Ìsẹjọba rẹ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ni ìgbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀- Iléeṣẹ́ Ààrẹ fún Obasanjo lésì

Ìsẹjọba rẹ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ni ìgbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀- Iléeṣẹ́ Ààrẹ fún Obasanjo lésì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìsọ̀rọ̀ ni ìgbèsì, Iléeṣẹ́ ààrẹ Orílẹ̀ yí ti fèsì padà fún ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan rí, Olusegun Obasanjo pé kò ní ẹ̀tọ́ láti bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣèjọba Ààrẹ Bola Tinubu lórí bí ètò ààbò ṣe mẹ́he ní Nàìjíríà.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan niluu Jos, to jẹ olu ilu ipinlẹ Plateau, Obasanjo bu ẹnu atẹlu ipo ti eto aabo wa lorilẹede Naijiria.

O ni awọn ọmọ Naijiria ni ẹtọ lati kesi oke okun pe ki wọn gba wọn nitori ijọba ti ja wọn kulẹ ni gbogbo ọna.

Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ni gbogbo ohun to jọ mọ igbesunami lorilẹede Naijiria gberasọ labẹ iṣejọba Obasanjo, ti wọn si fẹsun pe oun naa dakun rogbodiyan eto aabo to wa lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni ileeṣẹ aarẹ tun wọgile ọrọ Obasanjo to ni pe ki Aarẹ Bola Tinubu kesi ijọba oke okun fun iranlọwọ ti ko ba le gbe ogun ti iṣoro eto aabo.

“Sisọ pe ki aarẹ bẹrẹ fun iranlọwọ lati oke okun lati koju iṣoro eto aabo ki n ṣe apẹẹrẹ adari rere to nifẹ ilu lọkan.

Awọn ọrọ yii lo jẹ yọ ninu atẹjade kan ti oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ iroyin, Sunday Dare gbe sori ayelujara X.

Atẹjade naa tun sọ ọrọ pe ki Obasanjo to daba pe ki Aarẹ Tinubu ju wọle fun orilẹede oke okun, o yẹ ki Obasanjo ronu bi oun fun ara rẹ se kuna lati gbe ogun ti iwa igbesunami lasiko to wa ni ijọba.
“Ọrọ ti aarẹ nigba kan ri sọ nipa iṣejọba aarẹ Tinubu pe ko ni agbara lati da bobo awọn ọmọ Naijiria ni ko yẹ ko tẹnu Obasanjo jade, pe awọn araalu n koju ikọlu awọn agbebọn.

“Naijiria lonii ni koju ọpọ ikọlu lati ọdọ awọn agbesunami ISIS, al-Qaeda ati awọn agbebọn ti ẹnu ibode.

“Awọn agbebọn yii ni awọn ti wọn siṣẹ fun. Wọn n pin owo, ohun ija, ati awọn mii, to si jẹ erogba wọn ni lati pin orilẹede Naijiria.

“Ẹ jẹ ka pe wọn ni orukọ wọn, Agbesunami ni wọn,” ileeṣẹ aarẹ ṣalaye.

“O yẹ ka jẹ ko di mimọ pe awọn agbebọn yii gbera sọ lasiko ijọba alagbada Obasanjo. Bi wọn se n korawọnjọ, ti wọn n da ibudo silẹ, ijọba lasiko naa kọ lati gbe igbesẹ to yẹ.

“Nnkan to bẹrẹ pẹlu nnkan kekere, ni o ti di nnkan nla bayii lagbaye.

“Fun olori to jẹ pe asiko rẹ ni iwa igbesunami gberasọ, ni o ti ohun ti a n sọ kaakiri agbaye bayii.

Ileeṣẹ aarẹ tun jẹ ko di mimọ pe bi orilẹede Naijiria ṣe ṣetan lati ba orilẹede oke okun ṣiṣẹ pọ, ko ṣetan lati juwọ lẹ ominira rẹ fun orilẹede kankan.

“Naijiria yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu agbaye, bẹẹni ṣugbọn ko ni juwọlẹ fun ẹnikẹni .

“Naijiria nilo iranlọwọ ati igbọraẹniye orilẹede Amẹrika, ti ajọsepọ si n lọ lọwọ,” ileeṣẹ aarẹ fikun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here