Home Blog Page 112

MIKE ADENUGA @ 69: Ó DÙN, Ó PỌ̀, Ó PẸ́, OLÚWA LÓ Ń FÚN NI

Adenuga

Akeem Lasisi

– E ka nipa igbesi aye oludasile Globacom ati eko pataki to ko wa

-Idunnu n subu lu ayo ninu ile gbajugbaja onise okowo to tun je olowo tabua, Dokita Mike Adenuga, tori pe o ti pe eni odun kan din laadorin – 69 years bayii.

Dokita Adenuga je akanda eda to da ile ise Globacom sile, nibi ti opo eniyan ti n sise, to si je pe ile ise naa n se daadaa fun oro aje Naijiria.

Adenuga lo tun ni ile ise Con Oil ati awon okowo nla nla miiran.

Oun ni eni ti Olorun da lola latari bi o se tepa mose lati ibere pepe, to si je pe o ti figba kan gbe ilu oyinbo, ko to dari wale.

Kii se eni kan to maa n fa ijongbon tori pe o ni owo.

Bee, kii maa n se lau-lau kaakiri.

Opo eniyan naa lo mo pe Adenuga kii kuku se ilumomika to maa n be kaakiri, debi wi pe sasa ni apejo tabi aseye ti a ti maa n ri I .

Sugbon bi ko tie jade, owo re n jade, to si n tan kaakiri, to fi n se aye lore.

Idi niyi to fi je pe ile ise Globacom maa n nawo lati mu idagbasoke ba ilu, eyi ti awon oloyinbo n pe ni Corporate Social Responsibility, iyen CSR.

Bi apeere, Globacom maa n se iranwo fun awon amuludun bi olorin, onifiimu ati awon alawada komei.

Bakan naa, o ya awon kan laarin won ti won maa n pe ni Glo Ambassadors, ti won maa n se asoju ile ise naa nibi gbogbo.

Owo nla nla ni Adenuga maa n fun won.

Lara iru awon bee ni King Sunny Ade, Ebenezer Obey, D’Banj, Funke Akindele, Odunlade Adekola, PSquare ati alwada Gordons.

Bakan naa, Globacom maa n se akitiyan lori igbende asa ati ise wa.

Idi niyii ti o fi maa n gbaruku ti Ojude Oba ati Ofala Festival ti awon Igbo.

Iroyin fi ye wa pe Alagba Adenuga maa n gbaruku ti awon oba alaye, paapaa kakiri ile Yoruba.

Bakan naa, won ni o je eni kan to maa n fi emi imoore han upo

Idi niyii to fi je pe ojobii re maa n je eyi ti opo eniyan maa n fi okan si, ti won si maa n se adura fun un.

Idi niyii ti IROYIN OWURO naa fi karamasiki ojo eye naa, ti a si n gba a ni adura pe ki Olorun Oba tbo maa gbe e ga, ko si maa daabo bo emi re.

O dun, oo, o pe, won ni Oluwa lo n fun ni.

Ki Edumare tubo maa fi meteeta se Dokita Mike Adenuga lore o.

Eni to ni kin laa se laa se e fun: Sanwo-Olu fakoyo ni Ipinle Eko

Sanwo-Olu

Akeem Lasisi

–        Oko oju irin reluwee fe bere

–        O n ko opo ile iwe

–        Ilegbee awon akekoo n bo ni LASU

–        Osibitu awon omode Messey di atunko

–        O se ribiribi lori ona ati ise agbe abbl

 

Ti won ba n pa owe pe eni ti o ni kin laa se, oun laa se e han, o jo pe Gomina Ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo-Olu, ni won n so nipa re.

Awon eniyan kan ti ko mo ipa ati ebun to ni, pelu emi isinlu, se gbenugbenu nigba ti o sese n gbe apoti ibo.

Awon kan tie ni olori egbe All Progressives Congress ati oludije ipo aare, Asiwaju Bola Tinubu, kan fe fi Sanwo-Olu di gereu ni.

Sugbon leyin odun meta o le die ti gomina naa ti dori aleefa, lala ti lu, aruputu ti hu.

Gege bii eni to ni kin laa se, o ti se e han won.

Yala lori eto eko ni, eto irinna, eto ilera, eto oro aje ati iseranwo fun awon alaini, Sanwo-Olu ti n sanjo fun awon oludibo.

Nigba ti o koko gori aleefa, idoti wa kaakiri Ipinle Eko, ti gbogbo titi n run rai.

Bakan naa, opolopo ona aarin ilu lo ti baje.

Bee, opo awon ile iwe ni won n sunkun atunse.

Bi o tile je pe awon gomina to ti je ki oun to depo, bii Akinwunmi Ambode, Babatunde Fashola ati Tinubu funra re, gbiyanju to won, ti won si gboriyin lopolopo, nnkan ko senu rere lori awon nnkan ti a la sile yii.

Eyi fa a ti ariwo ati awuyewuye fi po ni awon osu akoko ti Sanwo-Olu fi wa nipo.

Sugbon, ni werewere, ni sise-n-tele, Sanwo-Olu ti mu ki opo awon isoro Eko di afiseyin ti eegun n fiso.

Lona kinni, idoti gelete gelete ti poora ni Eko.

Lona keji, opo ona to baje nigba naa ni won ti tun se, to si je pe owo ko duro rara lori won.

Ti a ko ba gbagbe, orisiirisii awon agbasese ni Sanwo-Olu gbe awon ona naa fun.

Bi won si se n sise lojooumo ni Komisanna Eto Iroyin ati Ilana, Alagba Gbenga Omotoso, maa n se atejade bi won se nsise lori awon ona naa lojoojumo.

Ko tan sibe o. Ijoba Sanwo-Olu ti fe so ala ki Eko ni reluwee di amuse bayii.

Oloogbe Lateef Jakande lo koko gbiyanju oko oju irin fun Ipinle naa.

Sugbon ijoba Ologun da iyanju naa nu ni odun 1984.

Igba ti awon gomina Fashola ati Ambode de ni won bere ise nla naa pada.

Sanwo-Olu de, o fe e loju, o si ri pe ise ko duro lori re.

Messey Hospital ti Sanwo-Olu n ko

Lara awon aseyori pataki ti o tun ti se ni atunko awon ile iwosan, paapaa ile owosan awon omode Messey Hospital, eyi to wa ni agbegbe Adeniji Adele tele.

O n se iwosan ofe kaakiri osibitu fun awon omode si omo odun mejidinlogun, at awon agbalagba ti won ti pe odun marundinlaadorin.

Lati igba ti won ti da ile eko giga Lagos State University, eyi to wa ni Ojo, sile, ko ni ilegbee awon akekoo ti a n pe ni hostel.

Bayii, Sanwo-Olu tib ere si ko olopo yara fun won.

Bakan naa ni  o n ko awon ile iwe alakobere ati sekondiri kaakiri ipinle naa.

Sanwo-Olu ti ko ile gbigbe estates to ti le ni egberun meta.

Pelu  awon ise ribiribi yii, opo eniyan lo gba pe atipada sipo re ni 2023, bi eni n feran jeko ni.

Ohun to tun maa se iranwo fun un ni bi o se n seto iselu ni ilana to to n ko gbogbo eniyan mora.

Awon oloselu ko ni wahala  kan pelu re, bee awon onise okowo, awon onimoto, iyaloja ati elere idaraya wa pelu re.

Bi ako ba gbagbe, ijoba Sanwo-Olu tib ere sii ya awon onifiimu lowo, ki idagabsoke tun le ma bai se won/

Awuyewuye PDP: Yanmuyanmu Wike ba le Atiku ni tibi, oro di suuru

Wike ati Atiku

 

Awuyewuye to n lo ninu egbe oselu Peoples Democratic Party lori bi Alaga won, Iyorchia Ayu, se tun wa nipo ko tii ro o.

Gomina Ipinle Rivers, Nyesom Wike, lo ko awon olori egbe naa miran kan sodi, ti won ni Ayu gbodo fi ipo naa sile.

Idi ni pe Oke Oya (North) NI Ayu ti wa, to si je pe ibe naa ni oludije ipo Aare won, Alhaji Atiku Abubakar, ti wa.

Wike wa n wo o pe eyi ko ba ofin egbe naa mu – ki oludije aare ati alaga wa lati abala ibi kan naa, ki awon Odo Oya ma w ani oju Kankan nibe.

O fi kun un pe o ya oun lenu pe adari eto ipolongo ibo fun Atiku, Oke Oya ni oun naa ti wa.

Lara awon ti won wa po pelu Wike lori oro yii ni Gomina Ipinle Oyo, Alagba Seyi Makinde; Oloye Bode George, Gomina Ekiti ana, Ayodele Fayose; ati Ojogbon Jerry Gana.

Atiku ko so pe oun ko oro Wike danu; sugbon o ni oun ko le deede yo Ayu, tori ofin naa lo gbe e depo.

O ni bi won tile yo o naa, ofin ni ki igbakeji re bo si ipo naa ni.

Bee, Oke Oya ani oun naa ti wa.

O wa jo pe oro naa so s I lenu, o wa buyo si i.

Sibesibe, Wike si n ke fatafata ni pe oun ko ni gba, oun ko ni gbo.

O jo pe Atiku ti gba kamu pe ko se oun to ba fe se, sugbon ko so bee sita.

O kan so pe Ayu nikan lo le funra re fiwe sile ni.

Bi ojo ibo se n bo lona, to si je pe Atiku ko ni fe padanu ibo Rivers, oro naa wa da bii yamuyamu to ba leni lepon: afi keeyan fi suuru pa a.

Ki omo iya meji kan fomo iya meji mi-in

Aare Ona Kakanfo Yoruba, Iba Gani Adams
Femi Akinsola
Ninu asa ati ise yooba,ko tona, be e ni ko bojumu ki omo iya Meji ti won je okunrin o fe omo iya meji ti won je obinrin.Asa ti ko bojumu ni,ni awujo yooba,bi o tile je pe iwadii,fihan pe awon lgede n se be e. Odi meji lo ni ka ma fi esuru pe esuru,ka ma fi esuru pe esuru,ka ma feyin adaba pe eyin odide e.    
Owo alaafia
Asa buruku ni ki eniyan pe owo kan ninu owo mejeeji ti Eledaa fi jinki re ni owo osi.Yooba gba pe ko wi owo osi,sugbon owo alaafia.Owo alaafia ni yooba n lo dipo o owo osi.
Ose pipa
Awujo ti o leto ni awujo yooba,won si ni ibowo pupo fun asaaju won,ni iwa ati ise.Won ka a wi n ti ko bojumu,ki eniyan ma a pose,nigba gbogbo.Yooba koriira ki eniyan ma a pose,papa a julo omo kekere,niwaju agbalagba.Won ka a si afojudi,ipeyinda irufe asa yii le ja si wahala ayeraye.
Yinmu
Ninu asa a yooba, ko tona ki eniyan o ma a yinmu.Enikeni ti o ba so irufe asa yi di baraku u re,ko si ani ani, ojo iwaju eni naa, wa ninu ewu, tori pe wahala le tibe wole fun-un,ti o si le e da ona eni naa ru pata pasta,lai ni atunse.
Ki won sin oku ni ihooho                          
Asa ti o le,ti o si rewa pupo ni asa a yooba,awujo ti o si leto ni.Yooba ka a si asa buruku,ki won sin oku nihooho.Enikeni ti o ba lo ilana yii, lati sin oku nile e yooba,won ka a si eranko.Yoruba gba pe, ipeyinda eni naa lewu pupo,tori o sunmo ki o fibanuje pari aye e re.ldi niyi ti yooba fi ma a n powe pe,eni ti yoo sin egbon e nihooho,ko roju maburo o re lowo.

Gbogbo awon oloselu ti mo sise fun ni won ko ri temi ro bayii – Fadeyi Oloro

Fadeyi Oloro

Agba oje osere tiata, Fadeyi Oloro, ti ke gbajare pe awon olose lu ti oun sise fun ko died iranwo si oun.

O ni bi o tile je pe ara oun ko ya, ti oun si n rawo ebe si won, won ko naani oun rara.

O ti pe die ti aisan ti gbe Fadeyi Oloro de.

Ki Pastor TB Joshua to ku, o se eto iwosan fun un ni soosi re, the Synagogue Church of All Nations.

Sugbon aisan naa tun ti pada, ti Fadeyi si n pe ipe fun iranwo.

Lara awon oloselu to daruko pe oun ti sise fun ni Asiwaju Bola Tinubu, Babatunde Fashola ati Babajide Sanwo-Olu.

Fadeyi ni oun ko le so pat obo se n se oun.

O ni ohun ti ohun kan mo ni pe kinni naa kan n wo kaakiri ara oun ni, to si n fun oun ni inira.