Ekiti Knowledge Zone: Oyebanji pín bílíọ̀nù kan ààbò náirà fún àwọn tí ìjọba gba ilẹ̀ wọn

Oyebanji

Sinkin ni inu awon eniyan kan n dun lojo Isegun to lo, nigba ti won n tewo gba iwe owo (cheque0 lowo Gomina IPinle naa, Ogbeni Abiodun Oyebanji.

Gomina naa fun awon eni oro kan ni owo naa, to je ti ‘Gba, ma binu’ lori bi ijoba se gba ile won fun agbaekale eto eko pataki ti Ekiti Knowledge Zone.

Lapapo, owo to je bilionu kan and aabo din aadota milionu (N1,450,000,000) ni ijoba fun won.

Nigba to n soro nibi eto naa to waye ni Ado Ekiti, Gomina Oyebanji mu da won eniyan loju pe ajinde ati idagbasoke eko je ohun ti ijoba oun mu ni okunkundun.