Home Blog Page 19

Ọmọ mẹ́sàn-án ni mo bí. Méje nínú wọn ló wà ní ìlú òyìnbó – Yinka Quadri

Quadri

Mudasir Alabi

Osere fiimu pataki, Alagba Yinka Quadri, ti so nipa oore nla ti Olorun ti se fun oun nidii ise tiata.

O ni omo mesan-an ni Olorun jogun fun oun, to si je pe meje ninu won lo wa ni oke okun.

Bakan naa, o ni oun ti ra ile mo ile, ti oun si ti ra moto mo moto.

Ninu fidio kan to ti n gba okan lara awon omoose re nimoran lori bi eniyan se n se aseyege lo ti so oro yii.

Alagba Quadri ni oun ko figba kan kuro nidii ise tiata ri.

O wa yombo baba to bi i lomo, eni to jo pe Olorun jogun owo ati dukia repete fun.

Osere naa se alaye pe baba oun maa n paaro moto fun oun ni nigba ti oun wa lodoo.

O fu kun un pe oun tun jogun ie lowo baba naa.

 

Ko̩miso̩nna o̩ló̩pàá Eko gb’ósùbà fún Alága Olufunke̩ lórí àgó̩ o̩ló̩pàá tuntun O̩re̩gun

Ko̩miso̩nna o̩ló̩pàá Eko gb’ósùbà fún Alága Olufunke̩ lórí àgó̩ o̩ló̩pàá tuntun O̩re̩gun

Yínka Àlàbí

Osu me̩rin pere ni Alaga Arabinrin Rekiya Olufunke Hassan fi ko̩ ago̩ o̩lo̩paa ni oregun. Ko̩miso̩na o̩lo̩paa ipinle̩ Eko, Olohunde Mo̩shood Jimoh funra re̩ lo wa si ago̩ o̩lo̩paa naa. O si so̩ ago̩ kekere di nla. Gbogbo awo̩n ara adugbo si pa ate̩wo̩ nla.
Ile ori oke ni Alaga ko̩ si ibe̩, bi o tile̩ je̩ pe ago̩ o̩lo̩paa ti wa nibe te̩le̩ ki ija kan to be sile̩ nipa o̩lo̩paa to seesi yinbo̩n pa ara ilu kan, eyi mu ki awo̩n o̩do̩ dana sun ago̩ o̩lo̩paa ni igba naa ni o̩jo̩ ko̩kandinlo̩gbo̩n, osu ke̩rin, o̩dun 2023.
Awon ara adugbo Oregun fe̩re̩ le maa sepe ni ibi ti adura wo̩n po̩ to. Wo̩n ni aimoye “ojo lo ti ro̩ ti ilb ti fa mu” wo̩n ni o̩po̩ Alaga ‘lo ti ko̩ja bi ejo to lo̩ lori apata’ ni onigbongbon .
Gbogbo awo̩n eniyan jankan jankan bi alaga CDA Oregun, O̩gbe̩ni Yo̩mi David, awo̩n opomulero e̩gbe̩ bii-
Kayode opayemi, Alh Olorunosebi, DCP Fatai Tijani. Com Oyedeji,  Abiodun Osineye ati be̩e̩ be̩b lo̩.
Imaam Jelili to je̩  Alfaa adugbo naa lo se adura ipari.

China ń gbèrò láti fagilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti Africa

China ń gbèrò láti fagilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti Africa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orílẹ-èdè China ti kéde pé òun ṣetán láti wọ́gilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti orílè-èdè Áfíríkà mẹ́tàléláàdọ́ta tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú orílè-èdè ọ̀hún .

Ikede yii jade nibi ipade to waye laarin China atawọn orilẹede Afirika, eyi ko si ṣẹyin bi Aarẹ Donald Trump Amẹrika ṣe kede afikun owo ori tariifu lori ọja to n wọ Amẹrika lati Afirika laipẹ yii.

China ni orilẹede ilẹ okeere to n ba Afririka dokowo julọ lagbaaye, China si ti wa ni ipo yii fun bii ọdun mẹẹdogun bayii.
Ẹwẹ, ọja ti ko din ni $170bn lawọn orilẹede Afirika ko wọ China lọdun 2023 nikan.

Atẹjade ti China atawọn orilẹede Afirika to ṣepade pọ fi sita bẹnu ẹtẹ lu bawọn orilẹede kan ṣe fẹ da ibaṣepọ to wa laarin awọn orilẹede naa ru nipa afikun owo ori tariifu.
Wọn wa ke pe orilẹede Amẹrika lati wa ojutuu si ede-ai-yede to ba waye lori idokowo lai mu wahala da ni.

Ti igbesẹ yii ba wa si imuṣẹ, yoo jẹ ara asọyepọ to waye pẹlu China lọdun to kọja lati wọgile owo ori tariifu ori ọja to n wọle lati orilẹede Afirika mẹtalelọgbọn ti wọn ko tii dagba daadaa.

Ni bayii, awọn orilẹede nla nla lati Afirika to n ba China dokowo bii Naijiria ati South Africa naa yoo jẹ anfaani yii.

Orilẹede China ko tii sọ igba ti igbesẹ yii yoo wa si imuṣẹ ni pato.
Ẹwẹ, orilẹede Eswatini nikan ni ko ni jẹ anfaani yii nitori o ri Taiwan gẹgẹ bi orilẹede olominira, eyi ti China ri gẹgẹ bi ẹkun to ya kuro.

Oriṣiiriṣii nnkan alumọni ni China n ko wọle lati Afirika lọwọ yii papaa julọ lati DR Congo ati Guinea.

Loṣu Kẹrin to kọja ni Trump kede afikun owo ori tariifu ida 50% lori ọja to n wọ Amẹrika lati Lesotho, ida 30% lori South Africa ati 14% lori ọja to n wọle lati Naijiria.

Akọwe owo orilẹede Amẹrika, Scott Bessent, sọ pe loṣu to n bọ ni Amẹrika yoo bẹrẹ si ni maa tẹle afikun owo ori tariifu yii lori ọja to n wọle.

Amọ, o fidi rẹ mulẹ pe awọn orilẹede to ba si fẹ ba Amẹrika sọrọ lori ati mu adinku ba owo tariifu naa si lanfaani lati ṣe bẹẹ.

Lọdun 2024 nikan, ọja ti ko din ni $39.5bn ni Amẹrika ko wọle lati ilẹ Afirika.

Ọpọ awọn ọja yii lawọn orilẹede Afirika ko san owo ori kankan lori wọn labẹ eto kan ti wọn pe orukọ rẹ ni AGOA eyi to tumọ si idagbasoke ilẹ Afrika ati ifunni ni anfaani.

Amọ, ko ni si nnkan to jọ bẹẹ mọ bayii lẹyin ti Trump ti kede owo tariifu ti yoo gori ọja to wọle lati Afirika.

Ìdálọ́lá fún Kudirat Abiola jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Tinubu sọ ní June 12

Ìdálọ́lá fún Kudirat Abiola jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Tinubu sọ ní June 12

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà, ọdún 2025 ni àyájọ́ ìjọba àwarawa pẹ̀lú ìrántí ètò ìdìbò tí MKO Abiola ti jáwé olúborí nínú ìdìbò Ààrẹ June 12, ọdún 1993.

Lọ́dọọdún sì ni àwọn Ààrẹ tó bá wà lórí àléfà, má ń bá aráàlú sọ̀rọ̀ láti ilé Ààrẹ.

Amọ ni ọdun yii, ile igbimọ aṣofin ni Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe ayajọ June 12, to si fi asiko naa kede awọn igbesẹ kan ti ijọba rẹ gbe.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Tinubu kede pe oun ti fi oye nla orilẹede Naijiria da awọn eeyan kan to ko ipa nla lasiko June 12 ọdun 1993 lọla.

Aarẹ Bola Tinubu fi oye nla da Kudirat Abiola, aya oloogbe Moshood Abiola, alaga ajọ eleto idibo (NEC) nigba naa, Humphrey Nwosu, to fi mọ igbakeji aarẹ nigba kan ri, Shehu Yar’Adua, pẹlu awọn yooku, lọla.
Tinubu kede eyi nigba to ba awọn araalu sọrọ fun ayajọ ijọba awarawa.

Bẹẹ ba gbagbe, Moshood Abiola ni wọn kede pe o bori eto idibo aarẹ ọdun 1993.
“Bi a ṣe n ṣe ayajọ ọdun mẹrindinlọgbọn ijọba awaarawa, ohun to tọ ni ki a fi oye nla da awọn eeyan to ko ipa nla lati ri pe a ri ijọba awaarawa gba fun orilẹede wa, lọla” Tinubu sọ.

“Pẹlu eyi mo n kede fifi oye CFR da Kudirat Abiola lọla, fun ipa to ko ni June 12.”

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun fi oye CON da Nwosu ati oye GCFR da Shehu Musa Yar’Adua lọla.

Awọn yooku ti aarẹ fi oye da lọla ni Rear Admiral Ndubuisi Kanu (CON), Alhaji Balarabe Musa (CFR), Pa. Alfred Rewani (CFR), Bagauda Kaltho (OON), Chima Ubani (OON), Dr. Beko Ransome-Kuti (CON), Alao Aka Bashorun (CON), Chief Frank Kokori (CON), Emma Ezeazu (OON), Bamidele Aturu (OON), Fredrick Fasehun (CON), Ọjọgbọn Festus Iyayi (CON), Dr John Yima Sen (OON), Alhaja Sawaba Gambo (CON), Dr. Edwin Madunagu (CON), Dr. Alex Ibru (CON), Chief Bola Ige (CFR), Pa. Reuben Fasoranti (CFR), Sen. Ayo Fasanmi (CON), Sen. Polycarp Nwite (CON) ati Dr. Nurudeen Olowopopo (CON),” Aarẹ kede.

Yatọ si eyi, awọn eeyan mi ti aarẹ tun fi oye da lọla ni ajafẹtọ ọmọniyan ati agbẹjọro, Femi Falana, Agba onkọwe, Wole Soyinka, ati Bisọọbu ijọ Sokoto Diocese, Hassan Kukah.
Aarẹ Tinubu tun jẹ ko di mimọ pe, irọ to jina sina si otitọ ni pe oun fi ofin de ajọ INEC lati ma ṣe faaye gba idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun gẹgẹ bii iroyin kan ṣe gbe sita.

Aarẹ ni oun ko gbe igbesẹ kankan pe ki INEC ma faaye gba idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun.

“N ko sọ eyi rara pe ko ma si idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun.”

O ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, yoo jẹbi ọpọ ẹsun ti ko ba fi aye gba ki awọn eeyan darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.

O wa fi asiko naa ki awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun lati ipinlẹ Delta ati Akwa Ibom, “Ẹ kaabọ si ẹgbẹ itẹsiwaju.”

Bakan naa ni Tinubu ni oun ko ṣetan lati ṣe iranlọwọ fun ẹgbẹ oṣelu kankan lati to ile wọn nitori inu oun dun bi o ṣe n daru.

“O dun lati ma wo bi ile yin ṣe n daru.”

Aarẹ Bola Tinubu ni oun ṣeleri lati daabo bo ẹtọ awọn araalu lati sọ ohunkohun ti wọn ba fẹ sọ sita.

Aarẹ sọ fun awọn ẹsọ alabo lati ma ṣe dẹru ba ẹnikẹni to ba bu ẹnu atẹ lu iṣejọba rẹ.

“Ijọba awaarawa faaye gba ki eeyan ma sọ ohun to ba fẹ tabi fi iwọsi ransẹ si ijọba.

“Ẹ pe mi ni orukọ, ẹ pe mi ni ohun ti ẹ ba fẹ pe mi, nitori ijọba awaarawa sọ pe ẹ ni ẹtọ lati ṣe bẹ.”

Bakan naa ni aarẹ kesi awọn oloṣelu pe ki wọn faaye gba ijiroro dipo ki wọn ma a paṣẹ wa a tabi tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Aarẹ Bola Tinubu ni ileeṣẹ aarẹ ti forijin oloogbe ajafẹtọ ọmọniyan, Ken Saro Wiwa ati awọn mẹjọ mii ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Ogoni, ti wọn n pe ni Ogoni Nine.

Tinubu ṣapejuwe awọn eeyan yii gẹgẹ bii akọni fun orilẹede Naijiria, to si tun kede pe wọn yoo gbe ami ẹyẹ kalẹ ni orukọ wọn .

Awọn ọmọ eeyan yooku ni Saturday Dobee, Nordu Eawo, Daniel Gbooko, Paul Levera, Felix Nuate, Baribor Bera, Barinem Kiobel, ati John Kpuine.

“Bakan naa ni mo tun fun wọn ni ami ẹyẹ nla ti orilẹede Naijiria; Ken Saro Wiwa (CON), Saturday Dobee (OON), Nordu Eawo (OON), Daniel Gbooko (OON), Paul Levera (OON), Felix Nuate (OON), Baribor Bera (OON), Barinem Kiobel (OON), ati John Kpuine (OON).

“Mo ma lo agbara mi lati fi idarijin ijọba fun awọn mii ti a si ma kede orukọ wọn ni aipẹ yii.”

Saro Wiwa ati awọn akẹgbẹ rẹ ni wọn fẹsun ipaniyan kan, ti wọn si yẹgi fun wọn ni ọdun 1995 labẹ iṣejọba Oloogbe Sani Abacha

Soun kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jò mẹ́jọ fáwọn obìnrin l’Ogbomoso

Soun kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jò mẹ́jọ fáwọn obìnrin l’Ogbomoso

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní bí kò bá nídìí, obìnrin kìí jẹ́ ikúmólú, àṣamọ̀ yìí kò sé lórí bí Ṣọun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afọlábí Ọláoyè, ti kéde kónílé ó gbélé ọlọ́jọ́ mẹ́jọ fáwọn obìnrin nílùú Ogbomoso nítorí ọdún Orò.

Ọba Olaoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe Aafin Ogbomoso, Toyin Ajamu, fi sita.

Kabiyesi sọ ninu atẹjade naa wi pe lalẹ ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala ni konile o gbele ọhun yoo bẹrẹ.
Lati aago mejila oru ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa ni ọdun Oro naa yoo tí gbinaya.

Ọdun naa yoo maa waye lati ago mejila titi di ago mẹrin idaji lojoojumọ titi di ogunjọ ọjọ Ẹti ọsẹ to n bọ ti ọdun naa yoo kasẹ nlẹ.
Soun wa rọ awọn obinrin niluu Ogbomoso lati duro sinu ile wọn titi ti ọdun Oro naa yoo fi pari.

Kabiyesi tun sọ ninu atẹjade naa pe awọn ọlọpaa ni yoo gbe ẹnikẹni to ba tapa si ofin konile o gbele yii.

Bakan naa ni Ọba Ghandi sọ ninu atẹjade ọhun pe ko gbọdọ si ilu lilu lati ibẹrẹ titi de ipari ọdun Oro naa niluu Ogbomoso.

Soun rọ gbogbo olugbe ilu Ogbomoso lati fọwọ sowọ pọ ki ọdun Oro naa le kẹsẹ jari.

Ààre̩ Tinubu f’àmì è̩ye̩ ńlá dá àwo̩n ò̩tò̩kù ìlú ló̩lá

Ààre̩ Tinubu f’àmì è̩ye̩ ńlá dá àwo̩n ò̩tò̩kù ìlú ló̩lá

Yínká Àlàbí

Asiwaju Bo̩la Ahmed Tinubu ni orileede yii o gbo̩do̩ ya abara mooreje̩. O ni a ko gbo̩do̩ gbagbe awo̩n to je̩ ki eto ijo̩ba awa-ara-wa o seese.
Aare̩ ni bi o tile̩ je̩ pe o̩po̩ ninu wo̩n ti je̩ O̩lo̩run nipe nipa igbiyanju ijo̩ba awa-ara-wa naa, o ni a ko lagbara lati ji wo̩n pada saye sugbo̩n o ye̩ ki a maa se iranti wo̩n si rere nitori pe iwe mimo̩ gan an so̩ pe “didun ni iranti olododo”.
Tinubu ni eyi lo faa ti awo̩n ati igbimo̩ awo̩n se forikori lati fi ami e̩ye̩ da wo̩n lo̩la.
Àwo̩n eniyan yii ni wo̩n ja fitafita pe eto ibo ti o tii lo̩ ni iro̩wo̩ iro̩se̩ ni ibo ‘June 12 o̩dun 1993’ ni eyi ti o gbe Oloogbe Mashood Abiola wole amo̩ ijo̩ba ologun Ibrahim Babangida fagi lee ni o̩dun naa, awo̩n O̩jo̩gbo̩n ni boya o̩ro̩ orileede yii iba ti lojutuu ti wo̩n ba je̩ ki Abio̩la se ijo̩ba naa.
Awo̩n ti oruko̩ wo̩n ti jade naa ni –

Kudirat Abiola – CFR
Shehu Musa Yar’Adua – GCFR
Prof. Humphrey Nwosu – CON
Rear Admiral Ndubuisi Kanu – CON
Alhaji Balarabe Musa – CFR
Pa Alfred Rewane – CFR
Bagauda Kaltho – OON
Chima Ubani – OON
Dr. Beko Ransome-Kuti – CON
Alao Aka Bashorun – CON
Chief Frank Kokori – CON
Emma Ezeazu – OON
Bamidele Aturu – OON
Fredrick Fasehun – CON
Prof. Festus Iyayi – CON
Dr. John Yima Sen – OON
Alhaja Sawaba Gambo – CON
Dr. Edwin Madunagu – CON
Dr. Alex Ibru – CON
Chief Bola Ige – CFR
Pa Reuben Fasoranti – CFR
Senator Ayo Fasanmi – CON
Senator Polycarp Nwite – CON
Dr. Nurudeen Olowopopo – CON
Prof. Wole Soyinka – GCON
Prof. Olatunji Dare – CON
Kunle Ajibade – OON
Nosa Igiebor – OON
Dapo Olorunyomi – OON
Bayo Onanuga – CON
Ayo Obe – OON
Dare Babarinsa – CON
Bishop Matthew Hassan Kukah – CON
Senator Shehu Sani – CON
Governor Uba Sani – CON
Barrister Femi Falana, SAN – CON
Prof. Shafideen Amuwo – CON
Barrister Luke Aghanenu – OON
Senator Tokunbo Afikuyomi – CON
Hon. Labaran Maku – OON
Dr. Tunji Alausa – CON
Mr Nick Dazang – OON
Hon Abdul Oroh – OON
Odia Ofeimun – CON
Seye Kehinde – OON
Barrister Felix Morka – CON
Barrister Ledum Mitee – CON
Hon. Olawale Osun – CON
Dr. Amos Akingba – CON
Prof. Segun Gbadegesin – CON
Mobolaji Akinyemi – CFR
Dr. Kayode Shonoiki – CON
Prof. Julius Ihonvbere – CON
Prof. Bayo Williams – CON
Senator Abu Ibrahim – CFR
Senator Ame Ebute – CFR
Uncle Sam Amuka Pemu – CON
Ken Saro-Wiwa – CON
Saturday Dobee – OON
Nordu Eawo – OON
Daniel Gbooko – OON
Paul Levera – OON
Felix Nuate – OON
Baribor Bera – OON
Barinem Kiobel – OON
John Kpuine –OON

Ogún o̩dún Glo l’ójúde O̩ba pè̩lú è̩bùn re̩pe̩te̩ – Ìròyìn Òwúrò̩

Ogún o̩dún Glo l’ójúde O̩ba pè̩lú è̩bùn re̩pe̩te̩ – Ìròyìn Òwúrò̩

Ara o ki n tan nile alara nigba kankan, be̩e̩ ni aanu ki wo̩n ileese̩ agbohunsafe̩fe̩ Glo.
Eyi lo tun mu ki ileese̩ naa gbe awo̩n agba olorin bii Ebenezer Obey, Wasiu Ayinde, Adewale Ayuba ati awo̩n olorin re̩pe̩te̩ wo̩ inu eto ajo̩yo̩ Ojude o̩ba naa.
Ogun o̩dun niyi ti ileese̩ naa ti n se agbate̩ru o̩dun yii ni ilu Ije̩bu Ode. Ti o̩dun yii tun wa buyari nitori awo̩n e̩bun o̩lo̩kan-o-kan bii o̩ko̩ ayo̩ke̩le̩, masinni e̩le̩se̩ me̩ta, ge̩ne̩reto̩ ati be̩e̩ be̩e̩ lo̩.
Ara awo̩n to je̩ e̩bun ni Idowu O̩labisi to je̩ onisowo lati Ije̩bu ode, Ope̩oluwa Osisanwo to je̩ e̩ni o̩dun mejilelaado̩ta naa je̩ e̩bun o̩ko̩ ayo̩ke̩le̩, awo̩n to je̩ masinni e̩le̩se̩ me̩ta (Ke̩ke̩) ni Hassan Toheeb to je̩ onisowo ni Ije̩bu Itele, Adenike̩ Olanrewaju je̩ onisowo igi ni Ije̩bu ode, Gazal Temito̩pe je̩ onisowo ni Olisha, Ije̩bu ode ati Lawal Tosin to je̩ onisowo igi ni ilu Ije̩bu ode.
Awo̩n to gba ge̩ne̩reto̩ ati ire̩si ko tile̩ niye. Gbogbo awo̩n eniyan wo̩nyi ni wo̩n fi e̩mi imoore han si ileese̩ Globacom.
Gomina ipinle̩ Ogun, O̩mo̩o̩ba Dapo̩ Abio̩dun ati Minisita fun asa ati eto igbafe̩- Musa Musawa Hannatu pe̩lu Ololorogun Sunny Kuku ti wo̩n je̩ O̩gbe̩ni o̩ja ti ile̩ Ije̩bu.

Táńkà agbépo laná ní Ibùsò̩ Aseese l’ópòpónà mó̩rosè̩ Eko sí Ibadan – Ìròyìn Òwúrò̩

Táńkà agbépo laná ní Ibùsò̩ Aseese l’ópòpónà mó̩rosè̩ Eko sí Ibadan – Ìròyìn Òwúrò̩

O̩jo̩ buruku esu gbomi mu ni o̩jo̩ We̩side o̩jo̩ ko̩kanla osu ke̩fa, o̩su yii nigba ti o̩ko̩ nla agbepo gbana ni agbegbe NASFAT ni opopona titi mo̩rose̩ Eko si Ibadan.
Ina naa po̩ de bi wi pe o dabu o̩na ti ko si je̩ ki o̩ko̩ kankan ko̩ja si o̩na Ibadan tabi Eko ni asiko ti a n ko iroyin yii jo̩.
Igbagbo̩ ni wi pe igba ti o ba fi maa di o̩wo̩ aago meje ale̩, awo̩n o̩ko̩ to n lo̩ ilu Eko maa raaye ko̩ja sugbo̩n ti awo̩n panapana ko ba tete de, o maa le die̩ fun o̩ko̩ kankan lati ko̩ja lo̩ si o̩na Ibadan lale̩ oni.
Gbogbo e̩ni ti ko ba pan dandan fun lati lo̩ o̩na Ibadan lonii ki wo̩n jo̩wo̩ so̩o̩ di o̩jo̩ miran.
Eledua si ba wa se, ko si e̩mi kankan to ba ise̩le̩ naa lo̩.
E wo fidio ina naa nisale̩.

Ìbúgbàmù Bódìjà! Mákindé buwọ́lu ₦4.08b fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí àti dúkìá wọn

Ìbúgbàmù Bódìjà! Mákindé buwọ́lu ₦4.08b fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí àti dúkìá wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oṣù méjìdínlógún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù ńlá tó wáyé ní agbègbè Bódìjà, nílùú Ìbàdàn, àwọn kan lára àwọn tó pàdánù dúkìá àti mọ̀lẹ́bí wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba owó ìràn lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Agbenusọ fun ẹgbẹ awọn olugbe Bodija Estate, Alufaa Muyiwa Bamgbose lo fidi iroyin naa mulẹ nibi ipade awọn akọroyin ti wọn ṣe ninu gbagede Pentorise, to wa ni Bodija nílùú Ìbàdàn.

Bamgbose ṣalaye pe ₦4.08 biliọnu ni ijọba ipinlẹ Oyo buwọlu gẹgẹ bii owo iranwọ fun awọn to lugbadi nigba ti ibugbamu naa sẹlẹ.
Eeyan maarun lo padanu ẹmi wọn nibẹ, ti ọkọ ayọkele mẹtadinlogoji si ba a lọ.

Iṣẹlẹ naa tun sọ eeyan mejilelọgọrun di alainilelori.

Alufaa Bamgbose sọ pe o le ni milliọnu marundinlogoji naira ti awọn ẹlẹyinju aanu fi ranṣẹ lati ṣeranwọn fun awọn to lugbadi nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti ipinlẹ Oyo ati ti ijọba apapọ, NEMA naa tun fi awọn ohun elo idẹrun ọlọkan-o-jọkan ranṣẹ.

Bamgbose ni awọn olugbe Bodija ti fi ẹka kan lole ti yoo ṣe abojuto aabo, iwọlewọde ati amojuto agbegbe Bodija lati gbogun ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

Àkójọpọ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ọdún Ojude Oba 2025

Àkójọpọ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ọdún Ojude Oba 2025

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọdún Ojúde Ọba 2025 dùn yùngbà, bẹ́ẹ̀ ló mi ìgboro tìtì, kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń sọ nípa rẹ̀ títí di òní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kẹfà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayẹyẹ náà ti wáyé láti ọjọ́ Àìkú tí í ṣe ọjọ́ kẹjọ oṣù yìí.

Ṣe ti oriṣiiriṣii aṣọ olowo iyebiye tawọn eeyan wọ nibi ọdun naa ni ki a sọ ni, abi tawọn ẹṣin ti wọn ṣe lẹṣọọ nibi ayẹyẹ naa?

Awọn eeyan jankan jankan to wa nibi ọdun ọhun nkọ? Kaakiri gbogbo agbaye lawọn eeyan ti wa fun ọdun Ojude Oba eyi to mi ilu Ijebu Ode titi.
Abajọ ti Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun fi sọ pe Ojude Oba ti di ọja agbaye bayii.

Nigba ti gomina n sọrọ nibi eto naa lo tun sọ pe ijọba yoo wa nnkan ṣe si gbagede ti wọn maa n lo fun ọdun naa eyi ti ko gba ero mọ.