẹ pataki ipenija to n koju awọn araalu.
Ọjọ ori: Ẹnikẹni to ba fẹẹ jẹ anfaani owo eto yii gbọdọ wa laarin ọdun mejidinlogun si ogo ọdun. Ẹni ti ko ba tii pe ọdun mejidinlogun, tabi ti ọjọ ori rẹ ti kọja ogoji ọdun ko lanfaani sii.

Orileede: Akopa gbọdọ jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Naijiria.

Idanimọ: Akopa gbọdọ ni nọmba idanimọ ti a mọ si NIN, eyi to n ṣiṣẹ.

Agbekalẹ okoowo: Ẹni to ba fẹẹ jẹ anfaani gbọdọ ni agbekalẹ ilana iṣẹ tabi okoowo to fẹẹ ko owo le lori, ati ọna ti yoo gba lati fi mu imugbooro ba iṣẹ tabi okoowo naa, eyi to si gbọdọ wa ni ẹkunrẹrẹ.

Ọna to ja geere lati ye gbogbo akopa ni wọn gbe ilana lati fi orukọ silẹ naa gba, to si wa ni ṣisẹ-n-tẹle.

Iforukọsilẹ: Akopa gbọdọ fi orukọ ara rẹ, adirẹsi rẹ ati ohun gbogbo to nii ṣe pẹlu okoowo rẹ silẹ, lori ayelujara https://www.fmyd.gov.ng/nyif_application.

Lẹyin iforukọsilẹ yii, akopa gbọdọ tun fi ilana eto iṣẹ tabi okoowo rẹ lẹkunrẹrẹ silẹ; bi apẹẹrẹ, erongba rẹ, eto iṣuna, bi okoowo rẹ yoo ṣe ṣe daadaa laarin ọja to yan laayo, to fi mọ awọn ilana ti yoo gbe e gba lati maa pawo wọle deede.

Akopa gbọdọ fi awọn iwe ati kaadi to ṣe koko silẹ loju opo ayelujara ọhun, bii kaadi idanimọ NIN, nọmba idanimọ ti banki (BVN), ile-ẹkọ ti o lọ, iwe ẹri okoowo rẹ lọdọ ijọba apapọ (CAC Document), ijọba ibilẹ, ẹgbẹ aladugbo (CDA certificate) ati bẹẹbẹẹlọ.

Awọn iwe miran ni akọsilẹ lẹkunrẹrẹ lori ilana ti o fẹẹ gbe okoowo rẹ gba lati le jẹ ko ṣe daadaa laarin awọn akẹgbẹ rẹ, eyi ti ko gbọdọ ju abala oju iwe marun-un (5pages) lọ.

Bakan naa ni akopa tun gbọdọ ni oniduro meji ọtọọtọ ti yoo fi orukọ wọn silẹ loju opo ayelujara yii.

Akopa yoo fi orukọ oniduro meji silẹ, to fi mọ adirẹsi wọn, iṣẹ ti wọn n ṣe, imeeli, ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ati ipo ti wọn di mu silẹ.

Lẹyin ti akopa ba ti ṣe eyi tan, o tun gbọdọ pada lọ ṣe ayẹwo awọn ohun ti o fi silẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ boya o pe tabi o ku diẹ kaato, ki o to fi ranṣẹ.

Mọ daju pe ko si atunṣe kankan mọ, lẹyin ti o ba ti fi ranṣẹ.

Iṣẹ́ tíátà ni kò jẹ́ kí n kàwé – Ibrahim Chatta

Iṣẹ́ tíátà ni kò jẹ́ kí n kàwé – Ibrahim Chatta

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbajúmọ̀ òṣèré sinimá ti ilúmọọka jákèjádò àgbáyé ni Ibrahim Chatta. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nínú ifọrọwanilẹnuwo yìí, Ọmọ Tapa ni bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì wá láti ìlú Mọdakẹkẹ ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ rẹ̀, ó ní láti kékeré lòun ti mọ pé iṣẹ́ òṣèré tíátà lòun yóó ṣe jẹun, láti ìgbà náà wá lòun sì ti gbájúmọ́ ní ṣàn án.

Ibrahim Chatta ni Iṣẹ tiata ti gba ọpọlọpọ nnkan sọnu lọwọ oun. Lara rẹ si ni lilọ si ile ẹkọ.

O ni lọpọ igba nigba ewe oun lawọn obi oun maa n ro wi pe ile ẹkọ loun wa, amọṣa to jẹ wi pe ode ere loun morile.

“Awọn obi mi maa n ro pe ile ẹkọ ni mo wa, ṣugbọn mo ti tẹle awọn onitiata lọ nitori mo maa n ṣe ere tiata alarinjo nigba naa.”

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, iṣẹ are to wa nigba naa ni Arinjo eyi tawọ oyinbo n pe ni, “Travel Theater” ki ere to yirapada si sinima to wa lode oni.

“Mi o pari ileẹkọ girama, mi o ni iwe ẹri iwe mẹwaa ṣugbọn mo n ṣe eto ẹkọ agbelegboye.”

Gbajumọ elere itage naa tun ṣalaye pe funra oun loun kọ ara oun ni ede oyinbo bẹẹni ko si iwe ti oun ko le ka.

Lọdun 1985, iyẹn ọdun mọkandinlogoji sẹyin, ni Ibrahim Chatta bẹrẹ iṣẹ ere tiata.

O ni nigba naa, nibikibi ti awọn ba gbe ere lọ, awọn a ti tete maa ba awọn ọmọ olounjẹ ati alata bẹẹbẹẹ dọrẹpọ nitori lasiko ti ebi ba n pa wọn, awọn wọnyi lawọn maa n gbara le lati ye niagba naa.

O ni gẹgẹ bi elere, eeyan gbọdọ mọ gbogbo nnkan nitori pe elere nilo ọpọlọpọ nnkan yala lerefe tabi ni ijinlẹ.

Ọpọ lo maa n wi pe, eekan onitiata yii ti yẹ ko ti gba ọpọ ami ẹyẹ ti awọn ti wọn wo pe wọn ko dangajia to lagbo oṣere ti gba.

Awọn ololufẹ Chatta a tilẹ maa sọ pe iye oriyin to n gba kere si ipa to ni lagbo oṣere lorilẹede Naijiria lọ.

O ni oun ko gbagbọ pe oun dara ju alare kan lọ nitori pe, gẹgẹbi ọrọ rẹ, “gbogbo alare ni maa n daa loju emi.”

O ni ọpọ awọn ami ẹyẹ ti wọn ti gbe kalẹ ti awọn ololufẹ oun maa n wo pe wọn o ti fun oun ni ami ẹyẹ ko dede ri bẹẹ, “emi ni mi o fi sinima mi silẹ fun ayẹwo ami ẹyẹ naa.”

Ìjọba àpapọ̀ tún fẹ́ yá àádọ́ta mílíọ̀nù dọ́là ní bánkì àgbáyé

Ìjọba àpapọ̀ tún fẹ́ yá àádọ́ta mílíọ̀nù dọ́là ní bánkì àgbáyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ètó ti parí báyìí lórí bí ìjọba orílèèdè yìí ṣe máa lọ̀ọ́ yá àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà lọ́wọ́ bánkì àgbáyé.

Owo ọhun wa fun rira mita tawọn araalu yoo maa lo ninu ile, ina sola sawọn ipinlẹ lorileede yii ati fun iṣẹ idagbasoke nilẹ Naijiria.

Minisita fun eto ọrọ aje orileede yii, Ọgbẹni Wale Ẹdun, lo sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọruu, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, lẹyin ipade pataki kan to waye laarin awọn aṣoju ijọba orileede yii atawọn alaṣẹ banki agbaye, lọjọ Aje, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, l’Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa.

O ni ijọba apapọ ti fẹẹ lọọ ya aadọta miliọnu Naira lọwọ banki agbaye lati fi ra mita, ati lati fi ṣe ina sola sawọn ipinlẹ gbogbo lorileede yii. Ju gbogbo rẹ lọ, Ẹdun ni wọn maa lo lara owo naa fun iṣẹ idagbasoke lorileede yii.

Minisita ọhun ni awọn aṣoju ijọba orileede yii bii oun funra oun ati oludamọran fun Aarẹ lori ọrọ ina, Iyaafin Olu Verheijen, ati Dokita Diop Ndiame, lawọn ṣepade pẹlu awọn alaṣẹ banki ọhun, tawọn si ti fẹnu ko laarin ara wọn lori ọna ti orileede yii maa gba jẹ anfaani owo yiya naa laipẹ yii.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lọ bayii pe, ‘‘Ipade pataki kan ti waye laarin awọn aṣoju ijọba orileede yii ati banki agbaye lọjọ Aje. Koko ipade naa ni pe ijọba fẹẹ ya owo ele lọwọ wọn. Aadọta miliọnu Naira lowo ta a fẹẹ ya, iṣẹ ina sola atawọn iṣẹ idagbasoke kan la fẹẹ fowo naa ṣe. Gbogbo eto naa ti pari, awọn alaṣẹ banki agbaye naa si ti sọ pe awọn maa ya wa lowo naa, nitori pe nnkan to daa la fẹẹ lo o fun.

Banki agbaye yii lọpọ awọn orileede nilẹ Adulawọ maa n sa lọọ ba lọpọ igba lati ya owo ele lọwọ wọn fun iṣẹ idagbasoke nilẹ wọn.

Lọwọ yii, Naijiria ni orileede to ti ya owo ju nilẹ Adulawọ. Owo ta a ya lọdun 2023 din diẹ ni biliọnu mẹta dọla ($2.7B) lọdun 2022, orileede Naijiria ya biliọnu mẹta din diẹ dọla ($2.9B).

Láti ọdún kẹrin, nìyí, ó ti sú mi, ẹ tú wa ká- Kafayat

láti ọdún kẹrin, nìyí, ó ti sú mi, ẹ tú wa ká- Kafayat

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iwájú Onídàájọ́ Issa Abdulrasheed, tilé-ẹjọ́ kọkọ-kọkọ Area-Court, tó wà ní agbègbè Wáráh, nílùú Ilọrin, níìpínlẹ̀ Kwara, ni Abilékọ Kafayat Nurudeen, wọ́ ọkọ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Nurudeen Ambali, lọ. Ẹ̀sùn tí ìyàwó tí í ṣe olùpẹ̀jọ́ fi kan ọkọ rẹ̀ ni pé kò sí ìfẹ́ mọ́ láàrin àwọn, obìnrin ọ̀hún ní ìgbeyàwó ọ̀hún ti sú òun, ó lóun kò fẹ́ẹ́ padà sí ọ̀ọ̀dẹ̀ ọkùnrin náà mọ́, nítorí kò sí ọmọ láàrin àwọn méjèèjì láti bíi ọdún mẹ́rin ṣẹ́yìn táwọn ti ṣègbéyàwó. Fún ìdí èyí, kí adájọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́rin tó wà láàrin àwọn ká.

O ni, ‘‘Oluwa mi, ọrọ mi ko pọ rara nile-ẹjọ yii, ohun ti mo n fẹ gan-an ni pe ki kootu tu igbeyawo to wa laarin emi pẹlu ọkọ mi ka, ki kaluku wa maa lọ ni ayọ ati alaafia, o ti su mi. Ko sifẹẹ kankan laarin awa mejeeji mọ.

‘‘Kin ni idunnu ẹlẹwọn mi to n so aago m’ọwọ, ọdun kẹrin ree ti mo ti wa lọọdẹ ọkọ mi, a a gbọ pa, a a gbọ po, ọwọ osun ni mo fi n nu ogiri gbigbẹ. Ọkọ mi lọọ fẹ iyawo miiran, iyẹn ti bimọ fun un, kin ni mo wa n duro ṣe lọọdẹ rẹ. Nigba ti wọn fun ọkọ mi niwee pe ko waa pade mi ni kootu, o ni oun ko ni i yọju sile-ẹjọ.’’

Olujẹjọ Nurudeen Ambali, ko kuku yọju si kootu lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ loootọ. Gbogbo bi adajọ ṣe n fun iyawo lomi suuru mu pe ko maa kọ ọkọ rẹ nitori pe Ọlọrun lo n ṣ’ọmọ ko wọ Kafayat leti, o yari jalẹ ni pe o ti su oun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, Onidaajọ Issa Abdulrasheed, sọ pe o ti han ninu ọrọ olupẹjọ pe ifẹ ọkọ rẹ ti yọ lọkan rẹ.

O tu igbeyawo to wa laarin Kafayat ati Nurudeen ka nilana ẹṣin Musulumi. O paṣẹ ki Abilekọ Kafayat ṣe oṣu mẹta nile awọn obi ẹ ko too lọọ fẹ ọkọ mi gẹgẹ bi ẹṣin Islaamu ṣe gbe e kalẹ.

Wàhálà dé bá El-Rufai, àwọn aṣofin ìpínlẹ̀ Kaduna kọjú oro síi

Wàhálà dé bá El-Rufai, àwọn aṣofin ìpínlẹ̀ Kaduna kọjú oro síi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àpapọ̀ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Kaduna, ti gba gbajúmọ̀ lọ́ọ́yà ajàfẹ́tọ́ọ̀-ọmọnìyàn nnì, Fẹmi Falana, láti bá wọn wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, Nasir El-Rufai, lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ́n fi kàn án. Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Keje, ọdún yìí, ni àgbà lọ́ọ́yà ọ̀hún máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣa àwọn ẹ̀sùn tó máa fi kan El-Rufai jọ kó tóó di pé ó máa gba ilé-ẹjọ́ lọ. Àwọn ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan gómìnà tẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ni pé ó koó owó ìpínlẹ̀ náà jẹ lọ́nà àìtọ́, àti pé ó ṣi ipò rẹ̀ lò lásìkò tó fi wà nípò gómìnà ìpínlẹ̀ náà fún ọdún mẹ́jọ.

Iwadii tawọn aṣofin ipinlẹ naa ṣe nipa iṣakoso ijọba El-Rufai fi han pe o ko obitibiti owo ijọba ipinlẹ naa jẹ lasiko to fi wa nipo.

Bakan naa lawọn aṣofin ipinlẹ naa rọ awọn araalu ọhun pe ki wọn ma ṣe feti sọrọ tawọn oloṣelu ipinlẹ naa kan ti wọn ba El-Rufai ṣisẹ lasiko ijọba rẹ n sọ pẹlu awọn oniroyin.

Atẹjade kan ti alaga igbimo oluwadii ati igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Henry Magaji, fi sita laipẹ yii, ni wọn ti sọ pe, ‘’Ipade pajawiri tawọn oloṣelu ipinlẹ naa ti wọn ba gomina ana ṣiṣẹ pọ ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Abuja, laipẹ yii, ti de setiigbọ wa. Nibi ipade awuruju naa ni wọn ti n naka abuku si igbimọ oluwadii to n ṣewadi nipa ẹsun iwa palapala ta a fi kan El- Rufai, lasiko iṣejọba rẹ nipinlẹ Kaduna. Ara lo n ta wọn ba a ṣe fẹẹ ṣewadii nipa ẹni to gba wọn si iṣẹ, iyẹn gomina tẹle naa. Ọgbọn ti wọn n da ni pe wọn fẹẹ tabuku igbimọ oluwadii naa, kawọn araalu ma baa nigbagbọ ninu wa ni.

‘’Ṣe ni wọn fi ẹtẹ silẹ ninu ipade oniroyin ti wọn pe, wọn n pa lapalapa kiri. Wọn ko ṣoju abẹ nikoo. Bo ba jẹ pe loootọ ni wọn nifẹẹ ipinlẹ Kaduna lọkan, sẹ lo yẹ ki wọn fara ṣiṣẹ fun igbelarugẹ ipinlẹ naa ni, dipo bi wọn ṣe lọwọ ninu iwa palapala to sakoba nla fun idasoke ipinlẹ naa bayii.

‘’Loṣu Kẹfa, ọdun yii, ni awọn aṣofin yii kan an nipa fun El-Rufai pe ki o da biliọnu mẹrindinlọgọrin to loun san fun agbaṣẹṣe kan pada sapo ijọba. Igbesẹ naa waye lẹyin ti igbimọ alabẹṣekele kan ṣewadi nipa ina apa ti ọkunrin naa na lasiko iṣejọba rẹ. Iwadii wọn fi han pe, gomina ana ọhun sanwo tabua naa fun agbaṣẹṣe kan ti ko ṣiṣẹ kankan laarin ilu naa.

‘’Yatọ si eyi, oniruuru awọn iwa ibajẹ ti ko ṣee gbọ seti ni wọn ni ọkunrin yii hu lasiko to fi wa nipo gomina, ta a si feẹ ba a ṣẹjọ lori rẹ’’.

Ni kukuru, awọn aṣofin ipinlẹ naa ti sọ pe awọn ṣetan lati gbena woju gomina wọn tẹlẹ yii. Agba lọọya nni, Fẹmi Falana, ni wọn si ran niṣẹ naa pe ko waa ba awọn wọ ọ lọ sile-ẹjọ.