Ariwo Asiwaju náà tún ni ni’ ilè̩ Hausa
Yínká Àlábí
Ò̩rò̩ púpò̩, iró̩ ló ń mú wá. Òhun tún ree…
Ariwo Asiwaju náà tún ni ni’ ilè̩ Hausa
Yínká Àlábí
Ò̩rò̩ púpò̩, iró̩ ló ń mú wá. Òhun tún ree…
Sikiru Ayinde Barister polongo ìbò fún Tinubu kó tó lo̩
Yínká Àlábí
Ò̩rò̩ púpò̩, iró̩ ló ń mú wá. Òhun ree…
Onírèsé ni Sheikh Abdulganiyy Aboto
Yínká Àlàbí
Yorùbá bo̩,wo̩n ni ‘tí onírèsé bá kò̩ tó ní òun kò fíngbá mó̩, èyí tó ti fín sílè̩ kò lè parun’.
Be̩e̩ ge̩ge̩ ni o̩ro̩ agba Aafaa O̩lo̩run to pada s’o̩do̩ Allah.
Díè̩ lára àwo̩n wáàsí bàbá náà rèé –
*Sheikh Abdulganiyy Nurayn Aboto, a longlist of his lectures*:
2. Ojo Al-qiyaamah – https://youtu.be/f1pgJRN6DsI
3. Ijiya Inu Saare – https://youtu.be/yyWJz-qWHGs
4. Kilo kan leyin Iku? – https://youtu.be/ZCWtYWgOnbk
5. Ta lo so pe Anobi Issa O ni pada wa? – https://youtu.be/llJefS3S9IA
6. Adabiyyah – https://youtu.be/FKBKRx3K2Hg
7. Igbeyin Aye – https://youtu.be/DceOcH858Zg
8. Ofin Olohun Meta – https://youtu.be/ya8accWu4Q4
9. Aye lu Jara – https://youtu.be/SwNmX8S40T0
10. Isra Wa Miraj – https://youtu.be/JPTbHRPeCjM
11. Hajj – https://youtu.be/ZndzdM4U23w
12. Musulumi Mejo Ti ko ni wo Alujannah – https://youtu.be/VexP11ofVHg
13. Qualities of a Good Leader – https://youtu.be/yXE-ZhJbVZM
14. Gbigba fun Olohun – https://youtu.be/fEam3Ftr96A
15. Ta ni Esu – https://youtu.be/jfTHSWro7fE
16. Isubu Eda – https://youtu.be/TuyGw0Y8aPk
17. Idaro Iku – https://youtu.be/J4ogR7mrv3g
18. Osunwon – https://youtu.be/WpPd6uiQ5Ts
19. Isokan – https://youtu.be/NuguKLbkXQM
20. Ojuse Obi – https://youtu.be/N50Yh2yCODo
21. Ofin Olohun Nipa Ebo Sise – https://youtu.be/gLcScnAOvFo
22. Ta ni Mumini – https://youtu.be/KVdmK8SYebA
23. Apere Obinrin rere – https://youtu.be/18659VljDf4
24. Boko-Haram – https://youtu.be/hIK6FFV1WUs
25. Ta ni Omo Olohun – https://youtu.be/oDXpj98GVuw
26. Ramadan Tafseer – https://youtu.be/mpALaJdI-iA
27. Ogun pinpin – https://youtu.be/_d-RY7vs5ps
28. Ojo Iwaju Odo – https://youtu.be/F-yJctkcXiQ
29. Polygamy in Islam – https://youtu.be/q0Gq-50RwJc
30. Omo Tito – https://youtu.be/nxEVwF2yRHU
“Egbinrin ote, bi a ti n pakan ni okan n ru ni oro orileede yii”. A ko tii bo lowo eto aabo to mehe kaakiri orileede ati owon ounje ni orisiirisii ti owon gogo epo petiro tun ti gba ilu kan. Bi ere, bi awada ni o se koko bere ni agbegbe Ariwa ki o to wa di pe o kari aye. Awon alase kan n fowo soya pe owon gogo naa ko le lo wakati merinlelogun tii se ojo kan.
Bayii, ni ipinle Eko ati agbegbe re naa ti n foju wina oda epo. Igbagbo awon ara ilu ni pe epo yii wa sugbon, awon aje-nidii-madaru ni won n wowọ mọ epo naa. Won ni ọpọ won lo ni epo sugbon ti won kan fe maa ni ara ilu lara.
Awon kan tilẹ ti n taa ni igba naira(N200), ọgọsan-an(N180), igba din mẹwaa naira(N190) ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọpọ won ni won ko yi mita won pada kuro ni aadosan-an naira(N170) sugbon won n fi kakuletọ si iye epo ti ẹ ba ra. Won si n je ki o ye onibara pe iye bayii ni epo ti awon, ni eyi to tumọ si pe iwọfun ni.
Ọwọn gogo ti won ni ko ni ju ọjọ kan lo ti wọ ojo kẹta lonii Ọjọ’ru, ojo kẹrindinlọgbọn osu kẹwaa ọdun okoolelẹgbaale-meji(26/10/2022). Alaga ẹgbẹ epo petiro ti aladaani ni agbegbe Gusu IPMAN (Independent Petroleum Marketers Assosiation of Naigeria), Ogbeni Dele Tajudeen ni epo tile ti won wa lati Apapa ti awon ti n gbee, awon oga kan ni ẹkun omi n se akoba fun awon oko lati gbe epo, awon kan ni ijoba apapo ko tile lepo bayii, won ni awon aladaani to ni epo lo n se eyi to wu won, awon kan ni gbese ti ijoba apapo je naa n se awon akoba kan.
Bayii, a ko mo eyi ti a fe di mu ninu gbogbo awijare awon alase epo petiro naa. Ju gbogbo re lo , Epo ti won kaakiri orileede yi.
Oludije du ipo Aare labe Asia egbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo n salaye foniroyin leyin ipade to se pelu awon ajo CAN (Christian Association of Nigeria) ati awon ijo MusulumiTijaniyya ni ilu Kano.
Ijo Redeem to wa lara awon ipago to tobi to si lero ju ni orileede yii ni Baba Enoch Adeboye n dari. Tinubu ni oro naa jade lenu baba naa ni igba ti Oluremi Tinubu to je aya oun n gba oye Pasito.
Tinubu n fi eleyii salaye fun araye pe asepo to dan moran wa laarin oun ati awon elesin kirisiteeni lorileede yii. O ni ki awon ti o mo oun maa salaye faraye pe oun o ki n se elesinmesin tabi eleyameya.
Agbara ojo to ba awon ipinle kan finra ni orileede yii ti doju so Otuoke tii se ilu Aare ana Omowe Goodluck Jonathan ni ipinle Bayelsa.
Gege bi akoroyin NAN se salaye nipa abewo re si Fasiti ijoba apapo to wan i ilu naa, o ni aseju woo se ti omi se si ile-iwe naa nitori pe ko tile see wo rara. O ni bi awon eniyan se n lo oko oju om I wo ile won naa ni awon ni lati wo oko oju omi de itosi ile-iwe naa.
Akoroyin NAN ran wa leti pe omi sose ni ipinle naa ni odun 2012 amo ti odun yii po ju. Lara awon ara ilu to salaye oun toju n ri ni Ogbeni Azibalau Oru ti o n rawo ebe si ijoba apapo lati siju aanu wo awon ni ijoba ibile Ogbia ti Otuoke wa. Oru ni opolopo dukia awon lo ti baje sinu omi naa. O tun ni eyi to buru ju nibe ni awon eran omi bii ejo ati awon eran omi buruku miiran lo ti gba inu omi yii kan.
Elomiran to tun ba akoroyin NAN soro ni Emmanuel Peter, eni yii ni yato sip e oko oju omit i awon n lo wole, o n I awon ole ko tun je ki awon gbadun, o wa rawo ebe si ijoba ipinle naa lati ma se je ki iya meji je awon gbe.
Elomiran tun ni Godknows Frank ti o je olori awon odo agbegbe naa, o ni lati igba ti ajalu omi yii ti bere ni awon ko ti ri oluranlowo Kankan siju aanu wo awon. O ni eni ti eniyan bar i lasiko isoro ni enikeji eniyan, o ni asiko niyi ti o ye ki gbogbo awon oludije du ipo kan siju aanu wo awon, ki ipolongo ibo won ma kan lo je ileri asan nitori pe ounje ti eniyan ba je ni igba tie bi n paa ni oba ounje.
Ogagun Waidi Shaibu lo n salaye foniroyin lanaa ojo Jimo nipa akitiyan won lati je ki alaafia joba lorileede yii. Ogagun ti Commading 7 Division ati Sector 1 Joint Task Force, North East Operation HADIN KAI ni leyin idojuko ti awon se pelu awon Boko Haram ni awon ti yọ awon akẹkọọbin Chibok meji, ekinni ni Rejoice Sanki omo odun merinlelogun(24) pelu omo meji nigba ti ekeji n jẹ Yagana Poly ti oun naa je omo odun merinlelogun pelu omo merin.
Ogagun yii ni ninu igbiyanju awon naa ni awon ti doola awon mokandinlogunrun-un(99) miiran, ti metadinlaadota (47) ninu won je obinrin ti awon to ku si je okunrin.
Ogagun Waidi ni igbiyanju awon yii waye laarin ojo kokandinlogbon(29) osu kesan-an si ojo keji osu kewaa odun yii.
Ojise Olorun Johnson Suleiman ti awon onise ibi kọ lu ni ana ọjọ Ẹti, ojo kokanlelogun, osu kewaa odun yii lo n forere pe, lati odun 2017 ni awon eniyan bururku yii ti n lepa ẹmi oun.
Apostle ni o yẹ ki oun darukọ awon onisẹ ibi naa, amọ o ku die nitori pe oun mọ daju pe won maa ko jalẹ peawon ko lepa emi ẹni Kankan. O ni isele ojo Jimo naa buru pupo nitori awon emi ti won ko le da ni won se lofo. Eniyan meje tan lo ba isele naa lo nigba ti won doju ibon kọ mọto oun ati awọn ti awon jọ n lọ.
Apostle jẹ ki o ye awon onise ibi naa pe “iku ati ọdọ Olorun nikan lo le mu oun lọ”. O ni oun si mo daju pe ẹlẹsẹ Kankan ko ni lo lai jiya. O ni gbogbo awon to n lepa emi oun ni asiri won maa tu faye laipe nitori pe oun ko mọ oun ti o n bi won ninu pelu ise Olorun ti oun gbe dani ti o si n te siwaju.
Apostle ni asiko oro ko tii to bayii nitori pe awon si n se idaro awon Olopaa merin pelu awon omo olomo meta to ba ajalu naa lo ni opopona Benin si Auchi.
Ọmọ Yahoo gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Ajo EFCC to n foju to awon onijibiti ni won ti ko awon omo Yahoo marun-un fun esun orisiirisii lo ile-ejo ni ilu Lafia to wa ni ipinle Nasarawa.
Awon omo Yahoo naa ni Francis Chukwuka Okwechime, Olaniyi Odunayo Precious, Israel Stephen Auta, Oluwabori Azeez Rafiu ati David Stephen. Okwechime dibon pe oun ni Joshep Michael to je Oga Soja ni orileede America. O se eyi lati lu enikan to n je Molly ni jibiti owo dola oodunrunlelaadota ($350). Nigba ti Olaniyi n lu jibiti tire lori ero ayelujara lati fi gba Ogbeni Samuel Mayona. Isreal naa n dibon pe oun ni Ivy Jordan omo orileede America lati maa fi lu jibiti orisiirisii lori ero ayelujara,Oluwabori n dibon pe oun ni John Albert ati Raymond Lee lati orileede Singapore fun jibiti ori ero ayelujara naa ni gbogbo re, Stephen ni tire ni oun ni Major_hack007 lati maa fi lu jibiti gbogbo eni to ba ko si lowo lori ero ayelujara.
Gbogbo won ni won gba pe awon jebi esun naa. Onidajo Afolabi ju Olaniyi ati Stephen si ewon odun meji tabi ki won san egberun lona aadojo si igba naira (#150,000 – #200,000). Isreal ati Oluwatobi gba ewon osu mefa tabi owo itanran egberun lona aadota naira (#50,000), Owo itanran ti Okwechime je egberun lona ogorun-un naira (#100,000).
Ile-ejo si je ki Olaniyi mo pe ko ni ri foonu Infinix Note 10 to fi n lu jibiti gba mo nitori pe ijoba apapo ti gbese lee.
Adájọ́ kọ̀ láti gbẹ̀bẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá lò
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Omo odun merindinlogun to n gbe ni Satellite Town ni ipinle Eko ni adajo Ejiro Kubeinje ti ni ki won da pada si Oregun nitori pe o fipa ja ibale omo odun mewaa kan. Oregun ni ibi ti won ti n se atunse fun awon omo ti ko ba tii to odun mejidinlogun sugbon ti won daran.
Ojo kejidinlogun osu kejo ni igbejo maa waye lori esun naa. Oga olopaa DSP Kehinde Ajayi ni isele buruku yii waye ni ojo kejilelogun, osu kefa ni ile-iwe Lead College to wa ni Satellite Town. DSP Ajayi ni arakunrin naa fipa ba omo naa lo ni eyi to ta ko iwe ofin ti abala iwa odaran to wa ni abala 137 ti odun 2015.
Awon eniyan ni boya ojo ori nikan lo le ko arakunrin naa yo nitori pe ti o ba je agbalagba lo da iru oran bee, ewon gbere ni . Idajo di inu osu kejo.

