Home Blog Page 102

Mr Macaroni ń dúnkokò láti se òsèré tíátà Deyemi Okanlawon lése.

Mr Macaroni ń dúnkokò láti se òsèré tíátà Deyemi Okanlawon lése.

Mary Fágbohùn

Ilumooka aderinposonu, Adebowale Adedayo so pe Deyemi bi oun ninu pupo.

O sapejuwe osere naa bii “okunrin to buru to si je odaju.”

Lori Twitter o wi pe, “Egbon, @_deyemi e n mu inu bi mi gidi. Ti mo ba ri yin ni igboro maa se yin lese. Eniyan buruku ati odaju ni e je.”

Amo sa, ninu oro miran lori Twitter, Mr Macaroni tan imole si i pe oun n soro lori ipa ti Deyemi ko gege bi “Folarin ninu fiimu Biodun Stephen tuntun SISTA.”

Koriya ni aworan emi ati iko̩ Barcelona kii se igberaga – Rema

Koriya ni aworan emi ati iko̩ Barcelona kii se igberaga – Rema

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria, Divine Ikubor, ti a mo si Rema, ti soro lori jijade re pelu awon olugbafe eye La Liga, Barcelona laipe yi.

E ranti pe olorin ‘Calm Down’ naa sere jade pelu awon agbaboolu Barcelona nigba ti won n se igbaradi won kan ibi ti won ti fun ni aso Barca eyi to je tire.

Asopo yi lo ti fa orisirisi ifesi lori ayelujara pelu bi opo eniyan se n so pe o fi idi ipo Rema mule pe onirawo agbaye ni.

Nigba to fi fonran ijade won on lede ni ori Twitter ni ojo Abameta, Rema tan imole si oro naa pe igbese ti oun gbe naa kii se lati seruba awon akegbe oun sugbon lati fi se moriya fun awon miran.

O wi pe, “Kii se lati mu ki ara ta enikeni, koriya ni mi se. @FCBarcelona #ultra.”

Burna Boy lé Wizkid bá, ó sì ko̩já rè̩ bí olórin Naijiria tí wó̩n wò jù

Burna Boy lé Wizkid bá, ó sì ko̩já rè̩ bí olórin Naijiria tí wó̩n wò jù

Mary Fágbohùn

Olorin olugbafe eye Grammy, Burna Boy bayii ti di olorin Naijiria ti a wo julo ni gbogbo oju awe ti a le e fi oju ri ti a ti n wo orin.

Atojo naa ni ate to leke ni Afrika (Top Chart Africa) se ni ojo Eti.

Burna Boy leke atojo Olorin Naijiria ti won wo ju (Most Streamed Nigerian Artistes) lori oju awe ti a le e fi oju ri pelu bilionu lona me̩jo̩ o le meta-din-ni-aadota akojopo wiwo(8.47 billion), eyi ti Wizkid tele pelu bilionu lona mejo o le mokandinlogoji wiwo(8.39 billion).

Davido ni bilionu meta o le merin-din-ni-ogorin (3.76 billion), Rema (bilionu meta o le meta-din-ni-aadorin), ati CKay (bilionu meta o le meji-din-ni-ogbon) to fi pe marun-un to leke.

Tekno, Flavour ati P-Square ni a ropo kuro ni ipo kewaa akoko to leke nigba ti Tems, Omah Lay ati Asake jade.

Ilé ayé dàrú nígbà tí o̩ko̩ mi fún olólùfé̩ rè̩ té̩lè̩rí lóyún – Toke Makinwa

Ilé ayé dàrú nígbà tí o̩ko̩ mi fún olólùfé̩ rè̩ té̩lè̩rí lóyún – Toke Makinwa

Mary Fágbohùn

Ilumooka osere tiata, Toke Makinwa, ti safihan pe oun ni ibanuje leyin ti oun mo pe oko oun ti oun ko sile, Maje Ayida, fun orebinrin re teleri loyun.

O so pe oun mo si oyun naa nigba ti o pe osu mesan-an.

Osere naa so eyi lori eto re alatelera eyi to se laipe yi lori YouTube vlog, Toke Moments.

E ranti pe oun ati oko re, Ayida, fi ara won sile ni odun 2015, amo sa, won tun igbeyawo naa ka ni odun 2017.

O so pe ise oun nikan lo tu oun ninu, nitori naa oun duro lori pe ise sise bo ti le je pe oun ni imolara ibanuje okan leyin ti oun mo si aisooto oko oun.

Makinwa so pe, “Mo ro pe iyen (ise mi) ni nnkan to dami loju ni aye. Gbogbo awon nnkan to ku to jora lo kuna.

“Mo ranti pe mo wole si inu yara igbohunsafefe (asoromagbesi), ni nnkan bii aago meje aaro Irohin Agbaye si n lo lowo. Mo si gba ipe kan lati odo eni to ni ile-ise asoromagbesi, o wi pe, ‘gbogbo eniyan n soro nipa re, mi o fe dasi sugbon awon eniyan n wo o pe nnkan le e daru fun o. Mo ro pe o ye ki o maa lo si ile.”

O so pe oun le e sise nitori pe oun tete ko pe “ki oun fi imolara oun sile si egbe ilekun ki oun si pada gbe won ti oun ba ti n lo si ile. Nitori naa, ti o ba ti wo yara igbohunsafefe, kii se nipa tire. Gbogbo re da lori awon ogooro eniyan ti won wa loju ona ise won; awon ni won n yi si ikanni ti won si n reti pe ki won da won lara ya, ki won fi oro to n lo to won leti, gbogbo nnkan to n sele ni agbaye.”

 

Kò sí o̩jó̩ ò̩la — Wizkid fi àlá kàyééfì rè̩ léde

Kò sí o̩jó̩ ò̩la — Wizkid fi àlá kàyééfì rè̩ léde

Mary Fágbohùn

Gbajugbaja olorin Naijiria Ayodeji Ibrahim Balogun, ti a mo nidi ise re si Wizkid, ti fi ala kayeefi to la lede.

Lori opolopo atejade lori itan Instagram re ni Ojobo, olorin naa so pe oun la ala pe ko si ojo ola.

Nigba to n so ala naa, Wizkid wi pe “Ko si ojo ola. E duro, e maa ro. Loooto, e ro o.

“Mo la ala pe ko si ojo ola. Gbogbo wa parapo a n wa ojo ola.”

Amo sa olorin to ti gba opolopo ife eye , ko so bi ala naa se lo ni pato.

Wizkid lo di olokiki leyin to gbe orin re ‘Holla At Your Boy’, jade, orin kan lati inu ‘Superstar’, awo orin re akoko.

Ìdí tí àdéhùn ìgbéyàwó mi se forísánpó̩n – Osere Moet Abebe

Ìdí tí àdéhùn ìgbéyàwó mi se forísánpó̩n – Osere Moet Abebe

Mary Fágbohùn

Ilumooka asakojopo fonran ati osere Naijiria, Laura Monyeazo Abebe, ti a mo si Moet Abebe, ti safihan pe oun ti se adehun igbeyawo tele sugbon to kuna.

Gege bi o se so, o ye ki oun ti se igbeyawo bayii sugbon nnkan ko jora laarin oun ati afesona oun teleri.

O safihan eyi ninu ijiroro pelu atokun eto, Chude Jideonwo.

Agbohunsafefe lori mohunmaworan naa so pe oun fi ibasepo naa sile nitori asilo.

O wi pe, “O ye ki n ti ni obinrin to ni ade lori bayii.

“Mo se adehun igbeyawo sugbon ko sise. Ati pe, o je ibasepo to kun fun iwa ipa. Mo wa ri pe kii se nnkan ti mo fe fun ara mi niyi.

“Mo wa ninu ibasepo naa fun bii odun meji ati abo. Kii se pe enikeni wa lati fa mi kuro (ninu ibasepo naa), mo kan ro o pe ko gbodo tesiwaju.

 

 

Àwọn Ọ̀ba aládé kórajọ ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu

Àwọn Ọ̀ba aládé kórajọ ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Sultan ìlú Sokoto, Alhaji Muhammadu Saad Abubakar kẹta ti ní ẹrù tó wà lọ́rùn Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu báyìí kọjá sísọ pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́ yìí.

Lásìkò tí àwọn ọba aládé àti ọrùn ilẹ̀kẹ̀ ṣe ìpàdé pẹ̀lú Tinubu ní ilé ìjọba, Abuja lọ́jọ́ Ẹtì ni Sultan sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Kẹfà ni Tinubu ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́balọ́ba ní gbogbo ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà orílẹ̀ èdè yìí èyí tí Sultan ìlú Sokoto kó sòdí lọ sọ́dọ̀ Ààrẹ.

Alhaji Saad Abubakar sọ àrídájú rẹ̀ fún Ààrẹ pé gbogbo àtìlẹyìn àti ìrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí àwọn ṣe fún ìjọba ni àwọn ti ṣetán láti ṣe kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lè tẹ̀ síwájú.

Ó ní gbogbo ìgbà tí Ààrẹ bá ti nílò àwọn ni àwọn ṣetán láti dáa lóhùn.

Ó fi kún pé àwọn ní ìgbàgbọ́ pé Nàìjíríà lábẹ́ ìdarí Tinubu yóò so èso rere fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi rọ Tinubu láti ṣe àmúlò àwọn lọ́balọ́ba fún àwọn ètò kọ̀ọ̀kan pàápàá nípa ètò ààbò.

Makinde fi òpópónà Akobo-Olorunda sọrí Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike

Makinde fi òpópónà Akobo-Olorunda sọrí Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde lọ́jọ́ Ẹtì sọrí òpópónà oní Ìbejì Akobo,Ojurin/Odogbo Barracks Olounda Abaa ní orúkọ Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nysome Wike.

Gómìnà sọ eléyìí lásìkò tó ń se ìfilọ́lẹ̀ òpópónà náà nílùú Ìbàdàn.

Ojú ọ̀nà ní ìgbàgbọ́ wà pé yóó parí láàrin oṣù méjìlá, tí yóó sì ná ìjọba ní bílíọ̀nù mẹ́sàn àti díẹ̀ ní owó náírà.

Makinde ní ìdá ọgbọ̀n nínú owó ojú ọ̀nà náà ni ìjọba ti san fún agbasẹ́se náà láti lè jára mọ́ iṣẹ́.

Ó tún wá fi dá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lójú pé ìjọba òun kò ní dẹ́kun síse iṣẹ́ ìdàgbàsókè tí yóó se ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní fún ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

NLC kò yọjú,TUC, ìjọba ṣèpàdé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ

NLC kò yọjú,TUC, ìjọba ṣèpàdé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí ti ní àwọn yóò ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC gbé síwájú àwọn tó fi mọ́ owó oṣù tó kéré jùlọ.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti TUC èyí tó wáyé fún bíi wákàtí mẹ́ta, Agbẹnusọ ìjọba àpapọ̀, Dele Alake ní àwọn máa wò ó tó bá jẹ́ wí pé àwọn ìbéèrè jẹ́ ohun tí ìjọba le ṣe àmúṣẹ rẹ̀.

Ó ní lára nǹkan tí ìjọba ń rò láti ṣe tẹ́lẹ̀ láti mú ìdẹ̀kùn báwọn lórí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí wọ́n yọ ni láti fi ojú fo owó orí fún wọn fún ìgbà kan ná.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé náà.

Alake ní ohun tó dájú ni pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò gbé ìgbìmọ̀ kan dìde èyí tí àwọn ìpínlẹ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò ní aṣojú níbẹ̀, tí wọn yóò sì jíròrò lórí owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ.

Ó ṣàlàyé pé kò sí aáwọ̀ láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nigeria Labour Congress, NLC lórí ìbéèrè wọn pé kí ìjọba fowo kún owó òṣìṣẹ́.

Bákan náà ló fi kun pé bí NLC kò ṣe sí níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Àìkú kò túmọ̀ sí pé wọ́n fojú kéré wọn.

Agbẹnusọ Tinubu ní ìjọba àpapọ̀ tún ti ń gbìyànjú láti kàn sí wọn fún ìpàdé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ẹ̀wẹ̀, TUC nínú ìbéèrè tí wọ́n gbé síwájú ìjọba àpapọ̀ ní kí ìjọba dá owó epo padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀ kí ìjíròrò fi wáyé láàárín wọn.

Ààrẹ TUC, Festus Osifo ní àwọn ní ìrètí pé ìjọba àpapọ̀ yóò gbọ́ tàwọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe ìlérí pàápàá lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ tí òṣìṣẹ́ yóò máa gbà.

Ọ̀gá méjì ò lè wakọ̀ kan ṣoṣo ni mo fi yọ Auxiliary nípò – Makinde

Ọ̀gá méjì ò lè wakọ̀ kan ṣoṣo ni mo fi yọ Auxiliary nípò – Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bí gbogbo nnkan bá yí padà, bí n ó ṣe ṣe nnkan mi nìyí kò yí padà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣàlàyé ìdí tó fi ní kí alága tẹ́lẹ̀ rí fún gááràjì ní ìpínlẹ̀ náà, Alhaji Mukaila Lamidi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Auxiliary lọ rọ́kún nílé.

Makinde ní ọba kò lè pé méjì láàfin ni òun fi fọwọ́ òsì júwe ilé fún Auxiliary.

Níbi ètò ìsìn ìdúpẹ́ fún ìbúrawọlé sáà kejì rẹ̀ ní ilé ìjọsìn Cathedral of St. Peter, Aremo, Ibadan lọ́jọ́ Àìkú ni Seyi Makinde ti sọ̀rọ̀ náà.

Makinde sọ àrídájú rẹ̀ wí pé ìjọba yóò ṣe àfọ̀mọ́ àwọn gáréèjì àti pé gbogbo àwọn tó ń da ìlú láàmú ni àwọn máa fi òfin gbé.

Ó ṣàlàyé pé kí ètò ìdìbò tó wáyé ni àwọn ti pe àwọn alókòóso gáréèjì sí ìpàdé láti ṣe ìkìlọ̀ fún wọn pé àwọn kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa fa wàhálà.

“A ṣàlàyé fún wọn pé tí a bá wọlé fún sáà kejì, a máa ri dájú pé àláfíà jọba, tí a máa ri pé ìrẹ́pọ̀ wà láàárín wọn.”

“Ẹnìkan ló fárígá pé òun kò lè bá àwọn yòókù ṣe, èmi náà sì sọ pé ìjọba méjì kò lè máa ṣàkóso ìlú kan.”