Home Blog Page 100

Ìpèníjà ńlá tí mo kojú láyé ni jíjẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà – Buhari

Ìpèníjà ńlá tí mo kojú láyé ni jíjẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà – Buhari
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti júwe ṣíṣe Ààrẹ
Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìpèníjà ńlá nínú ìgbésí ayé òun.

Buhari sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tó fi ránṣẹ́ sí àwọn Nàìjíríà.

Àtẹ̀jáde kan tí Mallam Garba Shehu fi síta lórúkọ Buhari rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbárùkù ti Tinubu kó lè ṣe àṣeyọrí

Ó ní ṣíṣe olórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ ohun tó le díẹ̀ àti pé jíjẹ́ olórí gba kí ènìyàn ní ìfarajìn kó sì rí àtìlẹyìn àwọn ènìyàn rẹ̀.

Lẹ́yìn náà ló kí àwọn Mùsùlùmí kú ayẹyẹ ọdún Iléyá, tó sì tún gbà á ní àdúrà pé ayọ̀ ni àwọn tó wà ní Mecca máa fi darí wálé.

Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Buhari fi ohùn kan léde pé ká ní òun yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ṣeéṣe kí Tinubu ma wọlé ìbò Ààrẹ.

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n ni Buhari gbé ìjọba Nàìjíríà kalẹ̀ fún Ààrẹ Tinubu ti ìlú dìbò yàn nínú ètò ìdìbò ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù kejì ọdún 2023.

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ 5,344.1Kg igbó nípìńlẹ̀ Èkó

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ 5,344.1Kg igbó nípìńlẹ̀ Èkó
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ṣoṣo ni ti olóhun bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ dà bí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń gbógun ti lílò òògùn olóró ní Nàìjíríà, NDLEA, ti gbẹ́sẹ̀ lé igbó tí òdinwọ̀n rẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún kílógíráámù, 5, 344.1Kg nípìńlẹ̀ Èkó.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ àjọ náà, Femi Babafemi fi síta, ó ní ọwọ́ tẹ òògùn olóró náà lẹ́yìn tí ìròyìn tẹ àjọ NDLEA lọ́wọ́ pe ọkọ̀ akẹ́rù kan yóò gba agbègbè Alpha Beach, lójú ọ̀nà Epe sí Lekki kọjá.

“ Àwọn òṣìṣẹ́ NDLEA dènà de ọkọ̀ tó kó òògùn olóró tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 2434.1kg, tí wọ́n dì sínú àádọta àpo, ní òwúrọ̀ kutu ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkandin lógún, oṣù Kẹfà.”

Ṣùgbọ́n awakọ̀ rẹ̀ fò jáde nínú ọkọ̀ tó sì sáré kó sínú ọkọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò tó ń bá rinrinajo .

Yàtọ̀ sí èyí, Ọgbẹni Babafẹmi sọ pé ọwọ́ tún tẹ àwọn ọkùnrin méjì kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana ní ogúnjọ́ oṣù Kẹfà bákan náà, níbi tí wọ́n ti wà pẹ̀lú ìwọn 2,910kg igbó ní Alpha Beach.

Kí ẹgbẹ́ APC le wọlé ìbò ni Buhari kò ṣe yọ ‘subsidy’ – Garba Shehu

Kí ẹgbẹ́ APC le wọlé ìbò ni Buhari kò ṣe yọ ‘subsidy’ – Garba Shehu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ọ̀rọ̀ tó bá dánilójú, kìí kọsẹ̀ létè ẹni.
Agbẹnusọ Ààrẹ àná Nàìjíríà, Garba Shehu ti ṣàlàyé ìdí tí Muhammadu Buhari kò ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù nígbà tó wà nípò.

Garba Shehu ní Buhari kọ̀ láti yọ ìrànwọ́ orí epo nítorí pé kò ì tíì tó àkókò tó yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó kúrò lórí ipò.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Shehu fi síta lọ́jọ́ Ajé ní ìjọba Muhammadu Buhari mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe ìdádúró yíyọ ìrànwọ́ orí epo náà fún àsìkò tó yẹ ni.

Ó ní irú ìgbésẹ̀ yìí kò lè wáyé lásìkò tí gbogbo nǹkan ń gbóná ní Nàìjíríà àti pé olórí rere kò ní hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Agbẹnusọ Ààrẹ àná náà ní ìjọba tuntun tó mọ nǹkan tó ń ṣe, tó sì ní ẹ̀mí láti ṣe dáadáa fún àwọn ará ìlú nìkan ló le gbé ìgbésẹ̀ tí Tinubu gbé.

Ó fi kun pé lára ìdí tí Buhari kò fi yọ ìrànwọ́ orí epo lásìkò tó ti fẹ́ gbé ìjọba sílẹ̀ ni láti ri pé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) jáwé olúborí ìbò Ààrẹ.

Ó ní àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ní dìbò fún APC tó bá jẹ́ wí pé Buhari ti yọ ìrànwọ́ orí epo náà bí ètò ìdìbò ṣe ń bọ̀ lọ́nà.

“Nígbà tí a ti dìbò tán, olórí tó bá mọ ohun tó ń ṣe gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti tẹ̀síwájú.”

“Mo ní ìgboyà nínú ìjọba tuntun yìí pé wọ́n máa ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò lọ́kan-ò-jọ̀kan tó máa mú àyípadà rere bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.”

Bákan náà ló gbóríyìn fún Ààrẹ Tinubu àti igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima fún yíyọ ìrànwọ́ orí epo àti ríri pé owó dọ́là jẹ́ bákan náà lọ́jà.

Shehu tún kan sáárá sí wọn pé wọ́n ṣe ètò náà dáadáa débi wí pé kò sí wàhálà kankan tó wáyé lẹ́yìn àwọn ìgbésẹ̀ yìí.

Ó tẹ̀síwájú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gá òun kò yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ní ọ̀pọ̀ ìrànwọ́ ni Buhari yọ bíi ti orí kẹrosíìnì, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ìrànwọ́ tí Buhari yọ yìí ló ti máa ń ṣe àkóbá fún ètò ìsúná Nàìjíríà

ìjọba ò gbèrò àti yí ìdájọ́ Rahman Adedoyin padà – Adeleke

ìjọba ò gbèrò àti yí ìdájọ́ Rahman Adedoyin padà – Adeleke

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti sọ pé irọ pátápátá ni ìròyìn to ní òun ń pinnu láti dáríjin Rahman Adedoyin lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dájọ ikú fún lórí ikú Timothy Adegoke.

Adedoyin atawọn eeyan mẹfa mii ni ọlọpaa fi ṣikun ofin mu ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021 lẹyin iku akẹkọọ naa nile itura Adedoyin.

Lẹyin igbẹjọ ẹsun naa ni ile ẹjọ sọ pe Adedoyin jẹbi ẹsun ipaniyan, to si dajọ pe ki wọn lọ yẹ igi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Gómìnà Ademola Adeleke, Olawale Rasheed fi léde, ó ní kò si ohun tó jọ pé ìjọba tó wà lórí oyè yóó tọwọ bọ ètò ìdájọ́.

Ó ní “ẹni ibì ni Gbogbo awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ kiri lọna ati ba orukọ Gómìnà jẹ.”

“ Gómìnà Adélékè kò ní lo agbgbara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bii gomina lati tọwọ bọ ètò ìdájọ láíláí. ”

“O ṣe pataki lati jẹ ki awọn araalu mọ pe gomina tabi ẹgbẹ oṣelu rẹ ko ni ohun ikọkọ kankan lati ṣe pẹlu igbẹjọ naa yatọ si pe ki erongba awọn araalu fun idajọ ododo wa si imuṣẹ.”

Rasheed tun sọ pe gomina ipinlẹ Osun ko fi igba kankan ni ajọṣepọ pẹlu Adedoyin, bẹẹ si ni ko ṣetan lati ṣe makaruru lọna ati dena idajọ ododo.

“A rọ àwọn aráàlú láti máṣe tẹti sí àhesọ ọrọ̀ tó ń ká a pé ìjọba wa fẹ́ dáríjin Adedoyin láti yí ìdájọ rẹ̀ padà .”

Lẹ́yìn náà ló gba àwọn aráàlú lá mọ ràn láti máṣe náání ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tí àwọn kan ń gbé kiri lórí ayélujára pé Gómìnà Adélékè fẹ́ dáríjin Adedoyin.

Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún atilẹyin wọn fún ìjọba Adélékè ní Gbogbo ìgbà.

Ẹ̀wẹ̀, ṣáájú ni àwọn ìròyìn kan ti kọ́kọ́ jáde ṣaájú àsìkò yìí pé họ́wùhọ́wù kan ń wáyé láàrin adájọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Gómìnà Adélékè.

Ìròyìn náà ni èrèdí họ́wùhọ́wù náà kò ṣẹ̀yín ìgbẹ́jọ́ Adedoyin lórí ikú Adegoke, àti pé Gómìnà Adélékè fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kí adájọ́ náà fẹ̀yìntì nígbà tí àsìkò ìfẹ̀yìntì rẹ̀ kò tíì tó.

Ileeṣẹ ti wọ́n ní k’awọn ọdẹ kan máa ṣọ ni wọ́n jà lólè

Ileeṣẹ ti wọ́n ní k’awọn ọdẹ kan máa ṣọ ni wọ́n jà lólè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn ọdẹ mẹ́rin kan, Habila Anbeyi, ẹni ọdún mẹ́rìndílógún, Naruka Sababou, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n, Audi Ali, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n, àti John Danladi, ẹni ọgbọ̀n ọdún, ni adájọ́ ilé-ẹjọ́ kan ti wọ́n ń pè ní ‘Grade1 Area Court,’ tó wà nílùú Kabusa, l’Abuja, Onídàájọ́ Abubakar Sadiq, ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ̀ọ́ ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe.

Ohun tí a gbọ́ ni pé ileeṣẹ kan tó ń pèsè ààbò fawọn aráàlú, èyí tí wọ́n ń pè ní ‘Falzal Security Company’, to wa lagbegbe Wuse, nílùú Abuja, lawọn mẹrẹẹrin ọ̀hún ti ń ṣiṣẹ́. Níṣe ni wọ́n gbìmọ pọ̀ láti jí epo diisu ileeṣẹ náà ta fún àwọn aráàta.

Ọlọpaa olupẹjọ, Ọgbẹni S.O Osho, to foju awọn ọdaran naa han nile-ẹjọ sọ pe Akaaza Samuel, to jẹ ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ ọhun lo lọọ fọrọ awọn odaran naa to ọlọpaa agbegbe Asokoro, niluu Abuja leti lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Agbefọba sọ pe, “Ẹyin mẹrẹẹrin yii, ẹ gbimọ-pọ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, tẹ ẹ si ji epo diisu ileeṣẹ tẹ ẹ ti n ṣiṣẹ. Igba lita (200lt) ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira lẹ ji gbe. Loju-ẹsẹ tẹ ẹ ti ji epo ọhun tan lẹ ti ta a fun ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Lawal lowo pọọku, ko too di pe, ọwọ awọn ọlọpaa tẹ yin.

“Loootọ, ẹ ti jẹwọ fawọn agbofinro lasiko ti wọn ni beere ọrọ lọwọ yin, ṣugbọn ijiya nla wa fun ohun tẹ ẹ ṣe yii labẹ ofin ilu yii”.

Bi ọlọpaa olupẹjọ ti ka awọn ẹṣẹ tawọn mẹrẹẹrin ṣẹ ṣi wọn lẹsẹ tan ni awọn paapaa ti gba pe loootọ lawọn jẹbi esun iwa ọdaran gbogbo ti wọn fi kan won pata, ti wọn si rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ naa pe ko ṣiju aanu wo awọn lori ọrọ to wa niwaju rẹ ọhun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Sadiq, ni ki ẹnikọọkan wọn lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọna ogun naira gẹgẹ bii owo itanran.

Bakan naa ni adajọ ni ki ẹnikọọkan wọn tun san ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn Naira fun ileeṣẹ ti wọn ja lole naa gẹgẹ bíi owo gba-ma-binu fun dukia rẹ ti wọn ji.

Ó ní bí wọ́n bá kọ láti sanwó ọ̀hún, òun yóó fi oṣù méjì kún ọjọ́ tí wọ́n máa lò lọ́gbà ẹ̀wọn.

Kò dájú pé Emefiele ò ní-ín sá kúrò ní Nàìjíríà tí ilé ẹjọ́ bá fún un ní béèlì – DSS

Kò dájú pé Emefiele ò ní-ín sá kúrò ní Nàìjíríà tí ilé ẹjọ́ bá fún un ní béèlì – DSS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní kinní kan ló mẹsẹ̀ kinní kan tọ̀ lórí àpáta.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Nàìjíríà ìyẹn Department of State Services, DSS ti rọ ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Abuja láti da ẹjọ́ tí gómìnà tẹ́lẹ̀ fún ilé ìfowópamọ́ báǹkì àpapọ̀, CBN wí pé àwọn ń tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú mọ́lẹ̀ nù.

Emiefiele nínú ẹjọ́ tó pè tako DSS àti ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè látọwọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀, J. B. Daudu ní DSS fi òun sí àhámọ́ lọ́nà àìtọ́.

Ó ní wọn kò fún òun ní ààyè láti rí àwọn ẹbí àti àwọn agbẹjọ́rò òun.

Àmọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, DSS ní tí ilé ẹjọ́ bá gba béèlì Emefiele, ó máa sá kúrò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni.
Agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà kín DSS lẹ́yìn nígbà tó ń júwe Emefiele bí ẹni tó le sá kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n bá ti tu sílẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn kò tẹ ẹ̀tọ́ Emefiele lójú mọ́lẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe wà ní àhámọ́ àwọn nítorí ẹ̀mí rẹ̀ kò sí nínú ewu kankan.

Wọ́n ní àwọn kò fi ìyà jẹ ẹ́ tàbí ṣe é báṣubáṣu ní àgọ́ àwọn tó wà àti pé àwọn gba àṣẹ láti ilé ẹjọ́ kí àwọn tó fi òfin gbé e.

Wọ́n fi kun pé èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ò tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú mọ́lẹ̀ rárá nítorí àṣẹ ilé ẹjọ́ ni àwọn ń tẹ̀lé.

Nínú àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n jiyàn rẹ̀ pé kò sí nǹkan tó jọ mọ́ ṣíṣe agbátẹrù àwọn agbéṣùmọ̀mí lára ẹ̀sùn tí Emefiele ń kojú àti pé kìí ṣe wí pé nítorí pé ó dá sí òṣèlú tàbí ṣe àyípadà owó náírà sí owó tuntun ló ṣe okùnfà rẹ̀ gbígbé rẹ̀.

Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀sùn tí Emefiele ń kojú dá lórí ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ, dída ètò ọrọ̀ ajé ìlú rú àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn tó fara pẹ.

Agbẹjẹ́rò ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, Tijani Gazal rọ ilé ẹjọ́ láti da ẹjọ́ tí Emefiele pè nù nítorí àwọn ẹ̀sùn náà kò rí ẹsẹ̀ walẹ̀.

Gazal tún ní ilé ẹjọ́ tí Emefiele gbé ẹjọ́ náà lọ kò ní àṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ ọ̀hún.

Lẹ́yìn atótónu láti ẹnu àwọn agbẹjọ́rò, adájọ́ Hamza Muazu tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Keje láti gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

Kò dájú pé ifá wà nítòsí láti yan Aláàfin Ọ̀yọ́ àti Ṣọ̀un Ogbomosho tuntun – Oluwo

Kò dájú pé ifá wà nítòsí láti yan Aláàfin Ọ̀yọ́ àti Ṣọ̀un Ogbomosho tuntun – Oluwo

Fẹ́mi Akínṣọlá
Kò jọ pé Oluwo tí ìlú Ìwó, Ọba Abdulrasheed Akanbi faramọ́ ìlànà fífi àṣà àti ìṣe yan ọba aládé rárá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èyí sì máa ń hàn nínú ìsesí ọba alayé ọ̀hún. Bí àwọn tí ọ̀rọ̀ àṣà gbérùn n gé ọba alayé ọ̀hún lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ló ń bọ̀rùka ,pabanbarì ib ẹ̀ ni pé ó tún ti fọ́ kèngbè ọ̀rọ̀ míràn mọ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àṣà yíyan àwọn ọba ní ilẹ̀ Yorùbá.

Bí ẹ kò bá gbàgbé, láìpẹ́ yìí ni Ọba Àkànbí ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn abẹ́lé kan lórílẹ èdè Nàìjíríà nínú èyí tó ti sọ pé Ifá kọ́ ló ń yan ọba mọ́ báyìí, àwọn Gómìnà ni.

Lọ́tẹ̀ yìí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi ṣọwọ́ sí akọ̀ròyìn, Kábíyèsí Oluwo ní gbogbo àwọn tó bá ń dúró de kí Ifá yan àwọn sí ipò ọba yóó dúró pẹ́ bí èèyàn tó ń wo iṣẹ́jú akàn létí odò ni.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèkàn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá ló ti fèsì sí ọ̀rọ̀ akọ tí Oluwo sọ wí pé Gómìnà ló ń fi ọba jẹ.

Àmọ́ báyìí ohun tí Oluwo tún ń sọ ni wí pé “ àwọn ọmọọba tí àpọ̀jù sinimá wíwò ń bá fínra ní yóó máa dúró de kí Ifá kéde àwọn ” gẹ́gẹ́ bí ọba.

“ Kí ló dé tí Ifá kò tíì yan Aláàfin Ọ̀yọ́ tàbí Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ tuntun? Àbí Ifá ti rìnrìnàjò ni kí á lè tètè pèé wálé láti wá fún àwọn ìlú wọ̀nyí ní ọba tuntun.”

Ọba Àkànbí ní Elédùmarè ló ń fi ọba jẹ, kìí ṣe Ifá. “Bi ipò ọba kan bá ṣí sílẹ̀, àwọn tó bá fẹ́ du oyè bẹ́ẹ̀ á lọ bá ìjọba ni. Gbogbo àwọn tó bá ń dúró de Ifá yóó wulẹ̀ dúró títí ayérayé ni.”

Ààrẹ Tinubu yóò rìnrìnàjò lọ Paris fún ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé

Ààrẹ Tinubu yóò rìnrìnàjò lọ Paris fún ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bọla Tinubu yóó darapọ̀ mọ́ àwọn adarí orílẹ-èdè lágbàáyé láti kópa níbi ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé, Global Financial Pact ti yóò wáyé ní ìlú Paris lórílẹ̀ èdè France.

Àtẹ̀jáde kan láti ilé iṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà ṣàlàyé pé Tinubu pẹ̀lú àwọn Ààrẹ yòókù lágbàáyé yóò péjú lọ́jọ́bọ ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹfà láti jíròrò lórí àdéhùn ìrànwọ́ ìṣúná fún àwọn orílẹ-èdè tó ku díè káàtó fún.

Àwọn orílẹ̀-èdè tí yóó jàńàní ìṣúná tó bá jáde lábẹ́ àdéhùn náà làwọn orílẹ-èdè ti wàhálà ọ̀rọ̀ àyíká, wàhálà nǹkan àmú ṣágbára àti àtúnbọ̀tán àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 bá fínra.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Ààrẹ Tinubu yóò máa rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ òkèèrè láti ìgbà tí ó ti gun orí àga Ààrẹ orílẹ-èdè Nàìjíríà lóṣù kàrún un.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé wọ́n fẹ́ da ilé wo nínú ọjà Alaba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé wọ́n fẹ́ da ilé wo nínú ọjà Alaba

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ará ilé ẹni bá ń jẹ kòkòrò tí kò dáa, tí a kò bá sọ fún un, hẹ̀rẹ̀hùrù rẹ̀ kò ní-ín jẹ á fojú lóorun.
Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ Eko ìyẹn Lagos State Building Control Agency (LASBCA), Gbolahan Oki ló fi ìkéde náà síta nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sínú ọjà náà lọ́jọ́ Ẹtì.

Oki ní láti ọdún 2016 ni àwọn ti ń ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olùgbé ilé náà, tí àwọn sì ti ń ṣe àmì si wí pé àwọn máa wó wọn àti pé àbẹ̀wò òun náà wáyé láti sọ fún àwọn tó ń gbébẹ̀ láti kó kúrò lẹ́yẹ ò sọkà.

Èyí ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa pòkìkí ọjà Alaba, níbi tí wọ́n ti máa ń ta ohun èlò ilé bíi ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, fírìjì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lórí ayélujára.

Àwọn ẹ̀yà Igbo ló pọ̀ tí wọ́n ń ta ọjà nínú Alaba tí àwọn kan sì ń sọ wí pé nítorí à ti gbẹ̀san ohun tó wáyé ní Eko lásìkò ìbò tó kọjá ló fa ìgbésẹ̀ ìjọba yìí.
Ẹ̀wẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Oki ní láti ọdún 2016, 2020, 2022 títí di ọdún yìí ni àwọn ti ń fún àwọn ènìyàn tó ni àwọn ilé náà ni ìwé pé kí wọ́n kúrò níbẹ̀.

Ó ní àkíyèsí ọdún méje náà tó láti fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀ láti kúrò àmọ́ dípò kí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ìkìlọ̀ níṣe ni wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tí wan bá ti dé ibẹ̀.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ilé náà kò bá wà lára àwọn ilé 349 tí àwọn fi léde ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pé àwọn fẹ́ wó àmọ́ nítorí àwọn kìí ríbi ṣe iṣẹ́ àwọn tí àwọn bá dé ibẹ̀ nítorí ìkọlù tí wọ́n máa ń ṣe sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn kò jẹ́ kí àwọn le fi wọ́n sínú rẹ̀.

“Ohun tí à ń ṣe báyìí ni láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ “Task Force” Eko láti lè ri wí pé á ri àwọn ilé náà wó palẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.

“Ó pọn dandan fún wa láti wó àwọn ilé náà báyìí nítorí wọ́n ti di ẹgẹrẹ mìtì, tí wọ́n sì lè ṣe àkóbá fún àwọn ilé mìíràn tó wà ní agbègbè wọn àti àwọn tó ń ta ọjà níbẹ̀ pàápàá.”

Ó fi kun pé ìjọba yóò tẹ̀síwájú láti máa pàtàkì ẹ̀mí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láì fi ẹ̀yà tàbí ohunkóhun ṣe, kí ìgbé ayé le rọrùn fún mùtúmùwà.

 

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta ọjà nínú Alaba International Market, Theo Ezeani sọ fún akọ̀ròyìn pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn ń gbọ́ pé ìjọba fẹ́ wó àwọn ilé kan nínú ọjà náà.

Ezeani ní àwọn kò rí ìwé ìkìlọ̀ kankan láti ọdún 2016 èyí tí ìjọba ní àwọn fi ṣọwọ́.

Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ kò mọ̀ nípa ìwé tí ìjoba ní àwọn ti ń kó ránṣẹ́ tó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun nítorí ó ti pẹ́ tí òun ti wà nínú ọjà náà.

“Kò sí pigbà kankan tí a sọ ohun tó bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìpàdé wa, àwọn tí a gba ipò lọ́wọ́ wọn náà kò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ fún wa, lórí amòhúnmáwòrán ni mo ti kọ́kọ́ rí ìròyìn náà lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì. ”

Ezeani ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn tó ni ilé gangan ni ìjọba kọ̀wé ránṣẹ́ sí àmọ́ àwọn tí àwọn ń ta ọjà níbẹ̀ kò gbọ́ nǹkankan.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́jà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ẹrù wọn kúrò níbẹ̀ nítorí ohun tí àwọn gbọ́ ni pé ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndílógún, oṣù Kẹfà ni ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ wíwó àwọn ilé náà.

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rọ Russia àti Ukraine láti jógun ó mí

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rọ Russia àti Ukraine láti jógun ó mí

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí ọrọ ńlá kò bá tíì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín tíì sinmi àròyé.
Ààrẹ orílẹ̀ èdè South Africa, Cyril Ramaphosa ti rọ Ààrẹ Russia, Vladimir Putin láti fòpin sí ogun tó ń gbé ti Ukraine.

Ramaphosa pàrọwà yìí nígbà tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú Putin ní St Peterburg lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ààrẹ South Africa ọ̀hún àtàwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ adúláwọ̀ mẹ́fà mìíràn ni wọ́n ṣe àbẹ̀wò lọ sí Russia àti Ukraine láti lọ bẹ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti dáwọ́ ogun dúró.

Ṣáájú ni Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky sọ fún àwọn ikọ̀ náà lọ́jọ́ Ẹtì pé òun kò ní bá Putin jíròrò nígbà tó bá ṣì gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ àwọn.

Putin náà sọ fún àwọn adarí ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà pé Ukraine kọ̀ láti jíròr]o pẹ̀lú òun.
Ramaphosa tún rọ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti tú àwọn ènìyàn wọn tí wọ́n fi sí àhámọ́ sílẹ̀ àti pé kí Russia dá àwọn ọmọdé tó kó lórí ilẹ̀ Ukraine padà sílé wọn.

Àmọ́ Putin fèsì padà pé Russia ń dá ààbò bo àwọn ọmọdé náà lọ́wọ́ ogun ni.

Ó ní àwọn kó àwọn ọmọ náà kúrò ní ibi tí pgun ti ń wáyé láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti ìlera wón ni.

Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ tọ ń rí sí ìwà ọ̀daràn ní àgbáyé ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ogun kan Russia lórí bó ṣe kó àwọn ọmọ náà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹebí wọn.

Wọ́n ní àwọn ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Russia fi tipátipá kó àwọn ọmọdé ilẹ̀ Ukraine lọ sí Russia lọ́nà àìtọ́.

Ramaphosa tẹmpẹlẹmọ pe ipa tí ogun náà ń ní lórí àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò kéré rárá tó sì gbọdọ̀ wá sí òpin láìpẹ́.

Ó ní ogun ti ṣokùnfà ìdènà gbígbé oúnjẹ oní wóóró láti ilẹ̀ Ukraine àti ajílẹ̀ láti Russia wọ àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ èyí tó ti ń fa ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ.

“Ogun kò lè máa lọ títí láé, ó yẹ kí gbogbo igun wá ọ̀nà láti fòpin sí ogun yìí, a sì wá láti sọ fún-un yín pé ogun tó ń wáyé yìí kò tẹ́ wa lọ́rùn.

Àmọ́ Putin ní kìí ṣe ogun tó ń wáyé náà ló jẹ́ kí gbígbé àwọn oúnjẹ wọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ dáwọ́ dúró àti pé òun kan sáárá sáwọn olórí ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà fún akitiyan wọn.

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó lọ síbi ìpẹ̀tù sááwọ̀ náà South Africa, Egypt, Senegal, Congo-Brazzaville, Comoros, Zambia àti Uganda.