Home Blog Page 105
Sanwo-Olu pelu Ara

Mary Seunfunmi Fagbohun

Gomina Babajide Sanwo-Olu ni Ojoruu, iyen Alaaruba, ni anfaani lati fi ijo re han nigba ti obinrin inilu, Ara, ba a lalejo.

Bi Ara se n lu ni Sanwo-Olu n jo, ti tapa-tese re si n ba gangan mu.

Arabinrin naa, Araoluwa Olumuyiwa lo si odo Sanwo-Olu lori awon omo alarinka to ti kojo, to n se eto iwuri fun.

Ijoba Eko lo n ran an lowo lori eto yii.

Gomina wa ro awon omobinrin ati omokunrin igboro ti won gba sile naa lati ma dekun lori ala won lati di eni nla lawujo.

Sanwo-Olu gba won niyanju ni ile ijoba ni Ikeja, Eko, nigba ti o gba alejo ayanbinrin ti oruko re gangan n je, Aralola Olumuyiwa, ati awon omo ti o n gbe popona ti o gba mora ti o si gba sile labe eto “Eko wu mi lori” eyi ti ijoba ipinle Eko n se atileyin fun.

Die lara won je eni ti awon obi won ko ko mora ati awon ti ipinya wa laarin ebi won. Awon miiran kuro nile nitori iya asilo, nigba ti awon miiran gba lati jiya loju popo leyin ti baba ati iya won ku tan.

Gbogbo ala won ati ireti won ni o di korofo, won wa di aninilara kiri adugbo, won si ri won gegebi ewu ilu ki won to gba won sile.

Awon ti oro kan naa ni igbe aye won ti n yi pada si rere nipase eto “Eko wu mi lori” ti Gomina Sanwo-Olu se atileyin fun. Gomina naa ro awon ti won gba sile naa lati mase so ireti nu lori ala won, sugbon ki won se amulo eto naa lati le e mu ki ebun abinibi won ru gege si i.

Gomina gboriyin fun ayanbinrin naa fun dida eto ti o n gba awon omo popona naa la, o si jeje lati gbaruku ti eto naa ati pe yoo lo o fun awokose rere lati mu ki awujo tesiwaju.

Sanwo-Olu fwa owosi ipese elo ise ati irinse fun ogorun lara awon omo naa ninu ise ti onikaluku won yan laayo.

 

Ikú òjijì: Mọ̀lẹ́bí Sammie Okposo gbà f’Ọ́lọ́run. Wọ́n ní ańgẹ́lì ló ń bá kọrin báyìí.

Okposo

Mary Seunfunmi Fagbohun

Molebi akorin igbala to gbese lojo die seyin, Sammie Okposo, ti soro lori ipapoda re o.

Won ni  olokiki olorin ihinrere naa ti lo ba Olorun re, koda, won ni awon angeli lo n ba korin po bayii.

“A tu ara wa ninu nitori ti a mo pe odo Jesu lo wa ti o si n korin pelu awon angeli,” ni won so ninu oro won lojo Eti, ninu iwe ikede kan ti Hecter Okposo bu owo lu.

O ni,  “Pelu okan wuwo sugbon pelu ijowo fun Olorun ni mo fi kede ipapoda oko, baba, egbon, aburo wa owon ati iranse Olorun, Sammie Okposo, eni ti o sun ninu Oluwa ti o si lo ba Oluwa pade ni ojo Eti, ojo karundinlogbon osu kokanla, odun 2022.

“A tu ara wa ninu nitori ti a mo pe odo Jesu lo wa ti o si n korin pelu awon angeli. A toro aaye fun molebi naa lati kedun ni alafia ni akoko yii.”

O ga ju! Sanwo-Olu ki ijo mole bo se gba obinrin onilu Ara lalejo.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ni Ojoruu, iyen Alaaruba, ni anfaani lati fi ijo re han nigba ti obinrin inilu, Ara, ba a lalejo.

Bi Ara se n lu ni Sanwo-Olu n jo, ti tapa-tese re si n ba gangan mu.

Arabinrin naa, Araoluwa Olumuyiwa lo si odo Sanwo-Olu lori awon omo alarinka to ti kojo, to n se eto iwuri fun.

Ilé aṣòfin America buwọ́lu ìgbèyáwò akọsákọ, abosábo.

Ilé aṣòfin America buwọ́lu ìgbèyáwò akọsákọ, abosábo.

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní bí òpin ayé bá ń kànkùn gbọ̀ngbọ̀n,àgbọ́damiẹnu ìròyìn letí yóó má á gbọ́.
Ṣùgbọ́n o,òfin tí a fi dá ìlú n náà la fi í ṣèlú, èyí ló díá fún bílé aṣòfin àgbà ní orílẹ̀-èdè America, ti buwọ́lu òfin tí yóó dáàbò bo ìgbéyàwó àwọn èèyàn tó ń fẹ́ irú wọn, àti ìgbéyàwó àwọn tí kìí se ẹ̀yà kan náà.

Ofin naa yoo lọ si ile igbimọ asoju-sofin, ti ireti wa pe yoo buwọlu, ti yoo si fi ranṣẹ si Aarẹ Biden lati fi àṣẹ si. Àwọn to ṣe agbatẹru ofin naa ni ireti pe yoo di àṣẹ, saaju kí ẹgbẹ́ oṣelu Republican to gbakoso ile aṣòfin ni oṣu Kínní. Sugbọn ṣa, ofin naa ko fi dandan si pe gbogbo ipinlẹ gbọdọ fi ontẹ lu igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin. Ofin tuntun yii fi ẹsẹ mulẹ lasiko ti ile ẹjọ́ to ga julọ ni America wọgile òfin ìjọba apapọ to n ṣe atilẹyin fun oyún ṣiṣẹ. Lati igba naa ni awọn to n polongo igbeyawo LGBT ti n fi ibẹru han pe igbeyawo naa le koju idunkoooko lọjọ iwaju. Asofin mẹtadinlọgọrun lo dibo lọjọ Iṣẹgun, ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu Republican mejila ninu wọn silo faramọ. Àwọn aṣòfin Republican kan fi ara mọ lẹyin ti wọn ṣe atunse si lati faaye gba ominira ẹ̀sìn.

Olori ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu to pọju nílé aṣòfin agba, Chuck Schumer, gbóríyìn fun igbeṣẹ awọn aṣòfin, to si sapejuwe òfin tuntun naa gẹgẹ bi igbeṣẹ si igbe aye to dọgba. “Bi buwọ lu ofin yii tumọ si pe gbogbo ọmọ America lo ni ẹtọ kan naa, lai naani iru eeyan ti wọn jẹ tabi ẹni tí wọ́n nifẹ si – ìwọ naa ni ẹtọ si itọju kan naa ati apọnle lábẹ́ òfin.” Sẹnetọ Tammy Baldwin, ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu Democrats, to jẹ Sẹnetọ akọkọ to fi ara rẹ han ni ẹni tó fẹ́ràn ìbálòpọ̀ ọkùnrin si ọkùnrin, lo ṣe agbatẹru òfin naa. O ni ofin tuntun yii yoo daabo bo akitiyan fun anfaani kan naa fun orisirisi igbeyawo ni America.

Òfin tuntun yii ni yoo ka ile ẹjọ́ to ga julọ lápá kò, to ba gbiyanju lati wọgile igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tàbí obìnrin si obìnrin lọjọ iwaju. Ofin tuntun naa tako òfin ti wọn ṣe lọdun 1996, Defense of Marriage Act, eyi to pàṣẹ pe laarin ọkùnrin ati obinrin nìkan ni igbeyawo gbọdọ ti ma a waye. Ile ẹjọ́ to ga julọ dajọ lọdun 2013 pe òfin naa ko ba òfin òfin orile-ede mu. Ofin tuntun yii tún pa a ni dandan fun awọn ipinlẹ lati tẹwọgba igbeyawo LGBT ti wọn ṣe ni ipinlẹ mii, kí wọ́n si fun tọkọtaya naa ni àwọn anfaani ijọba apapọ.

Àmọ̀tẹ́kùn já wọ aginjù àwọn ajínigbé l’Ọ́yọ̀ọ́, wọ́n da èròngbà wọn rú

Àmọ̀tẹ́kùn já wọ aginjù àwọn ajínigbé l’Ọ́yọ̀ọ́, wọ́n da èròngbà wọn rú

Ọrẹ Òtítọ́jù

Pẹ̀lú ìgbìyànjú ìjọba tówà lóde báyìí làábẹ́ ìṣèjọba Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ó súnmọ́ kí fulenge fulenge àwọn ajínigbé dínkù bí ikọ̀ elétò ààbò ilẹ̀ Yorùbá, Àmọ̀tẹ́kùn ìpínlẹ̀ ọ̀hún, ṣe ya wọ ibùba àwọn kọ̀lọ̀rànsí ajínigbé nínú aginjù,tí wọ́n sì palẹ̀ ẹ àwọn nǹkan ìjà olóró wọn lọ.

Oludari agba awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju lo fidi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ajọ naa ni Mọniya, n’Ibadan, lọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Ninu ipade oniroyin ọhun lọga awọn agbofinro yii ti sọ pe aṣeyọri ọhun waye latari awọn iṣẹlẹ ijinigbe kan to n waye lẹnu lọọlọọ yii, paapaa, eyi to waye loju ọna Ibadan si Eko laipẹ yii, eyi to mu ki awọn Amọtẹkun bẹrẹ si i fọ gbogbo aginju igbo ipinlẹ Ọyọ kaakiri lati wa awọn ọbayejẹ eeyan naa .

O jọ pe awọn agbesunmọmi paapaa ti gburoo pe awọn agbofinro n wa awọn kiri inu igbo, ni wọn ṣe sa asala fẹmi-in ara wọn lai duro gbe awọn nnkan eelo wọn.

Iyẹn lawọn Amọtẹkun ṣe deede kan baagi nla kan ninu aginju igbo, nigba ti wọn yoo si yẹ ẹ wo, ibọn ajamamaala AK47 mẹrin pẹlu ọta ibọn to le ni aadọta (50) lo wa nibẹ.

Bakan naa ni wọn ba aṣọ awọn soja to jẹ toke-tilẹ meji ninu apo ọhun, ati fila awọn ọmọ-ogun oju ofurufu ilẹ yii kan pẹlu igbo ati ọti buruku kan bayii ti wọn n pe ni kolorado.

Gẹgẹ bi Ajagun-fẹyinti Ọlayanju ṣe ṣalaye “Gbogbo wa la mọ bi eto aabo ṣe ri lasiko yii, paapaa lọna Ibadan si Eko. Gomina ba wa sọrọ, o ni ka lọọ ṣe gbogbo ohun ta a ba le ṣe lati ri i pe aabo wa fun awọn eeyan ati dukia wọn.

“A gbe ikọ oniwadii kalẹ lati wa awọn inu igbo kaakiri ipinlẹ yii, koda, a de Eko, awa pẹlu awọn ọlọpaa Eko si jọ forikori lori ba a ṣe le fọ awujọ wa mọ kuro lọwọ awọn ajinigbe atawọn ọdaran gbogbo.

“Lọjọ Jimọ ọsẹ to kọja la gbọ pe wọn ri awọn kan to dihamọra pẹlu ibọn nibi kan nipinlẹ Ọyọ nibi, mo ran awọn eeyan wa lọ sibẹ pẹlu awọn fjilante, wọn ni awọn ko ri eeyan nibẹ ṣugbọn awọn ri ijasa pe awọn eeyan kan n ṣe nnkan kan nibẹ nitori wọn ri awọn ọra omi ninu igbo nibẹ. Mo waa ni ki wọn lọọ tun ibẹ wa daadaa.

Nigba ti wọn waa pada lọ, wọn foonu mi pe awọn ri baagi kan ninu igbo, baagi yẹn si wuwo. Mo ni emi naa ti n bọ. A waa lọọ lugọ de awọn ọdaran to n lo awọn aginju igbo wọnyi fun iṣẹ ibi, a ko ri wọn, a tun wa wọn kaakiri inu igbo, a ko ri wọn.

“Nigba ta a yẹ baagi yẹn wo a ri i pe ibọn AK 47 mẹrin, ati ọta pẹlu awọn aṣọ ṣọja pẹlu igbo ati ọti ti wọn n pe ni kolorado lo wa ninu baagi yẹn. Igbo ati ọti ti wọn n mu yẹn lo jọ pe o maa n jẹ ki oju wọn ranko ti wọn fi maa n huwa ọdaran”.

O waa gboṣuba fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde fun atilẹyin to n ṣe fun awọn Amọtẹkun lati le pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn ara ipinlẹ naa.

Ninu ọrọ tiẹ, ọga ọlọpaa to ti fẹyinti, CP Fatai Owoṣeni, to jẹ oludamọran fun gomina Makinde lori eto aabo, fi awọn araalu lọkan balẹ lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya.

Ọ ni pẹlu awọn nnkan ija awọn ajinigbe ti awọn Amọtẹkun ti ko yii, ẹru yoo ti maa ba awọn ọdaran to ni wọn paapaa nitori niṣe lo da bii igba ti awọn Amọtẹkun ti gba agbara lọwọ wọn.

Àwọn ará ìlú bèèrè fún ìpèsè iṣẹ́ bí Ààrẹ ṣe ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní Bauchi àti Gombe

Àwọn ará ìlú bèèrè fún ìpèsè iṣẹ́ bí Ààrẹ ṣe ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní Bauchi àti Gombe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Bauchi àti Gombe ní ìlà oòrùn àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti rọ ìjọba Nàìjíríà láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà bí ìjọba yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní àwọn ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn ènìyàn náà nígbà tí wọ́n ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ohun tó ń jẹ́ àwọn níyà ní ìpínlẹ̀ àwọn ni àìníṣẹ́.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní agbègbè Kolmani tó jẹ́ ààlà Bauchi àti Gombe.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, arákùnrin kan, Usman Tahir ní ó ti pẹ́ tí inú òun ti dùn báyìí kẹ́yìn nítorí ó ti pẹ́ tí àwọn ti ń dúró kí ètò wíwa epo rọ̀bì wáyé ní agbègbè àwọn.

Tahir ní láti ìgbà tí àwọn ti wà ní kékeré ni wọ́n ti máa ń sọ fún àwọn wí pé epo rọ̀bì wà ní ìpínlẹ̀ àwọn ṣùgbọ́n tí wọn kò wà á títí di ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó ní àmọ́ ohun tó kù fún báyìí ni kí ìjọba bá àwọn ṣe ọ̀nà láti wá iṣẹ́ fún àwọn.

“Ìpínlẹ̀ wa wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn tí kò níṣẹ́ pọ̀ sí jùlọ àti pé ọ̀nà láti yọ àwọn ènìyàn kúrò nínú ìṣẹ́ ni ṣíṣe àwárí epo rọ̀bì náà yẹ kó jẹ́.”

Ní ti Adamu Warji ní tirẹ̀, ó rọ ìjọba láti ṣe òótọ́ láti pèsè iṣẹ́ òdodo fún àwọn ènìyàn nítorí àwọn kò fẹ́ kí irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn ààrin gbùngùn gúúsù ṣẹlẹ̀ sí àwọn náà.

“Àǹfàní ṣíṣe àwárí epo rọ̀bì la fẹ́ jẹ, a ò fẹ́ ohun tí yóò ba ilẹ̀ wa jẹ́.”

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ikọ̀ ìròyìn tó wà ní Kolmani sọ, ó ní lẹ́yìn tí Ààrẹ Buhari ṣe ìfilọ́lẹ̀ náà tán ni wíwá epo yóò tún tẹ̀síwájú láti mọ ibi tí epo rọ̀bì náà pẹ̀ka dé.

Ní ọdún 2016 ní wọ́n bẹ̀rẹ̀ wíwá epo rọ̀bì ní àríwá Nàìjíríà léyìí tó ṣe àfihàn rẹ̀ wí pé epo rọ̀bì wà ní àwọn ìpínlẹ̀ Bauchi, Gombe, Borno àti Niger.

Àjọ NNPC ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo rọ̀bì tí wọn kò ì típi ṣe àwárí ló wà ní àwọn ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà ni èròńgbà wà pé wọn yóò kọ́ ilé iṣẹ́ ìfọpo rọ̀bì sí agbègbè náà láti máa fọ epo rọ̀bì.

Gómìnà tuntun l’Ó̩sun f’ò̩nà ìta han O̩ba mé̩ta àti àwo̩n òsìsé̩ tó lé ní e̩gbè̩rún méjìlá

Gómìnà tuntun l’Ó̩sun f’ò̩nà ìta han O̩ba mé̩ta àti àwo̩n òsìsé̩ tó lé ní e̩gbè̩rún méjìlá

Yínká Àlàbí

Ana ode yii ni Senetor Ademola Adeleke gb’o̩pa ase̩ ipinle̩ O̩sun.
Oni o̩jo̩ keji ti ko ti i pe wakati merinlelogun tii se o̩jo̩ kan lo ti fi o̩na ita han gbogbo awo̩n osise ti gomina te̩le̩ ni ipinle̩ naa, O̩gbe̩ni Gboyega Oyetola gba sise̩ lati o̩jo̩ ke̩tadinlogun, osu keje o̩dun yii. Awo̩n osise̩ naa le ni e̩gbe̩run mejila. Awo̩n O̩ba ilu me̩ta ti awo̩n naa gbo̩do̩ fi apere sile̩ naa ni Akirun ti ilu lkirun, Aree ti Iree ati O̩wa ti Igbajo̩.
O̩ba me̩waa, igba me̩waa ni awo̩n agba Yoruba maa n wi, eyi lo n se̩le̩ lo̩wo̩ bayii ni ipinle̩ O̩sun. Abi “wo̩n ko saa le f’iyan joye awodi ko ma le gb’adiye̩”.

Ìjọba bó ẹgba sídìí obìnrin mẹ́ta, ọkùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n ká ẹ̀sùn àgbèrè mọ́ lọ́wọ́

Ìjọba bó ẹgba sídìí obìnrin mẹ́ta, ọkùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n ká ẹ̀sùn àgbèrè mọ́ lọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé n tí ò dá a ò lórúkọ méjì,bẹ́ ẹ̀ ìlú tí ó bá ń tẹ̀lé òfin, dájú sáká,ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹ bẹ̀ kò ní-ín lọ láì jìyà.
Èyí ló díá fún bí obìnrin mẹ́ta àti ọkùnrin mẹ́sàn án kan ṣe rí ìyà he lọ́wọ́ ìjọba Taiban, bí wọ́n ṣe dín dùǹdú ìyà fún wọn níwájú ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wá wo bọ́ọ̀lù lórí i pápá ní orílẹ̀-èdè Afghanistan.

Iléeṣẹ́ agbófinró ní orílẹ̀-èdè ọ̀hún sọ fún iléeṣẹ́ akọ̀ròyìn pé àwọn ẹgbẹ́ náà jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè síse, olè jíjà àti ìbá ọkùnrin lòpọ̀.

Ìgbà kejì rè é tí ìjọba Taliban yóó má a lu àwọn ẹlẹ́sẹ ní ìta gbangba.

Omar Mansoor Mujahid, agbẹnusọ ìjọba ọ̀hún ní àwọn obìnrin tó wà lára àwọn ọ̀daràn ni àwọn ti tú sílẹ̀ lẹ́yìn tì wọ́n jẹ̀yà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn sùgbọ́n ,díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin ọ̀hún sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Ó ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹlẹ́sẹ̀ náà jẹ ẹgba tó mọ́kànlélógún sí mọ́kàndínlógójì. Ó ní ẹni tó jẹ jù ni ẹni tó jẹ mọ́kàndínlógójì.

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni èèyàn mọ́kàndínlógún mìíràn jẹ irúfẹ́ ìyà yìí ní agbègbè Takhar ní àríwá orílẹ̀-èdè Afghanistan.

Ìléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwé ìrìnnà ní Nàìjíríà ti gbà láti máa ṣí ní Sátidé

Ìléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwé ìrìnnà ní Nàìjíríà ti gbà láti máa ṣí ní Sátidé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ tó n ríísí ètò ìwé ìrìnnà lórílẹ̀ èdè yìí Naijiria, NIS ti fún àwọn iléeṣẹ́ wọn ní àṣẹ láti máa ṣí ní Ọjọ́ Sátidé.

Adarí iléeṣẹ́ Nigeria Immigration Service(NIS) ló fi àṣẹ ọ̀hún léde nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi léde.

Níbẹ̀ náà ni wọ́n ti ṣàlàyé pé ìgbéṣẹ̀ ọ̀hún yóó fún àwọn èèyàn ní àǹfààní láti gba ìwé ìrìnnà wọn ní àsìkò.

‘’Ìgbìyànjú wa ni pé kì ìrọọ̀rùn wà fún àwọn ènìyàn láti gba ìwé ìrìnnà wọn tó ti wà ní ìkáwọ́ wa láti ìgbà pípẹ́.

‘’A rí i pé ìdíwọ́ wà láti ìgbà tí àrùn-un ajàmámààlà n nì , kòrónáfairọ̀ọ̀sì ti gbòde kan, eléyìí tó fa ìṣéde nígbà náà lọ́hù-ún, tí a kò sì ráàyè ṣiṣẹ́ dà bí alárà, èyí mú ìdíwọ́ bá àwọn èèyàn tó yẹ kí wọ́n rìrìnàjò tí wọn kò sì rí ìwé ìrìnnà an wọn gbà.’’

‘’Ìdánilójú wà pé tí àwọn òṣìṣẹ́ wa bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ ní Sátidé yóó mù-ún ìrrọ̀rùn bá gbígba ìwé ìrìnnà àwọn aráàlú.’’

Bákan náà ni wọ́n kéde pé àwọn ti gbé àwọn adarí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọn méjì ní ìpínlẹ̀ Ondo àti Èkìtì kí iṣẹ́ lè tẹ̀síwájú ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Yóò nira fún APC láti borí Makinde ní Oyo àmọ́ … – El-Rufai

Yóò nira fún APC láti borí Makinde ní Oyo àmọ́ … – El-Rufai

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kàdúná, Nasir El-Rufai ti ní APC ní láti ṣán ṣòkòtò o wọn le bí wọ́n yóó bá fi ẹ̀yìn-in Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó n tukọ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP janlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀.

Loju ọpọlọpọ, eyi da bii ki eeyan ni ẹnikan ri ootọ nilẹ ti ko si fi bo rara koda ko pa oun gan lara lọna kan tabi omiiran.

“Yoo nira fun ẹgbẹ oṣelu APC lati bori Gomina Seyi Makinde ni ipinlẹ Ọyọ.”

Nibi akanṣe eto idagbere fun oludari agba ileeṣẹ to n ri si eto ọgbin alarobọ, Nteranya Sangiga eyi to waye nilu Ibadan ni El-Rufai ti sọ ọrọ naa lọjọ Ẹti.

El-Rufai ranti bi oun ati Makinde nibi ipade igbimọ alaṣẹ ṣe n fa ọrọ boya ki wọn fi awọn ipinlẹ sinu isede Covid19.

“Lẹyin itakurọsọ yii, mo pada lọ si ipinlẹ temi mo si lọ kede isede. Seyi pada lọ si ipinlẹ tirẹ o si lọ ṣe nnkan ti o pe ni “isede oniha kan”, ṣugbọn ni ti ara rẹ, o se ara rẹ mọle toripe o lugbadi arun Covid.”

El-Rufai ni ẹwa to wa ninu Naijiria ni oniruuru aṣa ati iṣe eniyan lọtọọtọ, o ni oun ṣe nnkan ti oun lero pe o dara, bẹẹ si ni oun naa ṣe nnkan to dara fun ipinlẹ rẹ.

El-Rufai ṣapejuwe Seyi Makinde ati Akinwumi Adesina ti Banki idagbasoke ilẹ Afirika gẹgẹ akinkanju to n fi ipa rere silẹ to si ni wọn n fun awọn ọmọ Afirika ni ireti pe Afirika lee di ohun to ba fẹ da to ba ṣiṣẹ karakara.

Nigba to n sọrọ Gomina Seyi Makinde ni nnkan aladun ni fun oun lati sisẹ pọ pẹlu ajọ IITA lori oniruuru iṣẹ akanṣe lati mu ọrọ aje ipinlẹ naa buyaari sii nipasẹ awọn iṣẹ akanṣe ati lati gba awọn ọdọ nimọran ki wọn ṣamulo ẹka naa.

Seyi Makinde naa fi lede pe ọpọlọpọ lo jẹ ẹkọ latara akẹgbẹ rẹ Gomina El-Rufai to ṣapejuwe gẹgẹ bii eeyan nla to ni oye ati ifarajin pẹlu ipo adari rẹ.

Lẹyin to sọrọ nipa oniruuru ibadọrẹ ati ajọṣepọ to laami laaka to ti waye laarin oun ati El-Rufai, Seyi bọ sori ọrọ idibo.

“Asiko eto idibo la wa yii, mo si fẹ lo anfani yii lati sọ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ pe bi wọn ba fun mi ni anfani mii si lati sin wọn, a o gbe akanṣe eto “Start Them Early” lọ sawọn ile ẹkọ mii nipinlẹ Ọyọ.”

Lara awọn ilumọọka mii to wa nibi eto ti Makinde ati El-Rufai ti pade yii ni Akinwumi Adesina, Aarẹ Banki idagbasoke ilẹ Afirikav(AFDB); Rashidi Ladoja, gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, ati aṣoju Aarẹ nigbakan ri ,Olusegun Obasanjo

Toyin Abrahams fi òùntẹ̀ ìbùkún lu ìgbéyàwó Davido àti Chioma.

Davido ati Chioma
Mary Seunfunmi Fagbohun
Gbajugbaja oserebinrin ni, Toyin Abraham, ti fi idunnu re han si iroyin igbeyawo olorin olokiki ni, Davido, ati iyawo re Chioma Rowland, eyi ti o waye leyin ti won padanu omokunrin won, Ifeanyi Adeleke.
Ifeanyi ni o rii sinu odo iwe ebi naa, ni Banana Island, ni ilu Eko ni bi ose die seyin.
Oserebinrin naa gbadura, o si ya ebi na si mimo ni ede Yoruba ninu atejade kan lori Instagram:
O ko o wipe; “Omo Ola @davido 👏👏
Ayo e akun, inu e a dun.
OLORUN a wa pelu iwo ati Chioma 🤲🤲
Ilopo lo na ilopo OLORUN maa fun yin 🔥🔥.”