Home Blog Page 17

Àwo̩n báńdíìtì tún jí aké̩kò̩ó̩ bíi àádó̩ta ní ìpínlè̩ Niger

Àwo̩n báńdíìtì tún jí aké̩kò̩ó̩ bíi àádó̩ta ní ìpínlè̩ Niger

Yínká Àlàbí

Awo̩n janduku agbebo̩nrin tun gbinaya wo ile-iwe St. Mary’s ní Papiri, Agwara, ní ipinle̩ Níger, ní owurọ ọjọ́ Ẹtì, o̩jo̩ ko̩kanlelogun, Oṣù kọkànlá o̩dun 2025.
SSG ìpínlẹ̀ naa, Alhaji Abubakar Usman, àti o̩ga ọlọ́pàá tún jẹ́rìí si ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọn sọ pé a kò tíì mọ iye àwọn ọmọ tí wọ́n ji ko gan-an.
Agbe̩nuso̩ ọlọ́pàá ipinle̩ naa, CP Adamu Abdullahi Ellema, sọ pé àwọn ọmọ ogun àti agbofinro ti lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ si ni wa awo̩n ake̩ko̩o̩ naa.
Be̩e̩ si ni iwadii to gbopo̩n bii awo̩ Erin naa n te̩ siwaju lori ise̩le̩ laabi naa.
Ó tún sọ pé wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò ìdí tí ilé ẹ̀kọ́ fi ṣí sílẹ̀ láì tẹ̀lé àṣẹ ìjọba tó ní kí wọ́n ti gbogbo ilé ẹ̀kọ́ ní agbègbè yẹn nípa ààbò to n me̩he̩ lasiko yii.

Àpẹẹrẹ mẹ́jọ láti mọ̀ pe o ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara ,àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Àpẹẹrẹ mẹ́jọ láti mọ̀ pe o ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara ,àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbémi pamọ́ kí n pa ọ́, tú mi síta kí n fi ọ́ sílẹ̀ lórúkọ tí àrùn n jẹ́,ọ̀kan lára wọn ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ àìsàn tó máa ń ṣokùnfà ikú tó lé ní mílíọ̀nù kan ní ọdọọdún, tó sì jẹ́ pé kò sí èèyàn tí kò lè ni.

Ohun tó máa ń ṣokùnfà àìsàn yìí ni tí ṣúgà bá ti pọ̀ jù ní ara, tí ẹ̀yà tó máa ń fọ ṣúgà kúrò lára kò lè lọ gbogbo rẹ̀.

Àìsàn yìí le ṣokùnfà kí èèyàn ní àìsàn ọkàn, àìsàn rọpá rọsẹ̀, àìsàn kíndìnrín àti kí egbò má jiná tó le mú kí wọ́n gé apá tàbí ẹsẹ̀ èèyàn.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization, WHO sọ pé èèyàn tó tó mílíọ̀nù 422 ló ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà káàkiri àgbáyé – èyí tó jẹ́ àlékún ìdá mẹ́rin sí iye àwọn tó ni ní ogójì ọdún sẹ́yìn.

Ohun tó léwu níbẹ̀ jùlọ ni pé ìdajì àwọn tó ń ní àìsàn yìí ni wọn kò mọ̀ pé àwọn ni.

Àwọn àmì àpẹẹrẹ kan wà tó jẹ́ pé tí èèyàn bá ti rí lára, ohun tó tọ́ ni pé láti lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yẹ ò sọkà fún àyẹ̀wò.

Lára àwọn àmì àpẹẹrẹ náà ni:

Kí òùngbẹ máa gbẹ èèyàn jù: Lára àmì tí ẹni tó bá ní ìtọ̀ ṣúgà máa ń rí ni pé òùngbẹ máa ma gbẹ wọ́n ní gbogbo ìgbà kódà bí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ mu omi tán. Èyí sì máa ń wáyé bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n máa ń tọ̀ púpọ̀.
Ìtọ̀ gbogbo ìgbà: Èèyàn ma máa tọ̀ léraléra pàápàá ní alẹ́. Ní kété tí ó bá tọ̀ ni ìtọ̀ míì yóò tún máa gbọn èèyàn.
Àárẹ̀ ara: Ẹni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ma máa ri pé ó ń rẹ òun ní gbogbo ìgbà láì ṣe iṣẹ́ tàbí wàhálà kan pàtó.
Kí èèyàn máa gbẹ: Tí o bá ri pé ò ń gbẹ ju bí ó ṣe yẹ lọ láì sí pé èèyàn ní àìsàn kan tí kò jẹ́ kí èèyàn jẹun dáadáa, ọ sàn láti lọ ṣe àyẹ̀wò àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Kí ebi máa pa èèyàn léraléra: lára àmì àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni kí ebi máa pa èèyàn ní gbogbo ìgbà. Kódà bí èèyàn bá ń jẹun léra, ebi yóò ṣì tún máa pa èèyàn.
Kí ojú máa ṣú: Tí o bá ti ń rí àyípadà nínú bí ó ṣe ń ríran, tó jẹ́ pé ó máa ń ríran dada tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí o kò ṣàdédé ríran bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ó sàn láti ṣe àyẹ̀wò ìtọ̀ ṣúgà.
Kí egbò má tètè jiná: Tí egbò bá ń pẹ́ ju bí ó ṣe yẹ lọ kí ó tó jiná jẹ́ àmì àpẹẹrẹ ìtọ̀ ṣúgà.
Kí ẹnu máa bó ní gbogbo ìgbà: Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa ń ṣokùnfà kí èèyàn ní egbò ní ẹnu.
Èyí ni àwọn àmì àpẹẹrẹ tó ṣe gbòógì tí ẹni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà le máa rí, tó sì dára kí ẹnikẹ́ni tó bá ń rí irú àwọn àmì báyìí tètè kàn sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó péye.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara tó fi mọ́ ọkàn, kíndìnrín, ọkàn, ojú, àti ẹsẹ̀ ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa ń kóbá.

Bí àìsàn bá ṣe pọ̀ lára sí ló máa ń ṣe àkóbá fún ara sí.

Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà kìí jẹ́ kí ara le pèsè tàbí lo insulin, ẹ̀yà ara tó máa ń jẹ́ kí ṣúgà ara di ohun àmúṣagbára.

Tí èyí bá ti rí bẹ́ẹ̀, glucose tó máa wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn máa pọ̀ si tí kò sí máa ma ṣàkóbá fáwọn ẹ̀yà ara tó ṣe kókó láti gbé ayé ìrọ̀rùn.

Wo àwọn ọ̀nà láti dènà ìtọ̀ ṣúgà
Àwọn dókítà sọ pé àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ ohun tó máa ń tọ ìran àtàwọn ìgbé ayé tí èèyàn bá ń gbé.

Àmọ́ ó ṣe é ṣe àmójútó pẹ̀lú ọ̀nà wọ̀nyí:

Jíjẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore ní gbogbo ìgbà.
Yíyàgò fún àwọn oúnjẹ inú agolo àtàwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò.
Jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ní ṣúgà ní ìwọ̀nba.
Jíjẹ àwọn èso àti ẹ̀fọ́ lọ́pọ̀ ìgbà àti àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀wà ṣe.
Jíjéun lásìkò tó yẹ, tó sì dára láti dá oúnjé dúró lẹ́yìn tí èèyàn bá ti yó.
Ṣíṣe eré ìdárayá náà dára láti mú àdínkù bá iye ṣúgà tó ń wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn.
Àjọ tó ń ri sí ètò ìlera ní UK, National Health Service ní ó dára láti máa ṣe eré ìdárayá fún ó kéré tán wákàtí méjì àbọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan tó fi mọ́ ìrìn.
Yíyàgò fún sìgá mímu àtàwọn ohun tó fara pẹ jẹ́ ohun tó dára láti dènà àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Lára àwọn ìgbésẹ̀ láti dènà níní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni èyí àti láti gba ìwòsàn lórí rẹ̀.

Kókó ìpàdé Nuhu Ribadu pẹ̀lú aṣòfin Amẹrika lórí àwọn alákatakítí

Kókó ìpàdé Nuhu Ribadu pẹ̀lú aṣòfin Amẹrika lórí àwọn alákatakítí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Aṣòfin orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà tó sọ pé ìṣekúpani àwọn kìtẹ́nì n ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Riley Moore, ti ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí olùdámọ̀ràn Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ààbò, Nuhu Ribadu kó wọn sòdí.

Aṣofin Moore fidi rẹ mulẹ pe oun ṣe ifọrọwerọ pẹlu Ribadu gẹgẹ bii aṣoju Aarẹ Bola Tinubu niluu Washington D.C. l’Amẹrika.

Ọgbẹni Moore sọ pe ipade oun pẹlu Ribadu da lori iṣekupani awọn kristẹni ati ọṣẹ tawọn agbesunmọmi n ṣe ni Naijiria.
Moore ni oun ti sọrọ pẹlu Ribadu lori ọna lati fopin si iṣekupani awọn alaiṣẹ to n waye loorekoore ni Naijiria.

Aṣofin naa sọ pe awọn aṣoju ijọba orilẹede Naijiria sọ nipa awọn nnkan to n kọ ijọba Naijiria lominu lori ọrọ awọn agbesunmọmi ati bi Amẹrika ṣe le ṣeranwọn lati daabo bawọn awujọ tawọn agbesunmọmi yii n ṣekọlu si ni Naijiria.

Moore ṣalaye pe Amẹrika ṣetan lati fọwọ sowọ pọ pẹlu Naijiria, o ni oun sọ fun awọn aṣoju ijọba Naijiria wi pe Amẹrika ko ni gba ki wọn maa ṣeku pa awọn kristẹni lọ ni Naijiria.

Ọrọ ti Moore sọ yii wa ni ibamu pẹlu nnkan ti Aarẹ Donald Trump naa ti sọ tẹlẹ nipa Naijiria.

O ni oun yoo maa tẹsiwaju lati maa wo nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria, oun yoo si ri pe Naijiria ṣe ohun to yẹ lati fopin si awọn agbesinmọmi to n ṣe ikọlu sawọn eeyan ni Naijiria.
Lati oṣu Kẹsan an ọdun yii ni ọkan-o-jọkan awọn oloṣelu ti n sọ pe awọn alakatakiti ẹsin islam n ṣekọlu sawọn kristẹni ni Naijiria.

Ọrọ yii jade ninu iṣẹ iwadii Mike Arnold, oniroyin CNN, Van Jomes, Sẹnẹtọ Moore, Sẹnẹtọ Ted Cruz atawọn olorin ẹsin mii naa ti n sọrọ yii bakan naa.

Sẹnẹtọ Cruz to n ṣoju ipinlẹ Texas ti ṣagbatẹru aba kan loṣu Kẹsan an eyi to pe ni ”ába lati ṣe ẹsin to wu eeyan ni Naijiria ti ọdun 2025.”

Aba yii ni o fi fẹsun kan ijọba
Naijiria pe wọn n faye awọn alakatakiti ẹsin islam lati maa ṣekọlu sawọn kristẹni.

Sẹnẹtọ Moore naa ti sọ tẹlẹ pe wọn n ṣekupa awọn kirisitẹni nitori wọn n ṣe esin to wu wọn.

Moore si kọwe si akọwe ijọba awọn ipinlẹ l’Amẹrika, Marco Rubio, wi pe ko gbe igbesẹ lori ọrọ naa kiakia.

Ìkọlù tuntun ní Kwara, agbébọn pa èèyàn méjì, kó mẹ́rin sálọ

Ìkọlù tuntun ní Kwara, agbébọn pa èèyàn méjì, kó mẹ́rin sálọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn agbésùnmọ̀mí ti jí èèyàn mẹ́rin gbé lọ tí wọ́n tún ṣekúpa méjì mìíràn nílùú Bokungi, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Edu, níìpínlẹ̀ Kwara.

Iṣẹlẹ naa lo waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti awọn agbesunmọ kọkọ kọlu ile ijọsin CAC Oke Isgeun to wa niluu Eruku, ni ijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ kan naa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe irọlẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye lasiko ti awọn eeyan naa n ṣiṣẹ ninu oko irẹsi wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, asiko ti awọn agbẹ naa n kore irẹsi inu oko lawọn agbebọn ṣadede yi wọn ka.

Ẹni to ba awọn akọroyin sọrọ a mọ ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede ni “lootọ ni awọn agbebọn kọlu Bokungi to wa labẹ Lafiagi.

“Eeyan mẹrin ni wọn ji gbe lọ, a ṣi n ko iroyin naa jọ lọwọ.”

Oun ti a gbọ ni pe eeyan meji ni wọn ṣekupa yatọ si awọn mẹrin ti wọn ji gbe lọ.

Awọn olugbe ilu naa sọ pe awọn agbesunmọmi ọhun ṣọṣẹ fun ọpọ iṣẹju lai si idiwọ kankan ki wọn to dari awọn agbẹ naa sinu igbo ti wọn si gbe wọn lọ.
Wọn ni ọpọ awọn olugbe ilu ọhun lo ti na papa bora latari eto abo to mẹhẹ nibẹ ti ijinigbe si ti di ohun to n waye lemọlemọ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, pupọ awọn agbẹ to wa nibẹ ni ko lọ sinu oko mọ lati lọ kore nitori ibẹru awọn ajinigbe.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ati ijọba ipinlẹ naa ko tii sọ ohunkohun lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ipinlẹ Kwara yii kan naa ni agbebọn ti kọlu ile ijọsin lasiko ti isin n lọ lọwọ ti wọn si ji eeyan marundinlogoji lọ nigba ti wọn ṣekupa eeyan meji mii.

Àfi bí àwàdà! Nnamdi Kanu wẹ̀wọ̀n gbére

Àfi bí àwàdà! Nnamdi Kanu wẹ̀wọ̀n
gbére

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti sọ olọ́rí ẹgbẹ́ ajìjàgbara fún òmìnira ilẹ̀ Biafra, Nnamdi Kanu sí ẹ̀wọ̀n ayérayé.

Idajọ yii lo n waye lẹyin ọdun mẹwaa ti wọn kọkọ fi ṣikun ofin mu u.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ Omotoso sọ pe Kanu ko kabamọ ohun to ṣe ni gbogbo asiko ti igbẹjọ rẹ n lọ lọwọ bẹẹni ko tuuba.

O ni Kanu ṣe oniruru igbohunsafẹfẹ lawọn ọdun kan sẹyin lasiko to n pe fun ominira ilẹ Biafra, ati pe awọn igbohunsafẹfẹ ọhun lo ṣokunfa oniruru ifẹmiṣofo to waye ni ila oorun Naijiria nibi ti ọpọ agbofinro ti sọ ẹmi wọn nu.

Idajọ yii lo waye lẹyin ti ile ẹjọ naa ni Kanu jẹbi ẹgbogbo ẹsun meje ti wọn fi kan an, eyii to ni ṣe pẹlu igbesunmọmi.

Ọdun 2009 ni irawọ Kanu kọkọ tan kalẹ ni Naijiria lẹyin to bẹrẹ igbohunsafẹfẹ lori ẹrọ aṣọrọmagbesi Radio Biafra.

Ori redio naa lo ti n pe fun ominira ilẹ Biafra lati ilu London pe ki ẹya Igbo yapa kuro lara Naijiria
Adajọ James Omotosho ti ile ẹjọ giga apapọ ilu Abuja ti fidi rẹ mulẹ pe olori ẹgbẹ IPOB to n jija gbara fun orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu, jẹbi ẹsun igbesunmọmi onikoko meje ti wọn fi kan an.
Adajọ Omotosho ni Kanu ti hu oriṣiiriṣii iwa ipa eyi to ti ṣakoba fawọn eeyan rẹ to loun n ja fun un.

Lasiko to n ka idajọ naa ni adajọ sọ pe ki olori ẹgbẹ IPOB jade nile ẹjọ bi o ṣe n ka idajọ rẹ.
Oni ogunjọ oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii ni Adajọ Omotosho fi idajọ Kanu si eyi to le jasi idajọ iku gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe sọ.

Adajọ Omotosho bẹrẹ sii jokoo lori igbẹjọ Kanu lati oṣu Kẹta ọdun yii, lẹyin ti Kanu fẹsun kan Adajọ Binta Nyako to n ṣakoso igbẹjọ naa tẹlẹ pe o n figba kan bọkan ninu.

Lati igba naa ni Adajọ Ọmọtosho ko ti fi igbẹjọ naa falẹ rara titi ti oni ọjọ idajọ.

Nigba ti ile ẹjọ beere lọwọ Kanu pe ki lo ni lati sọ ni olori IPOB sọ pe ki lo de ti wọn fi ju oun satimọle lai ṣẹ.

Kanu sọ pe ki wọn fun oun ni beeli.

”Nnkan ti mo n beere ni pe ki wọn jẹ ki n gbe ẹjọ yii lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Bawo ni mo ṣe maa wa lahamọ lori ofin ti ko si ninu ofin Naijiria?

Mo fẹ ki wọn fun mi ni beeli,” Kanu lo sọ bẹẹ.

Amọ, adajọ fesi wi pe ko tọna lati gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ kotẹmilọprun lọwọ yii.

Nigba ti adajọ fẹ bẹrẹ sii maa ka idajọ rẹ ni Kanu sọ fun adajọ pe ko fi han ninu ofin nibi ti oun ti ṣẹ.

Bi adajọ ti fẹ sọrọ ni Kanu pariwo mọ ọn pe ko fi ofin to fẹ lo fun idajọ rẹ han oun.

Nigba ti Kanu ko jẹ ji adajọ sọrọ ni adajọ paṣẹ wi pe ko jade kuro ninu ile ẹjọ.

Kanu ko dakẹ ariwo, bo tilẹ jẹ pe adajọ ti paṣẹ pe ko jade kuro nile ẹjọ.

Bakan naa ni ko tun jẹ kawọn ẹṣọ alaabo fọwọ kan an.

Adajọ ni Kanu lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin idajọ oun, amọ, Kanu si n sọrọ lọ.

O ni adajọ ko mọ ofin, ati pe ofuutu-fẹẹtẹ ni idajọ ti ile ẹjọ fẹ gbe kalẹ.

Adajọ Omotosho fidi rẹ mulẹ pe o wa ninu ofin wi pe bi afurasi ko ba huwa bii Omoluabi, adajọ lagbara lati le e jade ti yoo fi ka idajọ rẹ.

Ènìyàn mé̩rin jé̩pè O̩ló̩run níbi ìwúyè ní Alimo̩s̩o̩

Ènìyàn mé̩rin jé̩pè O̩ló̩run níbi ìwúyè ní Alimo̩s̩o̩

Ìròyìn Òwúrò̩

Ki Eledua ma je̩ a ki a si ode lo̩. E̩ni ori yo̩, o di ile ni nigba ti ise̩le̩ nla se̩le̩ nibi iwuye ni ilu Alimo̩s̩o̩ to wa ni ipinle̩ Eko.
Opopona Anjo̩rin ni iwuye ti n waye nigba ti o̩ko̩ Tipa to ko ye̩pe̩ de, awo̩n to wa nibi inawo n gbiyanju lati fun o̩ko̩ oniye̩pe̩ naa lo̩na lati ko̩ja.
Awo̩n to wa ni agbegbe ibi ti wo̩n ta tanpoli si dide lati f’o̩wo̩ kun gbigbe kanopi naa pe̩lu o̩mo̩ onimo̩to ye̩pe̩ naa.
Awo̩n eniyan yii ko mo̩ pe waya ina kan ti ja sile̩, afi igba ti wo̩n gbe irin kanopi le waya naa ni awo̩n ti o̩wo̩ wo̩n kan e̩se̩ kanopi be̩re̩ si ni subu.
Bi ere bi awada, o̩ro̩ naa di tooto̩, awo̩n to subu ko le dide, ki o to di wi pe awo̩n kan taju kan ri waya ina.
Awo̩n to mo̩ nipa is̩e̩ ina sare yo̩ ina kuro lara opo, wo̩n si sare ko awo̩n to subu lo̩ si ile iwosan.
Aisan lo see wo, a ko ri ti o̩lo̩jo̩ se. Awo̩n alejo me̩ta pe̩lu o̩mo̩ onimo̩to ye̩pe̩ ko ye is̩e̩le̩ buruku naa.

Kó̩ò̩tù dá Kánu padà sí àhámó̩

Kó̩ò̩tù dá Kánu padà sí àhámó̩

Ìròyìn Òwúrò̩

Ile-e̩ko̩ gíga apapọ̀ ní Abuja ti dá olórí e̩gbẹ́ ajo̩ Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu, lẹ́bi ní ọ̀nà mẹ́ta nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀sùn ìfìpá fe̩ gbajo̩ba.
Nígbà tí a ń kéde ìdájọ́ ní Ọjọ́bọ, Adájo̩ James Omotosho sọ pé ẹ̀sùn tí àwọn agbẹjọ́rò ìjọba gbé kalẹ̀, pẹ̀lú àwọn fíìmù ìfọro̩-wani-le̩nu wo tí Kanu ṣe, níbi tí ó ti sọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù àti ìkìlọ̀ ìkà sí Nàíjíríà àti àwọn aráàlú rẹ̀, ló jẹ́ kí wọ́n dá a lẹ́bi.

Chiamaka Nnadozie tún gba ife è̩ye̩ CAF lé̩è̩ké̩ta

Chiamaka Nnadozie tún gba ife è̩ye̩ CAF lé̩è̩ké̩ta

Yínká Àlàbí

Ní Rabat ti Morocco ni aye̩ye̩ ife e̩ye̩ awo̩n agbabo̩o̩lu lo̩kunrin ati lobinrin ti n waye.
Eyi be̩re̩ ni ana o̩jo̩ kokandinlogun osu ko̩kanla, o̩dun yii. Ibe̩ ni wo̩n ti kede Chiamaka Nnadozie ge̩ge̩ bi agbabo̩o̩lu lobinrin to dara ju , to mo̩ bo̩o̩lu mu ju, to mo̩ ile s̩o̩ ju nigba ti wo̩n tun kede e̩gbe̩ agbabo̩o̩lu Super Falcons ge̩ge̩ bi iko̩ to dara ju ni ile̩ Adulawo̩.
E̩le̩e̩ke̩ta niyi ti Chiamaka maa gba ife e̩ye̩ naa lera-lera.

Tí o kò bá fi mí ló̩rùn sílè̩, wàá rí ohun tí ò ń wá nídìí ako̩ isu nídìí ewùrà – Regina Daniels

Tí o kò bá fi mí ló̩rùn sílè̩, wàá rí ohun tí ò ń wá nídìí ako̩ isu nídìí ewùrà – Regina Daniels

Ìròyìn Òwúrò̩

Regina Daniels ti kéde pé bí ọkọ oun ko ba fi oun lo̩run sile̩, gbogbo ohun ti awo̩n se ti ile fi jo ni oun a tu faye.

O ni gbogbo iwa ipaniyan, jibiti ati ile̩ onile̩ jija gba pata loum a tu fun gnogbo aye pbli eei to daju.

Nínú ìfiránṣẹ́ tí ó kede sí Instagram, Regina sọ pé Nwoko ti n lu jibiti pe̩lu oogun oloro ati awo̩n iwa ti eti ko gbo̩do̩ gbo̩ lati o̩dun pipe̩ se̩yin.

Ó salaye pé Nwoko ń gbìmọ̀ láti bà oun loruko̩ je̩ní gbangba àti ní ikọ̀kọ́, torí kò fẹ́ kí oun so̩ro̩ nítorí oruko̩ re̩ to n ràgà bò.

Regina tún sọ pé ó ti n mu oun ppapa mo̩ra lati igba ti oun ti wa ni o̩mo̩ s̩sun me̩tadinlogun.

O ni oogun oloro to fe̩ran lati maa lo ni o n fun oun naa mu ki aws̩n le gbadun ibalopo̩, ni rui to si se akoba pupo̩ fun oun.

Regina ni aimo̩ye igba ni oun ti gbe digba-digba lo̩ sinileniwosan nitori oogun oloro to n lo.

Arabinrin yii tin kilo̩ fun un, ki o lo̩ do ewe agbeje̩ mo̩wo̩ ki oun ma baa binu.

Alága tuntun e̩gbé̩ òsèlú PDP ní kí Trump àti àwo̩n alágbára ayé wá ran e̩gbé̩ àwo̩n ló̩wó̩

Alága tuntun e̩gbé̩ òsèlú PDP ní kí Trump àti àwo̩n alágbára ayé wá ran e̩gbé̩ àwo̩n ló̩wó̩

Yínka Àlàbí

APC fi ehonu wo̩n han nipa ìpè tí Tanimu Turaki, ẹni tí wọ́n pè ní Alága tuntun tí ẹgbẹ́ PDP pe. O pe fún àwọ́n orílẹ̀-èdè òkèèrè láti wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí ìjà tí ṣẹlẹ̀ ní ọ́fíìsì àgbà PDP ní Abuja.

Agbẹnusọ APC, Felix Morka, sọ pé ìpè Turaki jẹ́ ipe ti ko fo̩gbo̩n yo̩ ati ipe e̩ni ti ko nife̩e̩ orileese re̩.

Ó ní pé Turaki tí wọ́n kede sípò ní ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú kò yẹ kí o hàn bí ẹni tí kò mọ́ ohun tí ó ń ṣe.

Morka sọ pé dipo kí Turaki ṣiṣẹ́ láti dá àlàáfíà sílẹ̀ láàrin ẹgbẹ́ rẹ̀, ohun àkọ́kọ́ tí ó ṣe ni pe àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè wá dá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lóró, nígbà tí ìṣòro náà jẹ́ afo̩wo̩fa PDP fúnra wọn.

Ó tún sọ pé ìpè yìí jẹ́ ìkòrìíra orílẹ̀-èdè, tí ó sì lè jẹ́ ẹ̀sìn sí ààbò orílẹ̀-èdè. Ó rántí pé látàrí ọdún mẹ́rìndínlógún tí PDP ṣàkóso Nàìjíríà, kò sí ìgbà kan tí wọ́n pè fún ìwọlé orílẹ̀-èdè òkèèrè.

Morka ní ìpè Turaki fi hàn pé PDP kò lè ṣàkóso ìṣòro inú ilé tí ara wọn dá sílẹ̀, tí ó sì jẹ́ àmì ikú sí ẹgbẹ́ náà.

Ó kéde pé àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè kò ní gba ìpè PDP, torí pé ó yé kedere pé ìfarapa inú ẹni ni ó ń jẹ wọn.

Ní ikẹhin, Morka pè àwọn ará Nàìjíríà láti bá APC àti Ààrẹ Bola Tinubu dúró, bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ láti le ko orílẹ̀-èdè Naijiria de ebute ogo.