Sanwo-Olu bá ẹbí, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti ìpínlẹ̀ Ọsun kẹ́dùn ikú Onigbinde

Sanwo-Olu bá ẹbí, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti ìpínlẹ̀ Ọsun kẹ́dùn ikú Onigbinde

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ti Ìpínlẹ̀ Èkó se idaro ikú olùkọ́ni ikọ agbabọọlu orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀, Adegboye Onigbinde, ẹni tó ṣe amọ̀nà Nàìjíríà sí ìdíje FIFA World Cup ti ọdún 2002 ní Japan àti South Korea.
Sanwo-Olu ṣapejuwe iku agbabọọlu ti a bi ni Modakeke, ẹni ti o ku ni ọjọ Aje ni ọmọ ọdun mejidinlaadọrun-un (88 years), gẹgẹ bi pipadanu nla fun orileede yii, paapaa si awọn ololufẹ bọọlu afẹsẹgba.
Gomina naa, ninu atejade kan ti Oludamọran pataki re lori Iroyin ati Ipolowo, Ogbeni Gboyega Akosile, fi sita ni ojo Isegun, salaye Onigbinde gẹgẹ bi ẹni ti o dari awon Green Eagles si ipari idije Africa Cup of Nations ti odun 1984, gege bi ami orile-ede kan.
Gomina naa ṣapejuwe olukọni ti o ku naa gẹgẹbi olokiki bọọlu afẹsẹgba ati olori ti o ni ipa rere ninu idagbasoke bọọlu afẹsẹgba Naijiria.
“Mo rọ awọn ẹbi rẹ, awọn ọrẹ rẹ, awọn ẹlẹgbẹ rẹ, ati awọn ololufẹ bọọlu afẹsẹgba lati gba iku rẹ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun,” ni o salaye.
Sanwo-Olu tun fi ẹdun ọkan rẹ̀ hàn fún ìdílé Onigbinde, ìjọba ipinlẹ Osun àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà lórí ikú olùkọ́ni ikọ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here