Home Blog Page 14

Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà – Àwọn aṣòfin kan yarí

Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà – Àwọn aṣòfin kan yarí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aṣòfin kan nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ìjọba Tinubu lórí ìlànà tó ń gbà kojú ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Àwọn aṣòfin náà, láti ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà tó wà ní Nàìjíríà, kọminú lórí ìpèníjà ààbò ṣe ń fi ojoojúmọ́ peléke síi àti bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń wà nínú inú fu àyà fu lójoojúmọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́rú ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìlànà tí ààrẹ ń gbà kojú ìṣòro ààbò, tí wọ́n sì ní ààrẹ kò ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe yẹ.

Ṣáájú níbi ìjòkó ilé tó wá lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, àwọn aṣòfin fi ẹdùn ọkàn wọn hàn lórí ìpèníjà ààbò Nàìjíríà, tí wọ́n sì rọ ìjọba àpapọ̀ láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìpèníjà yìí.

Àwọn aṣòfin tí wọ́n kó ara wọn jọ náà bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba ṣe ń bá àwọn agbébọn jíròrò lórí ìkọlù tí wọ́n ṣe sáwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Lára àwọn aṣòfin náà ni Muhammed Soba láti ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá, Zakari Mohammed láti ààrin gbùngbùn àríwá, Olasupo Abiodun láti gúúsù ìwọ̀ oòrùn, Sadiq Ibrahim láti ìlà òòrùn àríwá, Uko Nkole láti ìlà oòrùn gúúsù, àti Bassey Ewa láti ààrin gbùngbùn gúúsù.

Wọ́n wòye pé ṣíṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sáwọn èèyàn Nàìjíríà nítorí wọ́n ń bá àwọn ọ̀daràn jíròrò dípò kí wọ́n fi òfin gbé wọn.

Wọ́n ní kìí ṣe irú àsìkò yìí táwọn èèyàn Nàìjíríà ń sunkún lórí pípè fún ààbò tó péye ló yẹ kí ìjọba máa bá àwọn tó jí àwọn ọmọdé gbé, tí wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn obìnrin láì bìkítà, tí wọ́n sì ń da ọ̀pọ̀ ìlú láàmú ló yẹ kí ìjọba máa bá jíròrò.
Nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé ní Kano, Kwara, Kebbi, Niger àtàwọn ìpínlẹ̀ míì, àwọn aṣòfin náà níṣe ni ìjọba dákẹ́, tí wọ́n sì ń gba ọ̀nà ẹ̀yìn láti máa bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìpàdé.

“Kò sí orílẹ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ tó máa ma bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìdúnàádúrà. Kò sí ibití bíbá àwọn agbébọn jíròrò ti so èso rere káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn.

“Ní Colombia, ìjíròrò tí ìjọba bá àwọn ikọ̀ Revolutionary Armed Forces mú àlékún bá ìjínigbé láti fi máa bèèrè owó, tó sì tún rọgun sápá àwọn ikọ̀ náà.

“Ní Afghanistan, ààyè tí wọ́n fi gba àwọn Taliban tó fi mọ́ pípàrọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló fi ààyè gba àwọn ẹgbẹ́ láti gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn aṣòfin náà ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti yàgò fún bíba àwọn agbéṣùmọ̀mí jíròrò àti pé ìgbésẹ̀ náà yóò túnbọ̀ máa pọnkún ìwà ipá tó ń wáyé.

Wọ́n ní ìjọba ń sọ pé àwọn kò kajú òṣùwọ̀n, tí wọ́n sì ń pè fún àlékún ìjínigbé àtàwọ n ìwà ọ̀daràn míì, tí kò sì ní jẹ́ káwọn aráàlú ní ìgboyà nínú wọn mọ́.

Àwọn aṣòfin náà tẹmpẹlẹmọ pé iṣẹ́ àkọ́kọ́ ìjọba ni láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.

Wọ́n ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò orílẹ̀ èdè tí àwọn ọ̀daràn yóò máa bẹ̀rù àwọn aláṣẹ, kìí ṣe èyí tí àwọn aláṣẹ yóò ti máa bẹ̀rù ọ̀daràn.

Yíyan asojú orílèèdè; Ò̩tá e̩ni ò kì ń pa òdù ò̩yà – APC

Yíyan asojú orílèèdè; Ò̩tá e̩ni ò kì ń pa òdù ò̩yà – APC

Yínká Àlàbí

E̩gbe̩ oselu APC ni o̩ta e̩ni o ki n pa odu o̩ya ni awo̩n e̩gbe̩ alatako fi o̩ro̩ awo̩n asoju orileede ti Aare̩ Tinubu fi ranse̩ se. Wo̩n ni ko si ohun ti ko dara ti awo̩n se.
Àkójọ àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè tí ìjọba Tinubu fi ránṣẹ́ fa ariyanjiyan láàrín APC àti àwọn ẹgbẹ́ olóṣèlú alatako. PDP sọ pé àkójọ náà kún fún àwọn ènìyàn tí ihuwasi wọn kò dáa, tí kò sì bójú mu pé wọ́n lè dúró ṣojú Nàìjíríà lókèèrè.
Wọ́n tún fi kún un pé èyí fi hàn pé Ààrẹ Tinubu kò ko̩biara si o̩ro̩ orílẹ̀-èdè yii.
Agbẹnusọ PDP, Ini Ememobong, sọ pé yíyan àwọn olóṣèlú tí orúkọ wọn ko dara lati lo̩ soju orileede yii ku die̩ kaa to.
Ó diidi darúkọ alákóso INEC te̩le̩ ri, Mahmud Yakubu, o ni ibo to se akoso re̩ ni ko̩nu-n-ko̩nu ninu, iru e̩ni be̩e̩ ko ye̩ ki o lo̩ doju ti wa ni oke okun.
Ní ti agbẹnusọ ADC, Bolaji Abdullahi, pè àkójọ náà ní “ọmọ juu iṣẹ́ fún àwọn t’ó wà ní ẹgbẹ́,” pé kò ní ètò gidi fún orílẹ̀-èdè.
Agbẹnusọ NNPP, Ladipo Johnson naa be̩nu ate̩ lu oruko̩ tún sọ pé kíkó Yakubu sínú àkójọ jẹ́ ohun tí kò bójú mu.
Awo̩n oruko̩ ti Aare̩ fi rans̩e̩ ni –
Ogbonnaya Kalu (Abia), Omokri (Delta), Mahmud Yakubu, Erelu Adebayo, Ifeanyi Ugwuanyi (Enugu), Okezie Ikpeazu (Abia), Nyesom Wike.
Awo̩n miiran tun ni – Tasiu Maigari, Yakubu Gambo, Nora Daduut (Plateau), Otunba Femi Pedro, Femi Fani-Kayode, Florence Ajimobi, Lola Akande, Grace Bent, Senator Jimoh Ibrahim (Ondo), Paul Adikwu (Benue).
Awo̩n to ku ni – Enebechi Okwuchukwu (Abia), Yakubu Danladi (Taraba), Miamuna Besto (Adamawa), Musa Abubakar (Kebbi), Syndoph Endoni (Bayelsa), Chima David (Ebonyi), Mopelola Adeola-Ibrahim (Ogun), Abimbola Reuben (Ondo), Yvonne Odumah (Edo), Hamza Salau (Niger), Ambassador Shehu Barde (Katsina), Ambassador Ahmed Monguno (Borno), Ambassador Muhammad Dahiru (Kaduna), Ambassador Olatunji Gambari (Kwara), àti Ambassador Wahab Akande (Osun).

Tinubu ní láti bojú àwo̩n báńdíìtì jé̩ kíákíá – Primate Ayo̩dele

Tinubu ní láti bojú àwo̩n báńdíìtì jé̩ kíákíá – Primate Ayo̩dele

Yínká Àlàbí

Primate Elijah Ayodele, olórí Ilé Ìjọsìn INRI, sọ fún Ààrẹ Bola Tinubu pé àwọn marún-ún tó lágbára ló wà lẹ́yìn ìṣèlè̩ buruku asekupani tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà. Ó ní bí a kò bá yọ wọ́n kúrò ní ọ̀nà, orílẹ̀-èdè ko ni bo̩ ninu ife̩mi sofo naa.
Ó kéde pé ìjọba gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ gan-an láti parí àìlera ààbò, torí àwọn tó ń dá a rú kò tíì dawọ dúró. Ó tún kilọ pé kí ìjọba má ṣe lo̩wo̩ ninu idunadura pe̩lu awo̩n e̩da buruku yii.
Ayodele ní kí Tinubu pè Sheikh Ahmad Gumi àti àwọn míì tí wọ́n ń n duna dura lati daa duro. Ó sọ pé bí ìjọba bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, ìpaniláyà á máa pọ̀ sí i, ó sì lè yí padà sí ohun tí a fi ń ṣe owo.
O tun fi kun un pe ti a ki ba so̩ra, isuna dura ti di okoowo agbaye fun awo̩n ajinugbe naa.
Bí Tinubu kò bá ṣiṣẹ́ takuntakun, ìpaniláyà lè dojú kọ ìjọba rẹ̀, kì í ṣe talákà nìkan, àwọn ọlọ́rọ̀ náà á pàdánù nǹkan gidi.

Àwọn jàǹdùkú gún Ọlọ́pàá kan pa l’Ondo

Àwọn jàǹdùkú gún Ọlọ́pàá kan pa l’Ondo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ di bóò lọ, kò yàgò fún mi ní agbègbè Arakale n’ilu Akure ni olù ìlú ìpínlẹ̀ Ondo, lásìkò tí èdèàìyédé wáyé láàrin àwọn ọlọ́kọ̀ èrò tó ń ta tíkẹ̀tì àti Ọlọ́pàá kan tó n se isẹ́ ní àyíká agbègbè náà.

Lásìkó àbẹ̀wò sí àgbegbè náà, àwọn ósojúùmikòró tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ sàlàyé pé ikọ̀ Ọlọ́pàá ọ̀hún n ṣe isẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lágbègbè náà lásìkò tí oní márúwá kan wa ọkọ̀ rẹ̀ lọ́nà tí kò bófin mu.

Wọn salaye pé, ni kete ti Ọlọpaa naa ri iṣẹlẹ yii, o gbiyanju lati sọ fun oni maruwa naa lati wa ọkọ rẹ si ẹba ọna ti ko ni ṣe idiwọ.

Sugbọn lasiko naa ni awọn oṣiṣẹ to n ja tikẹti naa de pẹlu ero pe se ni Ọlọpaa naa fẹ gba owo ẹyin, eyi lo fa ija, ti awọn to n ja tikẹti naa si gun Ọlọpaa yii, pẹlu ọ̀bẹ.

Osojumikoro miran ti ọrọ rẹ yatọ sọ pé, ṣe ni Ọlọpaa naa fẹ́ gba owo lọwọ oni maruwa náà, idi niyi ti awọn to n ja tikẹti fi da si ọrọ naa ko to di wahala eyi to gbẹmi ikọ Ọlọpaa naa.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo DSP Ayanlade Olushola sọ di mimọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọru ọsẹ yi.

Ayanlade sọ pe ede-ai-yede lo waye laarin awọn janduku kan ati Ọlọpaa to wa loju isẹ ti awọn janduku naa si gun Ọlọpaa naa.

O salaye pe kete ti Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo gbọ ọrọ naa o pasẹ fun awọn ikọ Ọlọpaa to n risi iṣẹlẹ pajawiri lati lọ si oriko naa. Kete ti wọn de oriko naa wọn fi panpe ọba mu awọn afunrasi meji ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Awọn mejeeji yi ni Shina Jacob ẹni ọdun marundinlọgbọn àti Felix Olalekan ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Ayanlade salaye pe loju kan naa ni wọn gbiyanju lati doola ẹmi Ọlọpaa ti wọn gun lọbẹ naa, sugbọn ẹpa o boro mọ, Ikọ Ọlọpaa naa ku lasiko to n gba iwosan.

Alukoro naa sọ siwaju si pe lẹyin iṣẹlẹ yi ni wọn lọ kakiri agbegbe Arakale ati awọn oriko miran ti awọn janduku pọ si lati ri daju pe, wọn fọ Ipinlẹ Ondo mọ pátápátá.

O salaye pe ko si ikọ ileeṣẹ Ọlọpaa to lẹtọ labẹ ofin lati tẹ ẹtọ awọn ara ilu mọlẹ, bẹẹni wọn ko ni foju ire wo ẹnikẹni to ba sakọlu si awọn ikọ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo.

Ayanlade sọ siwaju pe awọn afunrasi mejeeji yoo foju ba Ileẹjọ laipẹ fun idajọ to tọ lori iṣẹlẹ naa.

Níṣe ló dàbí kí n la gbohùngbohùn mọ́ Obasanjo lórí … – Fayose

Níṣe ló dàbí kí n la gbohùngbohùn mọ́ Obasanjo lórí … – Fayose

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ bí ẹni pé ohun tí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo sọ níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose kò ì tíì tán nínú rẹ̀.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Fayose ṣe tún sọ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe láìpẹ́ yìí pé níṣe ló dàbí kí òun gba gbohùngbohùn lọ́wọ́ Obasanjo níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun, kí òun sì là á mọ́ Obasanjo lórí bó ṣe ń sọ̀rọ̀ náà.

Fayose ní òun ti gbìyànjú láti parí aáwọ̀ pẹ̀lú Obasanjo ṣáájú ọjọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí karùndínláàádọ́rin tí òun ṣe náà.

Ó ní òun lo èèyàn kan gẹ́gẹ́ bí alárinnà láàárín àwọn méjéèjì ṣáájú ayẹyẹ náà.
“Gbogbo àwọn ìfaǹfà tí a bá ti ní sẹ́yìn, kí a fi sẹ́yìn. Tí mo bá ṣẹ̀ ẹ́ tàbí tí o bá ṣẹ̀ mí, ẹ jẹ́ ka fi sẹ́yìn,” Fayose sọ.

Ó ṣàlàyé pé òun kò pe Obasanjo síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun láti fi tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí òun kò ṣẹ Obasanjo.

Ó fi kun pé Obasanjo ló ṣẹ òun nítorí òun ló yọ òun nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà àti pé tí ẹnikẹ́ni yóò bá tọrọ àforíjì, Obasanjo ló yẹ kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ òun.

Fayose ní Obasanjo gba òun ní àlejò dáadáa nígbà tí òun ṣe àbẹ̀wò sí ilé rẹ̀, tó sì ṣèlérí pé òun máa wá síbi ayẹyẹ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ayẹyẹ míì ní orílẹ̀ èdè Rwanda.
Ó fi kun pé òun ṣe ètò owó $20,000 fún ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà láti wá síbi ayẹyẹ náà.

“Báwo ni èèyàn ṣe máa gba owó ẹni tí yóò sì tún máa wá sọ ìṣokúsọ nípa ẹni náà?” Fayose bèèrè
Ó tẹ̀síwájú pé ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Obasanjo sọ pé òun ni òun fẹ́ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn níbi ayẹyẹ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbákejì ààrẹ ni àwọn ti ṣètò tẹ́lẹ̀ láti parí ayẹyẹ ọ̀hún.

Ó júwe àwọn ọ̀rọ̀ tí Obasanjo sọ níbi ayẹyẹ náà bíi pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìkọlù sí òun ni.

“Báwo ni èèyàn ṣe máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹni tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún márùndínláàádọ́rin?

“Inú bí mi gan ní àsìkò yẹn, ó dàbí ẹni pé kí n gba gbohùngbohùn lọ́wọ́ rẹ̀, kí n là á mọ lórí ṣùgbọ́n mo gbà á mọ́ra nítorí igbákejì ààrẹ wà lórí ìjókòó.”

Fayose fi kun pé òun fẹ́ kí ìbáṣepọ̀ tòótọ́ wáyé láàárín òun àti Obasanjo ṣùgbọ́n ìwà Obasanjo túmọ̀ sí pé kò fẹ́ kí àlááfíà wáyé.

“Tí mo bá mọ̀ pé bí ó ṣe máa parí nìyẹn, kí ni mo nílò Obasanjo fún? Ṣé mo fẹ́ gbégbá ìbò ni?”

Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fòǹtẹ̀ lu Ìyànsípò Alága, ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun Àjọ OYSIEC

‎Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fòǹtẹ̀ lu Ìyànsípò Alága, ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun Àjọ OYSIEC

Fẹ́mi Akínṣọlá

‎Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti fìdí ìyànsípò Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Alága tuntun fún Àjọ elétò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC)

‎Bákan náà ni ilé aṣòfin ọ̀hún fìdí ìyànsípò Olóyè Kúnmi Agboọlá, Ọ̀gbẹ́ni Ọláńrewájú Adéòtí Emmanuel, Ọ̀gbẹ́ni Sunday Olúgbémiga Fálànà, Ọnarébù Rẹ̀mí Ayọ̀adé, Ọ̀gbẹ́ni Ọlátúndé Akíntúndé Theophilus, Arábìnrin Adébáyọ̀ Maryam Adépéjú àti Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé George Ìgè gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ìgbìmọ̀ Àjọ OYSIEC.

‎Nínú ìjókòó ilé tí Adarí ilé, Ọnarébù Adébọ̀ Ògúndoyin tukọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ni wọ́n ti fìdí ìyànsípò náà múlẹ̀.

‎Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn tí ilé tẹ́wọ́ gba àbọ̀ àti àbá ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó ilé aṣòfin tó ń mójútó àwọn ojúṣe pàtàkì, lórí àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún àwọn onítọ̀hún tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fi orúkọ wọn ránhúnṣẹ́.

‎Nígbà tí ó ń ka àbọ̀ ọ̀hún, Alága ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó náà, tó tún jẹ́ igbákejì adarí ilé aṣọ̀fin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọnarébù Abíọ́dún Fádèyí, jẹ́ kó di mímọ̀ pé Alága àti àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ OYSIEC, fi ìdáhùn tó yẹ, tó sì tẹ́ àwọn lọ́rùn, sí gbogbo ìbéèrè tí àwọn tàkòtò sí wọn àti wípé wọ́n fi hàn pé àwọn yẹ fún ipò ọ̀hún.

‎Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, kété lẹ́yìn ìfìdìmúlẹ̀ ìyànsípò rẹ̀, Alága tuntun Àjọ OYSIEC, Ọ̀mọ̀wé Babátúndé Afeez Adéníyì, sọ pé lọ́gba tí wọ́n bá ṣe ìbúra fún àwọn, ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ìríjú tí ìlú fẹ́ fi rán àwọn.

‎Ní ìtẹ̀sìwájú ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wé Babátúndé, ó ṣèlérí pé nígbà tí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ yóò bá fi wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àmójútó òun, àwọn yóò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ òfin ìdìbò.

‎Alága Àjọ OYSIEC, tún fi àkókò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ Gómìnà Ṣèyí Mákindé, fún bó ṣe fi ọkàn tán òun fún ipò ọ̀hún, pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ pé òun kò ní já Gómìnà àti àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kulẹ̀.

Ìkéde pàjáwìrì lẹ́kà ààbò tí Tinubu ṣe àti bó ṣe kàn aráàlù

Ìkéde pàjáwìrì lẹ́kà ààbò tí Tinubu ṣe àti bó ṣe kàn aráàlù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àná Ọjọ́rú ni Ààrẹ Bola Tinubu kéde òfin pàjáwìrí ní ẹ̀ka ètò àbò Nàìjíríà, paàpàá láwọn ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti di gbọnmọgbọnmọ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

Aarẹ tun paṣẹ ki wọn gba nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan siṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ologun lati le koju eto abo to mẹhe.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ gba oṣiṣẹ bii ẹgbẹrun lọna aadọta lati kun awọn ọlọpaa 370,000 to wa nilẹ lọwọ.

Onimọ nipa eto aabo naa, Akin Adeyi wa salaye koko ohun to maa sẹlẹ lasiko yii ti ijọba apapọ kede igbesẹ pajawiri lẹka eso aabo.

O ni ijọba ni ojuṣe lati ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fun araalu ki araalu naa si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.

Awọn koko to mẹnuba pe yoo sẹlẹ ree:

Naijiria yoo gbe gbogbo ofin to rọ mọ eto abo ti ṣẹgbẹ kan, ki awọn agbofinro le ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ lai si idiwọ kankan fun wọn.
Ofin pajawiri ni wọn yoo maa lo lakoko yii lawọn agbegbe ti ọrọ kan.
Awọn agbofinro le gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ lai kọkọ duro de aṣẹ lakoko naa. Boya tẹlẹtẹlẹ, o yẹ ka duro de aṣẹ kan lati ibi kan ki a to le gbe igbese lati pinwọ iwa ibi kan, ko ni si bẹẹ mọ,
Ẹni to ba wa lagbegbe kan lasiko iṣẹlẹ ibi ba n waye le gbe igbesẹ lati yanju ọrọ naa lai kii ṣe pe o kọkọ beere lọwọ ẹnikẹni, ti ẹnikẹni ko si ni beere lọwọ rẹ pe ‘kilode ti o fi ṣe bẹẹ.’ Kii ṣe pe ki ọgagun kan ṣẹṣẹ maa duro de aṣẹ lati oke… tabi ko maa sọ pe wọn ti ni ki a ma yinbọn si wọn mọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn irin gberegbere kan ko ni si mọ.
Ko ni nilo ki wọn ṣẹṣẹ kede konileogbe mọ, agbofinro kan le da eeyan duro ko si sọ pe ‘oya, maa lọ inu ile rẹ’ lai ṣe pe niṣe lo tẹ ẹtọ araalu naa mọlẹ lati rin lasiko to ba wu u.”
Ikede Aarẹ naa ti gbe ẹtọ araalu nipa ọrọ abo si ẹgbẹ kan ati pe gbogbo ẹka ileeṣẹ agbofinro ni Naijiria lo le ṣiṣẹ ara wọn lai si idiwọ kankan.
Ọlọpaa le ṣiṣẹ ṣọja, ti ṣọja yoo le ṣiṣẹ ọlọpaa; bẹẹ ni DSS le ṣiṣẹ NSCDC, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ Aarẹ lati gba nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan si ileeṣẹ ọlọpaa, Adeyi ni imọ ẹrọ ni a nilo, kii afikun ọlọpaa.

O ni “Ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu didaabo bo araalu bi ko ṣe ọrọ oṣelu pe ‘ti a ba fun awọn ọmọ wọn nisẹ diẹ boya wọn maa tun dakẹ.’

“Ọrọ ọlọpaa ati eto abo laye ode oni kii ṣe nipa ki ọlọpaa pọ lapọju, bikoṣe nipa lilo imọ ẹrọ.

“Asiko ti awọn orilẹede ti wọn mọ nnkan ti wọn n ṣe n sọ pe kii ṣe nipa ọpọ ero nileeṣẹ eto abo lawa ṣẹṣẹ n sọ pe a gbọdọ gba ọpọ ero siṣẹ ọlọpaa.

“Eeyan meji pere ninu yara kan le ṣe iṣẹ ẹgbẹgbẹrun eeyan pẹlu ẹrọ ‘drone’ to n fo loju ofurufu.”

O ni kii ṣe nipa gbigba ọpọ ero siṣẹ ọlọpaa ni eto abo yoo fi dara amọ nipa lilo imọ ẹrọ igbalode fun eto abo.
Onimọ eto abo naa sọ pe araalu gbọdọ maa sin ijọba atawọn agbofinro ni gbẹrẹ ipakọ paapaa lasiko ti ọdun n sunmọle yii.

Adeyi ni wọn gbọdọ maa bun ọlọpaa gbọ ni gbogbo igba ti wọn ba kofiri nnkan tabi eeyan ti ko yẹ layika wọn.

Lẹyin naa lo mẹnuba ọrọ awọn ọlọkada to n lo iboju lasiko yii.

O ni ko tọ fun ọlọkada lati maa lo iboju lati ṣiṣẹ nitori iru wọn le gbe eeyan lọ ti ẹnikẹni ko si ni mọ irufẹ ẹni to wa labẹ iboju ọhun.

O pari ọrọ rẹ pe oju ni alakan fi n ṣọri pe gbogbo araalu gbọdọ maa funra ki wọn si ṣọra fun ibi ti ọpọ ero ba pọju si lasiko pọpọṣinṣin ọdun nitori asiko yii gan ni awọn kọlọrọsi ẹda maa n ṣọṣẹ.

Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà – Àwọn aṣòfin kan yarí

Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà – Àwọn aṣòfin kan yarí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aṣòfin kan nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ìjọba Tinubu lórí ìlànà tó ń gbà kojú ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Àwọn aṣòfin náà, láti ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà tó wà ní Nàìjíríà, kọminú lórí ìpèníjà ààbò ṣe ń fi ojoojúmọ́ peléke síi àti bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń wà nínú inú fu àyà fu lójoojúmọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́rú ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìlànà tí ààrẹ ń gbà kojú ìṣòro ààbò, tí wọ́n sì ní ààrẹ kò ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe yẹ.

Ṣáájú níbi ìjòkó ilé tó wá lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, àwọn aṣòfin fi ẹdùn ọkàn wọn hàn lórí ìpèníjà ààbò Nàìjíríà, tí wọ́n sì rọ ìjọba àpapọ̀ láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìpèníjà yìí.

Àwọn aṣòfin tí wọ́n kó ara wọn jọ náà bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba ṣe ń bá àwọn agbébọn jíròrò lórí ìkọlù tí wọ́n ṣe sáwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Lára àwọn aṣòfin náà ni Muhammed Soba láti ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá, Zakari Mohammed láti ààrin gbùngbùn àríwá, Olasupo Abiodun láti gúúsù ìwọ̀ oòrùn, Sadiq Ibrahim láti ìlà òòrùn àríwá, Uko Nkole láti ìlà oòrùn gúúsù, àti Bassey Ewa láti ààrin gbùngbùn gúúsù.

Wọ́n wòye pé ṣíṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sáwọn èèyàn Nàìjíríà nítorí wọ́n ń bá àwọn ọ̀daràn jíròrò dípò kí wọ́n fi òfin gbé wọn.

Wọ́n ní kìí ṣe irú àsìkò yìí táwọn èèyàn Nàìjíríà ń sunkún lórí pípè fún ààbò tó péye ló yẹ kí ìjọba máa bá àwọn tó jí àwọn ọmọdé gbé, tí wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn obìnrin láì bìkítà, tí wọ́n sì ń da ọ̀pọ̀ ìlú láàmú ló yẹ kí ìjọba máa bá jíròrò.
Nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé ní Kano, Kwara, Kebbi, Niger àtàwọn ìpínlẹ̀ míì, àwọn aṣòfin náà níṣe ni ìjọba dákẹ́, tí wọ́n sì ń gba ọ̀nà ẹ̀yìn láti máa bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìpàdé.

“Kò sí orílẹ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ tó máa ma bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìdúnàádúrà. Kò sí ibití bíbá àwọn agbébọn jíròrò ti so èso rere káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn.

“Ní Colombia, ìjíròrò tí ìjọba bá àwọn ikọ̀ Revolutionary Armed Forces mú àlékún bá ìjínigbé láti fi máa bèèrè owó, tó sì tún rọgun sápá àwọn ikọ̀ náà.

“Ní Afghanistan, ààyè tí wọ́n fi gba àwọn Taliban tó fi mọ́ pípàrọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló fi ààyè gba àwọn ẹgbẹ́ láti gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn aṣòfin náà ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti yàgò fún bíba àwọn agbéṣùmọ̀mí jíròrò àti pé ìgbésẹ̀ náà yóò túnbọ̀ máa pọnkún ìwà ipá tó ń wáyé.

Wọ́n ní ìjọba ń sọ pé àwọn kò kajú òṣùwọ̀n, tí wọ́n sì ń pè fún àlékún ìjínigbé àtàwọ n ìwà ọ̀daràn míì, tí kò sì ní jẹ́ káwọn aráàlú ní ìgboyà nínú wọn mọ́.

Àwọn aṣòfin náà tẹmpẹlẹmọ pé iṣẹ́ àkọ́kọ́ ìjọba ni láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.

Wọ́n ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò orílẹ̀ èdè tí àwọn ọ̀daràn yóò máa bẹ̀rù àwọn aláṣẹ, kìí ṣe èyí tí àwọn aláṣẹ yóò ti máa bẹ̀rù ọ̀daràn.

Àwo̩n fijilanté Kogi gbéna wojú àwo̩n jàǹdùkú agbébo̩nrìn, eniyan meji jé̩ ìpè O̩lo̩run

Àwo̩n fijilanté Kogi gbéna wojú àwo̩n jàǹdùkú agbébo̩nrìn, eniyan meji jé̩ ìpè O̩lo̩run

Yínká Àlàbí

Ilé-ẹ̀kọ́ girama Kiri ní ìpínlẹ̀ Kogi ní awo̩n janduku agbebo̩n tun ko̩lu ni idaji o̩jo̩ We̩side.
Àwọn fijilante sare kó ara wọn jọ láti koju àwọn e̩ni ibi náà. Wo̩n si gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wo̩n ji ko lo̩wo̩ wo̩n.
Nibi ija naa, ọ̀kan nínú àwọn fijilante kú nígbà tí wọ́n ń dáàbò bo agbègbè, bẹ́ẹ̀ ni ará ìlú kan náà kú so̩wo̩ asita ibo̩n.
Alága ijo̩ba ibile̩ Kabba/Bunu, Zaccheus Dare Micheal, ninu alaye tire̩, o ni awo̩n fijilante ko je̩ ki awo̩n janduku naa raaye wo̩ ile e̩ko̩ naa. O ni, wo̩n gbeja pade wo̩n ni eyi ti ko je̩ ki wo̩n ri is̩e̩ ibi kankan se.
Ju gbogbo re̩ lo̩, Omofa John naa salaye pe eniyan meji ba ise̩le̩ naa lo̩.
Wọ́n kéde pé kí àwọn ará ìlú má ṣe tan ìròyìn tí a kò fidi re̩ múlẹ̀ káàkiri, tí ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò fojú winà òfin.
Àwọn agbofinro àti fijilante sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kaakiri awo̩n inu igbo to yi ilu naa kiri lati le fi awo̩n ara ilu lo̩kan bale̩.
Àwọn alákóso ní iṣẹ́ ààbò tún ń lọ lọwọ́ kí àlàáfíà pípé lè padà sí agbègbè náà.

Ilées̩é̩ o̩ló̩pàá gbé̩sè̩ lé o̩dún Egúngún ní ìpinlè̩ Èkó

Ilées̩é̩ o̩ló̩pàá gbé̩sè̩ lé o̩dún Egúngún ní ìpinlè̩ Èkó

Yínká Àlàbí

Ọ́fíìsì ọlọ́pàá ti ipinle̩ Èkó ti paṣẹ kí wọ́n dá àjọyọ̀ Egúngún tó yẹ kó waye ní Oregun dúró nítorì ààbò.
SP Abimbola Adebisi, salaye pe iwe ti wo̩n pin nipa o̩dun Egungun naa ko le sise̩ nitori asijo ti a wa yii. Eto aabo ni ako̩ko̩ ninu gbogbo ohun ti a ba n s̩e.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ìkìlọ̀ tí wọ́n tan ka lórí Oregun ní ọjọ́ ke̩tadinlo̩gbo̩n àti ikejidinlo̩gbo̩n, Oṣù Kọkànlá o̩dun yii ko ni le waye. Ago̩ o̩lo̩paa ni ko si nnkan meji bi ko se nitori aabo ilu ni asiko o̩dun keresi to n kannile̩kun yii.
Ó tún rántí pé a rí ìṣẹ̀lẹ̀ tó jọra ní Mafoluku, Oshodi, níbi tí wọ́n ti mú arufin mejìlá nitori eto aabo.
Kómísánà ọlọ́pàá, Olohundare Jimoh, ti paṣẹ pé kí wọ́n dá ajọdún náà dúró lẹsẹkẹsẹ, nítorí pé ààbò àti ìbámu kò sì ní ṣeé dájú mọ́. Ó kilọ̀ pé ẹni tí to na keti ikun si as̩e̩ ijo̩ba yoo foju wina ofin.
Adebisi sì gba àwọn ará níyànjú kí wọ́n tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ wọn ní àlàáfíà, tí wọ́n ba si ei awo̩n alagidi ti ko fe̩ tele ofin ki wo̩n pe awo̩n no̩mba pajawiri wọ̀nyí – 08063299264, 09053872208, 07061019374, 08065154338.