Home Blog Page 108

Ìdí tí àwo̩n olólùfé̩ mi ò se gbo̩dò̩ fi mí se àwòkó̩se – Geneveva Umeh

Ìdí tí àwo̩n olólùfé̩ mi ò se gbo̩dò̩ fi mí se àwòkó̩se – Geneveva Umeh

Mary Fágbohùn

Bi o tile je wi pe o n lo ere sise re to n dan bii itanna lati fi petu si awon oluwo Nollywood ninu fiimu, osere ti irawo re n yo bo, Genoveva Umeh, ti so wi pe oun kii se awokose fun enikeni nitori pe oun ko fe ki ohun ti awon eniyan n reti lati odo oun fa iru ipinnu ti oun yoo se.

Umeh, eni ti a mo julo fun ipa to ko gege bi Timeyin ninu fiimu, Blood Sisters, ati Zina ninu fiimu atelera ti Netflix, Far from Home, ninu iforowero kan laarin ose pelu Midweek Entertainment, wi pe oun ti se ipinnu naa nitori oun lodi si ki awon eniyan ma a so ara won mo ohun to se tabi ipinnu ti yoo se.

O wi pe, “Mo ro pe ipenija mi pe mo fe je ara mi, Mo fe se opolopo ise to ga sugbon mi o fe ki okiki bo mi mole. Awon nnkan ti mo fe dojuko niyi.

“Atipe, bi ise mi se n wu awon eniyan lori, mi o ro ara mi gegebi awokose. Mi o kii se awokose, mo kan je enikan ti o feran ise re ati pe nnkan ti o n wu awon eniyan lori niyi, iyen dara.

” Sugbon mi o fe ki awon eniyan so ara won mo gbogbo ohun ti mo se tabi ki won fami laso fun ipinnu kan ti mo se. Mo fe gbe ni ominira, mo fe je ara mi, mo si tun fe se opolopo ise to ga si i laisi ifungun mo ohun ti awon eniyan n reti.

Osere naa wi pe oun yan ere sise bi ise nitori pe oun ni okan lati se ise naa, o fikun n pe oun kawe gboye ninu ise amofin bi atileyin ti nnkan ba daru.

O wi pe, “Ise mi sese bere ni, mo si dupe fun bi ipa ti mo ko se je ti elebun pupo ti o si je oju awe to tobi pelu. Ipakipa ti yoo yimi pada, ni ma a se daadaa. Mo feran lati pe ara mi nija. Mi o feran lati ko ipa kan leemeji. Gbogbo iwa ni o yato bakan si ara won.

” Mo mu ere sise nitori pe mo ni ife si i gidi. O dabi eni pe mi o le e gbon n. Ni pataki, Mo ri pe o je ohun to mu inu mi dun julo. Bo ti le je pe, mo ro pe ohun ti mo feran ni. Mo ri pe ebun mi ni mo si ni okan lati se e.

“Fun ti imofin mi, mo fe ko je ohun ti mo le ri feyinti nitori pe leyin gbogbo re, mo je iran akoko ti yoo lo si ile okeere ni ebi mi, oye ise takuntakun ti awon obi mi se lati ri pe mo wa ni United Kingdom ye mi. Mi o fe jawon kule nitori pe ma a dabi adanikan jopon ni.”

Mi ò ki ń se olórin tó ń figagbága pè̩lú e̩niké̩ni – Harrysong

Mi ò ki ń se olórin tó ń figagbága pè̩lú e̩niké̩ni – Harrysong

Mary Fágbohùn

Gbajugbaja olorin, Harrison Okiri, ti a mo si Harrysong, ti so pe oun di olorin lati le e korin gidi, kii se lati figagbaga pelu enikeni.

Ninu iforowero kan pelu Sunday Snoop, o wi pe, “Gbogbo eniyan ni oba ni aafin tire. Awon olorin bii Davido, Burna Boy ati Wizkid n sise taratara lati ri pe awon ko kuro ni ipo asaaju ti won wa. Sibesibe, kii se pe awon elomiran ko sise takuntakun. Sugbon, ni ti emi o, mi o si nibi lati figagbaga pelu enikeni. Ti eniyan ba ni emi ifagagbaga, mi o lero pe eru eni bee le e bori re. O je ohun to se pataki lati ki awon to n se daadaa ku ise. Ti eniyan ba ki won ku oriire fun aseyori won, eniyan n fi ti won toro ni. Ko niilo owu jije tabi ilara sise. Bi mo se ri i; nigba ti Burna Boy gba ife eye Grammy, o mu ogo wa si Afrika, kii se Naijiria nikan.

Nigba to n soro lori eto re fun 2023, olorin naa wi pe, ” Mo n sise lori akojopo orin mi, ti mo pe akole re ni, Olorun laarin Eniyan (God Amongst Men). Mo le e fi da awon ololufe mi loju pe won yoo gbo iro tuntun nitori pe orin ti n yi pada. Ma a fun won ni ohun ti won feran.”

Olorin naa tun fi igbagbo re han pe orin afrobeats ni a ko le e lailai fowo ro seyin lagbaye. O fikun n pe, “Afrobeats ko le e kuro ni oju mapu. Ko seese. Omiran ni Naijiria sibe.”

È̩rù ń ba àwo̩n o̩kùnrin láti fé̩ àwo̩n òsèrébìnrin – Mojisola Adebanjo

 

È̩rù ń ba àwo̩n o̩kùnrin láti fé̩ àwo̩n òsèrébìnrin – Mojisola Adebanjo

Mary Fágbohùn

Osere tiata kan, Mojisola Adebanjo, so pe pupo okunrin Naijiria ri i bi ohun to le lati fe ati lati gba oserebinrin gbo nitori pe gbogbo igba ni won ma a n wa laarin awon eniyan, ati pe won si ni opolopo nnkan ti won ko nipa won.

O so fun Sunday Snoop pe, “Lati inu iriri, mo ti ri pe pupo okunrin ri bi ohun to le lati wa ninu ibasepo tooto pelu oserebinrin. O je ohun to le fun won lati gba wa gbo, nitori pe won gba pe a wa ni oju gbogbo eniyan; pelu awon itan ti won ma a n ko nipa oserebinrin. Opolopo awon okunrin ni eru n ba lati fe oserebinrin.”

Nigba to n soro lori iriri re akoko ni ibi ti won ti fe se fiimu, o wi pe, “Iriri mi akoko je eyi to dun. Mo ni orisirisi ero; inu mi dun ati pe eru si n ba mi bakannaa nitori pe opolopo oserekunrin tiata lo wa nibe. Sibesibe, mo gbonran jigi pelu igboya lati se ohun ti mo feran lati se ati ohun ti mo fe se. Mo niilo lati fi ise mi tele sile ki n le dojuko ise tiata mi.”

Lori ohun to ro nipa boya Nollywood je ‘ore’ fun obinrin, osere naa wi pe, “Beeni, ile-ise naa mu awon obinrin bii ore. Ti obinrin ba mo ohun to fe to si n se daadaa ninu ohun to n se, ile-ise naa yoo mu bi ore.”

Osere naa tun wi pe boti le je wi pe oun le e fe eni to kere, a mo aaye to wa laarin ojo ori naa ko gbodo po ju. “Ko si ohun to buru ninu ki eniyan fe eni to kere si i. Bi won se so, ‘onka lasan ni ojo ori’. Sibesibe, mo gba wi pe ki okunrin mi ju mi lojo ori, sugbon kii se ko dagba ju. Mo feran okunrin to ba tojubo, to loye, ti o si le e ronu ju ohun ti a ri lo.”

Èsù ló pààrò̩ ìtumò̩ GOAT, wó̩n ń paró̩ fún yin ni – Mike Bamiloye

Èsù ló pààrò̩ ìtumò̩ GOAT, wó̩n ń paró̩ fún yin ni – Mike Bamiloye

Mary Fágbohùn

Alase ati oludasile ile-ise okowo fiimu Mount Zion Faith Ministries, ti so pe awon ti won pe ara won ni “eni to ga ju ni gbogbo igba (Greatest Of All Time; GOAT) ko ni aaye ni orun. Olugberejade naa wi pe oro naa ‘goat’ (ti o tumo si ‘ewure’ ni ede Yoruba) ni itumo ni igba ikehin yii jinle gidi. O so eyi ninu atejade kan to fi lede ni oju opo Instagram re.

Nitori pe Jesu Kristi kede pe oun yoo yaa aguntan kuro laarin awon ewure, gegebi oun ti Olusoaguntan Mike so, oro naa ” ewure” ninu Bibeli je ami to duro fun awon ti ko setan lati so eso, alaigbonran, asote, ati alaigbagbo. O fi idi re mule pe itumo re gangan ni esu ti pada.

Ninu oro re, o wi pe “Mo ko oro yin pe itumo re ni eni ti o ga ju ni gbogbo igba. Itumo re gangan ni esu ti pada fun yin, kii se eyin funra yin! Won n paro fun yin ni; e o kii se ewure tabi eni ti o ga titi lai! Ijoba Olorun ko si fun awon ewure eniyan.”

Mò ń se ìgbáradì fún isé̩ abe̩ mìíràn láti mú kí ìbàdí mi fè̩ síi – Bobrisky

Mò ń se ìgbáradì fún isé̩ abe̩ mìíràn láti mú kí ìbàdí mi fè̩ síi – Bobrisky

Mary Fágbohùn

Idris Okuneye, ti a mo daadaa si Bobrisky, omokunrin Naijiria ajisebiobinrin eni to kede pe oun yoo se ise abe idi miiran lati le je ki akeyinsi oun ati egbe oun fe si.

Ikede naa ni o se ninu atejade ni oju opo Snapchat Bobrisky, ni ibi to ti se alaye pe oun ko ni si ni ori ayelujara fun igba die nitori ise abe naa.

Ipinnu Bobrisky lati se ise abe fun idi naa ni ko je iyalenu, bi ajisebiobinrin naa ti se fi han pe ohun to wu oun ni lati pa bi oun se ri da lati le e ri bi obinrin ninu gbogbo nnkan fi mo ewa won.

Eyi nii eredi fun awon ise abe to ti se seyin lati le e ni omu ati ibadi, ati lilo awon atike ati awon ohun elo asojuloge miiran, ti ara bibo titi ti omo dudu bi taya moto re fi di omo pupa bii ole awe, ko gbeyin.

Ikede Bobrisky yii ni o ti fa opololo oro ikunsinu laarin awon ololufe re, bi awon kan ti n se atileyin fun ti won si n kan saara si fun igboya to ni lati la iru eto naa koja, ni awon miiran n bu enu ate lu ipinnu re wi pe o lewu ko si pon dandan.

Awon kan tile beere iye ti ise abe naa to ati bo se rorun to, paapaa julo ni Naijiria ti opolopo ohun elo ilera ko je idagbasoke bi ti awon orile-ede miiran.

Pelu gbogbo re, Bobrisky ko yese lori ipinnu to se lati se ise abe idi miiran.

Mo ṣetán láti sin àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún sáà kejì báyìí – Oyetola

Mo ṣetán láti sin àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún sáà kejì báyìí – Oyetola

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ pé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà Gboyega Oyetola ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022, Gboyega Oyetola ti bá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀.

Oyetola nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ilé rẹ̀ tó wà ní Iragbiji ní oríire náà kì í ṣe fún òun nìkan bíkòṣe fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ APC.

Ó ní ó jẹ́ ìmúgbòòrò ètò ìṣèjọba àwaarawa láti fìdí i rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni òun jáwé olúborí ètò ìdìbò tó kọjá.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC fún àdúrótì wọn lásìkò tí gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà fi wáyé àti pé ayọ̀ wọn ni bí ìgbìmọ̀ Tribunal ṣe dá ògo àwọn padà.

Bákan náà ló rọ̀ wọ́n láti ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí wọ́n má bàá ẹnikẹ́ni fa wàhálà tàbí hùwà jàgídíjàgan lórí ìdájọ́ náà.

Oyetola tún yin àwọn agbẹjọ́rò tó ṣiṣẹ́ fun lákin fún ipa ribiribi tí wan kó láti lè jẹ́ kí ọjọ́ òní wá sí ìmúṣẹ.

Ó tẹ̀síwájú pé ìdájọ́ yìí yóò jẹ́ ìwúrí fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn láti gbájúmọ́ ètò ìdìbò gbogbogboò tó ń bọ̀ lọ́nà láti fi gbé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn wọlé.

Ó fi kún-un pé inú òun dùn gidigidi sí ìdájọ́ náà tí òun sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ọjọ́ òní nítorí ó bá òun ní òjijì.

Oyetola ní òun ti ṣetán láti sin gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun fún sáà kejì báyìí àti pé ó dá òun lójú pé òun ni òun gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò tó wáyé ọ̀hún.

Ọ̀wọ́n èpo àti Náírà tuntun ni wọ́n fẹ́ fi dènà ìbò 2023 – Tinubu

Ọ̀wọ́n èpo àti Náírà tuntun ni wọ́n fẹ́ fi dènà ìbò 2023 – Tinubu

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà ní bá á gúnyán, bá á rokà, ibi ẹ̀sun iṣu la ti í mọ̀.
Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti pariwo síta pé gbogbo ìgbésẹ̀ tí ìjọba Orílẹ̀ yìí n gbé ni láti dabarú ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2023 tí a wà yìí.

Oludije naa tii se ọmọ ẹgbẹ oselu kannaa pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari to n se ijọba lọwọ ni Naijiria wa salaye pe owo Naira tuntun ati ọwọngogo epo bẹntiroolu to wa nita lasiko yii ni wọn fẹ ẹ lo.

Tinubu lo sọrọ naa sita lasiko eto ipolongo idibo to ṣe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, l’Ọjọru, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023.

Ipolongo idibo naa to waye ni Papa Iṣere MKO Abiola to wa lagbegbe Kutọ niluu Abẹokuta, lo kun fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri ipinlẹ Ogun, to fi mọ awọn ololufẹ agba oloṣelu naa.

Asiwaju ni Naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade ko si nita f’awọn araalu lati na, bẹẹ si ni awọn araalu tun n jiya fun epo bẹntiroolu.

O ni ijọba apapọ ṣe bi ẹni pe wọn ko mọ ohun to n lọ nipa awọn ipenija mejeeji yii, nitori pe gbogbo ipinnu wọn ni lati dabaru eto idibo apapọ.

Amọ Tinubu wa fọwọ sọya pe ohun to da oun loju ni pe awọn ọmọ Naijiria ko nii gba, wọn yoo jade lati dibo lọpọ yanturu, nitori pe ayipada rere ni wọn n fẹ.

“Wọn ko fẹ ki idibo yii waye. Wọn fẹẹ dabaru ẹ ni. N jẹ ẹ maa gba wọn laaye bii?

Wọn ti bẹrẹ sii gbe ọrọ aisi epo rọbii dide. Ẹ ma mikan, ti ko ba si epo bẹntiroolu, a maa fi ẹsẹ wa rin lọ sibi ti a ti maa dibo, a si maa dibo wa.”

Ààrẹ Buhari ṣèfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ ojú omi mìíràn l‘Eko láti kó ọjà wọlé láti òkè òkun

Ààrẹ Buhari ṣèfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ ojú omi l‘Eko láti kó ọjà wọlé láti òkè òkun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní aríṣe láríkà, Ààrẹ Orílẹ̀ yìí, Muhammadu Buhari ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ omi èyí tó tóbi jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn “Lekki Deep Sea Port”.

Èròńgbà ìjọba ni láti pọkún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà láti pọkún owó tó ń wọlé lábélé.

Ní ọjọ́ Àìkú ni ọkọ̀ ojú omi tó kó ẹrù kọ́kọ́ balẹ̀ sí pápákọ̀ omi náà tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ dọ́là ṣaájú ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ajé.
Ní agbègbè “Lekki Free Trade Zone”, ìpínlẹ̀ Eko ni pápákọ̀ omi náà wà.

Gómìnà Babjide Sanwo-Olu ní òun gbàgbọ́ pé pápákọ̀ omi náà yóò pèsè iṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko, tí yóò tún máa owó gọbọi fún orílẹ̀ Nàìjíríà.

Ní oṣù Kejìlá ọdún 2017 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ pápákọ̀ náà lẹ́yìn tí ìjọba àti iléeṣẹ́ “The Lekki Port Investment Holding” tọwọ́bọ àdéhùn ọlọ́dún márùndínláàdọ́ta.

Bákan náà ni èròńgbà wà pé pápákọ̀ omi láti fi kó ọjà wọ orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí yìí yóò mú àdínkù bá ọ̀wọ́n gógó tó máa ń bá owó tí wọ́n fi ń kó ọjà wọlé.

Dele Ayemibo sọ fún akọ̀ròyìn pé òun rò ó wí pé ó yẹ kí wọ́n ti pèsè ọ̀nà ojú irin tàbí ọkọ̀ orí omi tí yóò máa gbé àwọn ọjà kúrò ní Eko láti mú àdínkù bá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀.

Ayemibo kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó pọn dandan láti pèsè ọ̀nà tó pọ̀ tí ọjà yóò máa gbà jáde kí ohun náà má ba à ní súnkẹrẹ fàkẹrẹ tó máa ń wáyé ní ọ̀nà Apapa.

Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì FUTA gbẹ̀mí ara rẹ̀ l’Akurẹ

Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì FUTA gbẹ̀mí ara rẹ̀ l’Akurẹ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹni tí ò kú ló nigbó òkè ọ̀hún.
Akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì ìmọ̀-ẹ̀rọ tìjọba àpapọ̀ tó wà l’Akurẹ, Ọlọna Joseph Oluwapẹlumi, ni wọ́n ló ti bínú pa ara rẹ̀ lórí ìdí tí kò tí ì yé ẹnikẹ́ni.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, akẹkọọ ọun, ẹni to ti wa ni ipele kẹta ni wọn ba nibi to pokunso si ninu yara ile to n gbe lagbegbe Aulẹ, niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, ọsẹ to kọja

Awọn akẹkọọ kan ti wọn jẹ ẹgbẹ oloogbe ọhun ni wọn ṣakiyesi pe ilẹkun yara rẹ ṣi wa ni titi pa lasiko ti wọn lọọ ki i laaarọ kutukutu ọjọ iṣẹlẹ naa.

Nigba ti wọn kan ilẹkun titi ti wọn ko ri ẹni da wọn lohun ni wọn pinnu lati ja ilẹkun yara rẹ, iyalẹnu lo si jẹ nigba ti wọn ba a nibi to ti n rọ diro diro lori iso pẹlu bọkẹẹti ipọnmi to fi ti ẹsẹ lasiko to n goke lati pokunso.

Awọn to sun mọ ọmọkunrin ti inagijẹ rẹ n jẹ Black ọhun daadaa ni lati bii ọsẹ diẹ sẹyin lo ti n fi ọrọ iku powe lori ikanni Fesibuuku rẹ.

Ọpọlọpọ igba ni wọn lo si maa n kọ ọ sibẹ pe oun n wa ẹni ti yoo fi owo ran oun lọwọ lori okoowo kan ti oun n ṣe.

Awọn ọrọ wọnyi lo jẹ kawọn eeyan kan maa ro pe ṣe ni akẹkọọ naa mọ-ọn mọ pa ara rẹ latari ironu aroju ati aisi oluranlọwọ fun un.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni oku akẹkọọ naa ti wa ni mọṣuari, ati pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lati fidi ohun to ṣokunfa iku rẹ mulẹ.

Èyí nìdí tí Ọ̀ṣínbàjò, Ngige àtàwọn kan kò fi polongo ìbò fún Tinubu – APC

Èyí nìdí tí Ọ̀ṣínbàjò, Ngige àtàwọn kan kò fi polongo ìbò fún Tinubu – APC

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Bí ó bá nídìí, obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú. Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ti ṣàlàyé ìdí tí lára àwọn èèkàn léèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú náà bí i Igbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọ̀ṣínbàjò, Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ àti ètò ìgbanisíṣẹ́, Dókítà Chris Ngige, Mínísítà tẹ́lẹ̀rí fún ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti ìrìnà, Rotimi Amaechi, kò fi kópa nínú ètò ìpolongo ìbó fún Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Aṣíwájú Bọla Ahmed Tinubu, wọ́n ní kì í ṣe tìjà, ọ̀rọ̀ náà ní bó ṣe jẹ́ ni.

Adari eto iroyin ninu igbimọ ipolongo ibo funpo aarẹ wọn, Amofin agba Festus Keyamọ, lo tanmọlẹ sọrọ naa lọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu Kin-in-ni yii, o ni aṣẹ ti ọga Ọṣinbajo, iyẹn Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, pa fun un pe ko gbaju mọ ọrọ iṣakoso lasiko yii, tori iwọnba oṣu perete lo ku fun saa ọdun mẹjọ wọn, aṣẹ ọhun ni ko jẹ kawọn eeyan ri Ọṣinbajo bo ṣe yẹ nibi eto ipolongo ibo APC. Ni ti Igbakeji aarẹ, aṣẹ ti wọn pa fun un ni pe ko doju kọ iṣejọba. Tẹyin naa ba si kiye si i, Aarẹ ti n tẹle wa lọ sawọn ibi ta a ti ṣepolongo ibo.

 

O ni: “Rotimi Amaechi, iyẹn gomina ipinlẹ Rivers nigba kan, wa si eto ipolongo ibo ta a ṣe ni Adamawa ati Jos laipẹ yii, o ti bẹrẹ si i lọ sawọn rali (rally) wa kaakiri, ṣugbọn eyi to ba wu u lati lọ lo maa n lọ, ipinnu ara-ẹni ni.

“Bakan naa, Ngige, iyẹn Chris, to jẹ gomina ipinlẹ Anambra nigba kan, ko sọrọ ta ko ẹgbẹ wa, o kan jẹ pe o ti sọ p’oun ko ni i sọpọọti ẹgbẹ kankan, tabi oludije funpo aarẹ kankan ni toun ni, o loun fẹẹ duro ni danfo gedegbe, oun lo si mọ idi to fi ṣe ipinnu bẹẹ. Amọ ẹnikan ṣoṣo niyẹn jẹ laarin minisita bii mẹtalelogoji ta a ni.”

O waa kadii ọrọ rẹ pe: “Ko si ani-ani nibẹ, iṣọkan ati ajọṣepọ ẹgbẹ APC wa duro digbi ni, ko da bii ti ẹgbẹ PDP ti wọn ti fẹrẹ wogba tan.”

Tẹ o ba gbagbe, lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan ti n ṣakiyesi pe ẹkọ o ṣoju mimu laarin ẹgbẹ oṣelu APC, pẹlu bawọn agbaagba kan to yẹ ki wọn ṣugbaa oludije funpo aarẹ ẹgbẹ naa, Bọla Tinubu, ṣe n mọ eto ipolongo ibo rẹ loju tẹki. Lara wọn ni Ọṣinbajo, bẹẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ọkunrin naa n jade lọ sawọn ode ayẹyẹ ati ariya mi-in bii ayẹyẹ ọgọrun-un ọdun ti wọn ti da ileewe Baptist Boys High School, Abeokuta, silẹ, eyi ti Ọṣinbajo pesẹ si, to si kopa to jọju nibẹ.

Wọn loju ti ẹgbẹ APC fi gunyan eto ipolongo rẹ kọ lo fi n gbọbẹ lọdọ awọn eekan eekan ẹgbẹ naa lasiko yii, amọ Keyamo ti ni didun lọsan yoo so fawọn nigbẹyin o.