Kemi Olunloyo bínú sí Esabod lórí bó ṣe fi ọmọ aláàbò ara bú u

Esabod

Bola Afolabi

Oniroyin ati onimo eto ilera ti a mo si Kemi Olunloyo ti fesi ibinu le bi asoro-faa lori ero ayelujara Esther Aboderin, ti opo eniyan mo si Esabod, se fi omo alaabo ara bu u.

Ni nnkan bi ose kan seyin ni Esabod so kobakungbe oro si Kemi, eni to je okan lara awon omo Gomina Ipinle Oyo nigba kan, Dokita Victor Omololu Olunloyo.

Awon mejeeji kii ri imi ara won laatan tele.

Esabod digbo lu Kemi latari bo se n soro si Iyabo Ojo ati omo re, Priscilla, pelu gbajugbaja akorin Davido.

Esabod ni omo oun ni awon mejeeji, ti Kemi si gbodo jawo ninu titanu ba won.

Ninu fidio to ti so eyi naa lo ti fi orisiirisii esun miran kan an.

Sugbon nigba ti Kemi n fesi le e, o ni ohun ti ko mu ogbon lowo ni ki won maa fi omo alaabo ara bu obi.

O ni iro tun ni Esabod pa pe gbogbo omo oun ni ara won ko pe.

Bakan naa, o ranti awon wahala ti Esabod ti da sile tele, to si je pe ebe lo n be oun.

Kemi tun fi kun pe ohun ti Esabod so lori oro ebi oun kii se otito rara.