Àwọn èrò ayélujára gbéná wojú Dele Farotimi àti àwọn mìíràn nípa ìtúsílẹ́ akẹ́kòó Ogbomoso
Ọjọ́ Ẹti ọjọ kẹwaa osu keje yii ni awọn akẹkọọ ati awọn olukọ to fẹẹ to aadọta jẹ jijiko ni ilu Ogbomoso, ni ijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Ọyọ.
Ijiko awọn eniyan yii ti da orisii itabuku ba ijọba Aarẹ Tinubu.
Awọn ajinigbe ti n ji akẹkọọ ko ni oke ọya sugbọn ti isalẹ yii yatọ.
Orisiirisii oko ọrọ ni awọn ẹgbẹ alatako ti rọjo si Aarẹ.
Awọn ajinigbe pa olukọ kan loju ẹsẹ ni ile-iwe naa, wọn tun pa olukọ kan ni akata wọn nigba ti wọn de inu igbo, ọdọmọde jojolo kan naa ku si akata wọn bi o tilẹ jẹ pe wọn ni ọmọ naa ti n saarẹ ki wọn to jii gbe.
Lẹyin ọjọ kẹrindinlọgọta ni awọn eniyan yii to ri itusilẹ pẹlu ifọwọ-sowọ-pọ awọn ologun, ọlọpaa inu ati tode pẹlu awọn ẹsọ alaabo bii iru ẹkun ti Sunday Igboho.
Ju gbogbo rẹ lọ, wọn ko awọn eniyan yii wale, eyi lo mu ki awọn ẹgbẹ alatako, Dele Farotimi ati awọn miiran maa beere pe ko le rọrun lati ko awọn eniyan yii laaye, wọn ni oku ajinigbe meloo lo wa, meloo ni wọn ko laaye ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Eyi mu ki awọn ololufẹ ati alarojinlẹ miiran maa kọ lu wọn pe kin ni wọn fẹ gan-an? Wọn ni o yẹ ki inu wọn maa dun bayii ni ko yẹ ko jẹ ibanujẹ fun wọn. Wọn ni ẹkun eke ni wọn tilẹ n sun nigba ti awọn eniyan yii wa lakata ajinigbe.
Awọn ololufẹ Tinubu ni se awọn ọlọtẹ yii fẹ sun oku awọn ajinigbe jẹ ni? Oko ọrọ ati epe n lọ lorisiirisii lori ayelujara.








