Ẹ sàánú mi, ẹ má jẹ́ kí àìṣàn káńsà pa mí – Oluwaseun Raheem

Oluwaṣeun Raheem to ni aisan kansa fẹẹ iranlọwọ yin.

Ọrọ Yoruba kan lo sọ pe ko si nnkan to to alaafia nile aye yii, nitori naa ni a ṣe n gbadura pe ki Ọlọrun ma fi aisan bẹ wa wo.

Arabinrin kan, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Oluwaṣeun Raheem lo ti n woju ẹyin alaaanu ọmọ orileede yii fun ti aisan jẹjẹrẹ, taa mọ si kansa lati bi ọdun meloo kan sẹyin .

Iwadii fi ye wa pe lati nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin ni aisan ọhun ti n ba Oluwaṣeun finra, nibi ọyan gan an ni kansa yii ti muu, ti ko si jẹ ko gbadun ara ẹ.

Irora yii ti wa pọ lapọju to fi jẹ pe gbogbo nnkan tawọn obi ẹ ni ni wọn ti taa tan to fi jẹ pe atijẹ wọn lakooko yii inira lo n jẹ fun wọn.

Ninu ọrọ ti Oluwaṣeun ba oniroyin wa sọ nileewosan to wa lo ti rọ awọn ẹlẹyinju aanu lati ran oun lọwọ, ki wọn ma jẹ ko gba ẹmi oun lojiji

Too, ẹnikẹni ti iwọ nipa lati ṣe iranlọwọ fun oun naa ni ẹnikeji rẹ, ẹ le fi owo naa ranṣẹ si nọmba Oluwaṣeun Raheem, 2334077316 UBA. Ẹ ṣe pupọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here