Mi ò pẹ̀gàn Biola Bayo o -Laide Bakare
Mary Fágbohùn
Gbajugbaja oserebirin Naijiria, Laide Bakare, ti sọ pe oun ko pegan ẹlẹgbẹ oun, Biola Bayo nitori igbeyawo rẹ to fori sogi.
Iroyin jabo pe Bakare fi fonran kan ninu eyi ti a ti ri to n jo lede lori Instagram.
O fi oro akole sori atejade naa eyi ti awọn ọmọ Naijiria maa n saaba lo lori ero ayelujara lati tọka si ikuna ninu ibasepo tabi ijakule.
“Gbogbo wa ni yoo kan (Na Everybody Go Chop Breakfast). Asiko lo ma yato. E kaaaro gbogbo,” o fi akọle sori fonran naa.
Atejade yii waye laarin ikede ikọsilẹ Biola Bayo eyi ti gbogbo eniyan n gba bi eni gba igba oti lori ayelujara.
Amo sa, nigba ti o n sọrọ leyin ti gbogbo eniyan denu bo o, Bakare sẹ pe oun ko fi Biola Bayo ṣe yẹyẹ, o ni sababi lasan ni.
Nigba to n ṣalaye atilẹyin rẹ fun Biola ninu fonran tuntun ti o fi lede ni ọjọ Eti, o sọ pe, “Awọn alasọye buburu ati awọn ẹgbẹ gbaranmi d’eleru, o dabii pe nnkan n se yin.
“Ojo karun un Okudu la si wa ni California, mi o le pegan arabinrin Biola Bayo rara. Adura mi wa pẹlu rẹ. Mi o mo ohun to n sele lowolowo. Mo n ṣiṣẹ lọwọ pẹlu ayẹyẹ ikẹkọjade ọmọbinrin mi. Eniyan buburu ni awon gbaranmi d’eleru yii o.”
Oṣere Biola Bayo ni ọjọ Isegun kede ipinya pelu ọkọ re, Oluseyi.