Home Blog Page 118

Gbajabiamila fajú ro sí àwo̩n ológun tó ń fojú tó ètò ìbò

Gbajabiamila fajú ro sí àwo̩n ológun tó ń fojú tó ètò ìbò

Yínká Àlàbí

Olori ile-igbimo̩ asofin kekere, Femi Gbajabiamila  lo so̩ ero inu re̩ jade nipa awo̩n Soja to n foju to eto ibo.
Gbajabiamila ni oun ti fi ofin ja ija naa nigba kan lori idibo ipinle̩ Ekiti ti ile-e̩jo̩ da oun lare.
O ni onikaluku lo ni ise̩ tire̩ ge̩ge̩ bi a se kaso̩ si wo̩n lo̩run. O ni ohun ti agbara awo̩n o̩lo̩paa ko ba ka mo̩ ni awo̩n ologun maa n fi ise̩ ogun wo̩n yanju. O ni ko to̩na rara, ki a wa fe̩ dibo, ki a wa ko awo̩n ologun ti wo̩n di iha mo̩ra sita.
Olori ile-igbimo̩ asofin yii ni e̩ni ti ko ba lo̩kan le fa se̩yin to ba ti foju kan awo̩n ologun yii ni eyi ti ko dara to fun ijo̩ba awa-ara-wa wa ti a fe̩ ki o goke agba.
Ilu Surulere ni o ti salaye yii nigba ti o lo dibo. O si ro̩ awo̩n oludibo ki wo̩n ma se ba o̩mo̩luabi wo̩n je̩.

Ojú ti àwo̩n tó ni ìdìbò kò ní wáyé ní ile̩ Igbo – Soludo

Ojú ti àwo̩n tó ni ìdìbò kò ní wáyé ní ile̩ Igbo – Soludo

Yínká Àlàbí

O̩jo̩gbo̩n Charles Soludo to je̩ gomina ipinle̩ Anambra lo n fi idunnu re̩ han nigba ti o lo dibo ni ipinle̩ naa.
O ni inu oun n dun bi eto idibo naa se n lo̩ wo̩o̩ro̩wo̩, ti awo̩n eniyan si fara bale̩. E̩ni to maa duro, duro be̩e̩ si ni e̩ni to maa jokoo naa fi ijokoo sii, lati dibo fun e̩ni ti o̩kan wo̩n yan.
Gomina yii gboriyin fun awo̩n ara ipinle̩ naa, o si ro̩ wo̩n ki wo̩n di ibo wo̩n ni iro̩wo̩ ati iro̩se̩.
Gomina yii kan naa tun ni gomina ile ifowo-pamo̩-si ti ijo̩ba apapo̩ (CBN) te̩le̩.

E̩ni tí kò dìbò, kò lé̩nu ò̩rò̩- Dangote

E̩ni tí kò dìbò, kò lé̩nu ò̩rò̩- Dangote

Yínká Àlàbí

Gbaju-gbaja onisowo to lowo ju ni ile̩ Afirika. Aliko Dangote ni o n salaye yii fun awo̩n oniroyin ni kete to dibo re̩ tan.
Adugbo Victoria Island ni ipinle̩ Eko ni o ti dibo naa ni nnkan bii aago kan aabo̩.
Dangote tun fi idunnu re̩ han bi awo̩n eniyan se tu yaayaa jade lati dibo fun e̩ni ti o̩kan wo̩n yan.
Eyi naa lo je̩ ko salaye pe e̩ni ti ko jade lati dibo, ko ni e̩to̩ kankan lati bu e̩nu ate̩ lu ijo̩ba kankan nitori pe ko se ojuse tire̩ naa.
Dangote tun gbe osuba fun ijo̩ba ati ajo̩ INEC fun imo̩ igbalode ti wo̩n tun gbe wo̩ eto idibo naa,

“O ò dàbí e̩ni tó ní kí n má sisé̩ òsèré tíátà mó̩” – Anita Joseph morírì o̩ko̩ rè̩

“O ò dàbí e̩ni tó ní kí n má sisé̩ òsèré tíátà mó̩” – Anita Joseph morírì o̩ko̩ rè̩

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Anita Joseph ti seranti bi ololufe re teleri kan se so fun n pe ki o dekun ise osere nigba ti o n moriri oko re ati ilumooka amorieniwu, MC Fish.

Nigba ti oko ati iyawo naa n sajoyo ajodun odun keta igbeyawo won ni ana, ojo kerinla osu keji eyi to tun bo si ayajo ololufe, ni osere naa fi aworan oun ati oko re lede fun gbogbo aye lati ri.

Ewe, o tun moriri ife aye re, bi o se safihan pe won o pinnu lati se igbeyawo. O tesiwaju lati fikun un pe oko oun ko gbiyanju lati yi oun pada kuro ninu ohun ti oun feran lati se. O ko sile ninu aroko ife re bi oko re se je oto gedengbe, o sapejuwe oko re gege bi afenifere re akoko to feran lati maa wo ere re ti ko si dabi ololufe re teleri to so fun un pe ki o dekun ise osere.

O ko o wi pe:

“O o gbiyanju lati yi mi pada tabi lati mu mi rewesi kuro ninu ohun ti mo feran, iwo ni afenifere mi akoko, o fe maa ri ere mi!!
Ko dabi eni to so fun mi ki n dekun ise osere!!
Ti o si fun mi ni gbendeke pe ki n ma ba awon ore mi se papo mo”

Daddy Freeze fèsì sí ò̩rò̩ ò̩ré̩kùnrin tó lé ò̩ré̩bìnrin rè̩ síta nítorí àìníwà

Daddy Freeze fèsì sí ò̩rò̩ ò̩ré̩kùnrin tó lé ò̩ré̩bìnrin rè̩ síta nítorí àìníwà

Mary Fágbohùn

Alagabagebe eda lori ayelujara, Ifedayo Olarinde, ti a mo nidi ise si Daddy Freeze,ti fesi si oro okunrin to le orebinrin re sita lori ainiwa re.

Ninu fonran kan ti instablog9ja fi lede, o safihan ibi ti okunrin kan ti so fun orebinrin re pe ko kuro ninu ile oun nitori ainiwa re, fonran naa safihan ibi ti orebinrin naa ti n se igbesile bi okunrin naa se n saroye ti okunrin naa ko si mo, ninu fonran naa, okunrin on so fun orebinrin re pe “jowo fi ile mi sile, a o ba ara wa mu, iwa re o sunwon jowo maa lo, mo ti n so eyi fun o tipe, o ko, o fe lo, obinrin naa si fesi pe ma a lo.”

Okunrin on safihan pe orebinrin oun je eni to ma n doju ija ko eniyan, o feran ija, o si ti fi agbara gba ewu re laaro yii. O fikun n pe orebinrin re naa fe fa nkan omokunrin oun yo, o ti gbena wo ju re laaro yii, ti kii ba se ti ikoraeni ni ijanu oro iba ju bee lo, nitori naa o so fun orebinrin re pe ko kuro ni ile oun.

Okunrin naa so fun orebinrin re pe oun ti n so fun n pe ki o maa lo, sugbon ti ko si fe lo. O safihan pe omobinrin naa maa n pariwo, ti yoo si maa di gbogbo awon alabagbe oun lowo, ati pe o ti gbena woju alabagba oun obinrin ti iyen si ti fi igbasile ohun ranse si i, eyi si je ohun itiju fun okunrin naa. O wa so fun obinrin on pe ko maa lo to ba je pe iya re lobi. O so fun n pe nkan o sise boseye awon ologe Eko maa n o pelu iyi ni ti nkan o ba ti lo sise boseye, nitori naa ki o fi oun sile.

Leyin ti Daddy Freeze ri ohun to sele laarin okunrin naa ati orebinrin re, o fesi o wi pe okunrin naa je onisuuru, o se e wo loju, obinrin naa ni apa keji da bii pe won fi igbejakoju ati wahala to dagba ni. O ti sun okunrin naa, e je ko fi sile, ni ohun ti Daddy Freeze so.

Ò̩ré̩kùnrin òsèré tíátà Nkechi Blessing ti fèsì sí àwòrán rè̩ tó fi léde

Ò̩ré̩kùnrin òsèré tíátà Nkechi Blessing ti fèsì sí àwòrán rè̩ tó fi léde

Mary Fágbohùn

Ilumooka osere tiata Yoruba, Nkechi Blessing, ti lo si oju opo Instagram re tuntun lati fi aworan ara re ni adagun odo-iwe han. O lo si oju opo Instagram re lati fi aworan naa lede, nibi to ti n jegbadun ara re ni adagun odo-iwe. Leyin ti orekunrin re ri awon aworan yi ko le e mu mura mo ni o ba so tenu re to si safihan si gbogbo aye iru ife to ni si i.

Ninu atejade naa, o se irun re loso eyi to fi ewa kun n. O wo aso iwe to baa lara mu. O wa lai lo atike rara. O n gbafe ni ibi adagun odo-iwe naa bi o n se n ya aworan ara re lorisirisi ara.

Osere naa ti gbe ara re kale gegebi okan lara awon osere tiata Yoruba ti won n gba tire, ope lowo ebun abinibi re ati ipa ti o n ko ninu fiimu, eyi lo ran n lowo lati di oruko agboole kan laarin awon ololufe fiimu Yoruba ni Naijiria.

Lori pe o ri atejade re tuntun naa, orekunrin re, Xxssive, sare lo fesi si i wi pe, “Igbeaye idanikan wa yi dun mi lemi; e wo omobinrin enikan.” Oro yi lo fihan daju pe orekunrin re naa moriri ise re tuntun naa, eyi to je esi oro to dara.

Ojoojúmó̩ ló ye̩ kí a máa sàjo̩yò̩ o̩dún olólùfé̩ – Kunle Afod

Ojoojúmó̩ ló ye̩ kí a máa sàjo̩yò̩ o̩dún olólùfé̩ – Kunle Afod

Mary Fágbohùn

Ilumooka osere tiata, oludari ati agberejade, Kunle Afod ti lo si ori ayelujara re lati fi aworan oun ati iyawo re, Desola Afod lede bi won se n se ajoyo ayajo ololufe. Ninu aworan naa, awon tokotaya naa wo iru aso kan naa ti won si denge niwaju ayaworan. Kunle so pe ojoojumo lo ye ki won maa se ajoyo ayajo ololufe, o fikun un pe gbogbo igba ni oun yoo yan iyawo oun gege bi ololufe oun. Oro ifori naa ka bayii pe, “Ojoojumo lo ye ki won maa se ajoyo ayajo ololufe, o fikun un pe gbogbo igba ni oun yoo yan o gege bi ololufe oun.”

Awon aworan awotunwo yii ni o ti fa ki awon afenifere ati awon ilumooka ma a kegbe pe eyi wu mi o. Ewe, won tun fi ifesi ife ranse si awon ti n ko iha si aworan won. Iyawo Kunle Afod, Desola fi ami ife kan sile o wi pe, “O se fun pe o je ara mi. Ku oriire ayajo ololufe ife mi. Maa ri o laipe”. Osere tiata, Adebimpe Akintunde tun fi ami ife ranse.

Ni osu die seyin, Kunle Afod ni oro re suyo ninu iwe irohin wi pe igbeyawo re ti fori sanpon. To si je pe leyinwa eyi ni irohin tun jade pe iro banta ni oro naa ati pe won si n gbe nigbe lokolaya pelu iduunu.

 

Destiny Etiko kí òsèré tíátà, Sharon Francis kú aye̩ye̩ o̩jó̩ò̩bí

Destiny Etiko kí òsèré tíátà, Sharon Francis kú aye̩ye̩ o̩jó̩ò̩bí

Ilumooka osere, Destiny Etiko ti lo si ori ayelujara re lati fi aworan ore korikosun re ati gbajugbaju osere tiata, Sharon Francis lede bi o se sajoyo ojo ibi odun kokanle-ni-ogbon. Destiny si gbadura pe ki emi re gun ninu oro pelu ibukun latorunwa. Oro ifori naa ka bayi pe, “Ku oriire ojo ibi Ugegbe Akwa. Mo gba a ladura pe ki emi re gun ninu oro pelu ibukun latorunwa. Opolopo ore-ofe alailabula ati owo yoo je tire”.

Sharon eni to n jegbadun asiko lowolowo ni Seychelles. Ni wakati die seyin, lo si ori ayelujara re lati fi aworan ara re lede. O so pe ojo ibi oun duro fun idagbasoke, o fikun n pe ohun to dara ni lati wa laarin awon ti won nife eniyan ati awon ti won n se abojuto eniyan nitooto.

Awon aworan awotunwo yii ni o ti fa ki awon afenifere ati awon ilumooka ma a fesi nitori ewa re. Ewe, won si soro soke lati ki i fun ti ojo ibi. Awon ilumooka jakanjakan bii Daniella Okeke, Esther Audu, Ruby Ojiakor, Stella Udeze, Alex Cross, ati Ugegbe Ajaelo ni won fi ami ife ranse si i.

 

Àjọ EFCC ṣàwárí N32.4m owó tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan fẹ́ fi ra ibò l’Eko

Àjọ EFCC ṣàwárí N32.4m owó tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan fẹ́ fi ra ibò l’Eko

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ó dá bí ẹni pé bí wọ́n ṣe ń gé àwon èèyàn kan lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń bọ òrùka.
Akitiyan àjọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgudujẹra ní Nàìjíríà, EFCC ti bẹ̀rẹ sí so eso rere báyìí látàrí àti gbógun ti katakara atawọn mọkaruru tó níí ṣe pẹ̀lú owó ṣáájú ìdìbò ipò ààrẹ àti ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí yóò wáyé ló nìí.

Iṣẹ ti yaa bẹrẹ fun wọn naa niyẹn o gẹgẹ bi wọn ṣe fi panpẹ ọba gba owo to to miliọnu mẹtalelọgbọn o le ẹgbẹrun lọna irinwo naira ti wọn fẹsun kan wipe rira ibo ni wọn fẹ fi ṣe ni ipinlẹ Eko.

Awọn oṣiṣẹ ẹka ajọ EFCC to wa ni ipinlẹ Eko naa lo ṣe kongẹ gbigba owo naa wọn si ti ko awọn afurasi to lọwọ ninu ẹsun naa si atimọle fun ifọrọwanilẹnuwo.

Alága àjọ EFCC, Abdulrasheed Bawa ti rọ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ aj6ọ náà tí wọ́n rán láti ṣiṣẹ́ lásìkò ìdìbò yìí pé kí wọ́n ní ìgboyà kí wọ́n sì má fààyè gba àwọn onímọ̀dàrú tàbí oníwà tó lòdì sí òfin láti ta epo sí aṣọ àlà ètò ìdìbò nípasẹ fífi owó ra ìbò.

Ó ṣeéṣe kí àwọn kan gbìyànjú áti dá ètò ìdìbò rú, àwa náà gọ dè wọ́n – Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu

Ó ṣeéṣe kí àwọn kan gbìyànjú áti dá ètò ìdìbò rú, àwa náà gọ dè wọ́n – Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní tí omọ bá gbọ́n gbọ́n-ọn kúkú lẹ́ẹ̀rùn, ìyá a rẹ̀ á gbọ́n gbọ́n àti sin-ìn sí padò.
Ní báyìí, adarí àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu ti ní ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti jí ìbò tàbí da ètò ìdìbò rú yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu, nítorí pé àwọn agbófinró yóò fi ìyà tó tọ́ jẹ onítọhún.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu sọ èyìí lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Àbújá ní gbọ̀gàn ilé ìgbàlejò International Conference Centre (ICC) tó wà nílùú Àbújá.

Gbọ̀ngán ICC yìí ni wọn yóò máa lò láti máa kó gbogbo èsì ìbò tó bá ń wáyé ní gbogbo ìpìnlẹ̀ jọ.

Bákan náà, gbọ̀ngàn ilé ìgbàlejò International Conference Centre (ICC) yìí ni wọn yóò lò láti kéde ẹni tó bá jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò Ààrẹ ọ̀hún.

Lára àwọn tó wà níbí ìpàdé náà ni adarí ilé isẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà Usman Alkali Baba, àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè òkèèrè, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn akọ̀ròyìn.