Gbọ́ nípa ìdánwò ‘mop-up’ tí àjọ JAMB kéde fún akẹ́kọ̀ọ́ 96,838, tí yóò wáyé lọ́jọ́ Sátidé

Gbọ́ nípa ìdánwò ‘mop-up’ tí àjọ JAMB kéde fún akẹ́kọ̀ọ́ 96,838, tí yóò wáyé lọ́jọ́ Sátidé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ JAMB tó ń ṣàkóso ìdánwò àsewọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì àt’àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn ní Nàìjíríà, ti kéde ọjọ́ Àbámẹ́ta òpin ọ̀sẹ̀ yìí, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà fún síse àfikún ìdánwò UTME ọdún 2025 yìí, tí wọ́n pè ní ”mop-up exam.”

Agbẹnusọ ajọ JAMB, Fabian Benjamin, lo fidi ọrọ yii mulẹ loju opo X ajọ naa.

Ṣaaju lati oṣu Karun un to kọja ni ajọ JAMB ti sọ wi pe awọn yoo kede asiko ti idanwo yii yoo waye.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ Jamb, Benjamin, ti ṣalaye loju opo X ajọ JAMB, idanwo ”mop-up” yii jẹ afikun si idanwo UTME ti kọkọ waye loṣu Kẹrin ati atunṣe idanwo ọhun to waye loṣu Karun un to kọja.

Idanwo ”mop-up” yii wa fawọn akẹkọọ ti wọn ko lanfaani lati ṣe idanwo UTME ọdun 2025 ni igba ti idanwo naa kọkọ waye.
Ajọ JAMB tun ṣalaye pe awọn akẹkọọ ti ko lanfaani lati kopa ninu atunṣe idanwo UTME to waye lẹyin aṣiṣe to ṣẹlẹ lati ọwọ JAMB naa yoo lanfaani lati ṣe idanwo yii bakan naa.

Ajọ JAMB sọ pe akẹkọọ 96,838 ni yoo kopa ninu idanwo ọjọ Abamẹta to n bọ naa.

Ọgọsan le mẹta ọna ni idanwo ọhun yoo si ti waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Agbẹnusọ JAMB ṣalaye pe akẹkọọ 5,096 ti wọn ko ri ayẹwo orukọ wọn ṣe lori ẹrọ kọmputa lọjọ ti idanwo UTME kọkọ waye ni isọri kinni awọn ti yoo ṣe idanwo ”mop-up” yii.

Isọri keji awọn akẹkọọ ti yoo ṣe idanwo naa lawọn akẹkọọ 91,742 ti wọn ko lanfaani lati ṣe idanwo UTME to kọkọ waye ati atunṣe rẹ to tẹle e fun idi kan tabi omiran.

Ọgbẹni Benjamin to jẹ alukoro ajọ JAMB ti wa rọ awọn akẹkọọ to ba wa ni isọri mejeeji yii lati bẹrẹ si ni tẹ iwe pelebe iforukọsilẹ fun idanwo naa lori ẹrọ kọmputa.

Ibi ti idanwo naa yoo ti waye ati asiko ti yoo waye lo wa ninu iwe pelebe naa.
Ajọ JAMB ṣalaye pe ago mẹjọ aarọ ni apa kinni idanwo naa yoo bẹrẹ lọjọ Abamẹta opin ọsẹ yii.

JAMB wa rọ awọn ti idanwo wọn yoo bẹrẹ ni ago mẹjọ lati wa ni ibi ti wọn yoo ti ṣe idanwo lati bii wakati kan tabi wakati abọ si akoko ti idanwo naa yoo bẹrẹ.

Bakan naa ni ajọ JAMB tun rọ awọn akẹkọọ lati ranti mu iwe pelebe iforukọsilẹ fun idanwo naa dani ti wọn ba n bọ.
O le ni miliọnu meji akẹkọọ ti wọn forukọ silẹ fun idanwo UTME ọdun 2025 yii.

Ajọ JAMB sọ pe akẹkọọ to din diẹ ni miliọnu meji (1.9m) lo ti jokoo ṣe idanwo ọhun bayii.

Yatọ si idanwo to kọkọ waye loṣu Kẹrin ọdun yii, ajọ JAMB tun ṣe idanwo mii fun akẹkọọ to le ni 300,000 loṣu Karun un.

Eyi wa fawọn akẹkọọ ti aṣiṣe to wa lati ọwọ JAMB ṣakoba fun esi idanwo UTME wọn.

Kudiẹ-kudiẹ to ṣẹlẹ lati ọwọ ajọ JAMB naa ṣakoba fun ibi ti wọn ti n ṣe idanwo ori kọmputa naa (CBT) marundinlaadọrin nipinlẹ Eko.

Bakan naa lo tun ṣakoba fun mejilelaadọrun ibi ti idanwo CBT ọhun ti waye ni ipinlẹ Anambra, Imo, Abia, Ebonyi, ati Enugu.

Iwadii JAMB fi han wi pe aṣiṣe wa ninu esi idanwo UTME ti wọn gbe jade lẹyin ti ọpọ eeyan ke gbajare pe awọn akẹkọọ to gba maaki to kere ti pọju.

Lẹyin naa ni alakoso ajọ JAMB, Ọjọgbọn Iṣhaq Oloyede, tọrọ aforijin, o si kede pe awọn akẹkọọ tọrọ kan yoo lanfaani lati tun idanwo naa ṣe.