Home Blog Page 117

Woli Arole laali ojise to so asotele iku omo Davido

Davido ati Ifeanyi

Mary Seunfunmi Fagbohun

Ilumooka aderin paniyan ni, Woli Arole, ti fi esun kan woli kan, Samueli Kig, lori bo se ni oun se asotele iku omo gbajugbaja olorin, Davido.

Oruko Woli Samueli ni o ti di ilumooka lori ero ayelujara leyin asotele ti o so nipa Davido ni ibeere odun ti a wa yi ti o si wa si imuse.

Leyin iku Ifeanyi Adeleke, iyen omo Davido, o jade lati ran gbogbo eniyan leti asotele re ti o so nipa omo naa ati pe o pe Davido ati gbogbo awon idile Adeleke lati wa oun kan, ki won ki o le da ibi ojo iwaju duro.

Woli Arole, eni ti inu re ko dun si iwa ti Woli yi hu, ni ise lo ye ki woli na gbadura ki o si ba awon idile na kedun.

Gegebi Arole se so, lati igba ti Olorun ti ba woli naa sooro nipa iku omo naa, ni se ni o ye ki o gbadura fun idile na dipo eyi ti o fi n se bi ariran.

O wi pe,”Leyin ipadanu, ohun ti o dara ju lati se bi eni emi ni lati gbadura fun idile ti oro kan ki o si bawon kedun.

Kii se akoko niyi lati so pe “Sebi Olorun ti so eyi funmi tele.

“DAKE ENU E.

Gbadura fun won, o tan.

Mase se bi ariran osi!!!!…”

Ìyàwó àsè̩sègbé O̩o̩ni ti mú inú bàbá o̩ko̩ rè̩ dùn bí ó se sí omi è̩ro̩ méjì sí Ilé-ifè̩

Ìyàwó àsè̩sègbé O̩o̩ni ti mú inú bàbá o̩ko̩ rè̩ dùn bí ó se sí omi è̩ro̩ méjì sí Ilé-ifè̩

Seunfúnmi Fágbohùn

Olori Temito̩pe̩, o̩kan lara awo̩n iyawo ase̩se̩gbe Ooni, Oba Adeyeye Ogunwusi ni o mo̩ bi oun se le ri oju rere awo̩n e̩bi o̩ko̩ re̩.
Iyawo tuntun yi ni o ti wu baba o̩ko̩ re̩ ati awo̩n eniyan Ife̩ lori nipa sisi omi e̩ro̩ si ilu lailai naa.
Temitope je̩ o̩kan lara awo̩n iyawo ase̩se̩gbe meje ti Ooni ki kaabo̩ si aafin ti awo̩n eniyan se apejuwe re̩ ge̩ge̩ bi idahun si iwa idojuti, awo̩n Olori ana -paapaa julo̩ Naomey- ti o ba o̩kan o̩ba je̩.
Temitope, ti o je̩ igbakeji alapejo Hope Alive Initiative (HAI), lo ti si omi e̩ro̩ meji si agbegbe o̩ja-tuntun, odo-ogbe, ni o̩jo̩ E̩ti.
Baba Ooni ti Ile-Ife̩, O̩mo̩o̩ba Ropo Ogunwusi, kansara sii, be̩e̩ pe̩lu ni Oba naa gboriyin fun un.
Olori Ogunwusi, ti o salaye pataki omi ni awujo̩, dupe̩ lo̩wo̩ Oba Ogunwusi fun anfaani lati se idasile̩ eto ti O̩lo̩run ni fun aye re̩.
Bi o ti so̩, O̩lo̩run ti gbe ise̩ riran awo̩n ti o ku die̩ kaa to fun le lo̩wo̩, ati wi pe ise̩ re̩ ko duro lori omi sise nikan, sugbo̩n o tun niise pe̩lu awo̩n o̩mo̩ orukan.
O ni :”Mo ro wi pe o ye̩ ki a yin iwa o̩mo̩niyan ti baba wa, Ooni hu fun jije̩ ki eleyii seese, nitori pe o nife̩e̩ gbogbo awo̩n eniyan re̩ ati awo̩n Iran Yoruba”.
Olori naa ro̩ awo̩n ara o̩ja lati lo omi naa bi o ti to̩ ati bo ti ye̩, ki wo̩n o si se itoju re̩ daradara fun lilo.
Olori na fikun un pe, o n gbagbo̩ pe omi naa yoo mu iye to dara ba idokowo awo̩n o̩lo̩ja naa.
O̩tun Babalo̩ja ti Odo-Ogbe, Oloye Olaoluwa Odeyemi, e̩ni ti o so̩ro̩ lati soju awon eniyan o̩ja na dupe̩ lo̩wo̩ Ooni ati Olori re̩ fun ife̩ ti wo̩n fihan nipa sise omi e̩ro̩ naa.
Odeyemi je̩je̩ pe wo̩n yoo lo omi naa fun anfaani gbogbo ilu.
Awo̩n eniyan pataki bi baba Ooni, Omooba Ropo Ogunwusi, Elerefe ti Erefe, Oba Mayowa Fayemi, Agbolu ti Agbaje-Ife, Oba Adekunle Adewale, ni o bu iyi kun aye̩ye̩ naa.

Mo so̩kún bí o̩mo̩ jòjòló lórí ikú Ifeanyi- Omoni Oboli

Mo so̩kún bí o̩mo̩ jòjòló lórí ikú Ifeanyi- Omoni Oboli

Seunfúnmi Fágbohùn

Ge̩ge̩ bi o̩po̩lo̩po̩ eniyan, o̩re̩ ati e̩bi ti n ba gbajumo̩ olorin ni, Davido, ke̩dun, e̩ni ti o padanu o̩mo̩kunrin re̩, Ifeanyi Adeleke, oserebinrin Omoni Oboli ti fi ibake̩dun re̩ han.
Bi osere naa ti fihan, o wi pe nigba ti oun ko̩ko̩ gbo̩ irohin naa, oun ko̩ lati so̩ro̩ lee lori nitori pe oun gba ladura wi pe ko ma se je̩ ooto̩.
Lehin ti oju o̩ro̩ naa jade tan, o wi pe o̩ro̩ naa dun oun to be̩e̩ ti oun fi so̩kun bi o̩mo̩ jojolo ti o si gba oorun loju oun.
Sibe̩, o fi lede pe ko si e̩ni ti o̩ro̩ naa lee dun bi Davido ati Chioma, ge̩ge̩ bi obi o̩mo̩.
O ro̩ awo̩n o̩re̩, ati awo̩n ololufe o̩ko̩ ati iyawo naa lati je̩ ki wo̩n wa laaye ara wo̩n ni akoko yii.
“Mo tiraka lati ma te̩ ate̩jade yii, mo ro wi pe bi mo ba se be̩e̩, ko ni je̩ ooto̩”
“Mo sokun bi o̩mo̩ jojolo bo tile̩ je̩ wi pe emi pelu Davido ati Chioma o kii se o̩re̩ timo̩timo̩. N ko le sun! Mo ji lowuro̩ yii, mo rii wi pe ooto̩ ni”
“Mo fi da o̩ loju pe IWO̩ NIKAN KO̩ LO WA! Gbogbo aye n ba o̩ ke̩dun.
“Ko le dun wa bi o ti dun o̩ to, sugbo̩n o ba o̩kan wa je̩! Ki O̩lo̩run tu o̩ ninu atiwo̩ ati e̩bi re̩ ni akoko yii.
“Ki E̩mi Mimo̩ ti o n fun ni ni alaafia fun o̩ ni alaafia ti ko ye o̩mo̩ araaye ni oruko Jesu.

Ìdíje du ipò igbákejì gómìnà Funke̩ Akindele ni PDP ti ń lé àwo̩n ò̩ré̩ àti onítíátà tókù lára rè̩

Ìdíje du ipò igbákejì gómìnà Funke̩ Akindele ni PDP ti ń lé àwo̩n ò̩ré̩ àti onítíátà tókù lára rè̩

Seunfúnmi Fágbohùn

Bi o ba n sise̩ pe̩lu oselu ipinle̩ Eko, waa mo̩ pe oselu nipo̩n ju alabasise̩ po̩ lo̩.
Eyi le je̩ e̩ko̩ fun irawo̩ osere ni, Funke Akindele, bi o ti se ipinnu re̩ lati darapo̩ mo̩ e̩gbe̩ oselu People’s Democratic Party ati titako e̩gbe̩ oselu All Progressives Congress ti o n se ijo̩ba lo̩wo̩lo̩wo̩.
Oun ni igbakeji oludije fun ipo gomina labe̩ asia e̩gbe̩ naa, nigba ti Jide Adeniran n lo̩ fun ipo gomina.
O̩ro̩ yi lo kan Adebayo Salami, Jide Kosoko, Saheed Balogun, Foluke Daramola, Damola Olatunji, ati Joke Silva.
Paapaa, Eniola Badmus ti o je̩ o̩kan ninu awo̩n o̩re̩ re̩ ti fihan pe oun ko si le̩hin re̩.
Amo̩ sa o, Tinubu ti fagilee ge̩ge̩ bi oludije. O so̩ wi pe, o je̩ oun idojuti lati daruko ‘Funke’ niwaju oun ge̩ge̩ bi oludije.

Mr Macaroni sò̩rò̩ sí olórí ò̩dó̩ nínú e̩gbé̩ òsèlú APC

Mr Macaroni sò̩rò̩ sí olórí ò̩dó̩ nínú e̩gbé̩ òsèlú APC

Ilumo̩o̩ka olude̩rin paniyan ni, Adebowale Adedayo, ti gbogbo eniyan mo̩ si Mr Macaroni, ti kede atile̩hin re̩ fun oludije ipo Aare̩ labe̩ asia e̩gbe̩ oselu Labour Party, Peter Obi, o so̩ro̩ idoju ija ko̩ni si olori o̩do̩ All Progressives Congress Dayo Isreali, eni ti o wi pe, e kede pe ko si anfaani yiyan e̩gbe̩ oselu miiran yato̩ si e̩gbe̩ APC.
Isreali lo so̩ wi pe oludije ipo Aare̩ ninu e̩gbe̩ oselu APC ti jawe olubori boya enikan fe̩ tabi o ko̩.
Macaroni se apejuwe re̩ ge̩ge̩ bi o̩ro̩ ipanilaya ati ti omugo̩ ti ko mu laakaye kankan wa.
Olude̩rin paniyan na ninu ate̩jade kan so̩ wi pe: ‘Emi ko mo̩ bi a ti n se ipolongo fun oloselu. Ni o̩dun 2023 ti o n bo̩ yi, Peter Obi ni e̩ni ti n o dibo yan!!! Opin re̩ niye̩n!!! O to ge̩!!!”
O fikun un pe, “afojudi olori o̩do̩ e̩gbe̩ oselu APC lo ti fihan pe awo̩n o̩mo̩ orileede Nigeria ko ni asayan kankan ninu idibo? Lati fipa mu awo̩n eniyan dibo fun wo̩n? “E̩ ko le pa gbogbo wa!!

Kò sí ohun tí ènìyàn lè se àyájó̩ lé lórí ní orílèèdè yìí – Wizkid

Kò sí ohun tí ènìyàn lè se àyájó̩ lé lórí ní orílèèdè yìí – Wizkid

Seunfúnmi Fágbohùn

Gbajugbaja olorin ni, Wizkid, ti so̩ro̩ lori rogbodiyan ti o n lo̩ ni orileede yii.
Bi o ti salaye, ko si ohun ti o seese ajoyo̩ le lori ni orile ede yi.
Nigba ti o n gboriyin fun bi onikaluku ti n se ohun ribiribi, o gbe osuwon ti o re̩le̩ fun orileede yi, bi o ti se ileri lati le gbogbo awo̩n agba oselu se̩hin ni o̩dun 2023.
Ninu ifo̩ro̩-wani-lenu wo pe̩lu Guardian ni UK’, ni o ti wi pe, ” Ko si ohun kan ti o seese ajo̩yo̩ le lori (ni Nigeria) yato̩ si pe awo̩n eniyan (Nigeria) je̩ akinkanju ninu orin kiko̩, ere idaraya, ide̩rin paniyan ati ninu gbogbo awo̩n eto idanilaraya lapapo̩. Awo̩n o̩do̩ Nigeria ni o se e fi yangan kaakiri agbalaye. Mo ni awo̩n o̩re̩ ti o yanile̩nu, ti wo̩n si n se ohun iyale̩nu.
“Ko ju be̩e̩ lo̩. Ko si ohun miiran. Sugbo̩n mo ni ireti pe iyipada yoo de. Bawo ni o se le pe̩ si? Mi o mo̩. Sugbo̩n o̩po̩lo̩po̩ nnkan ni o ti yi pada bi mo se n dagba sii.
Nigba ti o n pe gbogbo awo̩n o̩mo̩ Nigeria lati so̩ro̩ odi si ijo̩ba, olorin Essense ni “oun yoo ri tiwo̩n ro ni idibo ti o n bo̩ yi. Gbogbo awo̩n arugbo gbo̩do̩ gbe agbara sile̩ ni asiko yi. Wo̩n nilo lati lo̩ si ile awo̩n arugbo lati lo gbafe̩.”
Nigba ti o n gba awo̩n o̩je̩ oloselu niyanju lati fi oselu sile̩, olugbegba oroke ni e̩ye̩ Grammy se ileri lati gbogun ti wo̩n titi ti wo̩n yoo fi gbe agbara sile̩ ni eto idibo to n bo̩ lo̩na.

Àwo̩n àgbe̩ f’òǹtè̩ lu Tinubu

Àwo̩n àgbe̩ f’òǹtè̩ lu Tinubu

Yínká Àlàbí

E̩gbe̩ awo̩n agbe̩ lorisiirisii to wa ni ile Hausa lo n fi Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu lo̩kan bale̩ pe ti ibo ba ti ya lo̩dun to n bo̩, Asiwaju ni awo̩n maa te̩ ika fun.
Awo̩n e̩gbe̩ agbe̩ naa ni –  Maize Association of Nigeria, Miyetti Allah Keutal Hore, Rice Farmers Association of Nigeria and Federation of Agricultural Commodity Association of Nigeria.
Eyi naa mu ki Tinubu fi wo̩n o̩kan bale̩ pe ti oun ba ti wo̩le ibo, awo̩n naa ti bo̩ saye niye̩n, Tinubu ni oun maa je̩ ki orileede pada si olounje̩ yafun-yafun ti wo̩n mo̩ Naijiria si te̩le̩ ki o to di pe epo de.
Tinubu ni oun maa je̩ ki ipinle̩ ko̩o̩kan ni ounje̩ ti a maa mo̩ wo̩n si ni eyi to maa je̩ ki o ro̩run fun gbogbo agbe̩ lati di aladanla.
Ara awo̩n eniyan jankan-jankan to peju pese̩ sibi ipade naa yato̩ si Tinubu ni – alaga e̩gbe̩ naa Abdullahi Adamu, olugbalejo Abdullahi Sanni-Bello, Abubarka Badaru tii se gomina ipinle̩ Jigawa, Hon Umar Bago ti se oludije du ipo gomina labe̩  e̩gbe̩ oselu APC ni ipinle̩ Niger, Igbakeji oludije du ipo Aare̩ Se̩neto̩ Kashim Settima ati awo̩n eniyan janka-jankan miiran.

Peter Obi ò kún ojú òsùwo̩n ipò Ààre̩ – Melaye

Peter Obi ò kún ojú òsùwo̩n ipò Ààre̩ – Melaye

Yínká Àlàbí

Agbe̩nuso̩ fun eto idibo Aare̩ fun e̩gbe̩ oselu PDP Seneto Dino Melaye lo n salaye yii nipa inu ti Peter Obi bi.
Obi ni oludije du ipo Aare̩ labe̩ e̩gbe̩ oselu Labour Party.
Melaye ni iwa ti Oni wu nibi ifo̩ro̩-wani-le̩nu wo ti ileese̩ te̩lifiso̩n ARISE se akoso re̩ ti ko̩ko̩ jaa ge̩ge̩ bi oludije du ipo Aare̩.
Melaye ni e̩ni to ba n dupo Aare̩ nibi kibi gbo̩do̩ je̩ e̩ni ti ara re bale̩ bii ti Okowa to je̩ igbakeji re̩. E̩ni naa gbo̩do̩ ni suuru, e̩ni naa gbo̩do̩ je̩ onifarada, e̩ni naa tun gbo̩do̩ mo̩ igba ti eniyan n so̩ro̩ ati igba ti eniyan n dake̩, o tun ni e̩ni naa gbo̩do̩ mo oju ati ara.
Melaye ni Obi ye̩ ki o toro aforiji fun oun nitori iwa alaini suuru to wu si oun nitori ti o ba n ba iru ibinu be̩e̩ lo̩, yoo kan maa na awo̩n osise̩ re̩ sere ni.
Ori e̩ro̩ ayelujara twitter Melaye lo ti salaye yii.

O̩wó̩ te̩ àwo̩n nó̩ò̩si pè̩lú è̩yà ara òkú

O̩wó̩ te̩ àwo̩n nó̩ò̩si pè̩lú è̩yà ara òkú

Yínká Àlàbí
Yoruba bo̩ wo̩n ni, o̩jo̩ kan ni ti ole, o̩jo̩ gbogbo ni ti olohun.
Owe yi se̩ mo̩ awo̩n no̩o̩si ile-iwosan Ibadan Cenral Hospital to wa ni ilu Ibadan nigba ti o̩wo̩ palanba wo̩n segi.
Awo̩n no̩o̩si meji naa ni Muibat Olatunji o̩mo̩ o̩dun me̩tadinlo̩gbo̩n(27 years old) ati Oluwafunmilayo Omeh o̩mo̩ o̩dun mejilelogun ( 22 years old) pe̩lu awo̩n sikio̩riti meji ti ako̩ko̩ n je̩ Bamidele Bamiro o̩mo̩ o̩dun mejilelo̩gbo̩n (32 years old) ati Godwin Omomoh o̩mo̩ o̩dun mejilelogun (22 years old).
Gbogbo wo̩n lo foju ba ile-e̩jo̩ ti wo̩n si ni awo̩n e̩ya ara eniyan ti wo̩n ka mo̩ awo̩n lo̩wo̩ kii se e̩ru awo̩n.
Adajo Emmanuel Idowu ti ile-e̩jo̩ naa ti o fi ikale̩ si Iyaganku ri ilu Ibadan gba oniduro wcn pe̩lu e̩gbe̩run lo̩na igba naira fun e̩niko̩ckan.
Iwadii n te̩ siwaju, adajo̩ si sun igbe̩jo̩ naa si o̩jo̩ ko̩kandinlogun osu kejila o̩dun yii.

Mo ta Twitter dá Bluesky sílè̩ – Jack Dorsey

Mo ta Twitter dá Bluesky sílè̩ – Jack Dorsey

Yínká Àlàbí

Oludasile̩ gbaju-gbaja Twitter, O̩gbe̩ni Dorsey lo ti gbe Twitter ta ni bilio̩nu me̩rinlelogoji do̩la ($44 billion) ni o̩jo̩ ke̩rinla osu ke̩rin o̩dun 2022. Elon Musk to raa pari owo sisan naa ni o̩jo̩ ke̩tadinlo̩gbo̩n osu ke̩waa o̩dun yii.
Eyi lo mu ki o tun be̩re̩ Blusky ti ohun naa je̩ ayelujara ni o̩na ara.
E̩gbe̩run lo̩na o̩gbo̩n eniyan lo ti darapo̩ laarin o̩jo̩ meji. Bi Bluesky naa se tun darapo̩ mo̩ awo̩n eto ayelujara to ku niye̩n.