Home Blog Page 10

Ìjọba Makinde fẹ́ yá 300Bn awuyewuye sọ

Ìjọba Makinde fẹ́ yá 300Bn awuyewuye sọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí èèyàn bá dákẹ́, dájúdájú ti ara rẹ̀ yóó bá dákẹ́ bóyá èyí náà ló fàá,
láti bí ọjọ́ mélòó kan báyìí tí ẹnu fi ń bẹ̀rẹ̀ sí ní kun ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nítorí 300bn náírà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà buwọ́lù fún Gómìnà Ṣéyì Mákindé láti yá.

Ọkan lara ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ-oorun Ṣaki, to tun jẹ aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC, Họnọrebu Ibraheem Shittu lo kọkọ pariwo sita lori ayelujara Facebook wi pe, oun ko si ni ibi ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti buwọlu ẹyawọ ọọdunrun biliọnu Naira fun Gomina Ṣeyi Makinde.

Shittu ni iyalẹnu nla ni igbesẹ naa jẹ fun oun nitori pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ wa l’ẹnu isinmi ọlọsẹ mẹfa nigba ti oun gbọ iroyin nipa ẹyawo naa.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe ipade pajawiri kan ni awọn alakoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ sare ṣe ki wọn le fun Makinde ni anfaani lati ya owo naa lai fi ọrọ to awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to ku leti.

Ibeere ti Họnọrebu yii wa n beere ni pe, “ki lo de ti ijọba ipinlẹ Ọyọ tun fẹ lọ ya owo nigba to jẹ wi pe aleekun ti ba iye owo ti ijọba apapọ n fun un pẹlu ilọpo ẹẹdẹgbẹta?”.
Bakan naa lo tun n beere wi pe ki lo de ti awọn alakoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ko fi ọrọ to awọn ọmọ ile igbimọ naa leti ki wọn to buwọlu ẹyawo naa.

Lẹyin ọrọ ti Họnọrebu Shittu fi lede lori Facebook ni ọkanojọkan ariwisi ti n waye lori ọrọ naa.
Eyii lo mu ki ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ fesi ninu atẹjade kan ti adari ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju nile igbimọ aṣofin naa, Hon. Sanjo Adedoyin ati alaga igbimọ ile to n ri si ikede, iroyin ati ọrọ to niiṣẹ pẹlu ẹrọ igbalode, Hon. Waheed Akintayo (Ilumoka) buwọlu, ti wọn si fi ranṣẹ si awọn akọroyin.

Atẹjade naa tọka rẹ wi pe ọrọ ti Họnọrẹbu Shittu fi lede jẹ ọrọ to n ṣini lọna ti o si tun fi han wi pe Họnọrebu naa ko mọ ojuṣe rẹ.

Bakan naa ni wọn sọ siwaju sii wi pe gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin naa ni awọn sọ fun wi pe ipade pajawiri kan yoo waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun yii.

O ni awọn fi ikede sita ni oju opo Whatsapp ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ n lo.

Bakan naa ni wọn ya aworan atẹjiṣẹ ti wọn fi ranṣẹ si awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lori ipade naa.

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ tun ṣe alaye siwaju sii wi pe Họnọrebu Shittu to n fi ẹsun kan yii kii saba kopa nibi awọn ipade ti ile igbimọ aṣofin naa ba pe pẹlu alaye wi pe ida ogun pere ni iwọn bi o ṣe n kopa nibi awọn ipade ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ.

Wọn ni iwọsi nla gbaa ni isansa to n ṣe lẹnu iṣẹ rẹ n ko ba awọn eeyan ilu Ṣaki ti o n ṣoju nile igbimọ aṣofin.
Alaye ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ṣe ninu atẹjade ti wọn fi ranṣe ni pe biliọnu mọkandinlaadọjọ Naira(N149Bn) ni ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ fi san lara gbesẹ ti wọn jẹ ile ifowopamọ UBA(United Bank for Africa).

Biliọnu mọkanlelaadọjọ(N151Bn) to ṣẹku yoo jẹ lilo fun ipese awọn ohun elo amayedẹrun ati lati san owo iṣẹ fun awọn agbaṣẹṣe ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe iṣẹ fun jakejado ipinlẹ Ọyọ.
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2021, ile igbimọ aṣofin buwọlu ẹyawo biliọnu mẹfa Naira(N6Bn) ti Gomina Makinde gba lati ṣe awọn akanṣe iṣẹ ilu.

Ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2021 bakan naa, Makinde ya biliọnu mejidinlogun Naira mii.

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ tun buwọlu ẹyawo aadọjọ biliọnu Naira(N150Bn) fun Gomina Makinde ninu oṣu Kinni ọdun 2024.

Laarin ọdun 2025 taa wa yii, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti buwọlu ẹyawo igba biliọnu Naira(N200Bn) ninu oṣu Kẹta, wọn tun fi ontẹ lu ẹyawo aadọfa biliọnu Naira(N110Bn) ninu oṣu Keje, ko to di pe wọn pe ipade pajawiri lati buwọlu ẹyawo ọọdunrun Billiọnu Naira(N300Bn) ninu oṣu kẹjọ ọdun taa wa yii.

Ìdí tí ìjọba tún ṣe fi kún owó pásípọ̀ọ́tì sí ₦100,000 àti ₦200,000

Ìdí tí ìjọba tún ṣe fi kún owó pásípọ̀ọ́tì sí ₦100,000 àti ₦200,000

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ ti ṣe àfikún iye owó ìwé irinna Nàìjíríà lẹyin bíi ọdún kan ti wọ́n kọ́kọ́ fi owó lé ìwé ìrìnà ọ̀hún.

Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 yii ni ajọ to n ri si wọle-wọde ni Naijiria, NIS, kede afinkun naa.

Awọn iwe irinna ti afikun yii kan ni iwe irinna ọlọdun marun un to ni oju awẹ mejilelọgbọn ati iwe irinna ọlọdun mẹwaa to ni oju awẹ mẹrinlelọgọta.
Afikun tuntun wọnyii lo n waye lẹyin ti Olubunmi Tunji-Ojo de ipo minisitita fun ọrọ abẹle.

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 ni ijọba kọkọ ṣe afikun iye owo iwe irinna naa ti wọn si gbe owo eyii to jẹ ọdun marun lati N35,000 si 50,000, ti wọn tun gbe iye owo eyii to jẹ 70,000 si 100,000.
Ni bayii ijọba tun ti fi kun owo naa, to n tumọ si pe iwe irinna ọlọdun marun to jẹ N50,000 tẹlẹ yoo di N100,000 nigba ti iwe irinna ọlọdun mẹwaa to jẹ N100,000 bayii yoo di N200,000.

Amọ ṣa, afikun yii ko kan awọn to wa nilẹ okeere, awọn to wa ni Naijiria nikan lo kan.

Ki ni idi ti ijọba fi ṣafikun iye owo iwe irinna yii?

Agbẹnusọ ajọ NIS, ACI AS Akinlabi sọ pe afikun owo yii yoo bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 yii.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ṣe afikun naa lati le tunbọ jẹ iki we irinna ọhun jẹ ojulowo ati eyii to ba igba mu.

O ni “Lọna lati ri daju pe iwe irinna Naijiria jẹ ojulowo o si ba igba mu, ajọ wọle-wọde Naijiria kede fikun owo iwe irinna.”

Ajọ NIS tun sọ pe afojusun awọn ni lati ri pe awọn sin araalu ni ọna to tọ ati ọna to yẹ, ati pe awọn araalu ri iwe irinna naa gba lasiko.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu akọroyin, minisita fun ọrọ abẹle, Tunji Olubunmi-Ojo sọ pe afojusun oun ni lati ri pe awọn eeyan le maa forukọsilẹ lati gba iwe irinna naa lori ayelujara funra wọn.

O ni ohun kan ṣoṣo ti yoo maa gbe awọn eeyan lọ si ọọfisi ajọ naa ko ni lati ya aworan ara rẹ ati lati fi ika rẹ silẹ, awọn ohun to ku ni araalu yoo le ṣe funra wọn lori ayelujara.

Awọn to fẹ forukọsilẹ fun iwe irinna tuntun atawọn to ba fẹ ṣe atunṣe si orukọ wọn yoo le ṣe lori ayelujara lai kọkọ yọju si ọọfisi ajọ NIS.

Ṣaaju asiko yii, o maa n to ọpọ ọsẹ tabi oṣu ki eeyan to le ri iwe irinna rẹ gbọ amọ nnkan ko ri bẹẹ mọ bayii.

Wayi o, NIS ti ni aarin ọsẹ kan pere lawọn eeyan yoo ma ri iwe irinna wọn gba bayii lẹyin afikun owo yii.
Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti koro oju si afikun owo iwe irinna yii, paapaa lasiko ti nnkan le koko niluu.

Ni kete ti iroyin afikun naa jade lawọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si n sọ pe ijọba aninilara ni ijọba to wa lode latari pe kii ṣe irufẹ akoko yii lo yẹ ki ijọba maa fi kun owo iwe irinna.
Koda, awọn kan tilẹ sọ pe ijọba Aarẹ Bola Tinubu n mu aye nira faraalu, bẹẹ lo tun n m u ko nira fun araalu lati fi ilu silẹ.

Lara awọn alẹnulọrọ ilu to bu ẹnu atẹ lu afikun yii ni Peter Obi, oludije sipo Aarẹ to sọ pe niṣẹ ni ijọba to wa lode n mọọmọ di ẹru wuwo le araalu lori.

O ni ko yẹ ki iye owo iwe irinna le to 100,000 naira ambelete 200,000 naira ni orilẹede ti iye owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ko to 100,000 naira.

Yatọ si Obi, ọpọ awọn ọmọ Naijiria mii lo ni ko yẹ ko ri bẹẹ, paapaa lasiko yii ti ọrọ aje ko ṣe deede ni Naijiria.

Bi o ṣe le gba iwe irinna Naijiria

Ikò̩ o̩ló̩pàá dóòlà è̩mí Peller kúrò ló̩wó̩ àwo̩n ajínigbé

Ikò̩ o̩ló̩pàá dóòlà è̩mí Peller kúrò ló̩wó̩ àwo̩n ajínigbé

Mary Fágbohùn

Gbajumo oniforan lori TikTok ni iko olopaa Naijiria ti ja gba leyin ti awon ajinigbe ko luu.

Iroyin jabo pe gbajumo oun ni awon sunmomi agbebon kan ti enikan ko mo ji gbe nigba to n se fonran bii ise re lori TikTok ni Ojoru.

Amo sa, ninu iroyin to Jade ni aaro Ojobo, ojugba Peller ati akegbe re, Sandra Benede ti so di mimo pe awon olopaa ti ri gba pada.

Sandra ninu fonran so pe won ti ri Peller ati pe o wa lodo oga olopaa.

“Won ti ri o. Oga olopaa ti rii. Won o so ekunrere alaye fun wa sugbon won ti ri,” o salaye bee.

Afeez Owo sàlàyé ipa tí ìkànnì ayélujára kó nínú ìpínyà òun àti ìyàwó rè̩

Afeez Owo sàlàyé ipa tí ìkànnì ayélujára kó nínú ìpínyà òun àti ìyàwó rè̩

Mary Fágbohùn

Gbajugbaja osere tiata Naijiria ati oludari ere, Afeez Owo, ti salaye idi ti oun ati iyawo re̩, osere tiata Mide Martins fi pinya.

Osere naa so eyi leyin bi odun mewaa ti iroyin nipa ipinya won ti lo jakejado lori ayelujara.

Lasiko to n fidi Iroyin naa mule ni Osu kerin odun 2016, Mide salaye ninu atejade kan lori ayelujara fi esun kan Afeez pe o ko jade ninu ile fun oun “ni bii osu meta leyin ti ede aiyede kan waye lori itoju awon omo wa”.

Amo sa, lasiko ti n soro nipa isele naa lori eto ‘Behind The Fame’, Afeez ni atejade Mide lori ayelujara lo mu oro naa di isu ata yananyanan.

Nigba to n salaye bo se ku die ki ikanni ayelujara ba igbeyawo awon je, osere naa so pe oun ba iyawo oun pari ija leyin to pada wa toro aforijin lowo oun.

“Iroyin nipa ipinya wa lo kaakiri. Ija naa si di akoko ati to gbeyin bii tokotaya. O le gidi sugbon O̩lo̩run ba wa pari re̩.

“Mi o ro pe mo se nnkan to dara nitori mo fi ibinu kuro nile leyin ariyanjiyan kekere.

“Amo, ero mi ni lati lo ojo meji ni ile itura ki n si pada sile, sugbon o fesun kan mi pe mo kuro nile, mo wa pinnu lati wa nibe fun opolopo ojo.

“O pada wa toro aforijin, a si pari ija. Ija to ye ka yanju laarin ara wa ni, sugbon ikanni ayelujara ba wa fe loju pupo sii,” ge̩ge̩ bi o se salaye.

E ranti pe Mide Martins ni akobi obinrin ti ologbe osere tiata, Funmi Martins to jade laye ni osu karun un o̩dun 2002 fi sile̩.

Leyin igba die ti Funmi Martins ku, Afeez Owo, alakoso re se igbeyawo pelu Mide Martins ni 2003.

 

 

Inú mi kò dùn báyìí rí láyé – Toke Makinwa

Inú mi kò dùn báyìí rí láyé – Toke Makinwa

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere Toke Makinwa korin tuntun pelu bo se ki omo tuntun jojolo kaabo.

Laipe yi ni iroyin jade pe Toke Makinwa salabapin ayo pelu awon ololufe lori ayelujara ni bo se fi aworan oyun re lede.

O fi ona ara safihan pe omobinrin ni o n reti nipase fonran to ti n tu ebun jade ninu atejade kan lori Instagram re.

Osere naa fi iroyin ayo yi lede lori ikanni Instagram re ni Ojobo, ni bo se fi inu didun ati imoore han.

Makinwa ni iroyin jade pe o bimo si United Kingdom, to silekun abala tuntun ninu aye re.

Gbajumo ohun safihan oruko omobinrin re ni kikun bii Yakira Eliana Olakitan Iyanuoluwa Ikeoluwa Adunola, oruko to wu awon ololufe re lori bi itumo re se jinle to ninu asa ati emi.

“Mo di abiyamo, inu mi ko dun bi eyi ri. Omo mi to se iyebiye, ife ti mi o mo pe o wa. Okan mi ninu eda eniyan miran, ife mi,”
O fi oro ifori si.

Awon ololufe ati afenifere ti fi oro ikini ku oriire ranse si Makinwa lori ayelujara, won kan saara sii fun inu didun to safihan re bii abiyamo.

Hèèmọ̀! Àwọ̀n t’íṣà kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rí kọ̀npútà ìkọ́ni t’íjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ fún wọn bì èròjà ìwo fíìmù

Hèèmọ̀! Àwọ̀n t’íṣà kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rí kọ̀npútà ìkọ́ni t’íjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ fún wọn bì èròjà ìwo fíìmù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóòtù ètò “ogún ọmọdé” gbóríyìn fún ìjọba lábẹ́ ìṣàkóso gómìnà Onímọ̀ ẹ̀rọ Oluseyi Makiñde niìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún àwọn akitiyan rẹ̀ lórí ètò ẹ̀kọ́, síbẹ̀ kò sàí mẹ́nuba àìlákàsì àwọn olùkọ́ kan tó jànfàní ẹ̀rọ ìkọ́mọ tuntun tí àwọn olùkọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ọ̀hún, pé fíímù àgbéléwò ni wọ́n kó sórí ohun èló tuntun ọ̀hùn fún wíwò .
Ṣùgbọ́n ní ìfèsì sí ọ̀rọ̀ olóòtú, àléjò orí ètò ogún ọmọdé Ògbẹ́niFẹ́miAkínṣọlá sì gbà pé ìgbà ọ̀tun ti dé báyìí fún àwọn olùkọ́ àti gbogbo akẹ́kọ́ọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bí ìgbésẹ̀ tuntun t’íjọba gbé kalè bá lọ bó ṣe yẹ.

Gbólóhùn òkè yìí ló bí
àmọ̀ràn tó lọ s’ọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ fún ní ìdánilẹ́kọ́ọ̀ lórí lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìgbélárúgẹ ètò ẹ̀kọ́
láti rí i gẹ́gẹ́ bí ànfààní ọ̀tun tó lè mú àgbéga àti ìhùwàsí àwọn akẹ́kọ́ọ̀ yí padà sí rere dípò ó rírí bí
n bèbí ìléwó ọmọdé.
N ígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ètò orí rádíò iléeṣẹ́ Fresh FM 106:6 àlejò pàtàkì lórí ètò náà tí wọ́n pè ní ogún ọmọdé tó máa ń wáyé ní Sátidé, láàrin aago mẹ́fà sí méje àṣálẹ́, èyí tí ògbóntarìgì àgbóhùnsáfẹ́ ọ̀hún ọmọọbá Abíọ́dún Lawal Agbólúajé dárí, ni ọ̀rọ̀ náà ti jẹyọ.

Àlejò pàtàkì ọ̀hún Ọ̀gbẹ́ni Fẹ́mi Akínṣọlá ṣàlàyé pé, ètò kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ́ọ̀ ìwé lásìkò yìí tí fẹ́jú ju kí àwọn olùkọ́ sì tún máa di ìwé àkọsílẹ̀ ìlànà iṣẹ́ tàbí ìlànà àgbékalẹ̀ iṣẹ́ mọ́ àyà kiri.

Ó ní ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní ti ṣàwàrí gbogbo èròjà tí olùkọ́ nílò sójú kan ní àrọ́wọ́tó.
Ó tẹ̀síwájú pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà tí àwọn olùkọ́ tó ní ọjọ́ tó pọ̀ láti lò lẹ́nu iṣẹ́ ti kópa.

Àlejò orí ètò náà sọ pé, n tò lè jẹ́ kí ètò ìlànà tuntun náà ó nitumọ̀ kò ju bí àwọn olùkọ́ tó kópa níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe já fáfá sí, nípa mímọ pàtàkì lílò rẹ̀.

Ó ní ìjáfáfá wọn ni yóó mú kí wọ́n lè lo ìmọ̀ ìgbàlódé náà tí wọ́n ní kọ́ àwọn ẹ̀ka ilé-ẹ̀kọ́ wọn jákèjádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti agbègbè rẹ̀ dípò fífi wo fíímù tó lè dá làákàyè wọn làámú tàbí kó kó wọn lọ́kàn sókè.

Bákan náà ló so pé àwọn tó kópa ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà yẹ kí wọ́n lè fí kọ́ àwọn olùkọ́ tí kò ní ànfààní sí ìdánilẹ́kọ́ọ̀ ìmọ̀dọ̀tun yìí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọ́n abala olúkọ́ tó lọ fún sẹ́mínà nìkan tó sì n lò ó déédé nìkan ni àwọn akẹ́kọ́ ọ̀ yóó jèrè wọn.
Èyí sì lè padà fa awuyewuye tàbí kí ìmọ̀ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ kan ó gọbọi ju tàwọn ẹ̀gbẹ́ wọn nínú ìṣedéédé ìmọ̀ sàájú ìlànà ìkọ́ni onímọ̀ ẹ̀rọ tábúlẹ́tì.

Ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde gbọ́dọ̀ ri pé àwọn tó ṣagbátẹrù ètò ìlànà ìmò ẹ̀kọ́ ọ̀tun ọ̀hún mójútó bí èkọ́ ìlànà ìkọ́mọ tí àwọn olúkọ́ gbà náà yóó ṣé jẹ́ lílò fún ìgbà pípẹ́, bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn olùkọ́ tó lọ́jọ́ púpọ̀ lẹ́nú iṣẹ́ ni kó jẹ́ ànfààní ọ̀hún.

Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ,bí àmójútó bá wà, ìgbà ọ̀tun dé bá ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nípasẹ̀ lílo tábúlẹ́tì ìkọ́mọníṣẹ́ àti kíkọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àyẹ̀wò fún akẹ́kọ́ọ̀ ,tó fi dórí àkọsílẹ̀ pàtàkì tó ní-ín ṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́.

Ikú dóró! Ó pojú ò̩gá o̩ló̩pàá té̩lè̩ IGP Solomon Arase dé

Ikú dóró! Ó pojú ò̩gá o̩ló̩pàá té̩lè̩ IGP Solomon Arase dé

Ìròyìn òwúrò̩

Owuro̩ oni ni iroyin ayelujara be̩re̩ si ni gbee kaakiri pe O̩gbe̩ni Solomon Arase to je̩ o̩ga o̩lo̩paa patapata e̩le̩e̩kejidinlogun ti rewale̩ asa.
O̩ga o̩lo̩paa yii daye ni o̩jo̩ ko̩kanlelogun, osu ke̩fa, o̩dun 1956.
Ile iwosan Cedarcrest Hospital ni ilu Abuja ni o̩ga o̩lo̩paa yii dake̩ si.
Gbogbo igbiyanju lati fi idi iroyin iku o̩ga o̩lo̩paa yii mule̩ lo ja si pabo titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo̩.

‘O̩mo̩ ogún o̩dún péré ni mí, mo sè̩sè̩ ń bè̩rè̩ ayé ni’ -Peller

‘O̩mo̩ ogún o̩dún péré ni mí, mo sè̩sè̩ ń bè̩rè̩ ayé ni’ -Peller

Mary Fágbohùn

Oniforan aderinposonu Naijiria, Habeeb Hamzat, ti a mo si Peller, ti ro awon eniyan ti won n soro radarada sii lati se jeje pelu re, o ni omo kekere loun, ati pe oun si n kekoo.

Iroyin jade pe Peller di kiko oro ipegan nitori oro kubakugbe to so lori TikTok.

Ninu atejade kan to fi lede lori ikanni Instagram re, Peller ni o je ohun to se ajeji pe ki won maa pegan omode lona ti awon eniyan fi n bu enu ate lu isesi oun.

O tun so pe awon eniyan n wo asiko perepe ti oun fi siwahu ti won si ko eyin si idaraya ti oun mu wa.

“Mo se fonran bi wakati mefa, sugbon fonran ogbon iseju pelu ero rere ni won fi n nawo eebu si mi. O maa n sele loorekoore, fonran to kun fun oro odi ni won yoo yo, won a pa eyi to dara nibe ti,” o so bee.

“Omo ogun odun pere ni mi, mo sese bere aye ni, mo n gbiyanju lati pese fun emi ati ebi mi. Nigba miiran a maa dabii pe ki n jawo, ki n se nnkan ti ko bojumu.

“Mi o ribi ti won ti se si omo ogun odun bi won ti n se si mi yi ri, won n fami wale, won n kun mi si wewe… sugbon ni gbogbo igba, mo n dide.”

 

 

Ìmò̩ràn mi ni pé kí o pa o̩mo̩bìnrin náà – Kelvin Billions

Ìmò̩ràn mi ni pé kí o pa o̩mo̩bìnrin náà – Kelvin Billions

Mary Fágbohùn

Vivian Joseph, iyawo gbajumo onifonran aderinposonu Victor Nwaogu, yi fi oju okunrin kan lede, eni to fesun kan pe o so oro ti ko dara nipa omobinrin re.

Lori ikanni ibanidore Facebook re ni ojo Aje, o fi aworan okunrin kan eni ti oruko n je Kelvin Sommy Billions lede bi eni to gba a nimoran buburu.

Gege bi o se so, Kelvin so oro asoye kan nipa omo re labe atejade re kan, eyi ti opolopo awon olumulo lori ayelujara koro oju si.

“Ma a gba yin nimoran lati pa omo yii. O si kere, ki ibalokanje ma ba po fun un nigba to ba dagba tan. Imoran ni o”, Kelvin kowe.

Mrs. Nkubi fi aworan okunrin ohun lede pelu oro asote re, o sapejuwe re bi “oju apaniyan”.

Oro yi lo ti ru ibinu opo eniyan soke, ti won si ni arakunrin naa se ohun ti ko da rara.

 

Hèèmọ̀! Ọ̀dọ́bínrin kan kú sílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ l’Ọ́sun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Hèèmọ̀! Ọ̀dọ́bínrin kan kú sílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ l’Ọ́sun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà sọ pé òwò tí àdá bá mọ̀ ní-ín ká àdá léyìn.
Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti sọ fún akọ̀ròyìn pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú tó pa ọ̀dọ́bìnrin Bidemi Omole nílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ , Yinka, nílùú Ẹsa-Òkè n’ípìínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun akọroyin lalẹ ana ọjọ Aiku ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ti a wa yii.

Iṣẹlẹ naa ni a gbọ pe o ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Ẹti to kọja nigba ti Bidemi de si ile Yinka.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, ṣalaye pe ”lalẹ ọjọ Ẹti to kọja ni Bidemi de si ile ọrẹkunrin rẹ, Yinka niluu Esa-Oke.

Yinka sọ fun wa pe o fẹ rẹ Bidemi diẹ lalẹ ọjọ naa, eyi lo si jẹ ki o maa bii.

Lẹyin naa ni Yinka sọ fun awa ọlọpaa wi pe oun atawọn eeyan kan gbe Bidemi digba digba lọ sile iwosan lati du ẹmi rẹ.

Amọ, Yinka sọ pe nile iwosan ti wọn gbe ọdọbinrin naa lọ lawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe Bidemi ti jẹ Ọlọrun ni pe.”
DSP Ojelabi ko ṣai fidi rẹ mulẹ fun akọroyin pe Yinka to jẹ ọrẹkunrin Bidemi nikan ni afurasi tọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii lori iku ọdọbinrin naa.

”Ọrẹkunrin Bidemi ti wa ni ahamọ wa, a si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iku ọdọbinrin ọhun.”

Nigba ti akọ̀ròyìn beere lọwọ ọlọpaa bo ya Yinka yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ, DSP Ojelabi ni ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ ṣe iwadii wọn tan lati mọ ohun to ṣokunfa iku Bidemi ki wọn to maa sọrọ gbigbe ọrẹkunrin oloogbe naa lọ sile ẹjọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe laarọ ọjọ keji ọjọ Satide ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ yii ni wọn to mu ẹjọ naa wa sọdọ awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ ọhun.

Ohun ti a tun gbọ ni pe Bidemi n mura lati lọ fun iṣọ-oru ni ṣọọṣi kan ni lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.

DSP Ojelabi fikun ọrọ rẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣayẹwo oku ọdọbinrin lati mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ gan an.