FIFA World Cup 2026 : Ojú ogun le, mẹ́rin yọjú nínú akọni mẹ́jọ
FIFA World Cup 2026 ti orileede Canada, Mexico ati USA jọ se onigbọwọ rẹ ti de ibi to lapẹẹrẹ.
Oju ogun ti le bayii, awọn ti ko to gbangba sun lasiko ọyẹ ti pada sile.
Awọn akọni ko ni ju mẹjọ lọ nigba ti o ba fi maa di alẹ ọla ọjọ keje osu keje, ọdun yii. Awọn mẹrindinlogun lo n waa ko bayii, ibẹ si ni meje ti maa yọju. Ninu meje yii ni o ti maa ku mẹrin. Ninu mẹrin ni a ti maa ri awọn meji ti wọn maa se asekagba nigba ti awọn orileede meji ti wọn ba na maa figa-gbaga lati mu ipo kẹta jade. Ninu awọn mẹrindinlogun yii ,mẹjọ ti n yọju bayii, awọn bii – Canada,Brazil, Paraguay, Morocco, Norway, France, Mexico, England, Belgium, USA, Spain, Portugal, Switzerland, Egypt, Argentina ati Colombia.
Bayii, Morocco ti gbo ewuro soju Canada, France na Paraguay, Norway se ibawi fun Brazil, England na Mexico. Ni irọlẹ oni, Portugal maa wako pẹlu Spain, USA maa wako pẹlu Belgium, Argentina pẹlu Egypt ni ọla Tuside nigba ti Switzerland ati Colombia maa na tan bi owo l’ọjọ kan naa.
Awọn to gba bọọlu wọle awọn alatako wọn ju bayii ni – Lionel Messi (Argentina), Kylian Mbappe (France), ati Erling Haaland ti orileede (Norway). Awọn mẹtẹẹta ti gba bọọlu meje-meje wọle awọn alatako.
Ninu awọn mẹrindinlogun yii ni mẹjọ ti n yọju bayii, awọn to ti wẹ yan kanin-kanin ninu mẹjọ ti a n reti ni – Morocco, France, Norway, England…..









