NLC àti TUC ni dandan ni ìwọ́de fún àwọn òsìsẹ́

NLC àti TUC ni dandan ni ìwọ́de fún àwọn òsìsẹ́
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Ẹgbẹ́ àjọ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà (NLC) àti Ẹgbẹ́ àjọ àwọn òṣìṣẹ́ (TUC) sọ pé àwọn yóò ṣe àpérò ìṣọ̀kan àlàáfíà ní ọjọ́ kẹta oṣù Kejì láti ṣètìlẹ́yìn fún Ìgbìmọ̀ òṣiṣẹ́ àpapọ̀ ti ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ (JUAC).
Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kéde èyí nínú àtẹ̀jáde àpapọ̀ tí Ọ̀gbẹ́ni Benson Upah, Akọ̀wé Àgbà fún NLC, àti Ọ̀gbẹ́ni Nuhu Toro, Akọ̀wé Àgbà fún TUC, fọwọ́ sí ní Abuja.
Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ náà jẹ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìyanṣẹ́lódì tí àwọn òṣìṣẹ́ Federal Capital Development Authority (FCDA) tí JUAC ń darí, ṣe lórí owó oṣù tí wọn kò san.
Àwọn òṣìṣẹ́ lábẹ́ JUAC bẹ̀rẹ̀ iyansẹlodi ranpẹ ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kin-in-ni, wọ́n sì ti àwọn ọ́fíìsì pàtàkì ti ìṣàkóso pa, títí kan ilé ìkọ̀wé FCTA àti FCDA.
Ìdádúró náà tẹ̀lé òpin ọjọ́ méje tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ọjọ́ keje oṣù kin-in-ni, tí wọ́n sì béèrè pé kí àwọn aláṣẹ FCTA yanjú àwọn ẹ̀sùn iṣẹ́ àti ìrànlọ́wọ́ tó ti pẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti sọ, ìpèjọ náà ni láti tún fi ìdúróṣinṣin gbogbo ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ múlẹ̀ pé ìpalára sí òṣìṣẹ́ kan ṣì jẹ́ ìpalára fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà.
“Ìgbésẹ̀ náà yóò fi ìránṣẹ́ tó ṣe kedere hàn pé òṣìṣẹ́ yóò tako gbogbo onírúurú ìhalẹ̀mọ́ni àti àìṣòdodo sí àwọn òṣìṣẹ́,” ni wọ́n salaye.
Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sọ pé ìjà náà tọ́, kò ṣeé dúnàádúrà, wọn yóò sì dúró títí tí a ó fi rí ìdájọ́ òdodo gbà.
Wọ́n fi kún un pé ìtìlẹ́yìn wọn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ JUAC kò yí padà rárá, wọ́n sì dúró ṣinṣin.
Wọ́n rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ JUAC láti dúró ṣinṣin, ní ìgboyà, àti láti sopọ̀ mọ́ ara wọn nínú ìgbèjà ẹ̀tọ́ wọn.
NLC àti TUC sọ pé ìpèjọpọ̀ tí wọ́n gbèrò láti ṣe ni láti fi àtakò gbogbogbò hàn sí àìṣòdodo.
Wọ́n fi kún un pé wọ́n máa darí ìgbésẹ̀ àlàáfíà náà sí Federal Capital Development Authority (FCDA), wọ́n sì ń tẹnumọ́ pé ìpèjọ náà yóò jẹ́ èyí tó bófin mu àti èyí tó ní àlàáfíà.
Wọ́n pàṣẹ fún gbogbo àwọn ẹgbẹ́ alájọṣepọ̀ àti àwọn ìgbìmọ̀ ìpínlẹ̀ láti kó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ jọ fún ìpèjọpọ̀ náà, wọ́n sì fi kún un pé ìhalẹ̀mọ́ni àti ìnilára kò ní sọ ìpinnu àwọn òṣìṣẹ́ di aláìlera.
Wọ́n tún sọ pé a kò fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹ̀tọ́ wọn rí, ṣùgbọ́n a máa ń gba wọ́n nípasẹ̀ ìjàkadì gbogbogbò.
Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà fi dá àwọn òṣìṣẹ́ ní Federal Capital Territory (FCT) lójú pé wọn kò ní fi wọ́n sílẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here