FANTI carnival máa mi Eko tìtì

FANTI carnival máa mi Eko tìtì

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ọna kan ma wa ni titi fun ọjọ Aje nikan. Iroyin yii jade lati ileesẹ asa, igbafe ati iṣe ni ipinle Eko.
Ninu ikede naa ni wọn ti jẹ ko ye araalu pe awọn ọna naa ti maa wa ni titi lati aago meje aarọ titi di ọsan.
Awọn ona ti ayẹyẹ naa maa kan ni – King George titi de ile epo Mobil, Onikan Roundabout de TBS, Flagstaff House de TBS, Ita Marina titi de TBS, Opopona Campbell de old Defense building titi de Catholic Mission ni ọna ile iwosan Nicholas.
Ileesẹ naa gba awọn araalu niyanju lati gba awọn ọna ti ajọ LASTMA la kalẹ fun irọrun ni ọjọ naa. Wọn ni ki awọn to ba n bọ lati Obalende si Onikan Roundabout maa mori le Zone 2, nigba ti awọn to ba n bọ lati Bonny Camp si McEwen Bridge titi de Flagstaff House lọ TBS maa gba Bridge ti Obalende. Bẹẹ si ni awọn to n bọ lati ọwọ ita Marina si TBS naa maa gba Bridge ti Obalende bakan naa, ki alaafia le jọba lọjọ naa.
Ijọba ipinle Eko ni ki awọn eniyan jọwọ ba awọn fara daa ati pe awọn ko mọọmọ ni araalu lara. Won ni FANTI carnival naa se Pataki ki itan, asa ati ise pelu ewa ede Yoruba ma baa parun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here