Àwọn kan tún gbìyànjú láti gbẹ̀mí ọbalayé kan l’Ondo

Àwọn kan tún gbìyànjú láti gbẹ̀mí ọbalayé kan l’Ondo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orí kó ọba ilú Igoba ní ìpínlẹ̀ Ondo, Kábíyèsí John Adinlewa, yọ lọ́wọ́ ikú òjijì lẹ́yìn táwọn jàndàkú agbébọn kan ṣe ìkọlù sí i láti gbẹ̀mí rẹ̀.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko din ni afurasi mẹwaa ti awọn ti mu lori ikọlu naa bayii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Ayanlade Olusola, ṣalaye pe awọn janduku agbebọn naa ṣadeede ya bo awujọ Igoba ni ijọba ibilẹ ariwa Akure ni bii ọjọ meloo kan sẹyin lati ṣe awọn eeyan ilu naa nibi.

DSP Olusola ṣalaye ninu atẹjade ti o fi sita pe oniruuru nnkan ija oloro bii ibọn, ọbẹ, ogun atawọn nnkan mi to lewu ni wọn ko dani lasiko ti wọn ya bo ilu naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni awọn janduku ọhun kọlu obinrin kan torukọ rẹ n jẹ Ogunoye Oluomo, o si farapa, ti wọn si to ji nnkan rẹ ko lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni lẹyin naa ni wọn morile aafin Kabiyesi Adinlewa ti ilu Igoba ti wọn si gbiyanju lati ṣeku pa a.

Ọgbẹni Olusola ni Eledua lo ba ori ade naa ṣe e ti o fi moribọ lọwọ awọn kọlọnbiti ẹda naa to fẹ pa a.

Kete ti ẹnikan pe Kọmiṣọna ọlọpaa Ondo, CP Adebowale Lawal, lori foonu wi pe awọn janduku agbebọn kan ti ya bo Igoba ni ọga ọlọpaa naa paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọ si ilu naa ni kiakia nibi ti wọn ti mu afurasi janduku agbebọn mẹwaa.
DSP Olusola ni awọn afurasi ọhun ti n jẹwọ ipa ti wọn ko ninu ikọlu ilu Igoba.

O ni gbogbo wọn ni yoo foju bale ẹjọ ti ileeṣẹ ọlọpaa ba ti pari iṣẹ iwadii wọn.

Lara awọn nnkan ti ọlọpaa gba lọwọ awọn janduku ọhun lasiko ti wọn ṣọṣẹ ni ilu Igoba ni:

Ibọn agbelẹrọ meji

Ibọn nla oloju meji kan

Oriṣiiriṣii ọta ibọn

Oniruuru ogun

Ọbẹ ati ada ati oniruuru nnkan ija oloro mii.

DSP Olusola ni obinrin to ṣeṣe nibi ikọlu naa ti n gba itọju lọwọ nile iwosan.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa si n wa awọn iyoku awọn janduku naa ti wọn salọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni wamu wamu lawọn ọlọpaa duro si ilu Igoba bayii, ati pe ko si iyọnu kankan mọ niluu naa.

Ẹwẹ, kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tun fi da awọn araalu nipinlẹ naa loju wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ nipa pipese abo to peye fun wọn ati nnkan ini wọn.

Ọga ọlọpaa wa kilọ fun gbogbo awọn janduku ni ipinlẹ Ondo wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni gba fun wọn lati ṣiṣẹ laabi wọn nipinlẹ naa.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ọdaran to ba fẹ dan ọlọpaa wo yoo jẹ iyan rẹ ni iṣu, yoo si foju wina ofin.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ti wa rọ awọn araalu lati maa ba iṣẹ wọn lọ lai foya, ki wọn si maa fi to ọlọpaa leti ti wọn ba ti kẹẹfin ẹnikẹni o fẹ ṣiṣẹ laabi.