Adeleke kéde ìṣéde òní wákàtí mẹrinlelogun ní Ìgbájọ
Yinka Alabi
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ademola Adeleke, ti kéde isede oni wákàtí merinlogun ní ìlú Igbajọ lẹ́yìn tí wahala be ṣile ní agbègbè náà. Ìṣòro náà bẹ̀rẹ̀ ní owo alẹ́ Sọ́ńdé, wa sí òwúrọ̀ Mọ́ńdé, tí ó sì ní í ṣe pẹ̀lú ìkú Omooba Adegboyega Famodun tí ó kú lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Nínú ìkéde kan tí Kọlápọ̀ Alimi to se komisona fun eto iroyin ni ipinle Osun jise gomina pé kí ìlú náà wà ní títí di àsìkò tí àlàáfíà yóò fi joba pada.
Adeleke ni ijoba oun ko ni faaye gba iwa ipinle bi o ti wu ki o mo. O tún kéde pé ẹnikẹ́ni tó bá ń kópa nínú ohun tí yóò túbọ̀ fa rogbodiyan, yóò fojú wina òfin. Ó sì ránṣẹ́ sí Ọmọ-ogun, ọlọ́pàá, DSS àti NSCDC kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ àbójútó wákàtí merinlelogun ní ilu Igbajọ.
Ó tún kilọ̀ fún gbogbo ará ìlú àti àwọn tí kò jẹ́ ará ìlú pé kí wọ́n má se koja aaye won.









