Sáà kan ṣoṣo tó jẹ́ ọdún márùn ún tàbí ọdún mẹ́fà ti tó ọmọlúàbí – Seyi Makinde
Mary Fágbohùn
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe saa kan to jẹ ọdun mẹfa lo yẹ ki awọn oloṣelu ti wọn dibo yan maa lo lori ipo dipo saa meji ọlọdun mẹrin-mẹrin.
Makinde ni ọdun mẹfa to fun olori to ba mọ ohun to n ṣe lati mu irọrun ba awọn to n dari.
Gomina ọhun ti wa pe awọn aṣofin ki wọn gbe igbesẹ lori aba naa.
O ni “Mo ti lo ọdun mẹfa lori oye bo tilẹ jẹ pe a padanu ọdun 2020 ti kii ṣe ẹbi ẹnikẹni.
“A tun padanu nnkan bii ọdun kan miran ti a fi n ṣe ipolongo ibo fun saa keji, ni bayii, awọn eniyan tun ti n ba wa sọrọ lori ohun to yẹ ki a ṣe lẹyin eyi.
“Nitori naa mo lẹ sọ pe iye igba ti a fi ṣiṣẹ ni pato ninu ọdun mẹjọ naa ko ju ọdun marun un lọ.
“Idi niyi ti mo fi ro pe o yẹ ka yọ awọn idiwọ iru eyi kuro, saa kan ṣoṣo to jẹ ọdun marun un tabi ọdun mẹfa ti to ọmọluabi lati ṣe awọn iṣẹ ti o fẹ ṣe.”
Makinde sọ ọrọ yi nigba ti awon Musulumi ṣabẹwo sii nile ijọba to wa ni Agodi, ni ilu Ibadan lẹyin adura ọdun Ileya.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọrọ ofin ni aba ọhun, o jẹ ohun to yẹ ko ṣiṣẹ fun orilẹede Naijiria ti wọn ba le gba aba naa wọle.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ootọ ọrọ ni oun sọ nipa saa ti awọn oloṣelu n lo lori oye ko si yẹ ki ẹru maa ba eniyan lati sọ otitọ nitori ohun to fẹ jẹ tabi ipo to fẹ dimu.
Gomina Oyo tun ni kii ṣe igba akọkọ ti iru ọrọ bẹẹ yoo jeyo, ohun to yẹ ki awọn aṣofin Naijiria gbe yẹwo ni.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni igbakeji Makinde, Abdulraheem Lawal, Otun Olubadan ilẹ Ibadan, Rashidi Ladoja; igbakeji gomina tẹlẹ, Taofeek Arapaja; to fi mọ awọn igbakeji gomina meji mii nigba kan ri, Hazeem Gbolarumi ati Hamid Gbadamosi.