



Yóó ṣòro láti yí ìdàjọ́ náà padà nílé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn
Fẹ́mi Akínṣọlá
Agbẹjọ́rò àgbà nílẹ̀ yìí Amòfin Fẹ́mi Fálànà ti ní yóó ṣòro láti yí ìdàjọ́ náà padà nílé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn.
Fálànà sọ pé “Ohun tó yẹ kí àwọn olùdìbò lágbègbè yẹn ṣe ni kí wọ́n pe INEC lẹ́jọ́ pé àjọ náà fi ìbò o wọn ṣòfò.”
Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, yóó ṣòro fún àwọn agbẹjọ́rò Adeleke láti yí ìdájọ́ tó wà nílẹ̀ padà tí wọ́n bá dé ilé ẹjọ́ kọ̀tẹ́milọ́rùn.
Ó ní “Bí mo ṣe ń wo ìdájọ́ yìí, mo gbàgbọ́ pé yóó ṣòro láti yí ìdájọ́ náà padà.”
“Orí INEC ló yẹ kí wọ́n ti fọ́ àgbọn ohun tó ṣẹlẹ̀.”
“Ó yẹ kí INEC padà lọ tún èrò rẹ̀ pa kí irúfẹ́ nǹkan báyìí má baà wáyé mọ́.”
“Nítorí tí irúfẹ́ nǹkan báyìí bá wáyé nínú ètò ìdìbò Ààrẹ, ó lè dá rúgúdù tí apá INEC fúnra rẹ̀ kò ní-ín ká.”
Ẹ̀wẹ̀, Ademola Adeleke tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n gba ipò lọ́wọ́ ẹ̀ fún Oyetola ti sọ fún àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n má fa wàhálà kankan nítorí òun yóó gba ilé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn lọ.
Àmọ ṣá, àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ kan ti ṣe ìfẹ̀hónúhàn nílùú Osogbo lópin ọ̀sẹ̀.
Nínú dókítà 280 tí a ní, 199 wọn ló jẹ́ ayédèrú – Ìjọba Zamfara
Ọrẹ Òtítọ́jù
Gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara, Bello Matawalle ti sọ pé kò dín ní ayédèrú dókítà mọ́kàndínnígba (199) tó ń gba owó ìjọba láì ṣiṣẹ́.
Matawalle ló sọ ọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Maradun.
Gẹgẹ bii ohun ti gomina ọhun sọ, oṣoṣu ni ijọba n san owo fun ọ̀rìnlénígba (280) dokita ki aṣiri to tu pe dokita mọ́kànlélọ́gọ́rin (81) pere lo jẹ ojulowo ninu wọn.
O sọ siwaju si pe oun ti ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC ipinlẹ naa lati ṣawari awọn mọ́kàndínnígba ayederu dokita ọhun lọna ati dẹkun irufẹ iwa bẹẹ lọjọ iwaju.
Matawalle ni aṣiri awọn ayederu oṣiṣẹ naa tu lẹyin ti awọn bẹrẹ iforukọsilẹ gbogbo oṣiṣẹ ipinlẹ ọhun nibi ti wọn ti n gba oju ati ika wọn silẹ.
Gomina naa sọ pe igbesẹ ọhun ko ṣẹyin afojusun ijọba lati bẹrẹ eto lati maa san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, eyii to jẹ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
O ni “Ni kete ti a sọ pe a fẹ bẹrẹ si n san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, a o kan le maa san owo naa bẹyẹn, oni awọn igbesẹ ti a gbọdọ tẹle.”
Báńkì àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí kéde afìkún àsìkò tí owó àtijọ́ yóò kúró nílẹ̀
Ọrẹ Òtítọ́jù
Gómìnà Báńkì Orílẹ̀ yìí, Godwin Emefiele ti kéde pé ìjoba ti fi kún gbèdéke àsìkò tí wọn yóó kó owó àtijọ́ kúrò nílẹ̀ báyìí.
Emefiele ṣàlàyé pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari ni wỌ́n pinnu láti fi kún iye ọjọ́ tí wọn yóó kó owó náà kúò nílẹ̀ pátápátá.
Saaju ni wọn ti kede ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 gẹgẹ bi ọjọ to gbẹyin ṣugbọn bayii, wọn ti sun un siwaju di ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023.
Emefiele dupẹ lọwọ Buhari fun atilẹyin to sẹ fun un lasiko to n gbe igbesẹ akọni yii .
Emefiele tun salaye pe o ti to ida 75% ninu ọgọrun un owo atijọ to ti wọle bayii
Ati pe oun gbe igbesẹ naa ki odiwọn iye nnkan ti owo naira le ra ati agbara rẹ le gbe pẹẹli sii ni.
O ni yoo tun dena agbara owo ti awon ajinigbe n gba bii owo itusilẹ ni eyi ti yoo ran awon oṣiṣẹ alaabo lọwọ lati maa ri wọn mu lasiko.
Ojọ kẹwaa, oṣu keji ọdun yii ni wọn ko ni le maa na owo atijọ mọ nigboro Naijiria.
Emefiele sọ pe awọn ti ri 1.9 tirillion ninu 2.7 trillion to ha sita gba wọle pada ni Naijiria bayii.
Emefiele sọ pe to ba tun ti di ọjọ kẹwaa, oṣu keji si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2023 yii ni awọn eeyan ṣi ni oore ọfẹ lati paarọ owo atijọ wọn si tuntun ni banki Naijiria apapọ ti a mọ si Central Bank of Nigeria.
Ọṣe kan ni CBN tun ya kalẹ lati ṣe paṣipaarọ owo naa titi yoo fi kasẹ nilẹ tan lẹyin asiko gbedeke tuntun yii
Ẹ gbájúmọ́ ohun tí ẹ ní fárá ìlú lásìkò ìpolongo ìbò dípò èébú—Afẹ́nifẹ́re
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ètò ìdìbò gbogbogboò níbi tí àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò ti tún máa yan àwọn adarí tuntun tí yóò tukọ̀ orílẹ̀ èdè yìí àti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan fún ọdún mẹ́rin mìíràn, ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ti kọminú lórí bí ìwà ìpáǹle ṣe ń gbilẹ̀ níbi ètò ìpolongo ìbò láàárín àwọn olóṣèlú.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Afẹ́nifẹ́re, Jare Ajayi fi léde lọ́jọ́ Àìkú, Afẹ́nifẹ́re ní àwọn nǹkan tí àwọn olùdíje fẹ́ ṣe fún ará ìlú ló yẹ kí wọ́n gbájúmọ́ níbi àwọn ètò ìpolongo ìbò wọn dípò títàbùkù ara ẹni.
Afẹ́nifẹ́re ní ìpèníjà tó ń kojú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí kọjá kí àwọn olùdíje kan máa tahùn síra wọn lásìkò tó yẹ kí wọ́n fi máa sọ ohun gbòógì tí wọ́n ní fún ìlú lọ.
Èèkàn ẹgbẹ́ ilẹ̀ Yorùbá yìí ní lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àwọn olùdíje kàn ń sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn ni tí wọ́n bá dé òde láti polongo ìbò àti pé ìgbésẹ̀ yìí ti ń fa ìjà láàárín àwọn olólùfẹ́ wọn.
Wọ́n ní níbi tí òṣèlú Nàìjíríà dé dúró lónìí, kò yẹ kí àwọn olóṣèlú pàápàá àwọn tó ń wá ipò kan tàbí òmíràn ṣì wà ní ìpele tó jẹ́ wí pé èébú ni wọ́n ń bu ara wọn dípò kí wọ́n máa sọ ohun táwọn ara ìlú fẹ́ gbọ́.
Ajayi nínú àtẹ̀jáde náà fi kun pé àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí àwọn olúdíje àti àwọn agbẹnusọ wọn ń sọ sí ara wọn ń fún àwọn alátìlẹyìn wọn ní ìgboyà láti máa ṣèkọlù síra wọn èyí tó le fa ìtàjẹ̀sílẹ̀.
Ó tẹ̀síwájú pé onírúurú àwọn fídíò tó ń ṣàfihàn ìwà ipá tí àwọn ènìyàn ń wù síra ló ti ń gbòde lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí tó sì ní òpin gbọ́dọ̀ débá àwọn ìwà yìí tí ìdìbò gbogbogboò yóò bá lọ ní ìrọ̀wọ́rọsẹ̀.
Nígbà tó ń fi ìkọnilóminú rẹ̀ hàn lórí àwọn ìwà ìpáǹle yìí pẹ̀lú gbogbo ìwé àdéhùn àláfíà tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yìí tọwọ́bọ̀ pó kò ní sí làásìgbò lásìkò ìbò, Ajayi ní ìwádìí fi hàn pé kò dí ní ọmọ Nàìjíríà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ láàsìgbò òṣèlú lọ́dún 2022 nìkan.
Bákan náà ló fi kun pé olùbádámọ̀ràn Ààrẹ Muhammadu Buhari lórí ètò ààbò, Babagana Monguno náà fìdí i rẹ̀ múlẹ̀ ìkọlù méjìléláàdọ́ta láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ló wáyé láàárín oṣù kan péré ìyẹn láàárín oṣù Kẹwàá sí oṣù Kọkànlá ọdún tó kọjá.
Afẹ́nifẹ́re wá pàrọwà sí àwọn olùdíje àtàwọn olóṣèlú láti jìnà síwà bóobá a o pá, kí wọ́n gbájúmọ́ ètò tí wọ́n ní fún ìlú láti tán ìṣẹ́ àti òṣì tó ń bá àwọn ọmọ Nàìjíríà fínra.
Òkú tó sọnù níléèwòsàn è̩kó̩ṣé̩ ìṣègùn OOUTH ni Ṣagamu gbo̩dò̩ di rírí – Dokita Oluwabunmi Fatungaṣe
Láti ọwó̩ Adefunkẹ Adebiyi
Latari oku obinrin kan to deede di awati nileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo, Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital (OOUTH) to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, eyi to mu meji ninu awọn oṣiṣẹ to n ṣọ abala ibi toku naa wa sa lọ raurau, awọn alaṣẹ OOUTH ti ṣeleri pe awọn yoo wadii iṣẹlẹ naa delẹ, awọn yoo wa oku naa ri, awọn yoo si fi oju ẹnikẹni to ba jẹbi hande.
Ṣe lọjọ Ẹti to kọja ti i ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn,oṣu kin-in-ni ọdun 2023 yii ni awọn mọlẹbi oku naa lọ sileewosan OOUTH lati gba oku wọn ki wọn si sin in.
Oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni wọn ti gbe oku naa sibẹ gẹgẹ bi awọn mọlẹbi obinrin to ṣalaisi naa ṣe sọ.
Ṣugbọn si iyalẹnu awọn ẹbi oku,niṣe lawọn oṣiṣẹ OOUTH ko ri oku naa gbe jade. Oku mọkandinlaadọrin la gbọ pe wọn ko jade fawọn eeyan oku ti wọn wa sọsibitu naa, ṣugbọn ko si ti obinrin naa nibẹ rara.
Nigba ti iṣẹlẹ ọhun yoo si mu ifura dani patapata, meji ninu awọn oṣiṣẹ to n mojuto awọn oku naa tun sa lọ raurau, ẹnikẹni ko si ri wọn pe lori aago mọ.
Iṣẹlẹ yii di tọlọpaa ipinlẹ Ogun, iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati mọ ohun to ṣẹlẹ ti oku fi sọnu, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lati ri awọn oṣiṣẹ to na papa bora naa mu.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ iyanu yii, ọga agba lọsibitu OOUTH,Dokita Oluwabunmi Fatungaṣe,ṣaleye ninu atẹjade to fi sita, pe gbogbo ipa lawọn ti n sa lati wadii ohun to fa a ti oku fi sọnu.
Dokita Fatungaṣe sọ ọ di mimọ pe awọn alaṣẹ ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun yii ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹka tọrọ kan lati fidi otitọ mulẹ.
Bẹẹ lo ni awọn ti n ṣiṣẹ lori ẹrọ ayaworan ti wọn n pe ni CCTV to wa nileewosan yii, lori awọn aworan to ti ka silẹ.
Nibi ti ati ri oku naa ṣe koko lọkan awọn alaṣẹ OOUTH de, Fatungaṣe sọ pe awọn yoo ṣe ayẹwo DNA fawọn oku to wa nibẹ, lati da oku ti wọn n wa yii mọ.
O fi kun un pe ijọba ipinlẹ Ogun ti ro ileewosan yii lagbara pẹlu awọn irinṣẹ igbalode ati ohun elo tawọn nilo, idi naa si niyẹn to fi di aayo awọn eeyan. O ni iru ohun to ṣẹlẹ yii ṣajoji pupọ,ko si ni i lọ bẹẹ lai yanju.
O waa bẹ awọn eeyan oku ati gbogbo ẹni tọrọ yii kan, pe ki wọn ni suuru pẹlu ileewosan yii, awọn yoo wa oku wọn jade, awọn yoo si gbe e fun wọn lati sin in lọna ẹyẹ laipẹ rara.
Igbiyanju wa lati ba Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọrọ lati mọ ibi to de duro labala awọn ọlọpaa ko seso rere rara,Alukoro ko gbe ipe ta a fi ṣọwọ si i.
N’Ilaro, Abiọdun jale ni ṣọọṣi, o tun wọle meji ji foonu
Adefunkẹ Adebiyi
Ọmọkùnrin yii, Abiọdun Elegbede tọjọ orí rẹ ko ju mọkandinlogun (19) lọ lo ti wa lahaamọ awọn olópàá niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun bayii, ìyẹn lẹyin t’awọn fijilante So-Safe mu un l’Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kin-ni-ni ọdún yii, pe o fọ̀ ṣọọṣi jale ladugboo Agọ Ararọmi, Ilaro, bẹẹ lo sí tun ja awọn ile meji mi-in lole laduugbo kan naa.
Ọga agba fún So-Safe, Kọmandanti Sọji Ganzallo, ṣalaye ninu atẹjade ti ACC Moruf Yusuf ti i ṣe alukoro ajọ naa fọwọ si, pe awọn kan ni wọn pe So-Safe nigba ti wọn kofiri oju ọmọkùnrin kan ti wọn o mọ ri,to si jẹ awọn nnkan bii foonu merin ti dawati nibi t’awọn oninnkan ko wọn sì, ọwọ ẹlẹgiri naa ni wọn si ti ba wọn.
Nigba ti ikọọ fijilante ti SC Ọjẹrinde Wasiu ko sodi de’bẹ lo di mimọ pe Abiọdun Elegbede lọmọkunrin to jale naa n jẹ. Ati pe Ajegunlẹ lo n gbe, n’Ipobẹ, ijọba ibilẹ Ipokia nipinlẹ Ogun kan naa.
Awọn eeyan ti fi lulu da bira si i lara gidi k’awọn So-Safe too de, awọn agbofinro naa ni wọn pada gba a silẹ pẹlu foonu Itel mẹrin ti wọn ba lọwọ rẹ, kia ni wọn sì ti fa a le awọn olópàá teṣan Ilaro lọwọ fun itẹsiwaju iwadii ati bi yoo ṣe dele-ẹjọ.
Ilé-ẹjọ́ Kò-tẹ́-mi-lọ́rùn yóó fẹ̀tọ́ ọ wa léwa lọ́wọ́-Adeleke
Ọrẹ Òtítọ́jù
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ademọla Adeleke, ti sọ pé ìdájọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni èyí tí ìgbìmọ̀ to ń gbọ́ ẹ̀sùn tó sú yọ nínú ètò ìpínlẹ̀ náà tó wáyé lọ́dún tó kọjá dá. Ó ní òun yóó pe ẹjọ́ ọ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn lórí ìdájọ́ ọ̀hún.
Nigba to n sọrọ lori idajọ to gba ipo lọwọ rẹ ọhun, Akọwe iroyin Adeleke to sọrọ lorukọ gomina, Ọlawale Rasheed, sọ pe ibo adiju ti ile-ẹjọ naa gbe idajọ wọn le lori ti wọn fi ni Oyetọla lo bori lodi si ifẹ inu awọn oludibo ti wọn dibo wọn lọpọ yanturu fun oun.
Adeleke waa fọkan awọn ololufẹ rẹ balẹ, o ni ki wọn ma ṣe bẹru, bẹẹ ni ki wọn ma foya, nitori oun yoo pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ta ko idajọ naa. O fi kun un pe oun ṣi ni gomina ipinlẹ Ọṣun, ko si si ohunkohun to le yọ ohun nipo naa, nitori awọn araalu ni wọn fi ibo gbe oun wọle.
Adeleke ni, ‘‘Mo fẹẹ rọ ẹyin eeyan mi pe ki ẹ ni suru, a maa pe ẹjọ ta ko idajọ naa, mo si gbagbọ pe idajọ ododo yoo tẹ wa lọwọ. Mo fi n da ẹyin eeyan mi loju pe gbogbo ohun to ba yẹ lati ṣe ni a maa ṣe lati ri i pe ifẹ inu awọn eeyan ti wọn fi ibo yan wa ko bọ sọnu’’.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni olori igbimọ to n gbọ ẹjọ to su yọ lasiko idibo, Onidaajọ Tetsea Kume, sọ nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ pe ajọ eleto idibo ko tẹle ilana ati ofin ti orileede wa n tẹle lori eto idibo, bakan naa ni wọn ṣe lodi sofin eto idbo ti wọn ṣatunṣe si.
Igbimọ naa ni leyin ti awọn yọ adiju ibo, Oyetọla ni ibo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun o le mẹrinla ati diẹ, nigba ti Adeleke ni ibo ọọdunrun din mẹwaa ati diẹ (290,266).
Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti wọn kede Adeleke gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun to kọja ni Oyetọla ati ẹgbẹ APC ti gba kootu lọ, ti wọn ni adiju ibo waye lawọn ibi kan, ati pe Adeleke ko ni iwe-ẹri to kunju oṣuwọn lati dupo gomina l’Ọṣun, wọn ni ayederu ni iwe-ẹri to ni.
Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ wẹ Adeleke mọ lori ọrọ iwe-ẹri, ọkunrin ọmọ bibi ilu Ẹdẹ naa ko le mori bọ nibi ọrọ adiju ibo.
INEC ṣàfikún ọjọ́ tí àwọn aráàlú lè fi gba PVC wọn
Ọrẹ Akínṣọlá
Àjọ elétò ìdìbò, INEC, ti ṣe àfikún ọjọ́ tí àwọn aráàlú lè fi gba káàdì ìdìbò alálòpẹ́, ẹ PVC, wọn.
Ṣaájú ni INEC ti kọ́kọ́ sọ pé ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Kínní ọdún yìí ni àwọn yóó fòpin sí gbíga PVC náà kó tó sún síwájú pẹ̀lú ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn.
Ni bayii, INEC tun ti sọ pe awọn araalu le maa gba PVC ọhun titi di ọjọ karun un, oṣu Keji, ọdun 2022 yii.
Ninu atẹjade kan ti INEC fi ṣọwọ si awọn akọroyin lẹyin ipade kan to waye niluu Abuja lo ti kede bẹẹ.
Kọmiṣọna ajọ naa, Festus Okoye ni alaga ajọ ọhun, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ ki awọn eeyan le ri gba kaadi naa gba.
Atẹjade naa ni “Lẹyin awọn iroyin to n tẹ wa lọwọ kaakiri awọn ọọfisi wa, a ti pinnu lati fi ọsẹ kan kun iye ọjọ ti awọn araalu le fi gba PVC wọn.”
“Nitori naa, awọn araalu lanfani lati maa gba kaadi naa titi di ọjọ karun un, oṣu keji, ọdun 2023 yii.”
Okoye fi kun pe “Igba keji ree ti ajọ yii yoo sun ọjọ ti gbigba kaadi naa yoo dopin siwaju kaakiri Naijiria, eyii si ni igba ikẹyin ti yoo ṣe bẹẹ.
Yatọ si pe INEC ṣe afikun ọjọ ti awọn eeyan le gba PVC wọn, ajọ naa tun fi wakati meji kun iye akoko ti awọn eeyan le maa gba kaadi naa.
To n tumọ si pe ni bayii, gbigba kaadi naa yoo bẹrẹ lati aago mẹsan an aarọ titi di aago marun un irọlẹ ni gbogbo ọjọ to wa ninu ọsṣe, lai yọ ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku silẹ.
Fó̩nrán síse kò dúnkokò mó̩ ìpani lé̩rìn-ín aládúróse – Bovi
Mary Fágbohùn
Aderinposonu aladurose Naijiria, osere, ati onkowe, Abovi Ugboma, ti a mo si Bovi, ti so pe ona lati fonran sise ko idunkoko mo iderinpani aladurose.
Ninu iforowero kan pelu Midweek Entertainment, Bovi wi pe saaju ayelujara, fonran sise ni won n lo lati se igbelaruge ere itage iderinpani aladurose, o fi kun n pe o je ohun ti ko mu ogbon wa fun awon eniyan lati ro pe fonran sise je ihale fun iderinpani aladuro se.
O wi pe, “Fonran n hale mo iderinpani aladurose je ironu omugo. Fonran je fonran ati pe iderinpani aladurose je iderinpani aladurose. Fonran ti wa tipe, saaju ki ayelujara to de.
” Mi o mo ibi ti iwoye naa ti wa pe ikan n pakan lara, o je ohun ti ko mu ogbon kankan wa, mo si korira iru awuyewuye bee nitori pe saaju ayelujara, a n lo fonran lati se igbelaruge awon iderinpani aladurose wa, awon eniyan le e wo fonran ki won tun wa wo wa lori itage bi a ti n derin paniyan.
“Gbogbo ere iderinpani ti won se ni odun to koja, ni won ta tiketi re tan ti fonran re si lo kaakiri, nitori naa tani eni to mu aba wa pe ikan n je gaba lori ika? Ko mu opolo kankan wa ati pe mi o ro pe mo fe lati soro nipa eyi mo.”
Nigba ti o n se alaye siwaju si i, aderinposonu aladurose naa wi pe awon eniyan le e gbiyanju ohun ti won ba fe lai bo enikan mole.
O wi pe, “Gegebi eniyan, ohunkohun ti o ba lero pe o le e se, o gbodo gbiyanju re wo. Awon eniyan kan n se fonran, awon kan n derin pani lori iduro, awon kan je osere, onkowe, ati olugberejade, bi temi.
” Awon eniyan kan je olorin, osere tiata, ati aderinposonu, nitori naa ohun ti o ba mo nipa re, se e. Ti o ba se oriire, o dara o si sunwon, bi bee ko, gbiyanju re leekan si, ti o ba si ro pe o ko le e se ni opo igba, dekun sise re. O je akorohin loni, o si pinnu lati beere ere sise; gbiyanju re. Ta lo n pin aala? Ko si, nitori naa, ki lo de ti a n bo awon kan mole? Gbogbo eniyan ni a ki kaabo, aba temi re.”