Home Blog Page 16

Àwo̩n tó lówó ju Emefiele lo̩ pò̩ nínú àwo̩n ò̩gá NNPCL

Àwo̩n tó lówó ju Emefiele lo̩ pò̩ nínú àwo̩n ò̩gá NNPCL

Yínká Àlàbí

Ko tii to o̩se̩ meji bayii ti ijo̩ba apapo̩ ni ki ajo̩ elepo robi orileede yii lo̩ ro̩ kun nile.
Bi ijo̩ba se ni ki wo̩n fise̩ sile̩ ni tipa-tipa ni ajo̩ EFCC ti be̩re̩ ise̩ ni wara-n-sesa.
Ara awo̩n o̩ga patapata ti ijo̩ba fe̩yin wo̩n ti ni Mele Kyari, Abubakar Yar’Adua, Mele Kyari, Isiaka Abdulrazak, Umar Ajiya, Dikko Ahmed, Ibrahim Onoja, Ademoye Jelili, Mustapha Sugungun, Kayode Adetokunbo, Efiok Akpan, Babatunde Bakare, Jimoh Olasunkanmi, Bello Kankaya ati Desmond Inyama.
Ohun to fa awuyewuye ko ju ile ifo̩po orileede yii me̩ta to wa ni ilu Warri, Port Harcourt ati eyi to wa ni Kaduna.
Gbogbo o̩mo̩ Naijiria lo ti n se iye meji nipa awo̩n ile ifo̩po naa pe ko dabi e̩ni pe wo̩n n sise̩ bi iroyin se n gbee. Koda Aare̩ ana, alagba Olusegun O̩basanjo̩ ni iro̩ ni awo̩n ajo̩ yii n paa, baba yii ni ko si eyi to n sise̩ ninu wo̩n.
Ase gbogbo owo rogun-rogun ti ijo̩ba n ko kale̩ lo n wo̩ igbo atuu. Bi ijo̩ba se ni ki awo̩n o̩ga yii lo rokun nile ni wo̩n ti be̩re̩ si ni nawo̩ gan awo̩n ti o̩wo̩ wo̩n ko̩ko̩ te̩.
O̩kan ninu awo̩n ti ko si ninu awo̩n o̩ga patapata ti ijo̩ba da duro ni ajo̩ EFCC ti ka bilio̩nu lo̩na o̩go̩rin naira mo̩ lo̩wo̩.
Iwosi awo̩n ajo̩ EFCC ni pe ni igba ti awo̩n ba fi maa de o̩do̩ awo̩n o̩ga, owo ti awo̩n maa ka mo̩ o̩ko̩o̩kan wo̩n lo̩wo̩ maa ju ti oludari ajo̩ banki gbogbogboo ile̩ yii te̩le̩, o̩gbe̩ni Godwin Emefiele.

Àràmàndà: Davido ní àjọjù wà nínú bi ọmọ tóun sẹ̀sẹ̀ bí se jọ Ifeanyi tó d’olóògbé lọ́jọ́ṣí

Davido

Abi akorin afrobeats, Davido, nigbagbo ninu oro abiku ni?

Ni ile Yoruba, awon abuku ni omo to maa n pada si ibni t ti won ti wa laipe odun.

Idi niyii ti won fi maa n so pe abiku oloogun di eke.

Ara igbagbo Yoruba naa wa ni pe irufe awon omo bee maa n pada wa.

Ki won ma baa pada wa, tabi ki won le da won mo bo ba tin ri won, awon obi won maa n ge nnkna keekeeke lara won, to fi mo ika tabi eti.

Kin lo fa akawe yii?

Ohun to sele ni pe Davido ti so pe omokunrin ti oun sese bi naa jo Ifeanyi ni ajoju.

Lara awon ibeji to bi, o ni, eyi to je okunrin naa jo Ifeanyi gan-an.

O ni, “O da bii re lati oke dele. O ba mi leru gan-an.”

Mọ̀mọ́, mo ní n wá gba’re tèmí: Ekun Iyawo

ẸKÚN ÌYÀWÓ

Òkóńkòkó ni mí o

Tí mo kósùpá r’Òṣogbo

Tí mo w’ẹ̀wù oyè r’Ọbaàgùn

Orí tí ó d’olóyè kìí fẹ́

Orí mi ó d’olóyè bó dọ̀la

Ire lónìí, orí mi àfi’re

 

Mọ̀mọ́ mi, mọ̀mọ́ mi

Mọ̀mọ́, mo ní n wá gba’re tèmí

Kí n tó máa lọ

Ire tèmi ò mọ̀mọ̀ pọ̀

Ire mi ò mà kún wọ́

Ire ẹja lómi ló kúkú mọ

Ire kọ̀ǹkọ̀ lódò ló mà wà

Ire ọmọ bíbí inú ìyá o

Ìlúmọ̀mí bí ò tó mi lẹ́rù n ò lọ o

Ire lónìí, orí mi àfi’re

 

Bùlenge, bùlenge

Bùgé bùgé àkàrà

Mo ní ò ṣe lẹ́yìn erèé

Bùlenge ọmọ ń bẹ lọ́wọ́ yeye

Mọ̀mọ́ tí mo mú s’àkọ́bí o

Mọ̀mọ́ mi fún mi ní bùgé-bùgé ṣe

Ire lónìí, orí mi àfi’re.

 

  • Lati inu iwe EKUN IYAWO lati owo Akeem Lasisi
  • Contact: 08023687884

 

 

O̩mo̩ Atiku àti ti Tinubu fé̩ dá ìjà àgbà méjì sílè̩

O̩mo̩ Atiku àti ti Tinubu fé̩ dá ìjà àgbà méjì sílè̩

Yínká Àlàbí

Oludije du ipo Aare̩ labe̩ e̩gbe̩ oselu PDP, Alhaji Atiku Abubarkar lo ti so̩ fun Aare̩ Bo̩la Tinubu ki o kilo̩ fun o̩mo̩ re̩ Seyi ki o dekun lati maa dun ikoko mo̩ Isah.
Isah to je̩ abala kan olori e̩gbe̩ awo̩n ake̩ko̩o̩ (NANS) lo gbe e̩sun kan jade lori ayelujara pe Seyi fi owo milionu lona o̩go̩run-un naira lo̩ oun lati darapo̩ mo̩ e̩gbe̩ APC ti oun si ko̩ jale̩.
O ni lati igba naa ni awo̩n janduku kan ti n seru ba oun kaakiri ibi ti oun ba rin si.
Seyi ni oun ko ti ri iru eyi ri ni aye oun, ki eniyan maa paro̩ rabata-rabata be̩e̩. Seyi ni oun ko tile̩ pade Atiku Isah ri laye oun debi wi pe oun a wa gbe owo fun un lati tele oun.
O̩gbe̩ni Sunday Asefon to je̩ oluba sise̩ po̩ Aare̩ lori awo̩n ake̩ko̩o̩ to si tun je̩ olori e̩gbe̩ awo̩n ake̩ko̩o̩ te̩le̩ kin o̩ro̩ Seyi le̩yin pe iro̩ ni Isah n pa, o si tun ni awo̩n e̩gbe̩ alatako kan lo maa wa le̩yin re̩ fun iru ete buruku be̩e̩. O ni koda o da oun loju to ada pe o̩wo̩ gomina te̩le̩ ri ni ipinle̩ Kaduna, Nasir el-Rufai ko le mo̩ ninu ete naa lati le je ki awo̩n eniyan ke̩yin si Tinubu lati le ma dije du ipo ni o̩dun 2027.
Isah naa ni ko si e̩ni kankan ti o n ti oun ni itikuti. O ni lati bi o̩dun me̩san-an se̩yin bayii ni oun ti foju kan El-Rufai ke̩yin.
E̩gbe̩ Afe̩nifere naa ko sai gba awo̩n e̩gbe̩ awo̩n ake̩ko̩o̩ niyanju lati ma se je̩ ki awo̩n kan ti wo̩n ni itikuti lori iro̩, ki eto isejo̩ba awa-ara-wa le baa ke̩se̩ jari.

Wọ́n ti kó ọmọ Nàìjíríà 203 tó há sí Libya padà wálé

Wọ́n ti kó ọmọ Nàìjíríà 203 tó há sí Libya padà wálé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń dáhùn sí ìṣẹlẹ pàjáwìrì lórílẹ̀ -èdè yìí ti sọ pé ọmọ Nàìjíríà tí iye wọn jẹ́ igba-lé-mẹ́ta (203) làwọn ti gbà wọlé báyìí láti orílè-èdè Libya tí wọ́n há sí tẹ́lẹ̀.

Ajọ International Organization for Migration (IOM) pẹlu ajọṣepọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, ‘National Emergency Management Agency’ (NEMA), ni wọn ko wọn wale pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in.

Oju opo X ajọ NEMA ni wọn ti kede eyi lọjọ Iṣẹgun.

Nnkan bii aago mẹje alẹ ọjọ Isegun naa ni NEMA kede pe wọn balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed, Ikeja.

Ọkọ ofurufu Al Buraq ti nọmba rẹ jẹ 5A-BAC ni wọn lo ko wọn de.

Wọn ṣalaye pe awọm ọmọ Naijiria naa ko ri ọna ti wọn yoo gba fi Ariwa Libya ti wọn ti le wọn kuro silẹ ṣaaju asiko yii, ko too di pe iranlọwọ de fun wọn.

Kete ti wọn balẹ si papakọ ofufurfu Murtala Muhammed, ni awọn alaṣẹ ti tẹwọ gba wọn.

Agbalagba ọkunrin ti wọn jẹ aadọta niye (50), agbalagba obinrin mẹrindinlọgọrun (96), ọmọde mọkandinlọgbọn (29) ati awọn ọmọ ọwọ mejidinlọgbọn (28) ni awọn eeyan naa.

Atẹjade ti NEMA fi sita ṣalaye pe meji lara awọn ọkunrin naa ni wọn nilo itọju pajawiri nigba ti wọn ko wọn de.

Ileewosan ijọba to wa n’Ikeja ni wọn sare gbe wọn lọ fun itọju bi NEMA ṣe sọ.

Yègèdè! Ọmọ bíbí inú Sefiu Alao ń fi ìwé dárà nílù Òyìnbó

Alao

Bola Afolabi

Opolopo awon ololufe gbajugbaja onifuji ti a mo si Sefiu Alao ni won n ba a yo sese bayii, latari bi okan lara awon omo re Dokita Nofisat Adekunle,se ni itesiwaju ni ilu Oyinbo.

Arabinrin naa, to jo baba re bii imumu, lo n gba oye kun oye, to si n fi imo re se duniyan loore.

Bi apeere, o ti gba imo ijinle doctorate lati Walden University ni orile ede Amerika.

Eyi to tun je kasiara ibe ni pe imo ijile alakaso keji (MASTERS) meta ototo ni Nofisat ni lati University of Minnesota, the University of Buffalo, ati Plymouth State University, ti gbogbo won wa ni Amerika

Ni pataki, a gbo pe oga agba kan ni awunilori obinrin yii je ni gbajugbaja ile-ise ilu oyinbo  Halliburton.

Alao pelu Nofisat

Ki a wa maa wo ise Olorun, nigba ti Nofisat n fi imo iwe dabira ni Amerika, baba re, Sefiu Alao, eni ti a tun mo si Original Omo Oko, je akorin to fi Abeokuta se ibujokoo,gege bi  bi Rasheed Ayinde Fuji Merenge se fi Ibadan se ile.

Koda, awon ko gbe kadara won lo si Ipinle Eko bi awon akegbe won bii Adewale Ayuba, Abass Akande Obesere ati Osupa Saidi se se.

Sugbon e ko wa raye baii? Bi Sefiu tile se je ‘omo oko to gbo kirakira’ to, omo bibi inu re lo wa di araba ni ilu oba.

Olorun ma kare o. Ki Edumare tubo maa mu agbega ba Omowe Nofisat.

Òsèlú jé̩ kí ìmò̩ mi gbòòrò síi – Funke Akindele

Òsèlú jé̩ kí ìmò̩ mi gbòòrò síi –
Funke Akindele

Mary Fagbohun

Gbajugbaja oṣere Nollywood ati agberejade, Funke Akindele ti sọrọ nipa iriri rẹ ninu oṣelu, o ṣapejuwe iriri naa gẹgẹ bi irin-ajo iyipada ti o fun un ni agbara ati pe o mu oye rẹ nipa idari, iṣejoba ati idagbasoke orilẹ-ede jinle.

Nigba to n soro lori eto #WithChude Live eyi ti gbajumo ile ise iroyin Chude Jideonwo gbalejo re, Akindele soro nipa awon ohun to wuu lori lati darapo mo oselu ati awon eko to ko lona.

“Mo nilo lati ṣe atilẹyin fun awọn ẹlomiran. Idi niyi ti mo fi darapo mọ oselu. Mo wọle sinu rẹ, mo ri isesi awo̩n e̩da ninu oselu, mo mo̩ ibi ti wo̩n to obinrin sii labala oselu.

Akindele, eni to dije gege bi igbakeji oludije gomina fun ipinle Eko labe egbe oselu People’s Democratic Party ninu eto idibo odun 2023, so pe iriri oun ninu eto oselu lo ko oun ni igboya, ifarabale ati agbara imo.

O tẹsiwaju, “Mo duro, mo sọrọ, mo kọ eyi lati ibẹ, pe o ni lati ni igboya, o nilo igboya, o nilo lati lagbara, ohun ti yoo sele yoo sele, iberu yoo gbe ọ si aaye nikan.

“Nitori naa gbogbo eyi ni mo kọ lati inu ṣiṣe oṣelu. Ati pe mo mọ ọpọlọpọ awọn nọmba, mo si kọ ẹkọ diẹ sii, gba imọ diẹ sii, mo n kawe sii ni bayii, mo n nimọ sii nipa orilẹ-ede mi, mo n nimọ sii nipa ipinle mi.

“Nigba ti mo ba fẹ sọrọ, maa sọrọ pẹlu iṣiro, se o ye, pẹlu akojo naa. Nitori naa inu mi dun pe mo darapo mo oselu. Ti aaye ba tun gba mi, maa tun se oselu sii.”

 

Ìwòsàn ni orin Moses Bliss jé̩ – Davido

Ìwòsàn ni orin Moses Bliss jé̩ – Davido

Mary Fagbohun

Olorin Naijiria, Davido ti so fun olorin ihinrere Moses Bliss pe iwosan ni orin re je nigba ti won pade ni papa ofurufu, eyi mu inu awon afenifere re dun pupo.

Bí Moses Bliss àti ìyá rẹ̀ ṣe fẹ́ wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí London, Davido tọ̀ wọ́n lọ, ó sì kí Bliss tọ̀yàyà-tọ̀yàyà.

Ninu ibara-ẹni-sọrọ kukuru wọn, Davido gboriyìn fun orin Mose Bliss, o ṣapejuwe awọn orin rẹ bi “iwosan.”

Imọrírì nitootọ yii fun orin ihinrere ti tan iyin laarin awọn afenifere, to ṣe afihan ẹgbẹ ti o yatọ ti irawọ Afrobeats.

Moses Bliss wa ni Ilu Lọndọnu lati ṣabẹwo si iyawo rẹ ati ọmọ tuntun, to tun je mimu ileri ti o ṣe fun iya rẹ ṣẹ ni ọdun kan sẹyin.

Fonran ipade wọn ti lọ kaakiri, to n se itankale ayọ ati oro rere laarin awọn afenifere ti o ni riri ibowo laarin awọn olorin mejeeji.

Àràbà ni baba: First Bank tún yọ bí ọjọ́ pẹ̀lú ilé olókè mẹ́tàlélógójì ní Eko Atlantic

 

Akeem Lasisi

Ile ifowopamo First Bank ti tun fihan pe oun ni baba bayii o, pelu bo se bere kiko olu ileese kasiara miran ni ilu aramanda Eko Atlantic City ni Ipinle Eko laipe yii.

Kii se pe First Bank ko ni olu ilesse to see fi yangan tele.

Eyi to wa ni Marina, gabankogbi ni.

Ara naa lo kan fe da.

Se bi a sa keke ogun, aajo ewa la fi se; bi a si fa abaja ogbon, jo ewa naa ni.

Koda ka fi oju sile ni gombo, aajo ewa naa ni.

Olu ileese eyi ti ile ifowopamo ti je akoko ni Naijiria sese bere sii ko yii, aragbayamuyamu ni.

Iyen ni oloto to ni t’oun oto.

Ile naa ni yoo ga julo ni orile-ede Naijiria.

Se lojoun, Cocoa House la ma si ile akoko to ga julo ni Naijiria.

Sugbon eyi ti First Bank n gbe bo yii, aja metalelogoji (43 storeys) lo ni.

Kii waa se giga fiofio nikan ni o, bi won se fee ko o, arakenge ni.

Awon ohun alumooni, imo ero ati ohun itesiwaju oro aje ti yoo wa nibe koja ohun ti a n royin.

Idi niyi ti opolopo awon eeyan ja-n-kan-ja-n-kan se sugbaa First Bank ni nnkan bii ose kan seyin, nigba ti won n kede ibere ise lori ile naa.

Koda, Aare Bola Tinubu naa ba won yo sese.

Igbakeji Aaare, Kashim Shettima; Gomina Ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu; Alaga First Bank, Femi Otedola ati ore re olowo tabua, Aliko Dangote, pelu opo awon eeyan nla-nla lo wa ni Eko Atlantic City lojo naa.

Nigba ti Shettima, eni to soju Aare Tinubu n soro, o fi idunnu han pe First Bank se bi akoni, leyin pe o n mu itesiwaju ba oro aje.

O ni igbese ti banki naa gbe je eyi ti yoo tun je ki igbagbo tubo wa ninu oro aje Naijiria.

Bakan naa, Sanwo-Olu dunnu sinsin, to si kan saara si First Bank.

Inu Gomina dun pe Eko Atlantic ti di gboregejige, ti First Bank naa si gbe igbese itesiwaju nipa kiko olu ileese nla naa sibe.

Idi niyii ti inu Sanwo-Olu fi dun nigba ti o gbe iwe eri ifunni nile fun awon alase banki naa ningbangba walia.

Otedola, eni ti opo eniyan gba pe o wa lara awon to se agbateru lilo First Bank si Eko Atlantic, kan saara  si ijoba apapo, ijoba Ipine Eko ati awon alase Eko Atlantic.

O wa mu u da awon eniyan loju pe teru-tomo ni yoo maa je anfaani itesiwaju ti First Bank n se naa titi ayeraye.

Oga Agba fun banki naa, Olusegun Alebisou, naa n rerin-in idunnu bi gbogbo aye se yi i po, ti won si n pohun rere First Bank.

O se alaye hulehule awon ohun meremere ati ise ribiribi, eyi ti yoo tubo mu ilosiwaju ba banki naa, Ipinle Eko ati Naijiria lapao, eyi ti won yoo maa gbe se ninu ile kasiara naa.

Lai deena penu, IROYIN OWURO ki First Bank ku oriire.

Olorun a pari ile nla naa layo.

Bee, ilosiwaju nla-nla ni yoo maa ba ile Yoruba, Ipinle Eko, Naijiria ati Aaafirika lapapo o.

Èmi kò tó Fathia Balogun fé̩ – To̩pe̩ Adebayo̩ Salami

Èmi kò tó Fathia Balogun fé̩ – To̩pe̩ Adebayo̩ Salami

Mary Fágbohùn

Oṣere ati oludari ere Nollywood, Tope Adebayo, ti a mọ si Waheed ninu fiimu TV ti o gbajumọ, “Jenifa’s Diary” ti tako awọn aheso ti o ti pẹ nipa ibasepo ifẹ pẹlu agba oṣere, Faithia Balogun.

Ninu ifọrọwero̩ kan to ṣe laipe yii lori ikanni YouTube Baba Ibe TV, Adebayọ jẹwọ pe oun ni ibatan timọtimọ pẹlu Balogun, ẹni ti o dagba ju oun lọ, ṣugbọn o sọ pe ko si ifẹnumọ kankan laarin wọn.

O fi ibanujẹ han lori aheso naa, o ṣapejuwe rẹ bi eke ati eyi ti o ṣeeṣe pe ki Ibasepo timotimo won se okunfa.

Adebayo nigba to n soro lori iroyin to dun un ju ninu ile-ise naa, o ni, “Iro kan to dun mi lokan ni nigba ti awon eeyan fi esun kan eniyan bii temi pe mo n ba Aunty Faithia se. Se o mu opolo wa?

“Otitọ ni wi pe, iwọ lo fi esun yii kan mi ati pe ẹnu rẹ ni. Bi emi ati Aunty Fathia se sunmo ara wa pekipeki to, ko si ẹnikan ti o le mọ bi asopọ wa se lagbara to.

“Ṣugbọn, maa fi asiri kan silẹ fun ọ lonii, Fathia ati emi yoo tẹsiwaju lati wa nitosi ara wa nitori pe o jẹ oluranlọwọ mi.”

O salaye siwaju sii pe Balogun ti wa ni igun re nigba gbogbo, o si se atileyin fun ala re lati di oludari, paapaa lasiko ti baba oun, Salami Adebayo, ti a mo si Oga Bello n ṣiyemeji agbara oun lati se iyipada naa.

“Mo sọ fún bàbá mi pé mo fẹ́ di olùdarí, àmọ́ ó rẹ́rìn-ín, ó sọ fún mi pé kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ mú mi rẹ̀wẹ̀sì.

“Aunty Faithia wa nibẹ, nitori naa o kọju si baba mi, o sọ pe emi ni maa dari awọn iṣẹ fiimu re marun-un to n bọ.

“Mo n sọ fun ọ pelu ariwo ati ni kedere pe lati isẹ oludari akoko yii pẹlu iṣẹ akanṣe rẹ ni gbogbo agbaye ti gbagbọ ninu agbara mi, ati pe o ṣe ifilọlẹ mi bi oludari,” ni o salaye.

Adebayo sọ pe ẹnikẹni ti o ba duro ti o̩ ni akoko iṣoro ati aidaniloju ni ko yẹ ki o gbagbe. O fi han pe diẹ ninu awọn iṣẹ akanṣe Faithia Balogun ti o lowo si ni o jẹ aṣeyọri nla.

“O kan dun mi pe awọn eniyan gbagbọ pe nitori pe a sun mọ ara wa, dajudaju o tumo si pe a gbọdọ ni ibaṣepọ.

“E jọ̀wọ́, mo fẹ́ bẹ àwọn olùgbọ́ wa pé kí wọ́n mú èrò náà kúrò pé bí àwọn ako̩ ati abo ba ti sun mo̩ ara wo̩n, pé wọ́n ń fẹ́ra wọn ni,” o ma se o.