Àgbèrè kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ – Falz 

Àgbèrè kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ – Falz

 

Mary Fágbohùn

 

Gbajugbaja olorin ati osere tiata lorilẹede Naijiria, Folarin Falana, ti gbogbo eniyan mọ si Falz, ti da ariyanjiyan sile kaakiri lori ero ayelujara lẹyin ti o sọ pe agbere kii ṣe ẹṣẹ.

 

Alaye ariyanjiyan naa ni a sọ ni ọjọ Aiku lati oju opo X rẹ (Twitter tẹlẹ), nibi ti oṣere ti fi atejade kan lede nirọrun pe: “Agbere kii ṣe ẹṣẹ.”

 

Ọrọ ìwòye naa, bo tilẹ jẹ pe o kuru, ni o yara tan kale lori ayelujara, ti awon olumulo ayelujara si n fenu sii lotun lotun. Nigba ti diẹ ninu won satileyin fun alaye naa, awọn miiran da a lẹbi gidigidi, ni titọka si ẹkọ ẹsin ati awọn ifiyesi iwa.

 

Olumulo kan, VeryJules, segbe leyin ọrọ kan ti o sọ pe, “Ko wa okiki. Awọn onimoran Kirisiteeni miran gbagbọ pe awọn eniyan meji ti won faramo kiko ipa ninu ihuwasi ni a o le e ri bii ẹlẹṣẹ. Wọn jiyan pe o jẹ ofin OT kii ṣe NT wọn tun sọ pe o jẹ ofin ti eniyan ṣe ninu ọran yii, ofin PAULU ni NT kii ṣe atọrunwa. Sá kuro lọdọ wọn oo, AGBERE je ese.

 

LucasMolade sọ pe, “Yọ orukọ Kiristeeni kuro. Kiristeeni tumọ si eni bii Kirisiti, ati pe Kirisiti kii ronu bayii.”

 

BintDija kowe, “Kii ṣe iyalenu pe o ko tii ṣe igbeyawo.”

 

Silvah101 sọ pe, “Pupọ ninu gbogbo yin jẹ alagabagebe to gboye.

 

Technnick kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ti àwọn ẹlẹ́sìn, àgbèrè sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn: ìwà àgbèrè jẹ́ ohun to ba òfin mu ní orílẹ̀-èdè wa, ẹ fi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn tó mọ̀ nípa re jare.”

 

Winifunds sọ asọye, “Gbogbo wa ni o fẹ ko je ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn o jẹ bẹ. Agbere jẹ ẹṣẹ.”