Home Blog Page 116

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.

Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ó tó gba 270,000 Naira lọ́wọ́ ọ rẹ̀, nitori ikorita Bódìjà Ojúurin.

Ṣaájú ni àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára kan ti sọ pé ọkùnrin nà kú nítorí ọgbẹ́ ìbọn tí ó wọ̀ ọ́ lára.

À mọ́ ASP Òsífẹ̀sọ̀ sọ pé ẹ̀mí ọkùnrin ọ̀hún kò bọ́, tó sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ níléèwòsàn kan.

Òsífẹ̀sọ̀ sọ pé ìwádìí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fihàn pé àwọn adigunjalè náà tọ ipasẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Ibrahim láti ibì kan tó ti lọ̀ ọ́ ta ọjà nínú ìgboro Ìbàdàn, tó sì ń padà sí ibùgbé rẹ̀ ọjà Akinyele, níjọba ìbílẹ̀ Akinyele.

“Nítorí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ tó wà nì òpópónà márosẹ̀, Ibrahim pinnu láti gba ọ̀nàaàbùjá kan tí kìí ṣe ibi tí ọ̀pọ̀ èèyà ń gbà. Ibẹ̀ ni àwọn adigunjalè náà ká a mọ́.

“Láti orí ọ̀kadà tí wọ́n wà, ni wọ́n ti yìnbọn mọ́ Ibrahim ní àwọn ìka ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n tó ó gba owó tó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀.”

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìwádìí ti ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú ọ̀hún.

Arábìnrin kan fi è̩sùn kan o̩ko̩ Toyin Abraham pé ó fún òun lóyún

Arábìnrin kan fi è̩sùn kan o̩ko̩ Toyin Abraham pé ó fún òun lóyún

Seunfúnmi Fágbohùn

Alaboyun kan ti fi e̩sun kan Kolawole Ajeyemi ti o je̩ o̩ko̩ oserebinrin Toyin Abraham wi pe oun ni o fun un loyun.

Gege bi o̩mo̩binrin yi se so̩, oun ati Ajeyemi ti pero lati jo̩ wa papo̩ ki o to di ti Toyin.

Ninu fo̩nran kan ti o n lo̩ kaakiri, o ni oun ti loyun fun o̩kunrin naa lati o̩dun me̩rin se̩yin, o fi kun un pe oun si ti n gbe oyun naa kiri lati igba naa.

O fi e̩sun kan an siwaju sii pe, awo̩n e̩ni e̩mi ti so̩ fun oun pe ayafi ti Kolawole ba pada so̩do̩ re̩ ki oun to le ri o̩mo̩ naa bi.

Ohun tí Davido ati Chioma ń là ko̩já kò de̩rùn – Tuface

Ohun tí Davido ati Chioma ń là ko̩já kò de̩rùn – Tuface

Seunfúnmi Fágbohùn

Olokiki olorin ni, Innocent Idibia, ti gbogbo eniyan mo̩ si 2face, ni o ti fi e̩dun o̩kan re han lori ohun ti Davido ati obinrin re Chioma le e ma la ko̩ja le̩hin iku o̩mo̩ wo̩n, Ifeanyi.

Ifeanyi ni o ku le̩hin ti o ri sinu odo iwe ninu ile baba re̩ ni Banana Island to wa ni ilu Eko laipe̩ yii.

Ninu ate̩jade kan lori ayelujara ni 2face ti fi aworan awo̩n obi Ifeanyi han, ti o si ko̩ o̩ wi pe, ko si e̩ni ti ohun ti wo̩n n la ko̩ja le e ye.

O ko̩ o̩ sile̩ pe, oun ko mo̩ ohun ti oun le e so̩ ati wi pe o̩ro̩ naa dun un lati igba ti irohin ibanuje̩ naa ti jade lori ayelujara.

O so̩ pe:

“KO SI E̩NI TI O LE E YE NI TOOTO̩ OHUN TI AWO̩N O̩DO̩MO̩DE MEJI YII N LA KO̩JA LO̩WO̩LO̩WO̩”

EYI DUN NI DENU EEGUN. MI O MO̩ OHUN TI MO LE E SO̩.”

Iléẹjọ́ ò gba Akpabio gẹ́gẹ́ bíi olùdíje Sẹ́nétọ̀ ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom

Iléẹjọ́ ò gba Akpabio gẹ́gẹ́ bíi olùdíje Sẹ́nétọ̀ ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nílùú Abuja ti wọ́gilé ìdájọ́ iléẹjọ́ gíga láti yọ Godswill Akpabio gẹ́gẹ́ bíi olùdíje sípò sẹ́nétọ̀ lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún àríwá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tí Adájọ́ Damlami Senchi saájú rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ni Akpabio kùnà láti pèsè àwọn ẹ̀rí lásìkò tó yẹ.

Ìgbìmọ̀ ọ̀hún tẹ̀síwájú pé Akpabio, ẹni tó ra tíkẹ́ẹ̀tì láti dupò ààrẹ Orílẹ̀ yìí lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò kópa nínú ètò abẹ́nú tó wáyé ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún.

Tí àjọ elétò ìdìbò INEC, tó ṣe agbátẹrù ìdibo sì kéde Udom Ekpoudom gẹ́gẹ́ bíi olùdíje ẹgbẹ́ ọ̀hún.

Àgùntan kò je̩ lábe̩ Gè̩é̩sì ni ò̩ré̩ èmi àti Tiwa Savage – Ke̩mi Olunlo̩yo̩

Àgùntan kò je̩ lábe̩ Gè̩é̩sì ni ò̩ré̩ èmi àti Tiwa Savage – Ke̩mi Olunlo̩yo̩

Seunfúnmi Fágbohùn

Ako̩ro̩yin ati onise̩ isegun ni, Kemi Olunloyo, to so̩ro̩ lakootan lori idi ti o fi pinnu lati ma se ilara gbajumo̩ olorin ni, Tiwa Savage.

Nigba ti o n so̩ro̩ lori e̩ro̩ ayelujare, Kemi Olunloyo ni ibe̩re̩ pe̩pe̩ ilara re̩ nii se pe̩lu o̩ro̩ ti o jade pe olorin naa ni o n bo̩ oun.

Ge̩ge̩ bi Kemi ti se so̩, ko nireti wi pe Tiwa yoo dake̩ lori aheso̩ o̩ro̩ naa.

O nireti wi pe, Tiwa Savage yoo so̩ro̩, ti yoo si da gbogbo akiyesi naa danu.

Ninu ariyanjiyan re̩:

“TIWA O SE NNKANKAN FUN MI.

MI O BEERE FUN OHUNKOHUN.

MO KAN MUU GE̩GE̩ BI O̩RE̩ TI O KERE SI MI NI.

E̩ DAKE̩ ATI MA A SO̩ OHUN TI E̩ KO GBO̩.

LOOOTO̩! MO N BINU SI I NITORI WI PE O DAKE̩ NIGBA TI ADETOUN SO̩ PE TIWA SAVAGE NI O N BO̩ MI.

TIWA KO BO̩ MI O, KO FUN MI LOWO, BE̩E̩ NI MI O BEERE FUN UN”.

Mike Bamiloye rí àwo̩n tí ó ń kó owó náírà pamó̩ sílé bíi asiwèrè pó̩ńbélé.

Mike Bamiloye rí àwo̩n tí ó ń kó owó náírà pamó̩ sílé bíi asiwèrè pó̩ńbélé.

Seunfúnmi Fágbohùn

Ilumo̩o̩ka osere onigbagbo̩ ni, Mike Bamiloye ri iwa asiwere po̩nbele ninu igbe aye awo̩n o̩mo̩ Nigeria ti wo̩n n ko owo bantabanta pamo̩ sile.

Lati igba ti ile ifowopamo̩ apapo̩ lorileede yii ti kede pe wo̩n yoo gbe owo naira tuntun jade ni gbogbo awo̩n ti o ko owo ribiribi pamo̩ sile ti n tu u jade.

O so̩ro̩ yii lori e̩ro̩ ayelujare pe:

“Awo̩n eniyan kan lo se eyi!
Mi o mo̩ idi o?

Iwa asiwere po̩nbele lo gbo̩do̩ je̩!

Nigba ti o̩po̩lo̩po̩ awo̩n eniyan n sise̩ ti wo̩n si n jiya ninu osi ni awo̩n eniyan kan ti fi idunnu gbe owo ainiye ti wo̩n ko le e na pamo̩ sinu ile.

Eleyii je̩ e̩mi buburu to fe̩ fiya je̩ awcn alaise̩.

Awo̩n adari buru,

Sugbo̩n ki O̩lo̩run fi o̩wo̩ kan o̩kan wo̩n lati se ohun ti o to̩.
Nigeria yoo dara!

Ni oruko nla Jesu!

Gbogbo awo̩n ti wo̩n n mo̩o̩mo̩ seka fun awo̩n alaise̩ ni oju yoo ti.

Yoo dara fun orileede yi!

 

Nkechi Blessing se yanga si awon okunrin to n seju si i. O ni ko sona nibe mo.

 Eyin ilumooka, e ye se igberaga, e wa ife lawari - Nkechi Blessing gba awon akegbe re nimoran
Nkechi Blessing

 

Mary Seunfunmi Fagbohun

Nkechi Blessing se yanga si awon okunrin to n seju si i. O ni ko sona nibe mo.Alagabagebe oserebinrin ni, Nkechi Blessing Sunday, ti fi ateranse jade si awon odomokunrin ti won n denu ife ko o ni ori ero ayelujara.

Oserebinrin na ti o ran Ooni ife leti laipe yi pe oun nife si lati je iyawo Ooni, ti soro lori ero ayelujara lati se afihan awon odomokunrin ti o n fi ateranse ife ranse si i bii ‘omokunrin keekeekee’

Gegebi bi o se so, oun ko si ni arowoto eni kookan mo, bi oun ti se je ti elomiran.O ko o wipe:

“GBOGBO AWON OMOKUNRIN KEEKEEKEE N RO WIPE FIFI ATERANSE IFE SOWO SI MI NI ARAARO YIO JE KI N RI TI WON RO…

MO FI WON RERIN PUPO

MO TI DI TI ELOMIRAN, N KO SI LE SAKIYESI ENIKEJI”

E ranti wipe alagabagebe oserebinrin Yoruba na, ni o ti bori aisan ife ti o de baa lehin ijakule lati owo ololufe re atijo  ti o n gbe ni ilu UK, Opeyemi Falegan, ti o si ti fi igbakanna se afihan ololufe re tuntun ninu fonran kan lori ero ayelujara.

Nkechi Blessing, ti a bi ni ojo kerinla osu keji odun 1989, ni o je omo gbajugbaja olounje ati onisowo obinrin Iya Nkechi ni Abule Egba, ni ipinle Eko.

Nkechi Blessing je omo bibi ipinle Abia ni orile ede Nigeria.

Ti o si laluyo nigba ti o gbe ere Omoge Lekki ti Mercy Aigbe jade.

Nitori Gomina AbdulRasaq, Muka Ray-Eyiwumi fa awon osere lo si Kwara.

Gomina Abdurazak

Mary Seunfunmi Fagbohun

Awon egbe osere ni Kwara se ipolongo nla kaakiri igboro ilu Ilorin lati kede isejoba eleekeji fun Gomina AbdulRahman AbdulRasaq, lori ise takuntakun ti gomina naa ti se latehin wa.

Gbajumo oserekunrin ni, Muka Ray-Eyiwumi, eni ti o je oluranlowo gomina,  ni o se agbateru ipolongo naa, pelu awon alakoso ijoba ti won si wo ewu akanse ati fila ni bi ogorun won.

Ajo NAN rohin pe imura won n so erongba won si awon olugbe ileto naa nipase orin, ni bi won se n fi  asia ati iwe atejade ti o ni orisirisi akole han bii, Gomina AbdulRasaq leekeji; aropo merin ati merin o je mejo, Muka fun AA, larin awon toku.

Won jade lati agbegbe Igbimo awon onise ona ati asa ti ipinle naa ti o wa ni Geri Alimi Ilorin, koja si popona Ibrahim Taiwo, popona Emir,  popona Post Office-Challenge, ona Ahmadu Bello, titi de ile ijoba nibi ti won ti kase ipolongo na nle.

Agbekale eto yi wa lati owo  igbakeji oluranlowo agba fun Gomina lori asa ati irin ajo afe, Ogbeni Eyiwumi Muka Ray, ogbontarigi  osere Yoruba ati asagbejade ere ti o je omo bibi ijoba ibile Irepodun ni ipinle naa.

Lara awon osere ati alatilehin egbe oselu APC ti won kun ibi ipolongo yii ni, egbe osere ni orile ede Nigeria (ANTP), egbe ere itage ati isipopada aworan ni orile ede Nigeria (TAMPAN) egbe ode ati onise aabo, egbe awon onse fiimu ti orile ede Nigeria, egbe olorin ni orile ede Nigeria ti ipinle Kwara (PMAN).

Tonto Dikeh soro lori aleebu re to buru ju lo

Tonto Dikeh

 

Oserebinrin ati oloselu ni, Tonto Dikeh, ti toka si aipeye re ti ko le se iranlowo fun un.

Se Yoruba bo, won ni ejo kii se ejo eni ka ma moo da.

Gbogbo eniyan ni o ni aipeye tiwon bo ti wu ki won lagbara ti won si mo iwa hu to.

Lori oro tire, o wi pe, oun to buru julo aile ma aba awon eniyan sore tabi ojulomo fun igba pipe.

Opo eniyan yoo ranti  ilumooka okunrin ti a ma se bi obinrin ni, Idris Okuneye, ti a mo si Bobrisky, ti o je ore korikosun Tonto Dikeh ni igba kan ri ki won to pinya, eyi ti o yori si ija ti o yanilenu.

Tonto ti gba pe oun buru jai lati ni ore ati ba ojulumo kan se fun igba to pe.

Amo sa o, o wi pe, oun nife gbogbo won, awon ko kan le jo se wole-wode gbogbo igba ni.

O so pe,”LAASIGBO INU AYE MAA N JE KI ENIYAN GBAGBE LATI JE OLURANLOWO FUN AWON TI A FERAN. O JE OHUN TI KO MO MI LARA PUPO LATI MAA KO ORE ATI OJULUMO KIRI SUGBON MO FERAN GBOGBO YIN NI ONA TEMI TI O JE EEMO!!!

EMI NIYI TI MO N SO WIPE GBOGBO WERE AGBAYE, MO NI IRETI PE E WA DAADAA.”

Ibasepo awon gbajugbaja oserebinrin bii Toyin Lawani, Halima Abubakar, Anita Joseph, Swanky Jerry, Annie Idibia, Toyin Abraham ati bee bee lo ni o ti fori sanpon ni ona ti ko rorun.

Ori mi fere daru nigba ti mo gbo pe aisan Lupus wa ni ago ara mi – Kemi Afolabi

Kemi Afolabi

 

… Kemi Afolabi soro lori iriri re pelu aisan Lupus

Mary Seunfunmi Fagbohun

Ilumooka oserebinrin ni, Kemi Afolabi, fi asiri die han nipa bo se fee gba emi ara re n nigba ti o ti n ba aisan Lupus ja laipe sehin.

Gege bi oro re, inira ti oun doju ko po gan-an, ti o si n se laakaye re ni ijamba.

Nigba ti o n so nipa iriri lori aisan na, o wipe:

“Idaniloju ni pe aaraunopolo wa.

E ma se fi edun okan eniyan sere pelu iwa hihu tabi oro siso.

Ori mi fere daru nigba ti mo gbo pe aisan Lupus wa ni ago ara mi, ifoya pelu irewesi okan de bami. Mo korira gbogbo ohun ti mo n la koja.

Mi o ni okun lati se awon nnkan ti mo feran lati se, eyi je ki aanu ara mi semi.

Mi o fi gbogbo nnkan wonyi han fun awon ti mo feran.

O de ibi kan ti mo wa n ri i pe mo n fe se ara mi ni ijamba lopolopo ni. Mo maa n  gbo awon ohun ajeji kan.

Kemi Afolabi: Arokan nii fa ekun asun-un-dake

Mo je oloriire lati se konge awon eniyan nla ti won fi ife ooto han si mi eyi ti o ranmi lowo lati ni idaraya kankan ati wi pe mo dupe nitori emi ti mo n mi ti mo fi san ju eni to ti ku lo.

Leyin naa ni mo se ileri wi pe n o maa gbe pelu oun ti mi o le yipada. Mo wa n gba kadara wipe bi mo se ri re e.

Bi awon eniyan se n se ti nnkan ba waye yio je ki oye aye ye yin.

“Gbogbo eda ni o ni isoro ti won n koju.

Eyi ni lati gba awon eni ti o n la isoro kan koja niyanju lati ma se ropin tabi ni irewesi okan.

“E JOWO E GBA BO SE RI BAYII, KI E SI GBAGBO PE GBOGBO RE YI O YIPADA SI RERE BO PE BO YA.”