Home Blog Page 13

Àwọn ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá tó lo, ó kéré tán àádọ́ta ọdún lórí ìtẹ́

Àwọn ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá tó lo, ó kéré tán àádọ́ta ọdún lórí ìtẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Tó! Tó! Tó! Ká bií ò sí o.Èdùwà nìkan ló lè bi ọba.
Adé orí la fi ń mọ ọba, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn lá fi ń mọ ìjòyè, àgbà ni tara la fi ń mọ àgbà. Yẹpẹrẹ kí eku aṣín ni àpèrè ọba papàá jùlọ nílẹ̀ yorùbá.

Ní ilẹ̀ Yorùbá, ipò pàtàkì ni àwọn ọba wà nítorí ọba ni olórí ìlú, aláṣẹ, apàṣẹ wà á.

Ọba ní olórí ìlú, ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé nílẹ̀ Yorùbá, tí kò sí ẹni tó lè yipadà tàbí yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò bí ó tilẹ jẹ pé ayípadà tí ń bá àṣà yìí látàrí ìsesí àwọn olóṣèlú onímọtaraẹni nìkan tí wọ́n fẹ dojú àṣà yorúbá bolẹ̀.
Ipò jẹ́ ipò tí kò lọ́jọ́, ẹni tó bá ti jẹ ọba máa ń jẹ ẹ́ di ọjọ́ ogbó títí tí ọlọ́jọ́ máa fi de.

Dídágbà di ọjọ́ ogbó jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń tọrọ lọ́wọ́ Elédùmarè tí èyí kò sì yọ àwọn ọba náà sílẹ̀.

Ọba Stephen Adegoke Egunjobi II – Alafo ti ìlú Afo

Alafo ti ìlú Afo, Ọba Stephen Adegoke Egunjobi Keji ni Ọba ilẹ̀ Yorùbá tó wà láàyè, tó sì ti pẹ́ lórí oyè jùlọ.

Ìwádìí tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Alafo ni Ọba tó wà láàyè tó pẹ̀ lórí oyè jùlọ ní Nàìjíríà báyìí.

Ní ọdún 1958, ṣaájú kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó gba òmìnira lọ́dún 1960 ni Ọba Egunjobi jẹ ọba ìlú Afo, ìjọba ìbílẹ̀ Ose ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Ọba Egunjobi II ti lo ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin lórí ipò àwọn baba rẹ̀ báyìí.

Oba James Adelusi Aladesuru II – Onigede ti Igede-Ekiti

Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, ọdún 1959 ni Oba James Adelusi Aladesuru II gorí àpèrè àwọn babańla rẹ̀ gẹ́gẹ́ Onigede ti Igede-Ekiti.

Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni Ọba Oba James Adelusi Aladesuru II wà nígbà tó gorí ìtẹ́ ọba.

Níbi ayẹyẹ àádọ́rùn-ún Ọba James Aladesuru II tó wáyé lọ́dún 2023 ni Ọba náà ti sọ pé ẹ̀mí gígùn jẹ́ ohun tó máa ń tọ ìran àwọn nítorí àwọn òbí òun náà gùn púpọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, bàbá Ọba Aladesuru II, tí òun náà jẹ Onigede ìlú Igede-Ekiti tó sì pẹ́ lórí àpèrè kó tó wàjà.

Ìlú Igede-Ekiti ni oríkò ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun/Ifelodun ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ọba Sikiru Adetona – Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu

Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Karùn-ún, ọdún 1934 ni wọ́n bí Ọba Sikiru Adetona, Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijebu ní Ijẹbu Ode, ìpínlẹ̀ Ogun sínú ìdílé oyè Anikinaiya.

Ọdún 1960 ni Ọba Adetona jẹ Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu, èyí tó túmọ̀ sí pé ó ti lo ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lórí ipò Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu.

Bàbá rẹ̀ náà ti fìgbà kan jẹ Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu láàárín ọdún 1895 sí ọdún 1906.

Ọba Adetọna wà lára àwọn ọba tí ẹ̀mí wọn gùn lórí àpèrè baba wọn.

Ọba Olofinlade Afunbiowo Ojijigogun Asodeboyede Adesida Kìíní ni Deji ti ìlú Akure, ìpínlẹ̀ Ondo láàárín ọdún 1897 sí ọdún 1957.

Ọgọ́ta ọdún ni Ọba náà lòláyé èyí tó mú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba Yorùbá tí ẹ̀mí wọn gùn púpọ̀ lórí ilẹ̀ baba wọn.

Àkọ́ọ́lẹ̀ ní ọdún 1860 ni wọ́n bí ọba náà sáyé àmọ́ àwọn ìròyìn kan sọ pé ó jú ọjọ́ orí tó ń lò náà lọ.

 

Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi III – Aláàfin ìlú Oyo

Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta, Aláàfin ìlú Oyo, ìpínlẹ̀ Oyo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá tó gbajúmọ̀ púpọ̀ nígbà ayé rẹ̀.

Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹwàá ọdún 1938 ni wọ́n bí Aláàfin Adeyemi tó sì jáde láyé lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin ọdún 2022.

Ìkú Bàbá Yèyé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń pè é gorí àpèrè àwọn baba rẹ̀ ní ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá ọdún 1970.

Ọdún méjìléláàdọ́ta ló lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Aláàfin. Òun ni aláàfin tó pẹ́ jùlọ lórí ipò náà.

Ọba Adesoji Aderemi – Ọọni ilé Ifẹ̀

Ọba Titus Martins Adesoji Tadeniawo Aderemi Atobatele Kìíní jẹ Ọọni Ilé Ifẹ̀, ìpínlẹ̀ Osun láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1980.

Àádọ́ta ọdún ni Ọọni yìí lò lórí ìtẹ́ àwọn bàbá rẹ̀.

Yàtọ̀ sí ipò ọba tí Ọọni Atobatele Kìíní yìí jẹ, ó tún ṣe gómìnà ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà láàárín ọdún 1960 sí 1962.

Ọba Atobatele tó jẹ Ọọni lẹ́yìn ìpapòdà ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ademiluyi Ajagun tó wà lórí ipò náà rèwàlẹ̀ àṣà.

Ọba Jimoh Oladunni Oyewunmi Ajagungbade III – Ogbomoso

Ọba Jimoh Oladunni Oyewunmi Ajagungbade Kẹta ni Ṣọun ìlú Ogbomoso, ìpínlẹ̀ Oyo láàárín ọdún 1973 sí ọdún 2021.

Ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni Ọba náà jáde láyé lẹ́yìn tó lo ọdún mẹ́jìdínláàdọ́ta lórí ipò.

Ọba Ajagungbade Kẹta jẹ ọmọọmọ Ṣọun tó tẹ ìlú Ogbomoso dó, ìyẹn Sọun Ogunlola.

Onírúurú ohun ìdàgbàsókè ló wọ ìlú Ogbomoso nígbà ayé rẹ̀.

Buhari wọ káà ilẹ̀ sùn, àwọn ológun àti èèkàn ìlú ṣe ẹyẹ̀ ìkẹyìn fún un

Buhari wọ káà ilẹ̀ sùn, àwọn ológun àti èèkàn ìlú ṣe ẹyẹ̀ ìkẹyìn fún un

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kò sì ,ẹ̀dáó má fikú yọ ẹ̀dá ẹgbẹ́ rẹ̀, gbogbo wa ni a jẹ gbèsè ikú,ìgbà àti àsìkò ló sàrà ọ̀tọ̀

Ìbànújẹ́ bá gbogbo ọmọ ìlú Daura ní ìpínlẹ̀ Katsina nígbà tí wọ́n gbé ọmọ wọn, Muhammadu Buhari, ẹni tó ti fi ìgbà kan jẹ Ààrẹ ológun àti Àárẹ̀ tí a dìbò yàn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, wọ ìlú náà

Ki I ṣe igba akọkọ ree ti Buhari yoo wa si ilu rẹ ṣugbọn lasiko yii, wọn gbe wọle lai si ẹmi lara.

Ni dede aago mẹfa ku isẹju marun un ni wọn gbe Aarẹ ana, ẹni ọdun mejilelọgọrin wọ kaa ilẹ niwaju awọn iyawo, ọmọ, mọlẹbi, ara ati ọrẹ, pe o di gba.

Aarẹ Buhari lo ọdun mẹsan an ati oṣu mẹjọ ni ijọba, eyi to jẹ apapọ ọdun to fi tukọ orilẹede Naijiria, gẹgẹ bii ologun ati aarẹ ti a dibo yan, eyi to sọ di olori to pẹ ju ninu itan orilẹede Naijiria
Ọpọ awọn eeyan lo peju sibi eto isinku, lara wọn ni ati ri iyawo oloogbe, Aisha Buhari, Aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Bola Tinubu; igbekeji rẹ, Kashim Shettima; igbekeji Buhari fun ọdun mẹjọ, Yemi Osinbajo; igbakeji aarẹ nigba kan ri Atiku Abubakar; oniṣowo, Aliko Dangote; awọn gomina ati gomina tẹlẹ, minisita, lọbalọba, olori ẹṣin ati awon mii.

Saaju eto isinku, Tinubu tẹwọgba oku aarẹ ana ni paapa ofurufu Katsina kete to de lati ilu London

Awujale ilẹ̀ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, ti wàjà

Awujale ilẹ̀ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, ti wàjà

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ikú lòpin èèyàn,
Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, ti wàjà lẹ́nu ọdún mọ́kànlélàádọ́rún.

Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàlá oṣù Keje, ọdún 2025.

Agbẹnusọ fun aafin Awujale, Oloye Fassy Yusuf fidi iroyin naa mulẹ fun akọroyin .

Lati asiko diẹ lo ti dabi i pe ara Kabiyesi ko ya, paapaa bi ko ṣe kopa nibi ọdun Ojude Ọba to kọja.

Ninu gbogbo pọpọṣinṣin to waye lasiko ọdun naa, ohun kan ti awọn eeyan ko ṣai kiyesi ni aisi Kabiyesi ilu Ijẹbu Ode, Ọba Sikiru Adetọna to jẹ Awujalẹ ti Ijẹbu lori ijoko lasiko ajọdun naa.

Ìnàkunà ni Chelsea na PSG

Ìnàkunà ni Chelsea na PSG

Yínká Àlàbí

Ere bo̩o̩lu alafe̩se̩gba ti agbaaye fun awo̩n Club ti o̩dun 2025 de opin lonii.
Iko̩ agbabo̩o̩lu PSG ati Chelsea ni wo̩n we̩ ti wo̩n yan kaninkan ninu awo̩n iko̩ mejilelo̩gbo̩n to be̩re̩ idije.
Ami ayo me̩ta o̩to̩o̩to̩ ni iko̩ Chelsea gba wo̩le ti PSG ti wo̩n ko si le da o̩kankan pada.
Meji ninu ami ayo naa ni agbabo̩o̩lu Palmer gba wo̩le nigba ti Pedro gba o̩kan to ku wo̩le.
Iko̩ Chelsea lo gba ife̩ e̩ye̩ naa.

Ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀, Muhammadu Buhari ti jáde l’áyé

Ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀, Muhammadu Buhari ti jáde l’áyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan, Muhammadu Buhari ti jáde láyé.

Ọ̀san ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Keje, ọdún 2025 ni olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fun , Garba Shehu, fi ìkéde ikú rẹ̀ léde fún àwọn akọ̀ròyìn.

Shehu sọ pé ilé ìwòsàn kan nílùú London ni Buhari kú sí.

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Ààrẹ tẹ́lẹ̀ ọ̀hún ti wà nílé ìwòsàn náà, kó tó ó di pé ó jẹ́pè ọlọ́jọ́ .
Itẹ̀síwájú ìròyìn nípa Ààrẹ tẹ́lẹ̀ ọ̀hún sì máa wá ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́
A kú ara fẹ́rakù

Erin wo! Aare ana, Muhammadu Buhari, di oloogbe

Buhari

Aare orile-ede yii tele, Ajagunfeyinti Muhammadu Buhari, ti di oloogbe.

Ilu London ni Aare ana naa ku si, gege bi iroyin to jade lati agbenuso re kan tele, Bashir Ahmad.

Ninu atejade naa to gbe si ori ero ayelujara X, o ni awon ebi Buhari ti kede ipapoda re.

O si gbadura ki Olorun te e si afefe rere.

 

 

E̩ja ńlá lo̩ lómi, Buhari re ibi àgbà ń rè

E̩ja ńlá lo̩ lómi, Buhari re ibi àgbà ń rè

Yínká Àlàbí

Iroyin yajoyajo gbee laipe̩ yii pe Aare̩ ana, Muhamnadu Buhari dagbare faye ni ile iwosan kan ni ilu London.
Ki Eledua de̩le̩ f’e̩ni ire.

APC Eko f’àgbà han gbogbo e̩gbé̩ òsèlú tó kù

APC Eko f’àgbà han gbogbo e̩gbé̩ òsèlú tó kù

Yínká Àlàbí

E̩gbe̩ onigbale̩ APC ti fi igbale̩ gba gbogbo ibo Eko ti wo̩n di ni ana si o̩do̩ ara wo̩n.
Idibo ijo̩ba ibile̩ waye jakejado ipinle̩ Eko lanaa o̩jo̩ kejila osu keje o̩dun yii. Esi ibo naa waye lonii o̩jo̩ ke̩tala nibi ti e̩gbe̩ APC si ti gbo ewuro soju awo̩n e̩gbe̩ to ku.
Gbogbo ijo̩ba ibile̩ ati ti idagbasoke me̩tadinlo̩go̩ta (57) pe̩lu awo̩n ipo kanselo marundinlo̩gbo̩n din ni irinwo (375) ni wo̩n ko patapata nigba ti e̩gbe̩ oselu PDP mu ipo kanse̩lo̩ kan pere.
Gomina ipinle̩ Eko fe̩mi imoore han si awo̩n ara ilu fun bi wo̩n se je̩ ki eto idibo naa lo wo̩o̩ro̩wo̩.

Sanwo-Olu, O̩basa àti Gbajabiamila síwájú nínú ètò ìdìbò Eko

Sanwo-Olu, O̩basa àti Gbajabiamila síwájú nínú ètò ìdìbò Eko

Yínká Àlàbí

Ajo̩ eleto idibo da o̩jo̩ o pe, be̩e̩ ni wo̩n da osu to ko. Oni o̩jo̩ kejila osu keje ti ajo̩ eleto idibo f’o̩jo̩ si pe eto idibo maa waye jake jado ipinle̩ E̩ko naa lo waye ti eto naa si lo ni gbogbo ijo̩ba ibile̩ ogun ati ijo̩ba ibile̩ onidagbasoke me̩tadinlogoji to wa ni ipinle̩ Eko. Ko sogun, ko so̩te̩ kaakiri ilu, bi onikaluku se n dibo tan ni wo̩n n gba ile wo̩n lo̩.
Bi o tile̩ je̩ pe awo̩n ohun elo idibo pe̩ ko to de awo̩n adugbo kan bi Agege, Alimoso, Iyana ipaja ati awo̩n miiran, sibe̩ eto idibo waye kaakiri ipinle̩ Eko.
Adeniyi Adele ni gomina ipinle̩ Eko, Babajide Sanwo-olu ati Ibijo̩ke̩ to je̩ iyawo wo̩n ti dibo Alaga ati ti kanse̩lo̩ nigba ti Mudasiru Obasa to je̩ olori ile igbimo̩ asofin Eko di tire̩ l’Agege, Surulere ni Femi Gbajabiamila to je̩ Chief of Staff fun Aare̩ Tinubu l’Abuja ti di tire̩. Awo̩n ara Eko ko tu jade lo̩po̩ yanturu bi o̩po̩ se nii lo̩kan sugbo̩n eto naa lo̩ pe̩lu iro̩run.
Awo̩n ajo̩ agbofinro ko je̩ ki mo̩to kankan wo̩ ilu Eko lasiko idibo naa.
Igbagbo̩ gbogbo ara Eko ni pe esi ibo naa maa jade laipe̩.

Obìnrin bí o̩kùnrin  ni Alága Onígbòǹgbò

Obìnrin bí o̩kùnrin  ni Alága Onígbòǹgbò

Yínká Àlàbí

Olufunke Hassan ni Alaga ijo̩ba idagbasoke Onigbongbo.  Gbogbo itu meje t’o̩de̩ n pa ninu igbo ni arabinrin yii n pa. Is̩e̩ aseju le ma je̩ ki o pada wa s’ejo̩ba ni Onigbongbo, awo̩n oloselu o ki n fe̩ ki olori kan se bi e̩ni pari is̩e̩. Eyi wa lara ikunsinu ti awo̩n kan ni si gomina ipinle̩ Eko te̩le̩, Alagba Raji Fashola. Koda Oloogbe ajafeto̩- o̩mo̩niyan to gboju gboya, to si tun da nito̩ nipa agbe̩jo̩ro, Gani Fawehinmi ni is̩e̩ Fasola po̩ nitori pe ko ki n se ogbontarigi oloselu. Fawehinmi ni eyi lo je̩ ki ara Eko gbadun re̩. O̩po̩ araba oloselu maa n fo̩wo̩ ra is̩e̩ ni, wo̩n o ki n pari re̩. O te̩ awo̩n kan lo̩run lati maa tun is̩e̩ kan naa gbe jade le̩e̩me̩ta pe̩lu owo ro̩gun-ro̩gun.
Le̩nu o̩jo̩ kan, Alaga yii ti lo̩ pari o̩na Kajo̩la, pari ilees̩e̩ imo̩ e̩ro̩ ko̩mputa ni GRA, pari o̩na Masalasi , O̩lade̩jo̩ ni Olusosun, o̩na Sadatu ni Oregun,  o̩na Abiola ni Toyin koda die̩ lo ku ki is̩e̩ pari ni olu ilees̩e̩ ijo̩ba ibile̩ naa. Ibe̩ ni asekagba gbogbo akanse is̩e̩ ti ye̩ ko waye.
Alaga ni awo̩n ko fara mo̩ is̩e̩ aabo̩ tabi is̩e̩ ajanbaku tabi da boo eyi lo maa mu ki awo̩n sa gbogbo agbara ti O̩lo̩run ba fun awo̩n ki is̩e̩ naa le pari lo̩se̩ to n bo̩.