Ọmọ Ìgbò gbàjọba nínú ọkàn Ìyábọ̀ Òjó
.
Gbajugbaja oserebinrin Yoruba ni, Iyabo Ojo, ti gbe awon ti bo si agbami ife, bi o ti se fi ololufe re tuntun han.
Lori atedaje kan lori ero ayelujare, o fi han pe ololufe tuntun naa wa lati eya miran ati pe kii se omokunrin Yoruba.
Obinrin ti o ti bi meji naa so wi pe omokunrin Igbo kan ni o pada wole si oun lara. Eni ti o dupe lowo re fun fife ti o fe lopo ati bi o se n gbe emi re soke.
O ko o wi pe:
“O seun ifemi fun fife ti o fe mi ati gbigbe emi mi soke…
Kai, okan omobinrin Yoruba yi ni omokunrin Igbo kan ti wole si.”
Alice Iyabo Ojo ni o je oserebinrin, adari, ati olugbe ere jade. O ti sere ninu fiimu bii aadojo, pelu bii merinla ti o se laye ara re.
Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ lórí ìrìnàjò rẹ̀ nínú isẹ tíátà
Gbajumo oserekunrin ni, Muyiwa Ademola, ti so wi pe ebun atinuda re ti o sowon ni asiri ti o wa leyin bi oun se di ilumooka.
Ninu ijomitoro oro kan pelu iwe iroyin Punch, oserekunrin naa wi pe, “Mo ti n sere o ti le ni ogbon odun. Bi mo ba ni ki n ka akoko mi ni ile owe Girama pelu re, a o maa wo odun marundinlogoji. Ore ofe Olorun ni. Irinajo naa ko dan monran bi o ti ri. Sugbon, mo je ki ori mi duro lorun mi, mi o si yese nitori mo mo pe ebun atinuda mi sowon. Mo ti n ko itan lati igba ti mo ti wa ni ile iwe akokobere, eyi ni o si kimi laya lati tepa mo ise mi ni ile ise fiimu. Mo dupe lowo Olorun fun ibi ti mo wa bayii, mo si n lepa lati se pupo sii.”
Lori ohun ti o fun ni iwuri lati tesiwaju ninu ere tiata,
Ademola wi pe, “Fun mi, ere sise je gege bi ipe. O ma n dabi wi pe mi o pe ti mo ba gbiyanju lati se nnkan miran, nitorina mo ti pinnu lokan mi pe ere sise je ifarasin ti mo gbodo muse. Ohunkohun miran ti mo ba se, ma maa se pelu ere tiata ni. Inu mi dun pe gbogbo fiimu mi ti fowokan opolopo aye, bi opolopo ti mu eko ninu fiimu mi bii idiwon fun bi won yoo sese awon ohun kan ninu aye won.”
Gbenga Daniel fẹ́ kí Ìjọba Àpapọ̀ gba ìsàkóso Film Village tí Hubert Ogunde dá sílẹ̀
Gomina ipinle Ogun teleri, Otunba Gbenga Daniel, ti ke pe ijoba apapo lati tete gba ase lori abule fiimu, ìyẹn film village, ti o wa ni Ososa, ni Ìpínlẹ̀ Ogun, ti ogunna gbongbo eléré orí ìtàgé ni, Oloogbe Hubert Ogunde, da sílẹ̀.
O wi pe o se pataki fun ijoba lati se atunse ere agbelewo ati ile ise idaraya ni orile ede yi fun ere goboi and anfaani ti o po fun awon omo nibe.
Danieli, eni ti o je oludije fun ile igbimo asofin ti apa ila orun ipinle Ogun labe asia egbe oselu All Progressives Congress (APC), soro nibi eto idanilokowo kan ti o je okan lara awon ise ti Ijoba ibile Odogbolu ni ipinle naa seto.
Gegebi o se so, ipinle Ogun ni o bi opolopo awon osere ni orile ede Nigeria ti o si n tesiwaju lati je ibudo idaraya lagbaye.
O fi ireti re han pe atilehin ti o dan monran lati odo ijoba apapo, ile ise fiimu ati idaraya lai si ani ani yoo se iranlowo lati pese ise tabua ati nitori ki oro aje le e ma a dagba si nigbogbo igba ati idagbasoke orile ede yi.
Gomina teleri naa ranni leti bi oloogbe Ogunde, eni ti o je omo bibi Ososa, ni agbegbe ijoba ibile Odogbolu, ko ipa asaaju pataki ati irapada ere itage sise ni Nigeria, o fikun pe ohun ti a mo si fiimu agbelewo ni a le to ipase re lo si ise takuntakun akoni naa.
O wi pe, “ipinle Ogun n tesiwaju la ti maa je ibudo idaraya lagbaye. Ohun tuntun lati apa keji ti a n se ajoyo re lagbaye wa lati odo wa. Nigba ti inu wa n dun lati pin awon ebun abinibi pelu gbogbo aye, awa la ni i. E so nipa Olamide, D’banj, Kizz Daniel, Laycon, Fireboy DML, Asa, Wande Coal ati Reminisce, larin awon to ku, wa lati ibi”.
“Bi a ti se dari odun 1970, 1980, ati 1990 pelu awon bii Ebenezer Obey, Fela, Haruna Ishola, Wasiu Ayinde Marshal, Sir Shina Peters, Adewale Ayuba, Salawa Abeni, Batile Alake, Tope Alabi, bee ni a tun je adari lode oni. Kii wa se torin nikan o; ninu ere agbelewo lonii ni a ti ni awon oje bii Tunde Kelani, Yemi Shodimu, ati opolopo eniyan lati ipinle yii.
“Ipinle Ogun ni o ye ki a fun ni ero pataki ninu idagbasoke ile ise idaraya. Ajo igbimo ere ati asa lorile ede yi (NCAC) ni o ye ki o gba ase lori abule fiimu ni Ososa lati le e ma ri owo na daradara.
Danieli salaye pe larin awon eto amulo re lo si ile igbimo asoju ni lati mu ki ijoba apapo ni ife si ati se atilehin fun idagbasoke abule fiimu ni Ososa. O toka si pe eka ere agbelewo ti ile oke okun ati ti India ni o ti mu owo jaburata wole fun orile ede wonyi, o fikun pe Nigeria naa le e je ere yanturu lati eka ere agbelewo nipase sise idagbasoke ile ise na.
Oludije fun ile igbimo asoju naa jeje lati gbaruku ti abadofin ati eto imulo ti yoo gbe ile ise idaraya goke agba ti yoo si so eso eredi idasile re.
O wi pe, “Ohun nla kan ti o n ti eto oro aje ile America ni ere agbelewo, ohun nla kan ti o n ti eto oro aje ile India ni ere agbelewo. Bayii a ni ere agbelewo ti wa, ti won si n se daadaa. Nitorina, gbogbo isoro ainise ni ile yi, a le e lo awon ebun abinibi ti a ni ni ipinle Ogun.
“Lara ohun ti ano o se ni Abuja ni lati ti ijoba apapo lati wa gbaruku ti ominira abule fiimu ti a ni ni Ososa ti ijoba ibile Odogbolu.”