Ó tó gẹ́, mi ò lọ mọ́ – Nasboi
Mary Fágbohùn
Onifonran alawada ati olorin, Lawal Nasiru, ti gbogbo eniyan mọ si Nasboi, ni iroyin jabo pe o ni ijamba ọkọ eyi to je ko fi opin si irin-ajo jakejado ipinle merindinlọgbọn ti orilẹ-ede yi.
Nasboi sọ pe ọkọ oun kolu ọkọ ajagbe kan to wa leba ona.
E ranti pe laipẹ yii ni olorin naa bẹrẹ irin-ajo jakejado orilẹ-ede, ti o ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ipolongo lati gba ẹsẹ orin kan lati ọdọ akọrin Davido.
Amo sa, lẹyin ijabọ ijamba ọkọ naa, Nasboi ni oju opo ayelujara re fi da awọn ololufe rẹ loju pe oun wa ni alaafia ati pe o n se itoju are oun.
Gẹgẹ bi oro inu fonran, ara re balẹ, o sọ pe oun ko da irin-ajo ohun lẹbi fun ijamba ọkọ to sele.
O ni, “Mi o ti e mo ohun to sele, erin lasan ni mo n rin. Nitori pe eyi lagbara, ki n ya fi adagba eto ro sibi ni. Iṣẹlẹ iyalẹnu gba sugbon a dupe lowo Olorun ko si eni ti o farapa. Ko si eni to sese”
Ninu ifiweranṣẹ kan lori instagram o salaye pe pe “O ṣe Ọlọrun fun emi. Wakati diẹ sẹyin !! Ko si eni to farapa, ko si eni ti nnkan ya lara. Bayii mo n ronu boya ki n fi opin sii tabi ki n tẹ siwaju”.