WhatsApp ti fẹ́ máa jáwó fún oníbáàrà bíi àwọn ojú òpó ayélujára yókù

WhatsApp ti fẹ́ máa jáwó fún oníbáàrà bíi àwọn ojú òpó ayélujára yókù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé iṣẹ́ Mẹ́ta tó ni WhatsApp, Facebook àti Instagram ti kéde pé òun yóò bẹ̀rẹ̀ ìpolówó ọjà lórí WhatsApp.

Meta ni igbesẹ yii wa lati jẹ ki awọn to n ṣe fidio ta lori ayelujara, awọn olokowo atawọn ileeṣẹ lanfaani lati maa jere lori WhatsApp.

Ileeṣẹ Meta kede ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje pe isọri mẹta gboogi lawọn eeyan ti le maa ri owo lori itakun WhatsApp bayii.
Isọri akokọ ni nnkan ṣe pẹlu awọn tawọn eeyan yoo maa sanwo wo itakun wọn lori WhatsApp eyi ti wọn pe ni ”Channel Subscription.”

Isọri keji gẹgẹ bi Meta ṣe ṣalaye ni awọn itakun ti wọn n ṣe ipolowo rẹ eyi ti wọn pe ni ”Promoted Channels.”
Isọri kẹta ni ipolowo ọja lori ”Status” fawọn eeyan to n lo WhatsApp.

Gbogbo nnkan yii jẹ ọna ti WhatsApp n lo lati faaye gba ipolowo ọja lọna ti ko ni ṣakoba fun fifi ọrọ ranṣẹ lori WhatsApp.

”A ti n ro o tipẹ lati ṣe agbekalẹ ọna tawọn eeyan to n lo WhatsApp fi le maa pa owo lori itakun naa lai ṣe ipalara fun fifi ọrọ ranṣẹ.

A gbagbọ pe asiko ti to lati bẹrẹ eto naa lo jẹ ki a kede rẹ,” Ileeṣẹ Meta lo sọ bẹẹ.
Lori isọri ”Channel Dustribution,” ileeṣẹ Meta ni awọn to n lo WhatsApp yoo lanfaani lati maa sanwo loṣooṣu ki wọn le wo oriṣiiriṣii eto to ba wu wọn.

Ileeṣẹ Meta ni awọn eeyan yoo maa lanfaani lati maa gbọ iroyin to ba wu wọn to fi mọ iroyin ere idaraya.

Lori isọri ”Promoted Channels,” WhatsApp yoo maa fawọn eeyan oriṣiiriṣii ni eto ati okowo to ba wu wọn lati ṣe ipolowo rẹ.

Eyi yoo maa jẹ ki ọpọ eeyan ri ọja tabi nnkan tawọn eeyan ba n ṣe ipolowo rẹ.

Ileeṣẹ Meta ni isọri ipolowo ọja lori ”Status’ yoo fawọn eeyan lanfaani lati maa ṣe ipolowo ọja gẹgẹ bii o ṣe maa n ṣẹlẹ lori Instagram.

Bakan naa ni Meta ni eyi yoo maa jẹ ki awọn eeyan to n lo WhatsApp lanfaani lati mọ nipa ọja kan tabi omiran.

Ileeṣẹ Meta fikun ọrọ rẹ ninu atẹjade to fi sita pe awọn eeyan to n lo WhatsApp yoo tun lanfaani lati ni ibaṣepọ pẹlu awọn to ba fẹ ṣe ipolowo ọja.

Meta tun sọ pe eto abo gidi ti wa fun gbogbo eeyan to n lo WhatsApp, nitori naa, ko ni si wi pe bo ya ajoji kan yawọ oju opo ẹnikan kan.

”Nnkan diẹ lori orilẹede rẹ, ilu rẹ tabi ede rẹ ni a maa lo ti a ba fẹ ṣafihan ipolowo ọja fun ọ lori ”Status WhatsApp.

Amọ, a ko ni fun awọn to fẹ ṣe ipolowo ọja ni nọmba foonu rẹ rara,” Ileeṣẹ Meta ṣalaye.