Àwọn Ọba aládé ilẹ̀ Yorùbá fọwọ́ sí ìpadàbọ̀ Tinubu

Àwọn Ọba aládé ilẹ̀ Yorùbá fọwọ́ sí ìpadàbọ̀ Tinubu

Mudasiru Alabi

Àwọn ọba aládé gúúsù ìwọ̀-oòrùn fọwọ́sọ̀yọ̀ sí ìpadabọ ẹlẹẹkejì Tinubu, wọ́n kọ̀ láti jẹ́ kí owó ìrànlọ́wọ́ epo rọ̀bì (subsidy) padà bọ̀

​Àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ ní gbogbo agbègbè gúúsù ìwọ̀-oòrùn ti fọwọ́ sí ètò ìpadàbọ̀ sí ipò Ààrẹ Bola Tinubu, wọ́n sọ pé dídúró ti agbègbè gúúsù lórí agbara jẹ́ èyí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú òdodo, dídọ́gba, àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè.

Àwọn ọba náà ṣe àgbékalẹ̀ yìí nínú ìkéde kan tí wọ́n ka lẹ́yìn ìpàdé wọn tí ó wáyé ní ààfin Olubadan ti ìlú Ìbàdàn ní Ìbàdàn, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní ọjọ́rú.

Olubadan ti ìlú Ìbàdàn, Ọba Rashidi Ladoja, pẹ̀lú Ooni ti Ifẹ̀, Ọba Enitan Ogunwusi; Deji ti Àkúrẹ́, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi; Elegushi ti Ilẹ̀-Ọba Ikate-Elegushi, Ọba Saheed Ademola, àti àwọn ọba aládé mìíràn tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ní Gúúsù-Ìwọ̀-Oòrùn, ń ṣe ìpàdé ìkọkọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ìpàdé náà, èyí tí ó wáyé ní ọjọ́rú ní Ààfin Olubadan, Ọ̀kẹ́-Arẹ̀mọ, ní Ìbílẹ̀ Ìjọba Ìbàdàn Àríwá ní ìpínlẹ̀ náà, tún ní Ẹwi ti Àdo-Èkìtì, Alake ti Ilẹ̀ Egba, Ayangburen ti Ikorodu, Aseyin ti Iseyin, Ebumawe ti Ago-Iwoye àti àwọn mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó wà níbẹ̀.

Orísun náà fi kún un pé, “Àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí a gbé kalẹ̀ fún ìjíròrò náà ní ààbò, ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé, àti àwọn ètò ìdìbò gbogboogbò ọdún 2027, ati àwọn nǹkan míràn.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here