Home Blog Page 15

David Mark kò̩wé f’e̩gbé̩ PDP sílè̩

David Mark kò̩wé f’e̩gbé̩ PDP sílè̩

Yínká Àlàbí

Iroyin yajoyajo to jade laipe̩ yii n fidi re̩ mule̩ pe olori ile igbimo̩ asofin agba te̩le̩, alagba David Mark ti ko̩we f’e̩gbe̩ sile̩ bayii.  O ni oun ko le maa s’e̩gbe̩ ija loni rogbodiyan lo̩la. O ni ojumo̩ kan ijo̩ngbo̩n kan ni e̩gbe̩ naa. O ni bi oun ko se mo̩ eyi ti awo̩n olori e̩gbe̩ n se ni oun ko mo̩ eyi ti awo̩n o̩mo̩ n se.
Mark ni oun ko si fe̩ ki o di ariyanjiyan pe ara wa ni tabi ara wa ko̩ ni o je̩ ki oun fi iwe see.
Alagba yii ko tii so̩  inu e̩gbe̩ to fe̩ lo̩ darapo̩ mo̩ sugbo̩n o ni oun ko se PDP mo̩.
Bi o ba se n lo̩ iroyin maa je̩ ki a gbo̩.

Asẹ́wó kú s’ọ́wọ́ ènìyàn mẹ́ta l’Ondo

Asẹ́wó kú s’ọ́wọ́ ènìyàn mẹ́ta l’Ondo

Yínká Àlàbí

Ọga ọlọpaa DSP Oluṣọla Ayanlade salaye yii ni ilu Akure ni ana ọjọ Aje pe ọwọ sinkun ofin ti tẹ awọn eniyan mẹta ni ile itura Brothel to wa ni agbegbe Cathedral ni Akure. Arakunrin kan lo gbe alasewo kan lọ si ile itura. Nigba to di ki ere bẹrẹ ni arabinrin naa ni ara oun ko ya daadaa ati wi pe oun ko ni le se isẹ naa mọ.
Wọn bẹrẹ ariyanjiyan gidi lori ọrọ yii ni eyi to mu ki wọn ko ara wọn jade sita ti manega ilu itura naa gbiyanju lati ba wọn pari rẹ. Arakunrin to gbee lọ si ile itura ni ko si ija ki alasewo naa ba oun mu ẹgbẹrun meedogun ti oun fun un f’owo isẹ, alasewo naa kọ jale pe oun ko ni ko owo naa silẹ.
Ibi ariwo naa ti ọkunrin to ni owo ti pe awọn eniyan rẹ pe obinrin kan fẹ yan oun jẹ. Bi awọn naa se da debẹ mu ki ẹru ba awọn to ni ile itura, wọn si sare pe agọ ọlọpaa. Ọwọ awọn ọlọpaa tẹ mẹta ninu awọn ọkunrin naa, wọn si sare gbe alasewo naa lọ si ile iwosan awọn ọlọpaa to wa ni Akure.
Ile iwosan naa ni wọn ti salaye fun awọn ọlọpaa pe obinrin naa ti jẹ ipe Ọlọrun ko to de ile iwosan. Wọn ti tẹ obinrin naa si aaye igboku si ni ile iwosan fun ayẹwo to daju.
Iwadii si n tẹ siwaju ni ko jẹ ki Ọga ọlọpaa Ayanlade darukọ awọn ti ọrọ naa kan.

Mi ò fìgbà kan fìyà jẹ Mohbad – Sam Larry

Mi ò fìgbà kan fìyà jẹ Mohbad – Sam Larry

Mary Fágbohùn

Lodi si esun ti won fi kan Sam Larry nigba ti gbajugbaja olorin Naijiria n ni, Aloba Ilerioluwa Imole ti gbogbo eniyan mo si Mohbad jade laye pe o lowosi ohun ti o yori si iku olorin naa. Sam Larry ni ohun ko mo nnkankan nipa re.

Ninu ifọrọwerọ kan laipẹ pẹlu ajafitafita Verydarkman, Sam Larry sọrọ nipa fonran to lo kaakiri to safihan pe o dojukọ Mohbad ni eti okun kan.

Fidio naa fa ibinu pẹlu bi ọpọlọpọ awọn eeyan se gbagbọ pe o jẹ ẹri ikọlu.

Sam Larry sọ pe awon eeyan fun fonran naa ni itumọ oto ni, o ṣalaye pe oun sunmọ Mohbad lati beere pe ki o da owo ere kan to gba sugbon to ko lati wa pada.

“Fidio iseju aaya ni. Mo wa pẹlu ọmọ mi ni eti okun. Nigba ti mo ri Mohbad, mo lo sọdọ rẹ ati beere pe ki o fun mi ni owo ere to gba sugbon ti ko wa. Zlatan wa nibẹ o si yara wọle lati yanju rẹ. Ko si ikọlu kankan, mi o fiya je Mohbad ni gbogbo ojo aye re, “ni o so.

Sam Larry tun soro nipa ibi to wa lakoko iku Mohbad, o ni oun wa ni Dubai, nigba ti ẹlẹgbẹ rẹ Naira Marley wa ni Amsterdam.

 

Ọmọ méjì da èmi àti Sẹgun Ogungbe pọ̀ sùgbọ́n a kò f’ẹ́ra – Omowunmi Ajiboye

Ọmọ méjì da èmi àti Sẹgun Ogungbe pọ̀ sùgbọ́n a kò f’ẹ́ra – Omowunmi Ajiboye

Mary Fágbohùn

Gbajugbaja oṣere tiata, Omowunmi Ajiboye, ti sọrọ sita lori ajọsepọ to wa laaarin oun ati akẹgbẹ rẹ, toun naa jẹ ilumọọka oṣere tiata, iyẹn Segun Ogungbe.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipe yi, Ajiboye ni won ko ṣe igbeyawo tabi ni erongba lati fẹ ara won.

O ni Segun Ogungbe ko mọ awọn mọlẹbi oun yatọ si ọrẹ aburo oun kan to mọ ni ilu Eko.

Agba oṣere naa, to bi ọmọ meji fun Segun Ogungbe wa rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ṣe pẹlẹ pẹlu rẹ nitori ko ki n ṣe eeyan buruku.

Wunmi sọ ninu ifọrọwerọ naa to ṣe wí pe nigba ti oun wa ninu igbesi aye Segun Ogungbe, nnkan dara fun un, ti nnkan si tun dara fun nigba ti oun kuro ni ile rẹ.

“Ẹ jẹ ki n sọrọ yii, ko tan, emi ati Segun Ogungbe, a ko ṣe igbeyawo tabi ni erongba pe a o fẹ ara wa.

Ko mọ mọlẹbi mi, yatọ si ọrẹ aburo mi kan to n gbe ni Eko. Segun funrara rẹ le jeri si oro yi.

“Si awọn ololufẹ mi, mo n rawo ebe si yin pe ki e se pẹlẹ pẹlu mi.

Mi o ki n ṣe eniyan buruku, mi o si ba aye Segun Ogungbe jẹ.

“Nigba ti mo wa ninu aye rẹ, nnkan lọ daada fun, nigba ti mo kuro, ko yipada, nnkan si n lọ daadaa fun un.

“Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ki n gbadun aye mi. Mo gba adura pe ile yin o ni bajẹ,” ni Wunmi sọ.

Ọdun 2023 ni ipinya waye laaarin Segun Ogungbe ati Wunmi Ajiboye lẹyin ti wọn bi ọmọ meji fun ara wọn tán.

A kábàámọ̀ pé a polongo ìbò fún Tinubu – Lalude

A kábàámọ̀ pé a polongo ìbò fún Tinubu – Lalude

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere tiata, Lalude ti safihan pe oun ati awon akegbe oun miran gba egberun mewaa naira owo ounje ojoojumo lati polongo ibo fun Aare Tinubu lodun 2023.

Lalude so eyi nigba to n fi ika abamo bonu lori atileyin to se fun ijawe olubori Tinubu ninu eto idibo ohun.

Nigba to n soro ninu iforowero kan to n lo kaakiri lori ayelujara, osere naa salaye pe osu kan ati ose meta lohun ati awon akegbe oun bii meloo kan fi se ipolongo ipo laigba sile kan.

Lalude to koro oju si abajade ohun ti won se ohun ni egberun mewaa naira pere ni won gba bii owo ounje lojoojumo, won o si tii gba eyikeyi ere lati bi odun meji ti Tinubu ti wa lori alefa.

“Won kan n fun wa ni egberun mewaa lati fi jeun lojoojumo ni. O ye ko ju bee lo fun ipolongo, sugbon won pinnu lati fun wa ni egberun mewaa. Nigba ti won ri pe a n fi owo naa pamo, won din iye owo naa ku, nigba miran won o ni fun wa ni nnkankan lojo meji si meta.

“Leyin gbogbo ise ipolongo ipo fun osu kan ati ọsẹ meta, won ko lati sanwo fun wa. Gbogbo awon ti won fi anfaani to ye ka je mu ko ni soriire laye won,” Lalude so bee.

Osere naa soro leyin ojo die ti akegbe re, Alapini, ni oun kabamo ipolongo ibo yii.

Odun meji niyi leyin ti a dibo yan Aare.
E ranti pe pupo ninu awon ilumooka ni won kede atileyin fun Tinubu ninu eto idibo to koja bii Saheed Balogun, Bimbo Akintola, Toyin Abraham, Eniola Badmus, Olaiya Igwe, Seyi Law ati awon miran.

Wayi o, abajade re ko te opolopo awon omo Naijiria lorun, pelu awuyewuye to n jeyo lori ikanni ibanidore, pelu bi opolopo se yera fun won ti won si bu enu ate lu ipinnu won nitori bi eto oro aje se denukole ati aisiaabo to peye labe isejoba Muhammadu Buhari pelu awon asejoba labe egbe oselu All Progressives Congress (APC).

 

Ọwọ́ tẹ olóyè tó jí ọmọdébìnrin kan gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ọwọ́ tẹ olóyè tó jí ọmọdébìnrin kan gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo

Mary Fágbohùn

Oloye kan niluu Laaagba ni ijọba ibilẹ ila oorun Ondo, Adeniyi Ifedayo, ni awon ọlọpaa ti mu won si ti fi si atimọle lori ẹsun pe o ji ọmọdebinrin ọdun mejila gbe ti o si tun fipa ba a lopọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Olayinka Ayanlade, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun awon oniroyin.

Iroyin jabo pe Oloye Ifedayo ọhun tan ọmọbinrin naa wọ ile rẹ, nibi ti o ti i mọ fun ọsẹ meji to si n fipa ba ọmọde naa lopọ.

Ẹnikan to n gbe ni agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti wáyé, sọ fawọn akọroyin wi pe afurasi ọlọkada kan lo gbe ọmọ naa lọ si ile oloye naa.

Ẹni to wa lagbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye fikun ọrọ rẹ pé, ẹkọ ni Oloye naa n fun ọmọbinrin ọhun mu lojoojumọ, ti o si n tun fipa ba a lopọ.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Olayinka Ayanlade sọ pe afurasi ọlọkada to ṣiṣẹ pọ pẹlu Oloye Ifedayo ti sá lọ.

O fi kun un pé ileeṣẹ ọlọpaa si n wa ọlọkada yii.

”Awa ọlọpaa n sa gbogbo agbara ati ipa wa lati mu afurasi to ṣiṣẹ pọ pẹlu oloye naa.

Oloye Ifedayo ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii, a n gbiyanju lati wa gbogbo ẹri lori iṣẹlẹ naa.

Iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, afurasi oloye yii yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti a ba ti pari iwadii ti a n ṣe lori iṣẹlẹ naa.

Afurasi ọlọkada to gbimọ pọ pẹlu Oloye Ifedayo naa yoo foju ba ile ẹjọ ti ọwọ ba ti tẹ ẹ.

Ọrọ naa ti de olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo bayii fun iwadii to munadoko lori iṣẹlẹ naa,” Ayanlade lo sọ bẹẹ.

 

 

Kò sí ọpọlọ nínú kíkó ohun àlùmọ́nì rẹpẹtẹ jọ – Made Kuti

Kò sí ọpọlọ nínú kíkó ohun àlùmọ́nì rẹpẹtẹ jọ – Made Kuti

Mary Fágbohùn

Olórin Afrobeats Made Kuti ti sọ pé òun mọyì ìrọ̀rùn ju kiko ọrọ̀ àlùmọ́nì jo nítorí pé bàbá òun gbajúgbajà olórin Femi Kuti se tọ́ òun dàgbà.

Nigba ti o n soro lakoko ifọrọwero lori eto Breakdown ti Pulse gbe kale, Kuti ṣe beere idi ti opolopo fi n ko ọkọ ayọkẹlẹ pupọ jo, o ṣapejuwe wọn bi awọn ohun-ini ti iwuyi re kii pẹ.

Ó ni oun gba láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ara oun, nigba to mu itelorun ninu ara eni bi ohun pàtàkì ju kíkó àwọn ohun ìní pupo jo.

“Mo kan rii pe o jẹ ohun ti ko bojumu lati ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ pupọ,” ni o so, o tẹnumọọ pe ifẹ ọrọ-aye kii ṣe pataki fun oun.

“Mo je iru eniyan ti o n ṣe ohun ti o fẹ. Nitori naa ọpọlọpọ awọn ohun ti mo feran ni … Boya baba mi ni oye pupọ pẹlu bi o ṣe to wa dagba. Ṣugbọn ero temi ni pe, mi o bikita nipa awọn ọrọ̀ àlùmọ́nì rara. Fun apẹẹrẹ, ọkọ ayọkẹlẹ meloo ni o nilo lati wakọ? Ko ye mi idi ti o fi nilo ọkọ ayọkẹlẹ meje, mejo. Wọn je awọn ohun-ini ti iwuyi re kii pẹ. Laipe jojo, won ko ni wuyi mo lawujo.

“Nitori naa, o jẹ ohun ajeji si mi, ṣugbọn awon eniyan miiran nifẹẹ sii”, ni o salaye.

 

 

Ó sú mi o! Ìgbéyàwó elé̩è̩kejì tún forí lagi – Frank Edoho

Ó sú mi o! Ìgbéyàwó elé̩è̩kejì tún forí lagi – Frank Edoho

Yínká Àlàbí

Are̩wa o̩kunrin to je̩ ilumo̩o̩ka oniroyin, agbohunsafefe lori e̩rc te̩lifiso̩n ti gbogbo aye mo̩ si Frank Edoho ti ke gbajare pe igbeyawo oun tun ti fori so̩npo̩n.
Aanu arakunrin yii maa se eeyan nigba to n salaye ara re̩ lori ayelujara “Tea with Tay Podcast” ni o̩jo̩ satide.
O ni gbogbo ohun ti o̩ko̩ iyawo gidi ye̩ ki o se ni oun se sugbo̩n ko sise̩ fun oun.
O ni be̩e̩ naa ni pe̩lu Katherin Obiang to je̩ iyawo ako̩ko̩ oun naa se ti igbeyawo naa fi daru ni o̩dun 2011.
Edoho ni gbogbo wa mo̩ to maa n se “who wants to be a millionaire” lori e̩ro̩ te̩lifiso̩n. O ni ti Sandra Onyenuchenuya lo wa ya oun le̩nu ju. Frank ni oun ko tile̩ wa mo ohun to ye̩ ki oun se ti oun ko se lati mu wo̩n duro.
Frank ni boya oun ni ko tile̩ mo̩ ohun ti wo̩n n pe ni ife̩ gidi tabi awo̩n ni ko mo̩ iyato̩ ninu iyawo ile ati afe̩sona. O ni boya oun ko tile̩ ni e̩bun iyawo ni nitori pe ko ye̩ ki igbeyawo e̩le̩e̩keji daru pe̩lu iriri ti ako̩ko̩.

Portable àti Bobrisky ń lérí ìjà ìgboro sí ara wo̩n

Portable àti Bobrisky ń lérí ìjà ìgboro sí ara wo̩n

Mary Fágbohùn
Ijalabi olorin Naijiria Habeeb Olalomi Badmus, ti opo mọ si Portable, ti fesi si ajise-bi-obinrin Idris Okuneye, ti gbogbo eniyan mọ si Bobrisky se yi oruko re pada, o pe e nija lati jade sita to ba daa loju.

Bobrisky, ti o ṣẹṣẹ yi orukọ rẹ pada si Afolashade, ti pe akiyesi Portable, eni ti o beere pe iyipada orukọ naa se je ojulowo si.

Ninu fidio kan to ju sita lori Instagram, Portable ni a rii ti o n ṣe ẹlẹya ajise-bi-obinrin, o ni o fi owo yi ohun to wa làyà rẹ pada. O ni to ba daa loju ko bo sita wa ja, o beere Ferrari kan ati milionu lona ogorun-un naira ki o to le farahan.

Olorin alawuyewuye naa tun pe iya Bobrisky lati kilọ fun ọmọ rẹ ki o si ti owo re bo aso. O ni oun yoo ba oju rẹ jẹ pẹlu ese kan, o ni ko yoju sita naa.

Lasiko to gbe oro naa siwaju sii, Portable pe Bobrisky nija lati pada si orilẹ-ede Naijiria ki won le nawo ese si ara won, o sọ pe oun ti ṣetan lati fi iru eni ti oun je han.

 

Akọrin ẹ̀mí to ṣekúpa ò̩ré̩bìnrin ni ilé e̩jó̩ ti dájó̩ ikú fún

Akọrin ẹ̀mí to ṣekúpa ò̩ré̩bìnrin ni ilé e̩jó̩ ti dájó̩ ikú fún

Mary Fágbohùn

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Nasarawa tó fi ìlú Lafia ṣe ibùjókòó ti dájú ikú fún akọrin ẹ̀mí Oluwatimileyin Ajayi, fún ẹ̀sùn ṣíṣekúpa àgùnbánirọ̀, Salome Adaidu.

Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà ni Adájọ́ Simon Aboki tó gbọ́ ẹjọ́ náà ní kí wọ́n lọ yẹgi fún Ajayi títí ẹ̀mí yoo fi bọ́ lara rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ náà ninu oro rẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Ajayi jẹ̀bi ṣíṣekúpa Salome Adaidu tó sì tún kun òkú rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bi eni kun eran agbo èyí tó lòdì sí abala 221 ìwé òfin ìwà ọ̀daràn tí ẹ̀ka àríwá Nàìjíríà, tó sì jẹ́ pé ikú ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà.

Ṣáájú ni ìyá ọmọ náà salaye pé Salome ló ń ṣe ọkọ fún òun láti ìgbà tí bàbá rẹ̀ ti kú àti pé òun fẹ́ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo lórí ikú rẹ̀.

Nigba tí ìgbẹ́jọ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Ajayi sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Àkọ́bí ẹbí Adaidu, Patience Unekwuojo Adaidu sọ fún oniroyin pé òun mọ̀ pé kò sí nǹkan tó le dá ẹ̀mí àbúrò òun padà ṣùgbọ́n ohun tó dá òun lójú ni pé Timileyin náà máa jáde láyé lọ́jọ́ kan.

Patience sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún Timileyin Ajayi.

Ṣáájú kí ẹjọ́ náà tó dé ilé ẹjọ́ ni Patience sọ pé Ajayi kìí ṣe ọ̀rẹ́kùnrin àbúrò òun nítorí kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n nínú ẹbí àwọn.

Gẹ́gẹ́ bí nǹkan tí Patience sọ, ó ní Salome láwọn èròǹgbà tó dára fún ọjọ́ iwájú rẹ̀ àti pé ọ̀gá rẹ̀ ní Nicon Insurance ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sẹ́nu ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ayélujára èyí tó máa ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ Àbámẹ́ta kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.

Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún, tó ń ṣe àgùnbánirọ̀ ní iléeṣẹ́ Nicon Insurance tó wà ní Abuja ni Salome Adaidu kó tó jáde láyé.

Òun ni ọmọ karùn-ún nínú ọmọ mẹ́fà táwọn òbí rẹ̀ bí.