Home Blog Page 101

Àwọn alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà

Àwọn alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní olè kò ní-ín jà gbà, kó má ṣe é lójú fìrí,
amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbà fún Gómìnà Akeredolu lórí ọrọ̀ àkànṣe iṣẹ́, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ti bu ẹnu àtẹ lu àwọn olóṣèlú kan tó ní wọ́n ń ṣe ìpàdé bonkẹlẹ kiri láti fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo lólè

Ọmọwe Ọdẹbọwale nínú atẹjade kan èyí tó fi síta ṣàlàyé pé àwọn olóṣèlú kan ní ìpínlẹ̀ Ondo ń lo àìsíńlé ologini Gómìnà Akeredolu láti fi sọ araa wọn di èkúté ilé tó fẹ́ ti ẹnu bọ aṣuwọn ìpínlẹ̀ náà,

Ó ní ọgbọn tí àwọn olóṣèlú ọhún ń dá ni láti dá iná èdè àìyédè sílẹ̀ láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan lọnà àti leè fi gba àkóso agbára ní ìpínlẹ̀ náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ OAU kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé àkọ́kù

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ OAU kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé àkọ́kù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Treasure Salako.

Ní ọjọ́rú ni ìròyìn ní wọ́n bá òkú Treasure ní ilé àkọ́kù kan ní agbègbè Lagere, Ile Ife, ìpínlẹ̀ Osun.

Bákan náà ni wọ́n ní wọ́n bá ìgò ogun apẹ̀fọn sniper ní ẹ̀gbẹ́ òkú ọmọbìnrin náà tí ọ̀pọ̀ sì ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

Àmọ́ agbenusọ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola nígbà tó ń bá iléeṣẹ́ PUNCH sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú ọmọbìnrin náà.

Opalola ní àwọn ti gbé òkú Treasure sí ilé ìgbókùúpamọ́sí tí ilé ìwòsàn olùkọ́ni OAUTH, Ile Ife.

Ó ní nítorí àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà ni wọ́n fi ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

Ó ṣàlàyé pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú náà láti le fìdí ohun tó gba ẹ̀mí Treasure.

Ó fi kun pé gbogbo àwọn nǹkan tó bá yẹ kí àwọn ṣe ni àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, alukoro OAU, Abiodun Olanrewaju ní kìí ṣe inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé tó sì bá àwọn òbí ọmọbìnrin náà kẹ́dùn lórí àdánù ńlá náà.

Olanrewaju ní ikú Treasure kò dùn mọ́ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà nínú rárá.

Bákan náà ló rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù àti àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti máa ṣe àmójútó ara wọn, kí wọ́n sì máa wòye ẹni tó bá wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn dáradára.

Ó fi kun pé nǹkan tí àwọn gbọ́ ni pé ọmọbìnrin náà ń la àwọn ìdojúkọ kan kọjá èyí tó fa ìporúru ọkàn fún un bóyá nítorí náà ló ṣe gba ẹ̀mí ara rẹ̀.

Ó ní “a bá àwọn òbí Treasure kẹ́dùn, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni gbé irú ìgbésẹ̀ yìí bí ó ti wù kí nǹkan tí onítọ̀hún bá ń là kọjá ṣe lè lágbára tó.”

Abdulrasheed Bawa wà ní àhámọ́ DSS fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kò

Abdulrasheed Bawa wà ní àhámọ́ DSS fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bí ọrọ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Alága àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu, EFCC, Abdulrasheed Bawa ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìyẹn DSS.

Lẹ́yìn tí Ààrẹ Tinubu fọwọ́ òsì ilé júwe fún Bawa ni DSS ránṣẹ́ pè é láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn.

Ìròyìn ní alẹ́ pátápátá lọ́jọ́rú ni Bawa balẹ̀ sí àgọ́ àwọn DSS náà.

Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya, nínú àtẹ̀jáde kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Bawa ti wà ní àhámọ́ àjọ àwọn.

Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ti ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Bawa lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

“DSS ti ránṣẹ́ pé alága EFCC tí Ààrẹ ní kó lọ rọ́kún nílé.”

“Bawa ti wà ní àgọ́ wa báyìí, àwọn nnkan tí a torí rẹ̀ pe Bawa kò ṣẹ̀yìn àwọn ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ nípa rẹ̀.” Afunanya sọ nínú àtẹ̀jáde náà.

Tinubu yọ alága EFCC, Abdulrasheed Bawa nípò

Tinubu yọ alága EFCC, Abdulrasheed Bawa nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn EFCC, Abdulrasheed Bawa.

Tinubu ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé fún àìní gbèdéke ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ààrẹ ní nítorí à ti fún àwọn tó ń ṣe ìwádìí Bawa láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ ni òun fi ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn lọ́kan-ò-jọ̀kan, èyí tó lágbára kan Bawa.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbenusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní Ààrẹ ní kí Bawa kó gbogbo àkóso àjọ náà lé adarí ètò gbogbo lọ́wọ́ títí tí wọ́n máa fi parí ìwádìí Bawa.
Abdulrasheed Bawa ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tí wọ́n máa yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà àjọ EFCC láti ìgbà tí wọ́n ti dá àjọ náà sílẹ̀ lọ́dún 2003.

Ọmọ ogójì ọdún ni Bawa wà nígbà tó fi máa gba ipò náà nínú oṣù Keje ọdún 2020 lẹ́yìn tí Ààrẹ àná, Muhammadu Buhari yọ Ibrahim Magu lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.

Láti ọdún 2005 ni Bawa ti gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ́físà ní EFCC.

Òun ni ó ṣe ìwádìí ẹ̀sùn màkàrúrù owó tabua tí wọ́n fi kan Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ́rọ̀ epo rọ̀bì, Diezani Alison-Madueke.

Ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, kó tó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè fún ẹ̀kọ́ onípò kejì.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti òṣìṣẹ́ yóò máa wọkọ ọfẹ ní Kwara—-Gómìnà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti òṣìṣẹ́ yóò máa wọkọ ọfẹ ní Kwara—-Gómìnà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní ọmọ onílù ú kò níín fẹ kó tú ,láti mú kí irọrun dé bá àwọn aráàlú, pàápàá jù lọ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe gbowó lórí nítorí owó ìrànwọ́ epo tí wọ́n yọ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulraman AbdulRazaq, ti sọ pé láti Ọjọ́, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹfà, ọdún 2023 yìí, ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga níìpínlẹ̀ náà, pàápàá jù lọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì wọn, Kwara State University (KWASU), àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láwọn ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún yóó bẹ̀rẹ̀ sí i máa wọkọ̀ ọ̀fẹ́ lọ síbi iṣẹ́ wọn láàrin inú ìlú Ìlọrin àti gbogbo àgbègbè rẹ̀.

Lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹfà, ọdún yìí, ni AbdulRazaq fi àtẹ̀jáde yìí léde fáwọn oníròyìn látọwọ́ Akọ̀wé ìròyìn rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Rafiu Ajakaye.

Nínú àtẹ̀jáde náà ni Gómìnà ti sọ pé láti Ọjọ́rú, ìjọba yóò kó àwọn bọ́ọ̀sì nlá sáwọn ààyè kan nílùú Ìlọrin, tí yóó máa kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ wọn lọ́ fẹ̀ẹ́ fún ìrọ̀rùn lílọ bíbọ̀ wọn. AbdulRazaq tẹ̀síwájú pé gbogbo ọ̀nà ni òun yóó sán láti rí i pé ìrọ̀rùn dé bá àwọn òṣìṣẹ́ àti gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ Kwara lápapọ̀, tí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà yóò sì máa rúgọ́gọ́ sí i. Ó fi kún un pé láìpẹ́, àwọn adarí iléeṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà yóò máa sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa ètò yìí kan náà.

Aláwo ni yóò padà ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà, ayaafi —Mimiko

Aláwo ni yóò padà ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà, ayaafi…..
—Mimiko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ ,wọ́n ní èèyàn tó wẹjú lẹ̀rù ń bà.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ondo, Olusegun Mimiko ti ṣèkìlọ̀ pé pẹ̀lú bí àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ṣe ń fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ lọ ilẹ̀ òkèrè le padà ṣe àkóbá ńlá fún ẹ̀ka ètò ìlera orílẹ̀ èdè yìí.

Mimiko sàsọyán rẹ̀ pé, tí Nàìjíríà kò bá tètè wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ àwọn dókítà tó ń fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀ ní lemọ́lemọ́ yìí, ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ náà bọ́ sódì tó bá máa fi tó ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sí àsìkò yìí.

Ó ní ó ṣeni láàánú pé ìjọba ń fi owó kún owó ẹ̀kọ́ àwọn dókítà yìí, síbẹ̀ ní kété tí wọ́n bá ti gba ìwé ẹ̀rí wọn ni wọ́n ń mórílé ilẹ̀ òkèrè.

Níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde àkọ́kọ́ àwọn dókítà ilé ẹ̀kọ́ giga University of Medical Sciences, UNIMED tó wà ní ìlú Ondo, ìpínlẹ̀ Ondo ni Mimiko ti sọ̀rọ̀ yìí.

Ó ní òun ṣe àgbékalẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà, lójúnà àti sàmójútó bí kò ṣe sí àwọn tó gbero iru nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Gomìnà tẹ́lẹ̀ rí náà rọ ìjọba láti tètè dìde sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí kìí ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.

Bákan náà ló fi kun pé ìjọba nílò láti máa ṣe kóríyá fún àwọn dókítà kí wọ́n yé fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ mọ́.

Ó tẹ̀síwájú pé tí ìjọba bá ń pèsè àwọn ohun tó le fa kóríyá fún àwọn dókítà yìí, wọn ò ní máa wá ilẹ̀ ọlọ́ràá lọ sí ilẹ̀ òkèrè mọ́.

Mimiko ní ìjáfàra léwu lórí ọ̀rọ̀ náà nítorí bí a kò bá ṣọ́ra, ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn babaláwo ni àwọn aláìsàn yóò máa wá ìtọ́jú lọ tó bá yá.

Ààrẹ Bola Tinubu yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ Gómìnà Báǹkì àpapọ̀

Ààrẹ Bola Tinubu yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ Gómìnà Báǹkì àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sí n tó níbẹ̀rẹ̀ tí kìí lópin, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti pàṣẹ fún Gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà (CBN), Godwin Emefiele pé kó lọ rọọ́kún nílé náà.

Àṣẹ Ààrẹ Tinubu farahàn nínú àtẹ̀jáde kan tí ọfíísì akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà fi síta lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì.

Àtẹ̀jáde náà tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé pé, Ààrẹ gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí ìwádìí tó ń lọ lọwọ́ lọ́fíìsì Gómìnà báńkì àpapọ ọ̀hún àti àwọn àtúntò tó fẹ́ wáyé lórí ẹ̀ka ìṣúná lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

“ Ààrẹ Bọla Tinubu ti pàṣẹ fún Gómìnà Banki àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele CFR pé kó lọ rọọ́kún nílé lẹ́yẹ ò ṣọkà.

“ Èyí ń wáyé nítorí ìwádìí tó ń lọ lówó lórí ọfíísì rẹ̀ àti àtúntò ẹ̀ka ìṣúná tí ìjọba ń gbèrò láti ṣe.”

Ó súnmọ́ kí n gbá ojú Kwankwaso bí a bá pàdé nílé Ààrẹ ní Abuja- Ganduje

Ó súnmọ́ kí n gbá ojú Kwankwaso bí a bá pàdé nílé Ààrẹ ní Abuja- Ganduje

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní àwo pẹ̀lẹ́ kìí fọ́,ìgbá pẹ̀lẹ́ kìí fàya. Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ti sọ pé kání òun àti ẹni tó di ipò náà mú saájú òun , ìyẹn Abdullahi Ganduje bá pàdé ara wọn ní ilé-iṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà, lọ́jọ́ Ẹtì tí àwọn méjèèjì lọ kó ẹjọ́ bá Ààrẹ ni, ó ṣeéṣe kí òun fọ́ ọ létí.

Ganduje sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó fi n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ipade rẹ pẹlu aarẹ Tinubu lọ́jọ́ Ẹtì.

Ganduje n bu ẹnu àtẹ́ lu Kwankwaso lori ohun to pe ni igbesẹ gomina to wa lode nipinlẹ naa lọwọ, Yusuf Abba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Kwankwaso, n gbe lati wo awọn ile kan nipinlẹ naa.

Kwankwaso ni olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP fún ìbò Aarẹ tó kọjá, ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ló sì borí ìbò Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kano.

Bákan náà ni Ganduje pẹ̀lú ti fi ìgbà kan ri jẹ́ igbákejì fún Kwankwaso nigba to di ipo gomina mu ni ipinlẹ Kano, ki tírélà tó gba Ààrin wọn kọjá.

“Mo mọ̀ pé ó wà ni agbègbè ile nla yii ṣugbọn a ko tii pade. Boya Ká ní a lọ pade ni , bóyá ìgbájú olóòyì ni ǹbá kó fún un.”

Ganduje ṣàlàyé pé, bóyá ló pé ọjọ́ mẹ́ta lẹyìn tí Abba Yusuf wọle gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ naa tó fi wo awọn ile mẹrin to jẹ ajumọni laarin ijọba at’awọn aladani kan ni Kano.

Ó ní òun ti fi ọ̀rọ̀ náà tó ọ̀gá agba iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí. Bákan náà ó ní òun ti ṣàlàyé gbogbo bí nnkan ṣe lọ lórí rẹ̀ fún Ààrẹ Bọla Tinubu.

Yvonne Jegede sò̩rò̩ sí oníròhìn ayélujára tó so̩ pé, ó se ìgbéyàwó pè̩lú Ned Nwoko

Yvonne Jegede sò̩rò̩ sí oníròhìn ayélujára tó so̩ pé, ó se ìgbéyàwó pè̩lú Ned Nwoko

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Yvonne Jegede ti soro lori irohin kan pe o se igbeyawo bonkele pelu Sinato Ned Nwoko, oko Regina Daniels.

Irohin jade si ori ayelujara pe Yvonne yo gbogbo aworan re kuro ni oju opo Instagram re leyin igbeyawo bonkele naa.
Sugbon osere naa ninu atejade kan ni ojo Eti wi pe iro to jinna si ooto ni, o fikun un pe onirohin naa fe ba oun loruko je ninu.

O ro awon omo Naijiria lati ma se gba gbogbo oun ti won ba ri ni ori ayelujara gbo.

Pelu aworan igbeyawo naa o wi pe, “Nigba ti won ba so fun yin pe won mo ‘nnkan’ to n sele tabi won gbagbo pe nnkan ti sele, e beere lowo won bawo ni won se mo, won a so fun yin pe won ka tabi won gbo lori ayelujara. Ni opo igba, won a gbo lati odo awon oponu bi eni to n soro ninu atejade itiju to kun fun iro yi.

“Bawo ni o se le ni igboya pelu iru iro yi? Bawo ni o se le e paro pelu igboya?

“Bawo ni o se le e moomo ba eniyan je ti o si ba ibasepo ti o ni pelu awon elomiran je nitori pe o fe ki awon eniyan maa ka irohin re?

“Atejade to n panilerin yi je nnkan buburu ati iro ni gbogbo ero. Mi o ni yo ara mi lenu lati ba o ja. Mo mo pe ofin pe oun ti o ba se ni wa a gba ti n daamu ayanmo re nitori pe bi o ba ni okan, o ni maa wa ona ati ba aye elomiran je nigba ti aye tire ko ni ojutu.

“Bawo ni yiyo aworan mi kuro lori ayelujara se da nkankan? Afojudi lati daruko omokunrin mi, o ye ki n gba oju re ni.”

Mi ò lè fè̩ o̩kùnrin tó jé̩ ‘o̩mo̩ mummy’ – Angela Eguavoen

Mi ò lè fè̩ o̩kùnrin tó jé̩ ‘o̩mo̩ mummy’ – Angela Eguavoen

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Angela Eguavoen, ti so pe oun o le e fe okunrin to ba n so mo eti aso iya re.

Ninu iforowero kan pelu Saturday Beats, o so pe, “Mi o le e fe okunrin to ba je omo iya re. O gbodo je okunrin ara re. Bee ni, mo fe okunrin to ni enikan ninu ebi re to bowo fun ti o si n gbo tire. O gbodo je eni to duro lori oro to so, kii se eni ti nnkan kekere le e yi lokan pada.”

Eguavoen fikun un pe oun ko le e gba= ebi kankan laaye ninu ile oun. “Ko si ebi kan to le e gbe pelu emi ati oko mi ayaafi ti won (iya oko mi) ba wa ni ailera ti won si nilo olutoju. Mo je obinrin ti owo re kun fun ise mi o kii se iru obinrin ti yoo jokoo sile lati toju enikan. Mo je eni to gbagbo pe ki awon ebi maa gbe ni odo tokotaya ti won ba sese se igbeyawo ko dara,” ni o so.

Nigba to n soro lori awon osere ti won n kerora pe ore oju po ni ile-ise naa, o so pe, “Mi o mo nipa won. Mi o ni ore to po. Mo ni die lara won bii ore won si je oloooto si mi. Mo gbagbo pe ore sise ko gbodo fi si odo enikan. Ti a (awa ore) ba n je lati odo ara wa, enikeji ko ni ro pe mo n lo oun.

“Sugbon, ni ona kan tabi omiran, enikan yoo se ju enikeji lo ni ipele kan. Amo sa, pe enikan n se daadaa ju enikeji lo ko tumo si pe won o le e se daadaa si.”