China ń gbèrò láti fagilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti Africa

China ń gbèrò láti fagilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti Africa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orílẹ-èdè China ti kéde pé òun ṣetán láti wọ́gilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti orílè-èdè Áfíríkà mẹ́tàléláàdọ́ta tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú orílè-èdè ọ̀hún .

Ikede yii jade nibi ipade to waye laarin China atawọn orilẹede Afirika, eyi ko si ṣẹyin bi Aarẹ Donald Trump Amẹrika ṣe kede afikun owo ori tariifu lori ọja to n wọ Amẹrika lati Afirika laipẹ yii.

China ni orilẹede ilẹ okeere to n ba Afririka dokowo julọ lagbaaye, China si ti wa ni ipo yii fun bii ọdun mẹẹdogun bayii.
Ẹwẹ, ọja ti ko din ni $170bn lawọn orilẹede Afirika ko wọ China lọdun 2023 nikan.

Atẹjade ti China atawọn orilẹede Afirika to ṣepade pọ fi sita bẹnu ẹtẹ lu bawọn orilẹede kan ṣe fẹ da ibaṣepọ to wa laarin awọn orilẹede naa ru nipa afikun owo ori tariifu.
Wọn wa ke pe orilẹede Amẹrika lati wa ojutuu si ede-ai-yede to ba waye lori idokowo lai mu wahala da ni.

Ti igbesẹ yii ba wa si imuṣẹ, yoo jẹ ara asọyepọ to waye pẹlu China lọdun to kọja lati wọgile owo ori tariifu ori ọja to n wọle lati orilẹede Afirika mẹtalelọgbọn ti wọn ko tii dagba daadaa.

Ni bayii, awọn orilẹede nla nla lati Afirika to n ba China dokowo bii Naijiria ati South Africa naa yoo jẹ anfaani yii.

Orilẹede China ko tii sọ igba ti igbesẹ yii yoo wa si imuṣẹ ni pato.
Ẹwẹ, orilẹede Eswatini nikan ni ko ni jẹ anfaani yii nitori o ri Taiwan gẹgẹ bi orilẹede olominira, eyi ti China ri gẹgẹ bi ẹkun to ya kuro.

Oriṣiiriṣii nnkan alumọni ni China n ko wọle lati Afirika lọwọ yii papaa julọ lati DR Congo ati Guinea.

Loṣu Kẹrin to kọja ni Trump kede afikun owo ori tariifu ida 50% lori ọja to n wọ Amẹrika lati Lesotho, ida 30% lori South Africa ati 14% lori ọja to n wọle lati Naijiria.

Akọwe owo orilẹede Amẹrika, Scott Bessent, sọ pe loṣu to n bọ ni Amẹrika yoo bẹrẹ si ni maa tẹle afikun owo ori tariifu yii lori ọja to n wọle.

Amọ, o fidi rẹ mulẹ pe awọn orilẹede to ba si fẹ ba Amẹrika sọrọ lori ati mu adinku ba owo tariifu naa si lanfaani lati ṣe bẹẹ.

Lọdun 2024 nikan, ọja ti ko din ni $39.5bn ni Amẹrika ko wọle lati ilẹ Afirika.

Ọpọ awọn ọja yii lawọn orilẹede Afirika ko san owo ori kankan lori wọn labẹ eto kan ti wọn pe orukọ rẹ ni AGOA eyi to tumọ si idagbasoke ilẹ Afrika ati ifunni ni anfaani.

Amọ, ko ni si nnkan to jọ bẹẹ mọ bayii lẹyin ti Trump ti kede owo tariifu ti yoo gori ọja to wọle lati Afirika.