AFCON 2025 : Ìdí tí a ṣe pàdánù bọ́ọ̀lù sọ́wọ́ Morocco – Eric Chelle
Yínká Àlàbí
Olori awọn akọnimọọgba fun ikọ super Eagles, Eric Chelle ti salaye idi ti awọn to ko lọ si orileede Morocco se padanu bọọlu naa sọwọ orileede ti ife ẹyẹ naa ti n waye.
Ana ọjọ wẹside ni ikọ Atlas Lion of Morocco gbo ewuro soju super Eagles nibi idije wọmi n gbaa ti a n pe ni pẹnariti, meji pere ni super Eagles le gba wọle nigba ti Atlas Lion gba mẹ́rin wọle.
Pẹnariti waye lẹyin ti ikọ mejeeji ti pa itu meje ti ọdẹ n pa ninu igbo fun ara wọn.
Chelle ni “akitiyan awọn agbabọọlu super Eagles ko da bii ti awọn idije maraarun ti wọn kọkọ gba, ni eyi to mu wọn bori pẹlu ayo mejila nile alatako. Loootọ ni ikọ mejeeji n sọra wọn lọwọ lẹsẹ sugbọn o ja mọ iko Morocco lọwọ. Eyi ni wọn n pe ni ere bọọlu. O le ja si ibi to ba wuu”. Alaye yii ni akọnimọọgba naa se f’oniroyin ni orileede Morocco.









