Èròngbà pé mo fẹ́ tukọ̀ ìpínlẹ̀ Oyo kò tó nǹkan tí wọ́n ń gbẹ̀mí èèyàn sí – Oriyomi Hamzat

Èròngbà pé mo fẹ́ tukọ̀ ìpínlẹ̀ Oyo kò tó nǹkan tí wọ́n ń gbẹ̀mí èèyàn sí – Oriyomi Hamzat

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oludije sipo gomina labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat ti ke si awọn oloṣelu ki wọn ma ṣe ọrọ idibo ni bo o ba o pa, bo o ba o bu u lẹsẹ.

Oriyomi lo sọrọ naa lasiko to n fesi si ikọlu ti awọn eeyan kan ṣe si awọn alatilẹyin rẹ lẹyin to pada wale lati ilẹ Gẹẹsi.

Lasiko to n sọrọ lori ẹrọ redio rẹ Agidigbo FM pẹlu ibanujẹ lo sọ bẹẹ.

Eeyan kan lo ku lasiko ikọlu ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, erongba oun lati de ipo gomina ipinlẹ Oyo ko to nnkan ti wọn n gbẹmi eeyan si.

O ni “Ẹ sọ fun mi to ba jẹ pe ki n má díje dupo gomina mọ ní àlàáfíà yoo fi jọba nípìnlẹ̀ Oyo tí kò si ní sí ipaniyan mọ, máa jawọ.

“Gbogbo ẹni to pa Azeez to ṣe àwọn èèyàn leṣe lẹyin mi lose yìí, Ọlọrun a dajọ.

“Ẹnikẹni to bá wà nidi gbogbo ipaniyan àti rògbòdìyàn ipinlẹ Oyo, tó bá wá nínú kadara rẹ pe yoo de ipo gomina, láṣẹ Ọlọọrun kò ní de ibè mọ.”

Sọrọsọrọ ori redio naa sọ pe kii ṣe dandan ni ki oun di gomina ipinlẹ Oyo, oun yoo si jawọ ninu didu ipo naa ti awọn araalu ba sọ pe awọn ko fẹ oun.

Oriyomi sọ pe “To bá jẹ pe tí mo ba fòpin sí ìpinnu mi láti díje dupo ni wọn kò fi ní fọ igi mọ àwọn ìyáoniya lori mọ, maa fopin si.

“Ẹ rántí pé ipò ó tan o, oloṣelu a ku, ẹni tí a n dárí lè lóri ni yóò ku… Ẹ dákun nítorí Ọlọ́run, ẹ má pá àwọn èèyàn mọ.”

O tẹsiwaju pe oun kọ loun wa nipo gomina lọwọ yii, bẹẹ ni oun ko lẹnu niluu Abuja ti ọrọ naa fi le to koko to bẹẹ.

Lẹyin naa lo rawọ ẹbẹ si awọn to n fa wahala ki wọn jawọ ninu jagidijagan ti wọn n ṣe ki alaafia le jọba nipinẹ Oyo.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here