Home Blog Page 25

L’Ondo, Gómìnà Aíyedatiwa borí nínú ìbò abẹ́lé APC.

L’Ondo, Gómìnà Aíyedatiwa borí nínú ìbò abẹ́lé APC.

Gbọ́láhàn Quseem

Gómìnà tó wà lórí àléfà ní ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Orimisan Aíyedatiwa ló jáwé olúborí nínú ètó ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Eyi to n tumọ si pe Aiyedatiwa ni yoo ja du ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ APC ninu eto idibo ti yoo waye ninu ọdun 2024 yi.

Alaga igbimọ to dari eto idibo abẹle naa ni ipinlẹ Ondo, Gomina ipinlẹ Kogi, Ahmed Usman Ododo lo kede Lucky Aiyedatiwa gẹgẹ bi ẹni to jawe bori.

Aiyedatiwa ni ibo 48,569 láti f’ ẹyin ẹni to se ‘po keji, Olusola Oke to ni 14,915 ati awọn merinla miran ti
wọn jọ fí ‘gagbaga.

Ododo sọ pe awọn to ku, Wale Akinterinwa ni ibo 1,952, Mayowa Akinfolarin ni ibo 15,343, Jimoh Ibrahim ni ibo 9,456, Isaac Kekemeke ni ibo 1,045, Gbenga Edema ni ibo 395, Olamide Ohunyeye ni ibo 424, Jimi Odimayo ni ibo 490, Olusoji Ehinlanwo ni ibo 492, Morayo Lebi ni ibo 290.
Awọn to ku ni i Diran Iyantan toi ni ‘bo 348, Francis Faduyile ni ibo 353, Ifeoluwa Oyedele ni ibo 462, Funmilayo Waheed-Adekojo ni ibo 529 nigaba ti Funke Omogoroye ni ‘bo 115.

Gomina ipinlẹ Kogi náà sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ 171,922, lo forukọ silẹ lati dibo sugbọn awọn 95,178, lo kopa ninu eto idibo naa.

Ododo ṣalaye pe eto idibo naa lo waye lai si kọnu n kọhọ kankan ti gbogbo awọn oludije si figagbaga daadaa ni ‘lana ofin eto idibo orilẹ-ede Naijiria.

O dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn jade ni witiwiti lati yan ẹni tí yo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu eto idibo sipo Gomina to n bọ lọna. Ododo sọ pe ifarajin wọn lo mu ki eto ọun kẹṣẹjari.

Ododo wa rọ awọn oludije to ku lati ri eto idibo naa gẹgẹ bi ọrọ ọmọ iya, ati pe ko yẹ ko di ohun ti yo mu awọn miran darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu alatako nitori pe ọmọ iya ni gbogbo wọn, wọn si gbọdọ se ara wọn lọkan, bakanaa wọn gbọdọ ri daju pe ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu eto idibo to n bọ lọna.

Ẹwẹ, ni ijọba ibilẹ Ifẹdore ẹni to jẹ aṣoju agbegbe naa sọpe ko si eto idibo kan nijọba ibilẹ ọhun.

O ni wahala ṣuyọ eyi to mu ki awọn eniyan sa asala fun ẹmi wọn ti ko si si eto idibo kan rara ni gbogbo wọọdu ijọba ibilẹ naa.

Ní’lùú Eko, oníròyìn s’ àwárí ilé-ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó ń gba N42m lórí ọmọ kan lọ́dọọdún.

Ní’lùú Eko, oníròyìn s’ àwárí ilé-ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó ń gba N42m lórí ọmọ kan lọ́dọọdún.

Gbọ́láhàn Quseem

Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ làti gbọ́ pé ilé-ẹ̀kọ́ aláàkọ́bẹ̀rẹ̀ kan wà ní’lùú Èkó t’áwọn obí ti ń san mílíọ̀nù méjìlélógójì náírà lórí ọmọ kan ṣoṣo lọ́dọọdún.

Ẹwẹ, ile-ẹkọ Charterhouse to kalẹ si ilu Eko lagbegbe Lekki, ti jẹ ko di mimọ pe N42m l’obi kọọkan yo maa san lori ọmọ kan ti ile ẹkọ naa ba di ṣiṣi loṣu Kẹsan-an ọdun yii.

Ogunlọgọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n fi ẹhonu wọn han lori ayelujara lori owo gọbọi t’awọn obi o maa san nile ẹkọ naa.

Lẹyin N42m owo ile iwe, awọn obi o tun san miliọnu meji fun iforukọsilẹ, eleyii ti wọn o le ri gba pada mọ.

Ọpọ eeyan lo sọ pe owo naa ti pọju fun ẹnikẹni lati maa san fun ọmọ kan ṣoṣo pẹlu bi nkan ṣe ri lorilẹede Naijiria bayi.

Ni bayi naa, Damilola Olatunbosun, to jẹ adari ẹka ibaraẹnisọrọ ati igbaniwọle sile ẹkọ Charterhouse ṣalaye pe ile ẹkọ naa kii kan an ṣe ile-ẹkọ lasan.

Olatubosun ni ile-ẹkọ to lamilaaka ti muṣemuṣe rẹ si da muṣemuṣe ni ile ẹkọ Charterhouse eyi to gbaju gbaja kaakiri agbaye.

Olatubosun sọ mimọ pe ‘’ile ẹkọ Charterhouse jẹ ile ẹkọ t’awọn obi to ba mọ riri eto ẹkọ to ye kooro maa n fẹ lati mu ọmọ wọn lọ tori iyatọ wa
laarin ile-ẹkọ naa ati awọn miran.

O tun ṣ’alaye pe, ọpọ awọn obi lo ti gbe igbesẹ lati mu ọmọ wọn wa si ile ẹkọ naa tori wọn mọ pe ile-ẹkọ to wa nipo akọkọ laarin awọn ẹgbẹ ẹ ni ṣe.

Koda, N42m yi gan-an ko jọ wọn loju lati san tori owo ti wọn le san ni.

O fi kun pe lara awọn obi yi wa ni Naijiria, nigba t’awọn mi n gbe loke okun.

Wọn mọ riri iru eto ẹkọ t’awọn ọmọ wọn yo jẹ anfani rẹ ni ile-ẹkọ Charterhouse.

Ọrọ ki ṣe nipa bo ya owo ẹkọ naa wọn tabi ko wọn, ṣugbọn o ni ṣe pẹlu iru eto ẹkọ t’awọn akẹkọọ yoo jẹ anfaani rẹ.

Iru awọn obi to n mu ọmọ wọn wa si ile ẹkọ Charterhouse ti mọ pe owo t’awọn maa na maa pọju N42m lọ ti wọn ba fẹ ki awọn ọmọ wọn jẹ anfaani iru ẹkọ loke okun.

Bo tilẹ jẹ pe, a ko ti kọ gbogbo yara ikẹkọọ tan wa tan, mo le sọ pe ko si ile ẹkọ ni Naijiria to ni awọn ohun elo ikẹkọọ ati awọn ohun amayedẹrun to wa ni ile-ẹkọ Charterhouse.

Ko si iyatọ laarin ile ẹkọ Charterhouse at’awọn ile-ẹkọ to lamilaaka lorilẹ-ede Uk.

Bí kẹ̀ẹ́kẹ́ márúwá jíjí ṣe jẹ́ àwọn eléyìn lọ́wọ́ tó, ó pàpà yíwọ́

Bí kẹ̀ẹ́kẹ́ márúwá jíjí ṣe jẹ́ àwọn eléyìn lọ́wọ́ tó, ó pàpà yíwọ́

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù
Ọ̀jọ́ gbogbo bí ọdún ni tolè,ọjọ́ kan ṣoṣo ni ti olóhun tí àwọn yorùbá máa n sọ ti ṣẹ báyìí ó,bí ọwọ́ àwọn agbófinró ìpínlẹ̀ Èkó, lábẹ́ ìdarí Kọmíṣánnà ọlọ́pàá, CP Fayọade, ti tẹ géndé mẹ́rin kan tó jẹ́ jíjí kẹ̀ẹ̀kẹ̀ Márúwá ni iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò. Kẹ̀ẹ̀kẹ̀ mẹ́ta ni wọ́n lọ̀ọ́ jí gbé níléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti n ta àwọn kẹ̀ẹ̀kẹ̀ ọ̀hún, kọ́wọ́ tó bàwọ́n.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fi ọrọ yii lede loju opo ayelujara rẹ lọjọ Abamẹta, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ileeṣẹ kan ti wọn ti n to kẹẹkẹ Maruwa pọ, ti wọn si ti n ta a, eyi to fikalẹ si agbegbe Ọjọta, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran yii wọ, ti wọn si ji kẹẹkẹ mẹta gbe.

Hundeyin ni Akọwe ileeṣẹ onimaruwa ọhun lo mu ẹsun wa sileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti Ogudu, ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, pe awọn firi-nidii-ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe ẹda kan ti palẹ kẹẹkẹ mẹta mọ nileeṣẹ awọn ni nnkan bii aago meje idaji ọjọ naa.

Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti fọn sode, ti wọn si bẹrẹ si i tọpasẹ kẹẹkẹ naa kiri. Nibi ti wọn ti n fimu finlẹ ni wọn ti ri awọn afurasi ọdaran ti wọn ko fẹẹ darukọ wọn lasiko yii mu.

Hundeyin ni, “Ilu Ondo, nipinlẹ Ondo, ni wọn ti mu afurasi ọdaran kin-in-ni, wọn tọpasẹ rẹ dọhun-un ni, wọn si ba kẹẹkẹ Maruwa tuntun ti wọn ji lọwọ rẹ, nigba tọwọ ba afurasi keji ni agbegbe Mile 12, l’Ekoo, pẹlu kẹẹkẹ kan. Ipinlẹ Ogun, niluu Idiroko, leti ẹnubode Naijiria ati ilẹ Olominira Benin, lọwọ ti ba ẹni kẹta ati ẹkẹrin wọn pẹlu kẹẹkẹ tuntun ti wọn ji ọhun.

O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn, ati pe kete lẹyin iwadii, gbogbo wọn yoo lọọ kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Gbèse súyọ,màálù tó súnmọ àádọ́ta jẹ́ májèlé n’llọrin,wọ́n kú gífà

Gbèse súyọ,màálù tó súnmọ àádọ́ta jẹ́ májèlé n’llọrin,wọ́n kú gífà

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

À fi kí Ẹlẹ́dàá ó fòfò rẹ̀mí ni látàrí àjálù tó bẹ́lu àwọn òntàjà wọ̀nyí.
À fi bíígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lọ̀rọ̀ rí fún àwọn òntàjà kan tí wọ́n n ta màálù nínú ọjà Mandate, Adewọle, nílùú Ilọrin, ti i ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara, wà báyìí, pẹ̀lú bí màálù wọn tó lé ní ogójí ṣe kú lójijì látàrí májèlé tí wọ́n jẹ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ogúnjọ́, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí.

Oun ti a gbọ ni pe awọn ontaja ọhun ni wọn lọọ fi awọn maaluu wọn jẹko lati inu ọja Mandate, lọ si inu ọgba ileewe College of Arabic and Legal Studies, to wa ni agbegbe naa, ṣugbọn nigba ti wọn n dari pada bọ wale nirọlẹ ni awọn maaluu ọhun bẹrẹ si i wo lulẹ, ti wọn si n ku eyi to mu ki maaluu to le ni ogoji ku loju-ẹṣẹ, ti wọn si n sọ ọbẹ si wọn lọrun.

Ọkan lara awọn to n taja ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Olugbọn, to ba oniroyin ṣọrọ ṣalaye pe lasiko tawọn maaluu naa n dari bọ lati ibi ti wọn ti lọọ jẹ koriko ni wọn n ṣubu lulẹ latari pe wọn jẹ majele mọ ounjẹ ti wọn jẹ, o ni ọkẹ aimọye miliọnu lawọn ti padanu bayii ṣibi iṣẹlẹ buruku naa.

Olugbọn, ti waa rawọ ẹbẹ sijọba Kwara atawọn ẹlẹyinju aanu pe ki wọn ran awọn lọwọ lori adanu naa, nitori pe gbese nla lo wọle tọ awọn lasiko ti eto ọrọ-aje dẹnu kọlẹ, ti gbogbo nnkan ko si jọra wọn tẹlẹ, aforiti lawọn n ṣe.

Babalọja inu ọja naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni iṣẹlẹ ibanujẹ niṣẹlẹ naa jẹ fun gbogbo awọn to n ta maaluu ninu ọja, wọn waa rọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman Abdulrasaq, ko dide iranwọ fun awọn tọrọ kan.

Àpèrè Aláàfin: Ọ̀yọ́mèsì pe Gómìnà Mákindé lẹ́jọ́

Àpèrè Aláàfin: Ọ̀yọ́mèsì pe Gómìnà Mákindé lẹ́jọ́

Ọrẹ Òtítọ́jù
Kò jọ pé awuyewuye lórí taa ni yóó gàpèrè Ọba lẹ́yìn tí Ọba Lamidi Ọláyíwọlá Adéyẹmí kẹta gbésẹ̀ tíì lójútùú o pẹ̀lú u bí àwọn igun ti gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ti Ọ̀yọ́mèsì ṣe bẹ́nú fúnra wọn báyìí pẹ̀lú ẹjọ́ tí wọ́n pè ta ko gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjinníà Ṣèyí Mákindé, àti ìgbìmọ̀ ìjọba rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ oyè ọba ìlú Ọ̀yọ́ nù, ìgbìmọ̀ àwọn afọbaje ìlú ọ̀hún tún ti gbé Makinde lọ sí kóòtù, wọ́n ní ìdájọ́ tó dá a láre lọ́jọ́sí kò tẹ́ àwọn lọ́rùn rárá.

Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlnlogun (16), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, l’Onidaajọ Ladiran Akintọla, ti i ṣe adajọ ile-ẹjọ gjga ipinlẹ Ọyọ to wa niluu Aawẹ, nitosi Ọyọ, da ẹjọ naa nu patapata.

Marun-un ninu awọn Ọyọmesi yii, ti wọn tun jẹ Afọbajẹ ilu Ọyọ, ni wọn pẹjọ, wọn ni ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Gomina Ṣeyi Makinde, ko gbọdọ yẹ awọn lọwọ wo lori gbogbo igbesẹ ti awọn ti gbe lati gbe ọba tuntun gori itẹ gẹgẹ bii Alaafin tilu Ọyọ, nitori ọna ti awọn gbe kinni ọhun gba daa, o si wa ni ibamu pẹlu ofin ati ilana ifọbajẹ.

Nitori naa, wọn ni ki ile-ẹjọ paṣẹ fun Gomina Makinde ati kọmiṣanna feto idajọ pẹlu kọmiṣanna fọrọ oye jijẹ nipinlẹ naa lati fara mọ ẹni ti awọn fa kalẹ lati jọba, ki ijọba gbe ọpa aṣẹ fun un gẹgẹ bii Alaafin tuntun.

Wọn ni ẹni to n jẹ Ọmọọba Lukman Gbadegẹṣin ninu awọn ọmọ oye to n dupo ọba lawọn yan gẹgẹ bii Alaafin tuntun ni ọgbọnjọ (30), oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, awọn si ti fi orukọ rẹ ransẹ si ijọba,

awọn ko si fẹ ki wọn fagi le igbesẹ ti awọn fi yan ọkunrin naa bi ko ṣe pe ki wọn tẹwọ gba a, ki wọn si ṣe eto gbogbo lati gbe e gori itẹ.

Bakan naa ni wọn rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ pe wọn ko gbọdọ fi ibinu ẹjọ ti awọn pe yii rọ awọn loye, tabi yan awọn afọbajẹ mi-in lati fi ẹlomi-in to yatọ si Ọmọọba Gbadegẹṣin ti awọn ti fa kalẹ yii jọba.

Baṣọrun ilu Ọyọ, Agba-Oye Yusuf Layinka, to jẹ olori awọn Ọyọmesi (afọbajẹ), lo lewaju awọn olupẹjọ naa.

Orukọ awọn Ọyọmesi mẹrin yooku ni Lagunna ilu Ọyọ, Agba-Oye Wakeel Oyedepo; Akinniku, Agba-Oye Amusa Yusuf; Aarẹago Baṣọrun, Oloye Wahab Oyetunji; ati Alapo tilu Ọyọ, Oloye Gbadebọ Mufutau.

Koko ohun ti wọn tori ẹ pẹjọ ni pe ki ile-ẹjọ paṣẹ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ma ṣe tun yan ọmọ oye mi-in ti yoo jẹ Alaafin mọ, nitori nigba ti awọn yan Ọmọọba Gbadegẹṣin, gbogbo ofin ati ilana pata lawọn tẹle.

Nigba to n sọrọ lori awijare awọn olupẹjọ, Onidaajọ Akintọla, sọ pe niwọn igba ti awọn afọbajẹ ko ti fi abajade ipade ti wọn fi fa Alaafin tuntun kalẹ to ijọba leti ni ibamu pẹlu ilana, a jẹ pe ohun ti wọn ṣe ọhun ku diẹ kaato, nitori naa, ẹjọ ti wọn pe ko lẹsẹ nilẹ rara.

Ìròyìn Òwúrọ̀ ti ẹ gbọ pé, ko ju wakati meloo kan lọ ti ile-ẹjọ da ẹjọ ọhun nu, ti olori awọn agbejọro awọn olupẹjọ, Amofin-Agba Kunle Ṣọbaloju, ti pẹjọ kotẹmilọrun lori ọran naa.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, nile-ẹjọ yii ti kọ fagi le awijare awọn olupẹjọ, ti wọn si tun gbe ẹjọ mi-in dide ko too di pe ipa awọn eeyan naa pin nigba ti ile-ẹjọ da ẹjọ ọhun nu patapata.

Àfi sùúrù

*Àfi sùúrù*
Ẹni ayé yé jáwé ìyeyè
ni kòye.
ìdàndá lásán layé kò yémi
Só yé ọ?
Ẹni ayé yé kó sọ
Èèyàn táyé yé kó fọ̀
Ayé yé kò pamọ
Ìgbà dàgbà fìgbà hu langba
Tàgbà,màjèṣín tó ń fipò ṣègbè ìlú,
Ẹ finú pọnmi ayọ̀ síkùn,
Ẹ̀yin gan lẹ wáyé e re
Ànábì ò gbó tán tó fi bọ́kùn ẹ̀mí,
Jéésù ò jọjọ lọ́jọ́ orí sinmi sálákeji,
Agbára ò ràgbàlà ìdájọ́
À fi ká fọkàn mọ́ ,fàyà mọ́ àníyàn èrò rere
Báa bá ti finú mímọ́ wátẹ̀síwájú ẹni ń láálàṣé,
Ẹ jẹ́ á dunnú
A ti róore ayé kó lódindi
Ìwọ̀n sì lẹrù u bojì ó bààyàn.
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìkànnì Wásaàpù ni Gómìnà Kwara ti ń pàṣẹ ìlú lásìkò yìí -PDP

Ìkànnì Wásaàpù ni Gómìnà Kwara ti ń pàṣẹ ìlú lásìkò yìí -PDP

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), ní ìpínlẹ̀ Kwara, ti fẹsùn kan Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Abdulrahman Abdulrazaq, pé ṣe ló ń ṣe ìjọba Kwara nípasẹ̀ lílo àtẹ̀jíṣẹ orí ayélujára Wásaàpù, tó sì pa gbogbo àwọn iṣẹ́ àkànṣe òpópónà tó ń ṣe lọwọ́ ti gẹ́gẹ́ bíi aṣọ tó ti gbó.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Akọ̀wé tó ń gbé ìròyìn ẹgbẹ́ náà jáde, Ọ̀gbẹ́ni Oluṣẹgun Adewara, fi síta tó tẹ akọ̀ròyìn lọ́wọ́ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí, ló ti ní kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, lórí bó ṣe pa gbogbo àwọn iṣẹ́ àkànṣe òpópónà tó ń lọ ní ìpínlẹ̀ náà ti, tó sì ń bá ohun ti kò kàn án lọ́wọ́-lẹ́ṣẹ̀ kiri, pàápàá nípa òpópónà tó ń lọ lọ́wọ́ ní Èkó àti Calabar, tó pa àwọn èèyàn Kwara tó dìbò fún un tì.

Ó tẹ̀síwájú pé ohun ìyàlẹ́nu ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Kwara kò ṣe jẹ Gómìnà lógún mọ́, tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ló ń wà mọ́yà kiri.

Ó ni, “ Gómìnà wa ti kó lọ sí ìlú Àbújá tipẹ́, tó sì ń ṣe ìjọba Kwara látorí àtẹ̀jíṣẹ́ lórí Wásaàpù, tí yóò sì máa ya àwọn ayédèrú fọ́tò nígbàkúùgbà tó bá wá sílé.

“ Eléyìí kò lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́ rárá, nítorí pé Abdulrasaq ti sọ ìpínlẹ̀ Kwara di akúrẹtẹ̀ níbi tí kò ti sí ètò ààbò mọ́, tí ìjínigbé ń peléke sí i lójoojúmọ́. Bákan ni ẹ̀ka ètò ìlera àti ètò ẹ̀kọ́ ti dẹnukọlẹ̀, táwọn akẹ́ẹ̀kọ́ sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ igi gẹ́gẹ́ bí ìròyìn se gbé nípa ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Kánkán LGEA, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Asà, ní ìpínlẹ̀ náà.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti wáá késí Gómìnà Abdulrasaq, kó tètè padà wálé láti ìlú Àbújá tó lọ̀ọ́ jókòó sí, kó wáá lo gbogbo agbára rẹ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìgbáyé-gbádùn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara, kó sì lo ànfààní Alága ìgbìmọ̀ Gómìnà tó jẹ́ láti fi kóre wálé.

lkú bọlá jẹ́! Èèkàn olóṣèlú ìpìnlẹ̀ Kwara dágbére fáyé.

lkú bọlá jẹ́! Èèkàn olóṣèlú ìpìnlẹ̀ Kwara
dágbére fáyé.

lbrahim Adédèjì

Ọ̀kan nínú awọn ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ wa tẹ́lẹ̀, Sẹ́nétọ̀ Rafiu Ibrahim, la gbọ́ pé ó kú lójijì l’Ọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí, lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́tá (57).

ohun ti a gbọni pe aisan ranpẹ lo ṣe ọkunrin naa. Ojiji ni wọn ni ọkan rẹ daṣẹ silẹ, to si ku sileewosan kan niluu Abuja.

Sẹnetọ Rafiu Ibrahim jẹ ọmọ bibi ilu Òjòkú, ni Guusu ipinlẹ Kwara, o si ti figba kan jẹ ọkan lara awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja.

Owuyẹ kan sọ pe latibẹrẹ ọdun to kọja ni ara agba oloṣelu yii ko ya, ṣugbọn ti wọn ko pariwo rẹ sita, ko too waa di pe ọrọ naa yiwọ, ti aisan naa si pada mu ẹmi ọkunrin oloṣelu naa lọ.

O dije dupo ṣẹnatọ fun saa keji lọdun 2023, ṣugbọn o fidi-rẹmi, ti ipo naa si ja mọ ojugba rẹ, Lọla Ashiru, lọwọ.

Àwọn tó ní kí Ganduje lọ rọọ́kún nílé kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ APC – Abdullahi Abbas

Àwọn tó ní kí Ganduje lọ rọọ́kún nílé kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ APC – Abdullahi Abbas

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC níìpínlẹ̀ Kano ti sọ pé àwọn yóó gbé ìgbésẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe jáwé lọ rọọ́kún nílé fún Gómìnà tẹ́lẹ̀rí níìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Umar Ganduje, ẹni tó tún jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún lápapọ̀.

Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni ikun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Dawakin Tofa, iyẹn nibi ti Ganduje ti jade kede pe awọn ti jawe lọ rọọkun nilẹ fun baba naa.

Ko pẹ ti ikede naa bọ sita ni awọn agbaagba ẹgbẹ APC ni Dawakin Tofa naa sọrọ sita wi pe ala ti ko le ṣe ni ikede ọhun, ati pe ko le fẹsẹ mulẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kano, Abdullahi Abbas nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn to kede pe ki Ganduje lọ rọọkun nile ni wọn kii ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa.

Abbas sọ pe awọn to gbe ikede naa sita lo jẹ pe wọn sunmọ awọn oloṣelu to jẹ pe ẹgbẹ NNPP to n ṣakoso.

O ni awọn ti ṣagbeyẹwo iwe awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa lati agbegbe ti Ganduje ti wa, to si ni ko si eyi to jẹ oloye ẹgbẹ ninu wọn.

“Mẹtadinlọgbọn ni awọn to wa lati agbegbe kọọkan, a si yẹ wọn wo, a rii pe ko si eyi to jẹ oloye ninu wọn.”

Bakan naa lo sọ pe Haladu Gwanjo to kede pe ki Ganduje lọ rọọkun nile ti sọ pe oun yoo gba ile-ẹjọ lọ lati lọ ja fun ẹtọ ohun.

Abdullahi Abbas nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé “Eléyìí kó ní nnkan ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ ti wa, ìpinu tí ìjọba Kano àti ẹgbẹ́ òṣèlú wọn gb kalẹ̀ lèyí, a sì ríi pé ọ̀nà láti fi tàbùkù Ganduje ni.”

Bí Ọba Agbábìàká Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀ l’Ékòó se papòdà 

Bí Ọba Agbábìàká Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀  l’Ékòó se papòdà

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Kábíyèsí Ọba Kàbírù Agbábíàká, Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìsọlọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó ti jáde láyé; lẹ́yìn ádùrá ìtúnu ààwẹ̀ ní Ọjọ́rú nílùú Èkó.

Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ni Kábíyèsí Agbábíàká í ṣe kí ó tó jáde láyé. Ìwádìí fi yé wa pé Ọba Ọsọ́lọ̀ tó wàjà yìí jẹ́ ọba alayé tí kì í ṣe aládàníkànjọpọ́n, tí ó ṣì fi ayé rẹ̀ sin ìlú Ìsọlọ̀ àti ìpínlẹ̀ Èkó títí tí ọlọ́jọ́ fi dé. Ọba Agbábíàká ti fi ipa rere lélẹ̀ léyì táwọn èèyàn kò le gbàgbé láéláé.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìsọlọ̀, Họnọrebu Ọlásojú Adébáyọ̀ ló fìdí ìṣẹlẹ̀ yìí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta. Ó sọ pé “Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babájídé Sanwó-Olú ló fún òun láṣẹ láti kéde ìpapòdà Ọba Ìsọlọ̀, Kábíyèsí Kàbírù
Àlàní Adélàjà Agbábíàká Adéọlá Olúṣi Kẹta lọ́jọ́ kẹwàá oṣù Kẹrin ọdún 2024 yìí”.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babájídé Sanwó-Olú ń ṣèdárò Ọba Agbábíàká tó wàjà lọ́jọ́ ọdún ìtúnu ààwẹ̀. Sanwó-Olú sọ pé ”pẹ̀lú ìbànújẹ ọkàn ni òun fi gba ìròyìn ìpapòdà Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀.

Gómìnà Sanwó-Olú kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti àwọn èèyàn Ìsọlọ̀ lórí ìpapòdà Ọba Agbábíàká. Kí Elédùà tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí orúkọ rere tí ó fi sílẹ̀ má bàjẹ́ láéláé.”