Home Blog Page 20

Òǹkọ̀wé wọ gàù, wọ́n pè é lẹ́jọ́ fún ìwé tó kọ nípa ọmọ ààrẹ láì gba àṣẹ

Òǹkọ̀wé wọ gàù, wọ́n pè é lẹ́jọ́ fún ìwé tó kọ nípa ọmọ ààrẹ láì gba àṣẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ònkòwé ọmọ orílè-èdè Kenya kan, Webster Ochora Elijah, ló ti ń jẹ́jọ́ báyìí nítorí ìwé tó kọ nípa ọmọ Ààrẹ orílè-èdè náà, William Ruto, ìyẹn Charlene Ruto, láì gba àṣẹ kó tó kọ ọ́.

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kojá ni wọ́n fi ọwọ́ òfin mú Webster, wọ́n sì fi ẹ̀sùn pípe ara ẹni ní ohun tí kò jẹ́ kàn-án.

Iwe to pe akọle rẹ ni ‘Charlene Ruto and the Youth Uprising’, ni Charlene Ruto sọ pe ko yẹ ki onkọwe naa kọ lai sọ fun oun tẹlẹ.
Charlene sọ pe ohun ti onkọwe kọ nipa oun ko baa daa ju bẹẹ lọ, o yẹ ko kọkọ gba aṣẹ lọwọ oun ko too kọ ọ.

Ai gba aṣẹ naa lo pe ni aṣilo orukọ, to si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Iwe ipẹjọ ti wọn fi kede ẹsun naa ka pe lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un ni onkọwe kọwe naa pẹlu ero lati fi lu jibiti.

Ọun ati awọn kan ni wọn ni wọn jọ gbe igbesẹ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i mu awọn yẹn.
Ninu alaye awọn amoye nipa kikọ iwe nipa ẹlomi-in, wọn ni ko lodi labẹ ofin lati kọwe nipa eeyan lai kọkọ gba aṣẹ lọwọ ẹni naa.

Oloṣelu kan to tun jẹ agbẹjọrọ, Willis Otieno, ṣalaye pe “bii ẹni to n ṣi agbara ọwọ rẹ lo ni, ti eeyan ba sọ iwe kikọ di iwa ọdaran”.

“Onkọwe yii ko tako ofin nibi kankan”.

Oluyẹwo iwe, Mbugua Ngunjiri, lo ṣalaye bẹẹ lori iṣẹlẹ yii.

O tọka si bi wọn ṣe kọwe nipa aarẹ Kenya tẹlẹ, Uhuru Kenyatta, ni 2014,lai jẹ pe onkọwe naa gba aṣẹ lọwọ rẹ ko too kọ ọ.

“Miliọnu onkọwe le kọwe nipa eeyan ti wọn ko si ni i lufin nibi kankan. Ohun to le mu Charlene, ọmọ aarẹ sọrọ, ko ju ti wọn ba kọ ohun ti ko ri bẹẹ nipa rẹ”

Bẹẹ ni Mbugua Ngunjiri kọ ọ soju opo Facebook rẹ.

Ṣugbọn ọmọ aarẹ Kenya yii sọ fun awọn akọroyin pe o ti mọ wọn lara lorilẹede awọn lati maa fi orukọ awọn eeyan kọwe lai gbaṣẹ lọwọ wọn.

O ni ko yẹ ko ri bẹẹ.
Iwe to ko ẹni to kọ ọ si aroye yii ko si lori ayelujara, eeyan diẹ bayii lo si mọ onkọwe naa paapaa, ẹni ti wọn ni ọjọ ori rẹ ko ju mẹẹẹdọgbọn (25) lọ.

Yatọ si pe ko si lori ayelujara, wọn ko pin iwe naa sori atẹ rẹpẹtẹ pẹlu, awọn eeyan ko si mọ ohun ti iwe ọhun da le lori.

Awọn lọọya to n gba ẹjọ naa ro fun Webster to kọ ọ, sọ pe ohun to kọ ko lodi sofin.

Amofin Kennedy Mong’are, sọ fun awọn oniroyin pe oun gan-an ti kọwe nipa awọn eeyan pataki lawujọ ri, titi kan Raila Odinga to jẹ oloṣelu nla ati Aarẹ ilẹ America, Donald Trump.

Lọọya mi-in, Evan Ondieki, sọ pe awọn eeyan to wa nipo agbara gbọdọ mọ, pe araalu yoo gbọn wọn yẹbẹyẹbẹ nita gbangba.

To ba ti di pe araalu ko le sọ nipa wọn mọ, o tumọ si pe ẹtọ lati sọrọ ti n di titẹmọlẹ ni Kenya niyẹn gẹgẹ bo ṣe sọ.

“Ko yẹ ko le de ibi pe araalu yoo lufin nitori wọn lo aworan rẹ tabi kọ nipa rẹ.”
Bi a ba n sọ nipa eekan ọmọ aarẹ, ọkan ni Charlene Ruto laaye ara rẹ.

Igba kan wa ti wọn maa n fi ọmọbinrin yii we Ivanka Trump, ọmọ aarẹ America.

Ọpọ igba ni wọn ti fi Charlene ṣe alejo pataki lode, o si ti ba awọn olori ilu pade daadaa ni awọn ipade agbaye kiri.

Ni 2022, Charlene Ruto kede pe owo ilu kọ loun n lo lati fi gbọ bukaata ọfiisi ọmọ aarẹ ti wọn ya sọtọ fun un to si n dari ni Kenya.

Igbesẹ to gbe nipa orukọ rẹ ti wọn fi kọwe to di ẹjọ yii ko dun mọ awọn eeyan Kenya ninu.

Bẹẹ ni ile ẹjọ paapaa ti n kọminu si ai le sọrọ araalu ti wọn fẹẹ ko maa lọ bẹẹ yii.

Wọn fi eyi we bi wọn ṣe ti obinrin kan, Rose Njeri, mọle nitori ẹka oju opo ayelujara to ṣe fun araalu.

Oju opo naa wa fun ki araalu le fi aidunnu wọn han si kudiẹ-kudiẹ ijọba.

Ọjọ Ẹti ni wọn mu Njeri fun ẹka to n tako bijọba Kenya ṣe n nawo lọdọọdun naa.

Ẹsun iwa ọdaran lori ayelujara ni wọn fi kan an, ati lilo kọmputa nilokulo.

Wọn pada fi aaye beeli silẹ fun un di ogunjọ oṣu Kẹfa yii, nigba ti kootu yoo sọ boya yoo maa jẹjọ lọ tabi bẹẹ kọ.

Njeri paapaa ti dupẹ gidi lọwọ awọn eeyan Kenya, fun bi wọn ṣe panupọ gbeja rẹ, ti wọn jẹ kijọba mọ pe bi wọn ṣe mu un ti mọle ko yẹ rara ni.

Ojude Oba ti di ọjà àgbáyé – Dapo Abiodun

Ojude Oba ti di ọjà àgbáyé – Dapo Abiodun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọmọọba Dàpọ̀ Abíọ́dún ti ṣe àlàyé pé ayẹyẹ ọlọ́dọọdún tó máa ń wáyé nílùú Ìjẹ̀bú Òde, ‘Ojúde Ọba’ ti di ọjà tí gbogbo ayé n ná, ọjà yìí sì ti pakún ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ògùn l’ápapọ̀.

Ninu ọrọ ti o sọ nibi ayẹyẹ Ojude Ọba t’ọdun yii to waye lọjọ Aiku ni gbagede Ọba ti ọpọ eeyan mọ si ‘Pavilion’, Gomina Abiọdun ni gbogbo ile itura to n bẹ niluu Ijebu Ode ati ayika rẹ ni awọn alejo to wa fun ayẹyẹ naa gba tan, bẹẹ sini awọn oniṣẹ ọwọ naa ri ti aje ṣe.

Abiọdun fi kun ọrọ rẹ pe ayẹyẹ Ojude Ọba t’ọdun yii lo tobi julọ lati igba ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ naa nitori ọkan ọpọlọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ati ni oke okun ti fa si ajọdun naa.
Gomina ipinlẹ Ogun fi kun ọrọ rẹ pe Ojude Ọba kii ṣe ibi ayẹyẹ ti a ti n rin yan fanda ninu aṣọ alaranbara nikan, bikoṣe akanṣe eto ọlọdọdun ti a fi n ṣe akọsilẹ itan fun awọn iran to n bọ lẹyin.

O ni ayẹyẹ naa ti fi orukọ ilu Ijẹbu Ode ati ipinlẹ Ogun si ẹnu ọpọlọlọpọ eeyan lode agbaye, gẹgẹ bi o ṣe n pa kun eto ọrọ aje ipinlẹ naa.
Nitori idi eyii si ni ipinlẹ naa yoo si fi tẹsiwaju lati maa jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ ati ajọ ti o le mu okiki ipinlẹ Ogun lokiki si i lode agbaye.

O ni gbagede ti wọn lo fun Ojude Ọba ko gba ero mọ, o si ṣe ileri wi pe ijọba oun yoo wa nnkan ṣe si i.

Gomina Abiọdun dupẹ lọwọ igbimọ to ṣe eto Ojude Ọba ọdun yii fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe, o gbe oṣuba kare fun Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna ati awọn alejo pataki to fi ara han nibi ipejọpọ naa.
Lara wọn ni Minisita fun aṣa ati idagboke eto ọrọ aje nipasẹ ọgbọn atinuda, Hannatu Musawa, igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Olayide Adelami, Gomina tẹlẹri n’ipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Oṣọba, Olori Awujale ilẹ Ijẹbu, Adekemi Adetona ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn oṣere tiata bii Wale Ojo, Adedimeji Lateef ati Femi Branch ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.

Ọkanojọkan idile ati ẹgbẹ ẹlẹṣin to wọ aṣọ alaranbara lo rin yan fanda niwaju awọn alejo pataki to fi ara ha nibi ayẹyẹ naa.

Wọ́n fipá bá mi lò pọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́jọ láàárín wákàtí méje’ – Obìnrin Benue ṣàlàyé ìkọlù

‘Wọ́n fipá bá mi lò pọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́jọ láàárín wákàtí méje’ – Obìnrin Benue ṣàlàyé ìkọlù

Fẹ́mi Akínṣọlá

“Àwọn darandaran ya bo agbègbè wa, wọ́n kọẹ́ẹ̀ kọ́kọ́ mú àwa obìnrin, wọ́n fi wá pamọ́ sí ààyè ọ̀tọ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọlu àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń yìnbọn pa àwọn tí kò ríbi sá lọ nínú wọn.”

Bayii ni obinrin kan to foju wina ikọlu ni agbegbe Edikwu Ankpali, nijọba ibilẹ Apa, ipinlẹ Benue, ṣalaye fun akọroyin

Awọn eeyan ti wọn furasi pe darandaran ni wọn, ni wọn fẹsun kan wọn wa nidii ikọlu naa.

Ọjọ kin-in-ni si ọjọ keji oṣu Kẹfa, ọdun 2025 yii ni ikọlu ọhun waye.

Awọn obinrin bii mẹwaa ni wọn sọ pe ọpọ ọkunrin fipa ba lo pọ ninu ikọlu naa.
Wọn fi kun un pe awọn obinrin kan ṣi wa nileewosan bayii, ti wọn n gba itọju lọwọ latari ibalopọ ipa naa.

Ọkan ninu wọn sọ fun akọroyin pe ẹẹmẹjọ ni wọn fipa ba oun lo pọ laaarin wakati meje.

O ni lẹyin ti wọn ti kapa awọn ọkunrin ilu tan ni wọn bẹrẹ ibalopọ tulaasi naa laaarin ilu.

“Wọn ba mi lo pọ pẹlu ipa lẹẹmẹjọ ki ilẹ too mọ, awọn mi-in, ẹẹmẹwaa. Awọn darandaran naa to aadọta (50)”

Bẹẹ ni obinrin naa ṣalaye.

Ayẹyẹ Ojúde Ọba, t’ọdún yìí tún hẹ̀rìmọ̀

Àsà àti ìṣe

Aṣọ wíwọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

A fi àṣà àti ìṣe àsìkò yìí sọrí ayẹyẹ ọlọ́dọọdún Ojúde Ọba tí ọdún yìí. (June 2025)
Aṣọ jé ohun tí ènìyàń ń wọ̀ láti bo ìhòhò. Oríṣi ohun èlò ni a fi ń hun aṣọ, àwọn ohun èlò bíi òwú, ọ̀rá, awọ sílìkì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn híhun aṣọ, aṣọ tún nílò rírán kí ó tó le di wíwọ̀. Yàtò sí fún bíbo ìhòhò, aṣọ tún wà fún oge àti ìdánimọ. Àpẹẹrẹ oríṣi aṣọ ilé Yorùbá ni ìró àti bùbá, Agbádá, dànsíkí, búbù, kẹ̀mbẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (ní òpòlopò ìgbà) olùwọ àwọn asọ wọ̀nyí ma ń jẹ́ ojúlówó ọmọ Yorùbá .

Iró ati Bùbá jẹ́ orúkọ aṣọ tí ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn Obìnrin ẹ̀yà Yorùbá ní apá ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà má a ń wọ̀ . Ní ìbẹ̀rẹ̀, aṣọ yìí jẹ́ onípele márùn-ún, lára rẹ ni ìró èyí tí ó tóbi jù lọ tí wọ́n máa ń ró mọ́ ìbàdí. Nígbà tí Bùbá jẹ́ ẹ̀wù tí wọ́n ń máa ń wọ̀ lé orí ìró. Gèlè ní tirẹ̀, ni wọ́n máa ń wé sí orí. Wọ́n sì máa ń ró ìpèlé lé ori ìró kí ẹwà ìmúra wọn lè yọ dára dára . Wọ́n sì máa ń so ìborùn lé èjìká . Láfikún , orísìírísìí asọ èyí tó bá wu ni ni wọ́n le fi rán ìró àti bùbá , ó lè jẹ́ aṣọ òfì , léèsì, àǹkárá, dàńsíkí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ .

Abetí ajá, túmọ̀ sí “bí etí ajá”. Ó jẹ́ orísun Yorùbá, ìlú Ìbàdàn. Abetí ajá yìí ni fìlà tí a fi aṣọ òkè tàbí aṣọ àdìre rán. Ó jẹ́ apá kan ti aṣọ ọkọ ìyàwó máa ń wọ̀ nígbà ayẹyẹ ìgbéyàwó tàbí tí ọba, ẹni ọlọ́rọ̀ àti ẹni oyè máa ń wọ̀. Aṣọ òkè tí a fi ṣe fìlà abetí ajá yìí tún lè túmọ̀ sí aṣọ ipò gíga. Ó ní àgbékọjá méjì tó dàbí etí tó n má ń gbọ̀n bo etí, ìdí èyí ni wón máa ń pè é ní abetí ajá nítorí ó dàbí etí ajá. A máa ń wọ fìlà etí ajá yìí gẹ́gẹ́ bí aṣọ orí láti ṣe àfikún àwọn aṣọ abínibí bíi agbádá. Àṣà fìlà Yorùbá yìí dàbí ìgùn onígùn mẹ́ta tí ó ní etí méjì tí ó yọ jáde bí etí ajá. Àṣà yìí wọ́pọ̀ láàrin ọ̀dọ àti àgbàlagbà Yorùbá. Bákan náà, àwọn onílù ìbílẹ̀ Yorùbá kan fẹ́ràn láti wọ fìlà abetí ajá yìí. O lè wọ irú fìlà Yorùbá yìí kí o sì yí ipò àwọn ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ padà; wọ́n lè ṣe ìtọ́ka sí òkè, tàbí ṣe pọ̀ díẹ̀. Àṣà yìí jẹ́ ìgbà àtijọ́ àti pé ó jẹ́ olókìkí púpọ̀ pẹ̀lú aṣọ aṣọ-òkè àtijọ́.

Agbada jẹ́ aṣọ ìbílẹ̀ tí ó tóbi tí àwọn Yorùbá tí wọ́n ń bẹ káàkiri gbogbo ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà máa ń wọ̀, pàápàá jùlọ láàrin àwọn tí wọ́n ń bẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Benin, àti Togo. Agbádá jẹ́ èyí tí ó sáábà máa ń wá tí a sì máa ń wọ̀ pẹ̀lú bùbá tí ó jẹ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí ó le wá ní onírúurú, àti ṣòkòtò gígùn tí a le wọ̀ si pẹ̀lú. A sáábà máa ń wọ̀ ọ́ pẹ̀lú onírúurú fila tàbí abeti aja. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a máa ń wọ ìlẹ̀kẹ̀ ìbílẹ̀ lé Agbádá. Agbádá jẹ́ aṣọ ìmúra àwọn ọkùnrin èyí tí wọ́n máa ń wọ̀ lọ sí onírúurú ìjáde tàbí ibi ayẹyẹ. Ó máa ń wá ní onírúurú àràǹbarà.
Kí á má làágùn jìnà ẹ̀rí
máa jẹ́minìṣó ti wà nílẹ̀
yanturu látinú àpẹẹrẹ àṣọ tí àwọn bọ̀rọ̀kìní wọ̀ níbi yẹyẹ ojúde ọba tọdún yìí.
Ṣé àwọn àgbà ní ọdọ̀ọọdún ni pèrègún yọ pẹ̀lú àwọ̀ ọ̀tun, béèbù bá rà lébè, dandan ni ká fojú kan iṣu mùyẹ̀ ègbodò.
Ayẹyẹ Ojúde Ọba, t’ọdún yìí tún hẹ̀rìmọ̀ ,àwòdamiẹnu aláràǹbarà aṣọ ìbílẹ̀ tó
n ṣàfihàn ojúlówó ọmọ yorùbá tí kò gbàgbé orírun wọn ni wọ́n wọ̀ ṣe ìgbélárugẹ àṣà.
Kó má dà bí àsọdùn, ẹ mójú ṣẹ̀rí ọ̀rọ̀ .

Balógun Kúkù, bàbá olówó tó mú ẹ̀sìn Islam wọ ilẹ̀ Ijebu, tó tún bẹ̀rẹ̀ ọdún Ojúde Ọba

Balógun Kúkù, bàbá olówó tó mú ẹ̀sìn Islam wọ ilẹ̀ Ijebu, tó tún bẹ̀rẹ̀ ọdún Ojúde Ọba

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní òní ni yóó pète ọ̀la, ìtàn ni yóó ròyìn èèyàn.
Bí a bá wá n sọ̀rọ̀ nípa àkọni tiwa nílẹ̀ yorùbá, òdú ni Balógun Kúkù nilẹ Ìjèbú, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì mọ ilé àwòdamiẹnu tó kọ́ sílùú Ijẹbu Òde, èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn eléré tíátà má a ń lò fún eré wọn lásìkò yìí.

Asíwájú fún ìdílé Balógun Bello Kúkù nílùú Ìjèbú Òde, tó tún jẹ́ Ọgbeni Ọjà tilẹ̀ Ìjèbú, Olorogun Ọmowé Sunny Folorunso Kuku, sọ̀rọ̀ nípa ìtàn ayé akọni jagunjagun yìí, Balógun Kúkù.

Olorogun Kúkù, ti i se iran kẹfa si akọni jagunjagun naa ni, apetan orukọ baba nla idile awọn naa ni Bello Odueyungbo ( Ifa ko lọ sinu igbo) Bórogún.
Wọn fun un ni orukọ naa nitori bi iya rẹ ṣe bi, lo ku.

Orukọ naa wa lati ara gbolohun “iya Kú, ọmọ Kù”. Apapọ rẹ lo di Kúkù.

“Mama to bi baba nla wa yii ku laarin ọjọ mẹta to bi, mama mama rẹ lo tọ ọ dagba, to si kọ Kúkù ni ọna okoowo.

Kúkù n se okoowo karakata, to si n ta nnkan ijagun nilẹ Yoruba. Eyi lo sọ ọ di olowo tabua, milọnia, ko to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun.

Bi ogun ba wa nilẹ Yoruba, ẹni ti Kúkù ba se atilẹyin fun pẹlu nnkan ijagun, ni yoo bori ogun naa, to si ni orisirisi ọta ibọn to maa n ta fun ẹni kọọkan.
Ogbeni Ọja salaye siwaju si pe idi katakara eroja ijagun yii ni Balógun Kúkù ti di jagunjagun nitori o ni ibọn ati ọmọ ogun pupọ ti yoo daabo bo awọn to ba kọwọrin pẹlu rẹ.

“Bi ogun ba de, Balógun Kúkù lo ma siwaju ogun fun ilẹ Ijẹbu, o lowo lọwọ, onisowo ni, to si maa n doju kọ awọn adigunjale.

Oun si ni Awujalẹ maa n lọ lati jagun bii ogun Kiriji, ohun si ni Olori awọn Parakoyi onisowo to di ẹgbẹ awọn onisowo Chambers of Commerce loni yii.”
Nigba ti Oloye Sunny Kuku n salaye ipa ti Balógun Kúkù ko ninu awọn ẹsin igbalode ti igbagbọ ati Musulumi nilẹ Ijebu, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ.

Lara ohun to pa ni lẹrin ni itan bi Balógun Kúkù se gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ ti akude wọ igbesẹ rẹ naa.

Gẹgẹ bi Sunny Kúkù ti wi, awọn Krisitẹni lo wọ ilu Ijẹbu Ode wa, ti wọn si wa waasu fun Balogun Kuku lati di ọmọlẹyin Kristi tori o ni ero pupọ.

“Balógun Kúkù lo ni ilu, o si fẹran ẹsin Krisitẹni naa , to si gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ Pasitọ sọ fun pe yoo mu ọkan soso ninu iyawo marundinlaadọrin to ni.

Kuku wa sọ fun Pasitọ pe ko wa lọjọ kan lati wa se iribọmi fun oun, ti yoo si tun ba oun mu iyawo kansoso ninu awọn iyawo oun, ti yoo sẹku sinu ile.

Kuku pe awọn iyawo rẹ, to si salaye isẹlẹ yii fun wọn, awọn iyawo duro de Pasitọ, bo si se de, wọn ko pankẹrẹ bo Pasitọ, ti wọn si lu jade kuro ninu ile wọn.”

Ọgbẹni Oja ni idi ree ti Balogun Kuku ko se di ọmọlẹyin Kristi mọ, se o kuku mọọmọ da ete fun Pasitọ ni, to fẹ ba le gbogbo iyawo rẹ danu.”

Oloye Sunny Kuku tẹsiwaju pe lẹyin ti Kuku ko di Krisitẹni mọ, wọn wa fi ẹsin Islam lọ ọ, to si tẹwọgba nitori ẹsin naa fun ni anfaani lati ni ọpọlọpọ iyawo.

“Bi Kuku se di Musulumi ni ida aadọrun eeyan ilu Ijebu Ode naa yipada di Musulumi, to si we lawani fun gbogbo wọn.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ maa n lọ ki ọba Awujalẹ lasiko ọdun wọn ni ọdọọdun amọ bi Kuku ati awọn eeyan Ijebu Ode ṣe di Musulumi, ni wọn yi ikini naa pada si abẹwo si ọdọ ọba ni ọjọ kẹta ọdun Ileya.

Abẹwo asiko ọdun Ileya yii ni wọn pe ni Ojude Oba, ti Balogun Kuku yoo si lewaju awọn araalu lati lọ ki Awujalẹ.

Ẹsin Islam di itẹwọgba nilẹ Ijẹbu nitori Balogun Kuku, o lowo, o lọla, to si ni ero rẹpẹtẹ lẹyin.”

Awujalẹ fi Balogun Kuku jẹ oye Olorogun, to tumọ si Olori ogun, eyi ti idile Kuku n jẹ titi di oni oloni.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Sẹ́nẹ́tọ̀ Rashidi Ládọjà naa kirun ọdún

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Sẹ́nẹ́tọ̀ Rashidi Ládọjà rè é ,pẹ̀lú àwọn èèyàn bíi Teslim Folárìn, Hazim Gbọ́lárùmí àti àwọn èèyàn pàtàkì mìíràn tí wọ́n jókòó ní yídíì fún ádùrá ọdún

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Adémọ́lá Adélékè, darapọ̀ mọ́ àwọn mùsùlùmí ní Yídíì ìlú Ẹdẹ láti kírun ọdún

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Adémọ́lá Adélékè, darapọ̀ mọ́ àwọn mùsùlùmí ní Yídíì ìlú Ẹdẹ láti kírun ọdún

Sheikh Sulyman Amubieya dúran àgbò

Sheikh Sulyman Amubieya dúran àgbò ni kété tí wọ́n kírun tán ní pápá yídíì Amubieya tó wà ní ìyànà Bódìjà lbadan

Omíyalé pa ọgọ́rùn-ún èèyàn ní ìpínlẹ̀ Niger, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣègbé

Omíyalé pa ọgọ́rùn-ún èèyàn ní ìpínlẹ̀ Niger, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣègbé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó ti tó ogórùn-ún kan àti méwàá èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn báyìí nínú ìjàǹbá omíyalé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Niger.

Adele ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger, (Niger State Emergency Management Agency) NASEMA, Dokita Ibrahim Husain, fidi onka naa mulẹ fun akọroyin.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Alẹ Ọjọruu ọsẹ yii ni iṣẹlẹ omiyale ọhun waye nijọba ibilẹ Mokwa.

Ojo nla to rọ lo fa a ti omi fi ya bo awọn ile kiri, to ba ọpọ ile itaja jẹ pẹlu awọn ọja ti wọn n ta.

Ojo naa ko ṣai ba awọn nnkan oko jẹ pẹlu, bi alaye ti wọn ṣe.
Atẹjade ti NASEMA fi sita l’Ọjọbọ, ṣalaye pe agbegbe meji ni idaamu omiyale naa ba.

Awọn adugbo naa ni Tiffin Maza ati Anguwan Hausawa to wa niluu Mokwa, nijọba ibilẹ Mokwa.

“Ojo nla rọ fun ọpọ wakati, bẹẹ ni àgbàrá ojo bẹrẹ si i pọ si i to si n bo awọn ile mọlẹ.

“Omi naa bo ile to le ni aadọta (50), mọlẹ pẹlu awọn eeyan to wa ninu rẹ.”

Bẹẹ ni atẹjade NASEMA wi.

Ajọ naa ni oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ibilẹ Mokwa, awọn omuwẹ ati awọn akin eeyan to ba le ṣe iranwọ lati maa doola awọn eeyan ti ko ba ti i ku.

Bakan naa ni wọn ni wọn yoo maa gbe awọn to ba ti ku jade.
Atẹjade NASEMA tẹsiwaju, pe eeyan mẹta ti i ṣe obinrin kan ati awọn ọmọde meji lawọn ti doola ẹmi wọn.

Ileewosan ijọba to wa ni Mokwa ni awọn mẹta naa wa bayii bi NASEMA ṣe wi, wọn n gba itọju fun ijaya to mu wọn ati ara ti wọn fi ṣeṣe.

Ni ti awọn ti wọn ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ajọ yii sọ pe oku eeyan mọkanlelogun (21) ni awọn gbe jade.

Ṣugbọn iroyin to gbode bayii ni pe o ti le ni oku ọgọrun-un (100) ti wọn gbe jade latari ijamba naa.

Ninu ọrọ olori agbegbe Mokwa, Muhammad Shaba Aliyu, o ni o ti le ni ọgọta ọdun (60), ti iru iṣẹlẹ bayii ti waye gbẹyin.

O rọ ijọba lati ran wọn lọwọ ni gbogbo ọna.

Iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii, a o maa mu iroyin wa bo ba ṣe n lọ.

Kàyééfì! Rògbòdìyàn ní Òmù Àrán láàrin ọlọ́pàá, afurasí ọmọ Yahoo àti àwọn ọ̀dọ́

Kàyééfì! Rògbòdìyàn ní Òmù Àrán láàrin ọlọ́pàá, afurasí ọmọ Yahoo àti àwọn ọ̀dọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìfẹ̀hónuhan ńlá gbilẹ̀ nílùú ìlú Òmù-àrán ní ìjọba ìbílẹ̀ Irẹpọdun ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ifẹhonuhan naa to bẹrẹ lọjọ Aìku, ọjọ Kẹdọgbọn oṣu karun un, to si tun tẹsiwaju ni Ọjọ Aje, Ọjọ kẹrindinlọgbọn osu karun un bakan naa.

Gẹgẹ bí iroyin tí a gbọ, Ọgbẹni Sẹgun to jẹ ọmọ bibi ilu Omu-aran ṣalaye pe Ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye.

Awọn eeyan diẹ farapa lasiko ifẹhonuhan naa gẹgẹ bii ohun ti a ri gbọ.

Segun ni lati bi ọjọ melo kan si asiko yii ni awọn ọlọpaa ti mu awọn ọdọ ni ilu naa, ti wọn si n fẹsun kan wọn pe wọn lọwọ si iwa ọdaran ori ẹrọ ayelujara .
O fikun pe ọrọ yii lo bi ọpọ awọn ọdọ ilu ninu ni pe ati awọn to n se Yahoo ati awọn ti ko ṣe Yahoo lawọn agbofinro mu ti wọn ṣi ahamọ wọn.
Segun salaye pe eyi lawọn ọdọ ri gẹgẹ bi iwa irẹnije ti wọn fi yari mọ awọn agbofinro lọwọ.

Bakan naa, Ọgbẹni Lekan Ọlawale sọ pe awọn ọdọ ilu binu si iwa ilọnilọwọ gba tawọn agbofinro n hu ni ilu naa.

“Awọn agbofinro mu awọn ọdọ ilu ti wọn kìí se ọmọ yahoo, ti awọn obi wọn si n lọ fi owo gba wọn kalẹ lagọ ọlọpaa, nigba to di ọjọ keji wọn tun tun wọn mu pada.

“Eyi lo si bi awọn ọdọ ati awọn obi mi ninu ti wọn fi bẹrẹ ifẹhonuhan lana.”

O fikun kun ọrọ rẹ pe ibi tawọn ọdọ ti wọn jẹ yahoo ti n se fàájì lawọn ọlọpaa ti lọ mu wọn.

“Ti awọn ọdọ si bẹrẹ si ni dana sun taya lana, ti wọn ṣi lọ koju awọn ọlọpaa, lẹyin naa lawọn ọlọpaa lọ mu awọn ọdọ ninu ile lọ kọọkan ati ẹni to kan ati ẹni ti ko lọwọ ninu ọrọ naa.
Lekan Ọlawale salaye pe wọn ti ko awọn ologun wọ ilu Omu-Aran bayii.

O fikun pe oni ọjọ isẹgun lọja ìlu Omu-aran, ṣugbọn wọn o ni naja lọla nitori iṣẹlẹ yii.

O salaye pe bi wọn se bẹrẹ ifẹhonuhan, ni wọn gba aafin kabiyesi ilu naa lọ.

“Ibi ti wọn ti n fẹhonuhan lọwọ lawọn ọlọpaa ti tu wọn ka pẹlu afẹfẹ tajutaju (tear gas).”

“Igba ti agbara awọn ọlọpaa ko fẹ ka wọn mọ lawon osisẹ ajọ eleto abo ara ẹni labo ilu Civil Defence naa kun wọn lọwọ.

Ibẹ naa ni awọn ọmọ ologun ti wọle de, ni ọrọ si di bo lọ, ko yago fun mi.”

O ni se lawọn obirin naa tu jade lọpọ lati darapọ mọ awọn to n fẹhonuhan.

Ninu atẹjade kan eyi ti alaga ẹgbẹ idagbasoke ilu Omu-Aran, Ọgbẹni Niyi Adeyeye fi sita, o rọ awọn araalu naa lati gba alaafia laaye.

Alaga naa ni araalu to ba ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iṣẹlẹ naa, ko fi to awọn leti.
Ninu ọrọ rẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Adetoun sọ pe rogbodiyan naa bẹrẹ lọjọ Sunday ọjọ kẹdọgbọn oṣu yii lasiko ti awọn ọlọpaa lọ mu ogbologbo alagbata ogun oloro ti orukọ rẹ n jẹ Azeez, AKA A Z.

Lasiko ti wọn gbe lọ si agọ ọlọpaa lawọn janduku ọdọ da awọn ọlọpaa lọna, ti wọn si gbe Afunrasi na lọ.

O salaye pe wọn tun lọ dana sun ọkada ọlọpaa to jẹ ẹṣọ alaabo fun Kabiyesi ni aafin.

Adetoun fi kun pe awọn janduku ọdọ yii kan naa lọ kọlu agọ ọlọpaa tawọn ọlọpaa ko si ri iṣẹ ṣe.

Bakan naa lo ni awọn janduku yii kọlu ile ifowopamọ alabde ti Olomu Aperan, wọn ju okuta, wọn si ba CCTV camera jẹ ati awọn ọkọ mẹta to wa ni ile ifowopamọ si naa,

O salaye pe bi awọn ọlọpaa se de sibẹ, ni wọn na papabora, ti awọn ọlọpaa si doola awọn oṣiṣẹ marun ile ifowopamọ si naa.

Adetoun ni ọwọ ti tẹ eeyan marun lori iṣẹlẹ ikọlu naa.

O ni Kọmisona ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo ti pasẹ ki eto aabo tun gbopọn si pẹlu iparaaro awọn ọlọpaa yika igboro ilu naa.

Adetoun ni iwadii si tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa, o wa rọ araalu lati gba alafia laaye ki wọn si fọwọso wọpọ pẹlu ajọ ọlọpaa.